Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Jáwọ́ Nínú Ṣíṣàì Fẹ́ Ṣe Àṣìṣe Kankan?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Jáwọ́ Nínú Ṣíṣàì Fẹ́ Ṣe Àṣìṣe Kankan?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Jáwọ́ Nínú Ṣíṣàì Fẹ́ Ṣe Àṣìṣe Kankan?

“Àìfẹ́ ṣe àṣìṣe kankan ti gbà mí lọ́kàn pátápátá.”—Carly.

À ÌFẸ́ ṢE ÀṢÌṢE KANKAN—ìyẹn ríronú pé kò gbọ́dọ̀ sí àléébù rárá nínú gbogbo ohun téèyàn bá ń ṣe—jẹ́ ohun tó máa ń da ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ lọ́kàn rú.

Ìwé náà, Perfectionism—What’s Bad About Being Too Good? sọ pé: “Ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ ló wà nínú kéèyàn fẹ́ láti ṣe nǹkan lọ́nà tó dára gan-an, èyí tí kò burú, àti kéèyàn máa tiraka láti ṣe ohun tí kò ṣeé ṣe láé, èyí tó kù díẹ̀ káàtó. Àwọn tó máa ń sapá láti ṣe nǹkan lọ́nà tó dára gan-an máa ń fẹ́ kí gbogbo ohun tí wọ́n bá ń ṣe wà létòlétò kó sì kẹ́sẹ járí, àmọ́ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ tún máa ń gba àṣìṣe wọn, wọ́n sì mọ ọ̀nà tó tọ́ láti gbà wá nǹkan ṣe sí àṣìṣe náà. . . . Àmọ́ o, ìgbà gbogbo làwọn ẹlẹ́mìí-ṣe-é-kó-má-kù-síbì-kan máa ń bẹ̀rù pé àwọ́n lè lọ ṣe àṣìṣe. Àwọn ìlànà tí wọ́n máa ń gbé kalẹ̀ fún ara wọn ti máa ń ga jù.”

Ǹjẹ́ ó dà bíi pé àpèjúwe yìí bá ọ mu? Bí àwọn ìlànà tó o gbé kalẹ̀ fún ara rẹ bá ti ga ju bó ṣe yẹ lọ, o lè má lè ṣe àwọn nǹkan láṣeyọrí. Ó lè di pé kó o máà fẹ́ dáwọ́ lé ohun tuntun. Tàbí kẹ̀, o lè máa sún ṣíṣe àwọn nǹkan pàtàkì tó yẹ kó o ṣe síwájú nítorí ìbẹ̀rù pé o lè lọ ṣàṣìṣe. O tiẹ̀ lè máà fẹ́ ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí kì í bá ṣe àwọn nǹkan lọ́nà tó o fẹ́, ó sì lè tipa bẹ́ẹ̀ sọ ara rẹ di mákàn.

Bí àpèjúwe tó wà lókè yìí bá bá ọ mu lọ́nà kan tàbí òmíràn, ṣàgbéyẹ̀wò ohun tí Bíbélì sọ nínú Oníwàásù 7:16, tó kà pé: “Má di olódodo àṣelékè, tàbí kí o fi ara rẹ hàn ní ẹni tí ó gbọ́n ní àgbọ́njù. Èé ṣe tí ìwọ yóò fi fa ìsọdahoro wá bá ara rẹ?” Òótọ́ ọ̀rọ̀ ni, bí ẹnì kan bá jẹ́ ẹlẹ́mìí-ṣe-é-kó-má-kù-síbì-kan, ó lè “fa ìsọdahoro” sórí ara rẹ̀! Kódà, ìwádìí ti fi hàn pé jíjẹ́ ẹni tí kì í fẹ́ kù síbì kan ló máa ń fa àwọn ìṣòro oúnjẹ jíjẹ, irú bíi sísá fún oúnjẹ tàbí jíjẹ àjẹkì. a

Èyí lè wá mú kó o béèrè pé, ‘Báwo ni mo ṣe lè jáwọ́ nínú ṣíṣàì fẹ́ ṣe àṣìṣe kankan?’ Ká sòótọ́, yíyí ìrònú ẹni padà lórí kókó yìí kò rọrùn. Àmọ́, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, ó ṣeé ṣe. Nígbà náà, jẹ́ ká wo irú ojú tí Ọlọ́run fi wo kéèyàn máà fẹ́ ṣe àṣìṣe kankan.

Àìfẹ́ Ṣe Àṣìṣe Kankan—Ṣé Ohun Tọ́wọ́ Lè Tẹ̀ Ni?

Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kó o má ṣàṣìṣe rárá àti rárá? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ìyẹn ò ṣeé ṣe, ó sọ pé: “Kò sí olódodo kan, kò tilẹ̀ sí ẹyọ kan . . . Gbogbo ènìyàn ti yapa lọ, gbogbo wọn lápapọ̀ ti di aláìníláárí.” (Róòmù 3:10-12) Ǹjẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ yẹn kò gba ìrònú gidi? Wọ́n jẹ́ ká mọ̀ pé ẹnikẹ́ni tó bá ń gbìyànjù láti má ṣàṣìṣe rárá àti rárá wulẹ̀ ń tan ara rẹ̀ ni.

Gbé àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù yẹ̀ wò, ẹni tó dájú pé àpẹẹrẹ títayọ ló jẹ́ nípa tẹ̀mí. Síbẹ̀, kò ṣeé ṣe fún Pọ́ọ̀lù pàápàá láti sin Ọlọ́run láìṣe àṣìṣe. Ó jẹ́wọ́ pé: “Nígbà tí mo bá fẹ́ láti ṣe ohun tí ó tọ́, ohun tí ó burú a máa wà pẹ̀lú mi. Ní ti gidi, mo ní inú dídùn sí òfin Ọlọ́run ní ìbámu pẹ̀lú ẹni tí mo jẹ́ ní inú, ṣùgbọ́n mo rí òfin mìíràn nínú àwọn ẹ̀yà ara mi tí ń bá òfin èrò inú mi jagun, tí ó sì ń mú mi lọ ní òǹdè fún òfin ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wà nínú àwọn ẹ̀yà ara mi.” (Róòmù 7:21-23) Àyàfi nípa ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run nìkan ni Pọ́ọ̀lù fi lè jẹ́ Kristẹni olùṣòtítọ́.

A dúpẹ́ pé, Ọlọ́run kò fi dandan lé e bẹ́ẹ̀ ni kò retí pé kí ẹnikẹ́ni nínú wa jẹ́ ẹni pípé tí kò gbọ́dọ̀ ṣe àṣìṣe rárá. “Òun fúnra rẹ̀ mọ ẹ̀dá wa, ó rántí pé ekuru ni wá.” (Sáàmù 103:14) Àyàfi nínú ayé tuntun Ọlọ́run nìkan ni ẹ̀dá èèyàn máa tó lè di ẹni pípé lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.

Yí Èrò Rẹ Padà

Kí ìgbà yẹn tó dé, kò ní bọ́gbọ́n mu láti máa ronú pé o lè máa ṣe nǹkan lọ́nà pípé pérépéré láìkù síbì kan. Ní tòótọ́, ó yẹ kó o máa ní in lọ́kàn pé wàá máa ṣàṣiṣe látìgbàdégbà. (Róòmù 3:23) Àní, nígbà míì, a kì í tiẹ̀ mọ̀ pé a ti ṣàṣìṣe pàápàá! Sáàmù 19:12 sọ pé: “Àwọn àṣìṣe—ta ní lè fi òye mọ̀ wọ́n?” Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Matthew sọ ọ́ lọ́nà yìí pé: “O kì í ṣe ẹni pípé—kò sì sí ẹnì kankan lórí Ilẹ̀ Ayé tó jẹ́ ẹni pípé. Bó o bá ń ní in lọ́kàn pé oò gbọ́dọ̀ ṣe àṣìṣe kankan, oò ní láyọ̀ láéláé. . . . Irọ́ tó jìnnà sóòótọ́ ni kéèyàn máa ronú pé òun kò fẹ́ ṣàṣìṣe, kò tiẹ̀ ṣeé ṣe ni.”

Pẹ̀lú èrò yìí lọ́kàn rẹ, oò ṣe gbìyànjú láti yí díẹ̀ lára àwọn èrò tó o ti ní lọ́kàn tẹ́lẹ̀ padà? Bí àpẹẹrẹ, ṣé o ti fẹ́rẹ̀ẹ́ lo ara rẹ yọ́ níbi tó o ti ń gbìyànjú láti fẹ́ kó jẹ́ pé nǹkan tìẹ ló máa dára jù? Bíbélì sọ pé, “asán . . . àti lílépa ẹ̀fúùfù” ni irú wàhálà àṣekúdórógbó bẹ́ẹ̀ máa jálẹ̀ sí. (Oníwàásù 4:4) Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ péré ló máa ń di ẹni tó ṣàṣeyọrí jù lọ. Béèyàn bá tiẹ̀ wá ṣàṣeyọrí ọ̀hún pàápàá, kì í pẹ́ tí ẹlòmíràn tó mọ̀ ọ́n ṣe ju olúwarẹ̀ lọ á fi yọjú.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wá nímọ̀ràn pé: “Mo sọ fún gbogbo ẹni tí ń bẹ láàárín yín níbẹ̀ láti má ṣe ro ara rẹ̀ ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ; ṣùgbọ́n láti ronú kí ó bàa lè ní èrò inú yíyèkooro.” (Róòmù 12:3) Má tanra rẹ o! Ńṣe ni kó o yí èrò rẹ padà, kó o sì mọ àwọn ohun tí agbára rẹ gbé àti ibi tó o kù sí. Máa gbìyànjú láti ṣe nǹkan lọ́nà tó dára gan-an, àmọ́ má sọ pé oò fẹ́ ṣe àṣìṣe rárá. Gbé àwọn ohun tí wàá máa lépa kalẹ̀, àmọ́ kí wọ́n jẹ́ èyí tí ọwọ́ rẹ á lè tẹ̀.

