Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ewu Tó Wà Nínú Oge Àṣejù

Ewu Tó Wà Nínú Oge Àṣejù

Ewu Tó Wà Nínú Oge Àṣejù

KÒ SÍ tàbí ṣùgbọ́n pé wíwọ aṣọ tó lòde lè mú kí ìrísí rẹ túbọ̀ fani mọ́ra kí ara rẹ sì túbọ̀ balẹ̀ láàárín àwọn èèyàn. Bó o bá wọ aṣọ tó bá ọ mu dáadáa, èyí lè bo àwọn àléébù ara kan tàbí kó tiẹ̀ túbọ̀ gbé ẹwà rẹ yọ. Ó tún lè nípa lórí irú ojú táwọn ẹlòmíràn á máa fi wò ọ́.

Àmọ́ o, àwọn ohun kan wà tó kù díẹ̀ káàtó nínú kéèyàn kàn máa ra aṣọ ṣáá, èyí tá ò lè fojú pa rẹ́. Àwọn tó fẹ́ràn àtimáa ra aṣọ lè rí i pé àwọ́n di ẹni tí kò mọ̀ ju ríra aṣọ tuntun nígbà gbogbo. Ó ṣe tán, àwọn iléeṣẹ́ aṣọ kì í yé ṣe aṣọ jáde lọ́pọ̀ yanturu. Èyí ò ṣàdéédéé rí bẹ́ẹ̀ o, nítorí pé bí aṣọ bá ṣe tètè ń kógbá sílé sí ni èrè àwọn iléeṣẹ́ aṣọ ṣe ń pọ̀ sí i tó, níwọ̀n bí èyí á ti fún wọn láǹfààní láti ṣe aṣọ tuntun jáde. Gẹ́gẹ́ bí Gabrielle Chanel tó jẹ́ ránṣọránṣọ ṣe sọ, “bí aṣọ ṣe ń dé, laṣọ ń lọ.” Nípa bẹ́ẹ̀, ẹni tí kò bá kíyè sára lè máa rò pé gbogbo aṣọ tó bá ṣáà ti jáde lòún gbọ́dọ̀ ní.

Ewu mìíràn tó tún wà níbẹ̀ ni jíjẹ́ kí ìpolówó ọjà máa nípa lórí ẹni. Ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ owó dọ́là làwọn iléeṣẹ́ aṣọ ń ná láti polówó ọjà wọn, wọ́n sì sábà máa ń ṣàfihàn àwọn tó ń wọ aṣọ wọn bí ẹni tó ń gbé ìgbé ayé yọ̀tọ̀mì. Àwọn nǹkan téèyàn ń rí wọ̀nyí lè nípa lílágbára lórí ẹni. Olùkọ́ kan ní orílẹ̀-èdè Sípéènì sọ pé: “Kò sóhun tó ń ba àwọn ọ̀dọ́langba lọ́kàn jẹ́ tó kí wọ́n máà ní irú bàtà tó lòde.”

Ohun Tó Ń Jẹ́ Kí Aṣọ Ìgbàlódé Fani Mọ́ra

Àwọn ẹgbẹ́ kan wà tó máa ń wọ irú aṣọ kan pàtó láti fi dá ara wọn yà sọ́tọ̀. Aṣọ tí wọ́n ń wọ̀ lè fi hàn pé wọ́n ń ta ko àwùjọ, pé ohun tó bá wu àwọn làwọ́n lè ṣe, kódà ó lè fi hàn pé oníwà ipá ni wọ́n tàbí pé wọ́n kórìíra ẹ̀yà kan pàtó. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn aṣọ wọ̀nyí lè máà bójú mu tàbí kó burú jáì, síbẹ̀ ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé bákan náà ni gbogbo àwọn tó bá wà nínú ẹgbẹ́ náà ṣe máa ń múra. Kódà, àwọn èèyàn kan tí ò fara mọ́ èròǹgbà ẹgbẹ́ náà lè nífẹ̀ẹ́ sí wíwọ irú aṣọ bẹ́ẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn tó bá ń múra lọ́nà yìí lè jẹ́ kí àwọn èèyàn máa rò pé àwọ́n fara mọ́ èròǹgbà ẹgbẹ́ náà.

