Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Fífòòró Ẹni—Ìṣòro Tó Kárí Ayé

Fífòòró Ẹni—Ìṣòro Tó Kárí Ayé

Fífòòró Ẹni—Ìṣòro Tó Kárí Ayé

“Bó o bá wá síléèwé lọ́la pẹ́nrẹ́n, ńṣe la máa gbẹ̀mí ẹ.”—Kristen, ọmọbìnrin akẹ́kọ̀ọ́ kan nílẹ̀ Kánádà, ni ọmọbìnrin mìíràn kan tí kò mọ̀ rí fi ikú dẹ́rù bà bẹ́ẹ̀ lórí fóònù. a

“N kì í ṣe ẹni tó sábà máa ń ka nǹkan sí rárá, àmọ́ ìṣòro ọ̀hún pọ̀ débi pé mi ò fẹ́ lọ síléèwé. Ńṣe ni inú mi á dà rú, àràárọ̀ ni mo sì máa ń bì lẹ́yìn tí mo bá ti jẹun tán.”—Hiromi, ọ̀dọ́langba kan nílẹ̀ Japan, ló sọ̀rọ̀ yìí nípa ohun tí àwọn afòòró ẹni fi ojú rẹ̀ rí.

ǸJẸ́ ẹnì kan ti fòòró rẹ rí? Ó ti ṣẹlẹ̀ sí ọ̀pọ̀ lára wa nígbà kan tàbí òmíràn. Ó lè jẹ́ pé ilé ẹ̀kọ́ lèyí ti ṣẹlẹ̀ tàbí níbi iṣẹ́, ó tiẹ̀ lè jẹ́ pé inú ilé wa gan-an ló ti ṣẹlẹ̀—níbi tí irú àṣìlò agbára bẹ́ẹ̀ ti ń wáyé lọ́nà tó gàgaàrá lóde òní. Bí àpẹẹrẹ, ìròyìn kan láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì fi hàn pé, ó lé ní ìdajì àwọn àgbàlagbà tí àwọn ọkọ tàbí aya wọn tàbí ẹni tí wọ́n jọ ń gbé láìṣègbéyàwó ń nà lẹ́gba ọ̀rọ̀. Àwọn afòòró ẹni àtàwọn tí à ń fòòró lè jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin, wọ́n sì lè jẹ́ ọlọ́rọ̀ tàbí tálákà. Bákan náà, kò síbi tí irú àṣà yìí ò sí lágbàáyé.

Ohun wo gan-an ló ń jẹ́ fífòòró ẹni? A ò lè sọ pé ohun kan báyìí ni ní pàtó, ṣùgbọ́n nǹkan púpọ̀ ló wé mọ́ ọn, irú bíi yíyọni lẹ́nu tàbí fífínni níràn. Ó sábà máa ń bẹ̀rẹ̀ látorí ṣíṣe àwọn nǹkan kéékèèké títí tó fi máa di nǹkan ńlá, kì í wulẹ̀ ṣe ohun tó máa ń wáyé lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo tàbí fún àkókò kúkúrú kan lásán. Ọ̀mọ̀wé Dan Olweus tó jẹ́ afìṣemọ̀rònú, ọ̀kan lára àwọn tó kọ́kọ́ fara balẹ̀ ṣe ìwádìí nípa ìfòòró ẹni, sọ pé lára àwọn ọ̀nà téèyàn sábà máa ń gbà hu irú ìwà yìí ni mímọ̀ọ́mọ̀ fẹ́ láti tọ́ni níjà àti kí ẹni tó juni lọ máa fìyà jẹ ẹni tí kò lágbára tó o.

Kò dájú pé a lè fi ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo ṣàlàyé ohun tó ń jẹ́ fífòòró ẹni àmọ́, ẹ̀rí fi hàn pé ó jẹ́ “mímọ̀ọ́mọ̀ han ẹlòmíràn léèmọ̀ nítorí àtifi ayé sú u.” Ohun tó ń fa ìdààmú ọkàn fúnni níbẹ̀ kì í ṣe ohun tó ṣẹlẹ̀ síni nìkan, àmọ́ ìbẹ̀rù ohun tó tún ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀ síni tún wà níbẹ̀. Lára àwọn ohun tí àwọn afòòró ẹni máa ń ṣe síni ni fífini ṣẹ̀sín, ṣíṣe lámèyítọ́ ẹni ṣáá, sísọ̀rọ̀ àlùfààṣá síni, ṣíṣòfófó ẹni, àti fífipá múni láti ṣe ohun tí kò mọ́gbọ́n dání.—Wo àpótí tó wà lójú ìwé 12.