Bí àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù rọ Tímótì láti di “aṣiṣẹ́ tí kò ní ohun kankan láti tì í lójú, tí ń fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.” (2 Tímótì 2:15) Bẹ́ẹ̀ ni, Pọ́ọ̀lù dámọ̀ràn ṣíṣe nǹkan lọ́nà tó dára gan-an, àmọ́ kò sọ pé èèyàn ní láti di ẹni pípé. Lọ́nà kan náà, gbé àwọn góńgó tó bọ́gbọ́n mu kalẹ̀ fún ara rẹ. Bóò bá sì mọ ohun tó o lè kà sí ohun tó “bọ́gbọ́n mu,” bá àwọn òbí rẹ tàbí àgbàlagbà kan tó o lè finú hàn sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.

Àwọn kan tiẹ̀ dá a lábàá pé kó o dìídì gbìyànjú láti ṣe àwọn nǹkan kan tóò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ ọ́n ṣe, irú bí ṣíṣe eré ìdárayá kan tóò tíì ṣe rí tàbí lílo ohun èlò ìkọrin kan tóò tíì lò rí. Lóòótọ́, bó o ti ń kọ́ láti ṣe ohun kan tóò ṣe rí, kò sí àní-àní pé wàá ṣe ọ̀pọ̀ àṣìṣe. Àmọ́, ìyẹn kì í ṣe ohun tí etí ò gbọ́dọ̀ gbọ́. Èyí lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rí i pé ara ẹ̀kọ́ kíkọ́ ni ṣíṣe àṣìṣe jẹ́.

Ohun yòówù tó o lè máa gbìyànjú láti ṣe ní àṣeyọrí, yálà o fẹ́ kọ àròkọ kan ní iléèwé ni o tàbí o fẹ́ mọ bí wọ́n ṣe ń fi dùrù kọ orin ni o, gbé ìmọ̀ràn mìíràn látọ̀dọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù yẹ̀ wò, ìyẹn ni pé: “Ẹ má ṣe ìmẹ́lẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ àmójútó yín.” (Róòmù 12:11) Bẹ́ẹ̀ ni, má ṣe máa pa àwọn nǹkan tó yẹ kó o ṣe tì, tàbí kó o máa sún wọn síwájú, kìkì nítorí pé ẹ̀rù ń bà ọ́ pé o lè ṣì wọ́n ṣe.

Ọ̀dọ́ kan ti sọ ọ́ dàṣà láti máa sún àwọn iṣẹ́ iléèwé tó yẹ kó ṣe síwájú, yóò sì máa ṣe àwáwí pé òun “ń ṣètò ara òun” ni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó dára kéèyàn jẹ́ ẹni tó wà létòlétò, ṣọ́ra kó o má màa lo ìyẹn bí àwáwí fún sísún àwọn ohun tó yẹ kó o ṣe síwájú. Ọ̀dọ́bìnrin yìí ti wá rí i pé “béèyàn bá ní láti mú ọ̀kan nínú yálà kó fún olùkọ́ rẹ̀ ní iṣẹ́ àṣetiléwá tí kò fi bẹ́ẹ̀ tẹ́ ẹ lọ́rùn tàbí kó má tiẹ̀ fi ọ̀kankan sílẹ̀ rárá, èyí tó dára jù ni pé kéèyàn wá ohun kan fi sílẹ̀.”

Mú Èrò Tí Kò Dára Kúrò Lọ́kàn!

Lóòótọ́, ó lè ṣòro láti fara mọ́ àwọn nǹkan téèyàn ṣe àmọ́ tí kò tíì dán mọ́rán tó. Àwọn èrò tí ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì báni ṣì lè máa gbà ọ́ lọ́kàn síbẹ̀. Kí wá lo lè ṣe? Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé, wàá ṣèpalára fún ara rẹ bó o bá ń jẹ́ kí àwọn ìrònú rẹ dá lórí àwọn èrò tó máa kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ. Nítorí náà, sa gbogbo ipá rẹ láti rí i pé oò gba àwọn èrò tí kò bójú mu nípa ara rẹ láyè nínú ọkàn rẹ. Kọ́ láti máa fi àwọn àṣìṣe rẹ rẹ́rìn-ín. Ó ṣe tán, Bíbélì sọ pé, “ìgbà rírẹ́rìn-ín” wà. (Oníwàásù 3:4) Tún rántí pé Jèhófà kò fẹ́ ọ̀rọ̀ èébú—ì báà jẹ́ ara wa la darí rẹ̀ sí.—Éfésù 4:31.

