Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí A Ṣe Lè Wà Níwọ̀ntúnwọ̀nsì Nínú Ọ̀ràn Aṣọ Wíwọ̀

Bí A Ṣe Lè Wà Níwọ̀ntúnwọ̀nsì Nínú Ọ̀ràn Aṣọ Wíwọ̀

Bí A Ṣe Lè Wà Níwọ̀ntúnwọ̀nsì Nínú Ọ̀ràn Aṣọ Wíwọ̀

BÍBÉLÌ sọ pé Ọlọ́run “ti ṣe ohun gbogbo daradara ni ìgba tirẹ̀.” (Oníwàásù 3:11, Bíbélì Mímọ́) Ibi yòówù ká yíjú sí, a máa ń rí àwọn ohun tó lẹ́wà. A tún máa ń rí ẹwà lára ẹ̀dá èèyàn pẹ̀lú.

Iṣẹ́ àwọn aránṣọ ni láti fi aṣọ bù kún ẹwà wa. Àmọ́ ṣá o, bí àpilẹ̀kọ ìṣáájú ti fi hàn, wọ́n ti yí ohun tí ẹwà jẹ́ padà. Ọ̀jọ̀gbọ́n nípa ìfìṣemọ̀rònú, Ruth Striegel-Moore sọ pé: “Rírí àwọn obìnrin tó pẹ́lẹ́ńgẹ́ nígbà gbogbo ti mọ́ wa lára débi pé àwọn là ń kà sí ẹni tó lẹ́wà.”

Dájúdájú, kò ní bọ́gbọ́n mu ká jẹ́ kí aráyé sọ wá di dà bí mo ṣe dà nípa ohun tí wọ́n kà sí ẹwà. Nínú ìwé rẹ̀, Always in Style, Doris Pooser sọ pé, “kò sídìí fún àwọn obìnrin òde ìwòyí láti lọ máa yí ara wọn padà tàbí kí wọ́n máa fi ohun tí wọ́n jẹ́ pa mọ́ nígbàkigbà tí wọ́n bá rí àwòrán tuntun nípa ẹni tí wọ́n kà sí aláìlábùkù.” Kí nìdí tó fi yẹ ká jẹ́ kí iléeṣẹ́ ìròyìn máa pinnu irú ẹni tó yẹ ká máa fara wé fún wa? Pooser sọ pé: “Báwo ni ì bá ti dára tó ká máa fi ara wa sílẹ̀ bí Ọlọ́run ṣe dá wa dípò ká máa gbìyànjú tìpátìkúùkù láti yí ohun tá a jẹ́ padà.”

Ẹwà Tí Kì Í Ṣá

Kì í ṣe níní ìrísí tó dára nìkan ló ń jẹ́ kí ara ẹni balẹ̀ láàárín àwọn èèyàn, ká sì tún láyọ̀. Judy Sargent, tó ti ní ìṣòro àìjẹunkánú nígbà kan nítorí ìbẹ̀rù sísanra, kọ̀wé pé: “Àtinú ni ojúlówó ayọ̀ ti máa ń wá. Kò sinmi lórí bí ẹnì kan ṣe pẹ́lẹ́ńgẹ́ sí.” Bíbélì tiẹ̀ tún sọ̀rọ̀ síwájú sí i lórí kókó yìí. Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Kí ẹwà yín fi ohun tí ẹ jẹ́ ní tòótọ́ ní inú lọ́hùn-ún hàn, ẹwà tí kì í ṣá ti ẹ̀mí ìṣejẹ́jẹ́ àti ẹ̀mí tútù, èyí tó ṣeyebíye jù lọ lójú Ọlọ́run.”—1 Pétérù 3:4, Today’s English Version.

Ẹwà tí kì í ṣá tí Pétérù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ tayọ ẹwà ara ìyára nítorí pé ó máa ń wà títí lọ, ó sì níye lórí lójú Ọlọ́run. Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn, ọlọgbọ́n ọba kan sọ pé: “Òòfà ẹwà lè jẹ́ èké, ẹwà ojú sì lè jẹ́ asán; ṣùgbọ́n obìnrin tí ó bẹ̀rù Jèhófà ni ẹni tí ó gba ìyìn fún ara rẹ̀.”—Òwe 31:30.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹwà nípa tara máa ń fa àwọn èèyàn mọ́ra lónìí, ọ̀pọ̀ ṣì máa ń bọ̀wọ̀ fún ẹni tó bá ń fi àwọn ànímọ́ Kristẹni hàn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni níyànjú pé: “Ẹ . . . fi àkópọ̀ ìwà tuntun, [àti] . . . ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, àti ìpamọ́ra wọ ara yín láṣọ.”—Kólósè 3:10, 12.

