Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣíṣèbẹ̀wò Sí Jerúsálẹ́mù Ní Ìlú Quebec

Ṣíṣèbẹ̀wò Sí Jerúsálẹ́mù Ní Ìlú Quebec

Ṣíṣèbẹ̀wò Sí Jerúsálẹ́mù Ní Ìlú Quebec

ÀWỌN olùṣèbẹ̀wò tó bá lọ sí ìlú Jerúsálẹ́mù òde òní lè máa fojú inú wo bí ìlú náà ṣe rí lásìkò tí wọ́n ń kọ Bíbélì. Àmọ́ ṣá o, ó ṣeé ṣe láti rí ìran pípẹtẹrí kan nípa ìlú ìgbàanì yìí ní ibì kan tó fi nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ ààbọ̀ kìlómítà jìnnà sí ìhà ìwọ̀ oòrùn ìlú Jerúsálẹ́mù, ìyẹn ní ìlú kékeré kan tó wà níbi Odò St. Lawrence lórílẹ̀-èdè Kánádà. Níbẹ̀, àwọn olùṣèbẹ̀wò lè rí ìran àrímáleèlọ kan nípa Jerúsálẹ́mù àti àyíká rẹ̀. Àmọ́, báwo nìyẹn ṣe lè ṣeé ṣe? Àwọn ìpínrọ̀ tó tẹ̀ lé e yóò ṣàlàyé fún wa.

Nínú ilé olóbìírípo kan ní ìlú Sainte Anne de Beaupré, ní àgbègbè Quebec, ni ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ ọnà ara ògiri tó tóbi jù lọ lágbàáyé wà, ìyẹn ni Àwòrán Jerúsálẹ́mù Tí Wọ́n Yà Sára Ògiri. Àwòrán fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ yìí jẹ́ mítà mẹ́rìnlá ní gíga, ó sì jẹ́ àádọ́fà mítà ní fífẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ohun tó wà ní ìlú Jerúsálẹ́mù ló fara hàn nínú iṣẹ́ ọnà yìí, síbẹ̀ ohun ìwúrí ni àwòrán yìí jẹ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, nítorí pé àwòrán tó dà bí ìlú náà gẹ́lẹ́ yìí lè jẹ́ kéèyàn lóye bí ìgbésí ayé ṣe rí ní ìlú Jerúsálẹ́mù lásìkò tí wọ́n ń kọ Bíbélì.

Nípa dídúró sórí pèpéle kan tó wà láàárín ilé olóbìírípo náà, àwọn olùṣèbẹ̀wò lè rí bí ìgbèríko tó yí ìlú Jerúsálẹ́mù ká ṣe rí. Bí wọ́n bá ṣe ń wo àwòrán fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ náà lọ yí ká, wọ́n á rí ìlú olókìkí náà ní kedere, àwọn ògiri gíga rẹ̀, tẹ́ńpìlì ológo rẹ̀ àtàwọn ààfin olówó iyebíye rẹ̀. Bákan náà, wọ́n tún lè rí ìran fífanimọ́ra kan tó ń ṣàfihàn àkókò tí Jésù lò gbẹ̀yìn lórí ilẹ̀ ayé. Iṣẹ́ ọnà àgbàyanu yìí lè wú àwọn òǹwòran lórí débi pé wọ́n lè máa ronú pé ibi tí àwọ́n ń wò yẹn gan-an làwọ́n wà, bí ẹni pé wọ́n wà láàárín ọ̀pọ̀ èrò tó ń rìn lọ ní òpópónà ìlú Jerúsálẹ́mù.

Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ pé àwòrán fífanimọ́ra tó ń fi ìlú Jerúsálẹ́mù hàn kedere yìí kì í ṣe ohun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yà o. Ká sòótọ́, Paul Philippoteaux, gbajúmọ̀ ayàwòrán kan láti ìlú Paris, ló ṣiṣẹ́ lórí rẹ̀ láti ọdún 1878 sí ọdún 1882. Àwọn ayàwòrán márùn-ún mìíràn—méjì láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, méjì láti ilẹ̀ Faransé àti ọ̀kan láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì—ló ràn án lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ ọnà kíkàmàmà yìí. Àmọ́ o, Bruno Piglhein, ayàwòrán ọmọ ilẹ̀ Jámánì kan, tó ti pinnu láti wá nǹkan ṣe sí bí àwọn èèyàn kò ṣe lóye bí ìgbésí ayé ojoojúmọ́ ṣe rí lásìkò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ni wọ́n sọ pé ó kọ́kọ́ dábàá yíya àwòrán náà. Lẹ́yìn tí wọ́n parí iṣẹ́ ọnà náà ní ìlú Munich, lórílẹ̀-èdè Jámánì, wọ́n ṣe àfihàn rẹ̀ fún gbogbo èèyàn láwọn olú ìlú ńláńlá tó wà nílẹ̀ Yúróòpù. Látọdún 1895 ni wọ́n ti gbé e kalẹ̀ sí ibi tí gbogbo èèyàn ti lọ ń wò ó lórílẹ̀-èdè Kánádà.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 31]

Gbogbo fọ́tò: Cyclorama de Jérusalem inc.