Bí aṣọ ṣe ń dé laṣọ ń lọ, òmíràn kì í tiẹ̀ lò ju oṣù díẹ̀ lọ. Ó lè jẹ́ pé gbajúgbajà olórin kan ló máa kọ́kọ́ wọ irú aṣọ bẹ́ẹ̀ tàbí àwọn tó ń dá àṣà tuntun sílẹ̀. Àmọ́ o, àwọn aṣọ kan wà tí kì í lọ. Bí àpẹẹrẹ, jíǹsì aláwọ̀ búlúù ló wọ́pọ̀ láàárín àwọn ọ̀dọ́ tó ń fi ẹ̀hónú hàn láwọn ọdún 1950 àtàwọn ọdún 1960. Àmọ́ báyìí, tọmọdé tàgbà ló ń wọ̀ ọ́, kò sì sí ìgbà tí wọn kì í wọ̀ ọ́.

Fífẹ́ Láti Ní Ara Tí Kò Lábùkù

Àwọn tó gbé oge karí lè dẹni tó ń ṣàníyàn nípa ìrísí wọn ju bó ṣe yẹ lọ. Àwọn tí wọ́n máa ń lò fún fífi ìmúra polówó sábà máa ń ga wọ́n sì máa ń pẹ́lẹ́ńgẹ́, gbogbo ìgbà la sì máa ń rí àwòrán wọn. a Ẹni tí wọ́n kà sẹ́ni tí ara rẹ̀ kò lábùkù ni wọ́n máa ń lò láti polówó gbogbo nǹkan, látorí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ títí dórí midinmíìdìn. Àjọ Tó Ń Ṣèwádìí Lórí Ohun Tó Ń Ṣẹlẹ̀ Láwùjọ nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì fojú bù ú pé, “àwòrán àwọn obìnrin òrékelẹ́wà tó jojú ní gbèsè táwọn ọ̀dọ́bìnrin òde ìwòyí ń rí lọ́jọ́ kan ju èyí táwọn ìyá wa rí ní gbogbo ìgbà tí wọ́n wà léwe lọ.”

Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn àwòrán táwọn ọ̀dọ́mọbìnrin máa ń rí yìí lè ṣàkóbá fún wọn. Bí àpẹẹrẹ, ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, àbájáde ìwádìí kan tó jáde nínú ìwé ìròyìn Newsweek fi hàn pé mẹ́sàn-án nínú mẹ́wàá àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin aláwọ̀ funfun ni bí ara wọn ṣe rí kò tẹ́ lọ́rùn. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ohun táwọn kan lára wọn ò lè ṣe láti ní ara tí wọ́n kà sí èyí tí kò lábùkù. Síbẹ̀, Àjọ Tó Ń Ṣèwádìí Lórí Ohun Tó Ń Ṣẹlẹ̀ Láwùjọ sọ pé kò tó ìdá márùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn obìnrin tó lè bá irú àwòrán tí wọ́n ń rí náà mu. Síbẹ̀, ìfẹ́ àníjù fún ara pípẹ́lẹ́ńgẹ́ ti sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀dọ́bìnrin di ẹrú. Ó ti sọ àwọn kan dẹni tó ń sá fún oúnjẹ nítorí ìbẹ̀rù sísanra, kì í sì í rọrùn láti jáwọ́ nínú àṣà yìí. b Ọmọ ilẹ̀ Sípéènì kan tó jẹ́ afìmúra polówó, Nieves Álvarez, tó ní ìṣòro àìkìí-jẹun-kánú nítorí ìbẹ̀rù sísanra, sọ pé: “Títóbi ju bí mo ṣe wà lọ bà mí lẹ́rù ju ikú lọ.”

Ká sòótọ́, oríṣiríṣi nǹkan ló lè fa ìṣòro àìkìí-jẹun-kánú tàbí jíjẹ àjẹjù. Àmọ́, Dókítà Anne Guillemot àti Michel Laxenaire sọ pé: “Fífẹ́ láti pẹ́lẹ́ńgẹ́ lọ́nàkọnà náà wà lára ohun tó ń fà á.”