Dípò tí wàá fi máa wo ara rẹ bí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan nígbà gbogbo, máa fi ọ̀rọ̀ tó wà nínú Òwe 11:17 sílò, èyí tó sọ pé: “Ènìyàn tí ó ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ń bá ọkàn ara rẹ̀ lò lọ́nà tí ń mú èrè wá, ṣùgbọ́n ìkà ènìyàn ń mú ìtanùlẹ́gbẹ́ wá bá ẹ̀yà ara òun fúnra rẹ̀.” Nítorí náà, gbé ìbéèrè yìí yẹ̀ wò, Ǹjẹ́ fífẹ́ láti máa ṣe nǹkan láìsí àléébù rárá ti mú kó rọrùn fún ọ láti ní ọ̀rẹ́? Kò dájú. Bóyá o tiẹ̀ ti máa ń pa àwọn èèyàn tì torí pé wọn ò lè ṣe kí wọ́n má ṣe àṣìṣe. Nítorí náà, kí lo lè ṣe?

Fi àṣẹ Bíbélì yìí sílò, èyí tó sọ pé: “Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn.” (Kólósè 3:13) Bẹ́ẹ̀ ni, nípa títúbọ̀ lo òye nínú ọ̀nà tó o gbà ń bá àwọn èèyàn lò, á túbọ̀ ṣeé ṣe fún ọ láti gbádùn ìbádọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn!

O lè máa wò ó pé, ‘Kí nìdí táwọn èèyàn á fi fẹ́ máa yẹra fún mi nítorí mo jẹ́ ẹlẹ́mìí-ṣe-é-kó-má-kù-síbì-kan?’ Ó dára, ìwọ wo bó ṣe máa rí lára àwọn ẹlòmíràn bí wọ́n bá gbọ́ tóò ń sọ nípa àwọn ìlànà gígagíga tó o gbé kalẹ̀ fún ara rẹ. Ìwé náà, When Perfect Isn’t Good Enough ṣàlàyé pé: “Ṣíṣàròyé ṣáá nígbàkigbà tóò bá gba gbogbo máàkì tán nínú ìdánwò kan lè mú kí inú máa bí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tó jẹ́ pé ńṣe làwọ́n ṣì ń tiraka láti gba máàkì tó pọ̀ díẹ̀.” Nítorí náà, sapá láti má ṣe jẹ́ ẹni tí kì í rí apá ibi tó dára sí, tó jẹ́ pé tara rẹ̀ nìkan ló mọ̀. Èyí á jẹ́ kí àwọn èèyàn túbọ̀ fẹ́ láti máa rìn mọ́ ọ.

Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Carly ṣàkópọ̀ kókó yìí nípa sísọ pé: “Mo máa ń dìídì sọ fún ara mi pé ẹ̀mí-ṣe-é-kó-má-kù-síbì-kan tí mo ní gbọ́dọ̀ wábi gbà.” Ọ̀nà wo lo lè gbà ṣèyẹn? Máa ṣàṣàrò lórí irú ojú tí Ọlọ́run fi ń wo nǹkan. Bí kò bá tíì ṣeé ṣe fún ọ síbẹ̀ láti mú èrò yìí kúrò lọ́kàn rẹ, bá àwọn òbí rẹ tàbí Kristẹni kan tó dàgbà dénú nínú ìjọ rẹ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Tọ Ọlọ́run lọ nínú àdúrà kó o sì bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti yí èrò rẹ padà. Àdúrà ṣe kókó béèyàn bá fẹ́ bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀mí-ṣe-é-kó-má-kù-síbì-kan.—Sáàmù 55:22; Fílípì 4:6, 7.

Máa rántí nígbà gbogbo pé Jèhófà kò béèrè pé ká jẹ́ ẹni pípé; ohun tó ń béèrè lọ́wọ́ wa kò ju pé ká jẹ́ olùṣòtítọ́ sí òun. (1 Kọ́ríńtì 4:2) Bó o bá ń tiraka láti jẹ́ olùṣòtítọ́, wàá rí i pé wàá láyọ̀ gidi, kódà bóò tiẹ̀ jẹ́ ẹni pípé.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Ìbẹ̀rù àìfẹ́ ṣe àṣìṣe lè máà jẹ́ kó o ṣe àwọn nǹkan láṣeyọrí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

Gbígbìyànjú láti kọ́ nǹkan tuntun lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti má ṣe jẹ́ kí ṣíṣe àṣìṣe máa dùn ọ́