Ẹ Wá Gbọ́ Àsọyé fún Gbogbo Èèyàn “Àwọn Wo Ló Ń Fi Ògo fún Ọlọ́run Lónìí?”
Ẹ Wá Gbọ́ Àsọyé fún Gbogbo Èèyàn “Àwọn Wo Ló Ń Fi Ògo fún Ọlọ́run Lónìí?”
Lójú àwọn ẹlẹ́sìn, ó lè jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu pé ká tún ṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ̀rọ̀ nípa fífi ògo fún Ọlọ́run. Ṣebí Ọlọ́run ni Ẹni Gíga Jù Lọ, Ọba Aláṣẹ ayé òun ọ̀run. Báwo wá ni èèyàn lásán-làsàn ṣe lè máa fi ògo fún un? Èèyàn lè fi ògo fún un, nítorí pé Bíbélì gbà wá níyànjú láti “bẹ̀rù Ọlọ́run, kí [a] sì fi ògo fún un.” (Ìṣípayá 14:7) Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe èyí ni nípa ‘gbígbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti pípa á mọ́.’ (Lúùkù 11:28) Dájúdájú, nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti fífi ìlànà rẹ̀ sílò nínú ìgbésí ayé wa, á ṣeé ṣe fún wa láti fi ògo àti ọlá fún Jèhófà Ọlọ́run, Ẹni tó ni Bíbélì.
Àmọ́, àwọn wo ló ń fi ògo fún Ọlọ́run lọ́nà yìí? Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ń sọ pé ẹlẹ́sìn làwọn, àmọ́ ṣé kìkì nípa jíjẹ́ ẹlẹ́sìn lèèyàn fi lè fi ògo fún Ọlọ́run ni? Báwo ló ṣe lè dá wa lójú pé ọ̀nà tí à ń gbà jọ́sìn dùn mọ́ Ọlọ́run nínú, tí èyí á sì tipa bẹ́ẹ̀ fi ògo fún un? A óò dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àsọyé tó ń tani jí náà, “Àwọn Wo Ló Ń Fi Ògo fún Ọlọ́run Lónìí?” Àsọyé fún gbogbo èèyàn yìí ni a óò sọ ní àwọn àpéjọ àgbègbè àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ láti oṣù October. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún irú àpéjọ bẹ́ẹ̀ la ó ṣe jákèjádò ayé. Bí o bá fẹ́ mọ ibi tó sún mọ́ ọ jù lọ, kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ tàbí kó o kọ̀wé sí àwọn tó ṣe ìwé ìròyìn yìí. Ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ wa ti May 1, 2003, ṣètòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ibi tí a ó ti ṣe àpéjọ náà ní Nàìjíríà.