Láìsí tàbí ṣùgbọ́n, bí oge ṣíṣe ṣe ní àǹfààní náà ló tún ní àwọn àléébù nínú. Ẹ̀dá èèyàn máa ń fẹ́ láti múra lọ́nà tó dára, kí wọ́n sì tún ní aṣọ tuntun. Àmọ́, àṣerégèé nínú aṣọ wíwọ̀ lè mú ká máa wọ aṣọ táá mú káwọn èèyàn máa fi ojú burúkú wò wá. Bá a bá sì wá ka ìrísí wa sí ohun tó ṣe pàtàkì jù, a lè bẹ̀rẹ̀ sí ní èrò òdì náà pé bá a ṣe rí lóde ara lohun tó ṣe pàtàkì ju irú ẹni tá a jẹ́ nínú lọ. Álvarez tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ lókè sọ pé: “Ó yẹ ká ti bẹ̀rẹ̀ sí mọ̀ pé irú ẹ̀dá tẹ́nì kan jẹ́ ló ṣe pàtàkì ju irú aṣọ tó wọ̀ sára lọ.” Àmọ́, kò dájú pé àwọn èèyàn lè tètè yí èrò wọn padà. Nígbà náà, báwo la ṣe lè wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì tó bá di ọ̀ràn aṣọ wíwọ̀?

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wọ́n sábà máa ń retí pé kí àwọn afìmúra-polówó “ga ní nǹkan bíi mítà méjì ó kéré tán, kí wọ́n rí pẹ́lẹ́ńgẹ́ gan-an, kí ètè wọn nípọn, kí ẹ̀rẹ̀kẹ́ wọn yọ sókè, kí ẹyinjú wọn tóbi, kí ẹsẹ̀ wọn gùn, kí imú wọn ṣe sosoro àmọ́ kó máà tóbi jù,” lohun tí ìwé ìròyìn Time sọ.

b Àjọ Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà Tó Ń Rí Sí Ìṣòro Àìjẹunkánú Nítorí Ìbẹ̀rù Sísanra Àtàwọn Ìṣòro Mìíràn Tó Rọ̀ Mọ́ Ọn fojú bù ú pé, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà nìkan, mílíọ̀nù mẹ́jọ èèyàn ló ní ìṣòro àìjẹunkánú nítorí ìbẹ̀rù sísanra, àìsàn náà sì máa ń pa àwọn kan lára wọn. Èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn èèyàn wọ̀nyí ni kò tíì pé ọmọ ọdún mọ́kànlélógún tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ìṣòro oúnjẹ jíjẹ.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

Ṣé Èèyàn Á Sì Wọ Irú Èyí Sọ́rùn?

Ní gbogbo ìgbà ìrúwé àti ìgbà ìwọ́wé, àwọn iléeṣẹ́ aṣọ ńláńlá ní ìlú New York, Paris àti Milan máa ń ṣàfihàn aṣọ táwọn àgbà ọ̀jẹ̀ aránṣọ rán. Yàtọ̀ sí owó gọbọi tí wọ́n máa ń dá lé àwọn aṣọ wọ̀nyí, ọ̀pọ̀ nínú wọn ni kò bọ́ sí i rárá tàbí kí wọ́n má tiẹ̀ ṣeé wọ̀. Aránṣọ kan nílẹ̀ Sípéènì, Juan Duyos sọ pé: “Kì í ṣe torí káwọn èèyàn lè wọ àwọn aṣọ àràmàǹdà tí à ń rí yẹn ni wọ́n ṣe ń rán wọn. Ohun tó mú kí wọ́n máa ṣe àfihàn àwọn aṣọ wọ̀nyẹn kì í ṣe nítorí pé wọ́n fẹ́ tà wọ́n fún àwọn èèyàn bí kò ṣe láti pe àfiyèsí sí orúkọ iléeṣẹ́ tàbí aránṣọ tó rán wọn. Bí àpẹẹrẹ, bí àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn ṣe ń kan sáárá sí ọ̀kan-kò-jọ̀kan àwọn aṣọ wọ̀nyí lè mú kí lọ́fíńdà tí orúkọ iléeṣẹ́ aránṣọ náà wà lára rẹ̀ tà wàràwàrà.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Fífẹ́ láti ní gbogbo aṣọ tó bá jáde lè kó ọ lówó lọ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Wíwọ irú àwọn aṣọ kan lè jẹ́ káwọn míì lérò pé ò ń bá irú àwọn èèyàn kan kẹ́gbẹ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Àwọn kan ti dẹni tó ń sá fún oúnjẹ nítorí ìbẹ̀rù sísanra, kì í sì í rọrùn láti jáwọ́ nínú àṣà yìí