Aṣọ tó lòde kì í pẹ́ lọ. Bópẹ́ bóyá, aṣọ ìgbàlódé tó wà níta máa di ohun tí aráyé ò gba tiẹ̀ mọ́. Síbẹ̀, kò sí bí àwọn èèyàn ṣe lè máa buyì fún wa tó, bí ìrísí wa bá dára àmọ́ tí ìwà wa ò dára, kò ní pẹ́ tí wọ́n á fi máa ní èrò tí kò tọ́ nípa wa. Rántí pé, “èso ti ẹ̀mí,” ìyẹn irú àwọn ànímọ́ bí ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, ìwà rere àti ìkóra-ẹni-níjàánu, kì í lọ.—Gálátíà 5:22, 23; 1 Tímótì 2:9, 10.

Ṣùgbọ́n ṣá, ìyẹn ò wá sọ pé ká kàn máa wọṣọ bá a bá ṣe rí o. Aline, láti ilẹ̀ Faransé, sọ pé kì í rọrùn láti wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì tó bá dọ̀ràn aṣọ wíwọ̀. Ó sọ pé: “Nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ọ́, n kì í fi ọ̀ràn aṣọ ṣeré rárá. Mo máa ń fẹ́ láti ra gbogbo aṣọ tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ dóde torí pé ó máa ń jẹ́ kí ara mi balẹ̀ láàárín àwọn èèyàn. Bó bá tiẹ̀ wá lọ jẹ́ aṣọ tí wọ́n lẹ orúkọ gbajúmọ̀ aránṣọ kan mọ́ lára ni, ìyẹn á ti lọ wà jù.”

Aline ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Àmọ́, nígbà tí mo wá dàgbà, mo ní láti gbọ́ bùkátà ara mi, mo sì tún bẹ̀rẹ̀ sí lo èyí tó pọ̀ jù lára àkókò mi nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. Mo wá rí i pé bí mi ò bá fẹ́ ṣe ju ara mi lọ, kì í ṣe gbogbo aṣọ tó bá dóde ni mo gbọ́dọ̀ rà. Mo bẹ̀rẹ̀ sí ra àwọn aṣọ mi lásìkò tí owó ọjà bá wálẹ̀. Mo sì rí i pé mo ṣì lè fi ìwọ̀nba owó díẹ̀ ra aṣọ tó dáa sára. Kókó tó wà níbẹ̀ ni pé, kó o máa ra aṣọ tó bá ọ mu dáadáa, èyí tó bá onírúurú ipò mu, tó o lè lò pẹ̀lú àwọn tó o ti ní sílé tẹ́lẹ̀, tí kò sì ní tètè lọ. Dípò kí n máa jẹ́ kí ohun tó lòde sún mi ra aṣọ, èmi fúnra mi ni mo wá ń pinnu ohun tó bá mi mu báyìí. Mi ò sọ pé aṣọ ò ṣe pàtàkì sí mi mọ́ o. Àmọ́, irú ẹ̀dá tí mo jẹ́ ló ṣe pàtàkì ju ìrísí mi lọ.”

Nínú ayé tó jẹ́ pé ìrísí làwọn èèyàn kà sí bàbàrà ju àwọn ànímọ́ téèyàn ní lọ yìí, ó yẹ káwọn Kristẹni máa fi ìránnilétí Bíbélì tó gba ìrònújinlẹ̀ yìí sọ́kàn, ìyẹn ni pé: “Ohun gbogbo tí ń bẹ nínú ayé—ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú àti fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími—kò pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Baba, ṣùgbọ́n ó pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ayé. Síwájú sí i, ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.”—1 Jòhánù 2:16, 17.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Àtinú ni ojúlówó ẹwà ti máa ń wá, kò sinmi lórí ohun tó o wọ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Aṣọ tó bá bá onírúurú ipò mu, tó o sì lè lò pẹ̀lú àwọn tó o ti ní sílé tẹ́lẹ̀ ni kó o máa rà