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àkókò tí Kristen, ọ̀dọ́langba tá a mẹ́nu kàn ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, lò ní ilé ẹ̀kọ́ làwọn afòòró ẹni fi hàn án léèmọ̀. Nígbà tó wà ní ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, àwọn tó ń fòòró rẹ̀ máa ń lẹ ṣingọ́ọ̀mù mọ́ irun rẹ̀, wọ́n máa ń fi bó ṣe rí bú u, wọ́n sì máa ń dẹ́rù bà á pé àwọn á na kísà sí i lára. Nígbà tó dé ilé ẹ̀kọ́ gíga, ọ̀rọ̀ náà burú sí i débi pé wọ́n máa ń fi ikú dẹ́rù bà á lórí tẹlifóònù. Ní báyìí tó ti pé ọmọ ọdún méjìdínlógún, ó kédàárò pé: “Ibi tó yẹ kéèyàn ti lọ kẹ́kọ̀ọ́ ni iléèwé jẹ́, kì í ṣe ibi tí wọ́n á ti máa fi ikú dẹ́rù bani, tí wọ́n á sì máa tini gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n.”

Ògbógi kan tó mọ̀ nípa ìṣiṣẹ́ ọpọlọ sọ pé: “Àṣà yìí kì í ṣe ohun tó dára, àmọ́ ó sábà máa ń wáyé nínú àjọṣe ẹ̀dá. Àwọn èèyàn kan fẹ́ràn àtimáa fojú bu àwọn ẹlòmíràn kù.” Bí irú ìwà yìí bá ń bá a lọ bẹ́ẹ̀, ó lè yọrí sí kí ẹni tí wọ́n ń fòòró náà gbẹ̀san nípa ṣíṣèpalára fún onítọ̀hún tàbí kó tiẹ̀ gbẹ̀mí ẹ̀ pàápàá. Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin akólòlò kan tó ń ṣiṣẹ́ ní iléeṣẹ́ ọkọ̀ akérò kan làwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ fi ń ṣẹ̀sín tí wọ́n sì ń fòòró ṣáá débi pé, nígbà tí ara rẹ̀ ò gbà á mọ́, ńṣe ló yìnbọn pa mẹ́rin lára wọn, ó sì pa ara rẹ̀ lẹ́yìn náà.

Ìṣòro Tó Kárí Ayé Ni Ìfòòró Ẹni

Káàkiri ayé ni ìfòòró ẹni ti máa ń wáyé láàárín àwọn ọmọdé tó ń lọ sí iléèwé. Ìwádìí kan tó wà nínú ìwé ìròyìn Pediatrics in Review fi hàn pé lórílẹ̀-èdè Norway, ìdá mẹ́rìnlá nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọdé ló jẹ́ afòòró ẹni tàbí ẹni tí à ń fòòró. Ní orílẹ̀-èdè Japan, ìdá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún nínú àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ló sọ pé wọ́n ń fòòró àwọn, nígbà tó jẹ́ pé nílẹ̀ Ọsirélíà àti Sípéènì, ìṣòro yìí ń wáyé láàárín ìdá mẹ́tàdínlógún nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́. Nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ògbógi kan gbéṣirò lé e pé, ó lé ní mílíọ̀nù kan àwọn ọmọdé tí ń fòòró ẹni tàbí tí àwọn mìíràn ń fòòró.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Amos Rolider tó ń ṣiṣẹ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gíga ti Emek Yizre’el fi ọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó dín mẹ́jọ akẹ́kọ̀ọ́ láti ilé ẹ̀kọ́ mọ́kànlélógún. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwé ìròyìn The Jerusalem Post sọ, ọ̀jọ̀gbọ́n náà ṣàkíyèsí pé “ìdá márùndínláàádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún wọn ló ṣàròyé pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ àwọn máa ń gbá àwọn lábàrá, wọ́n máa ń ta àwọn nípàá, wọ́n máa ń ti àwọn tàbí kí wọ́n máa yọ àwọn lẹ́nu ṣáá.”

Àṣà búburú kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń wá sójú táyé báyìí ni lílo àwọn ẹ̀rọ tó ń fi ìsọfúnni ránṣẹ́ láti fòòró ẹni—ìyẹn ni lílo tẹlifóònù alágbèéká àti kọ̀ǹpútà láti kọ ọ̀rọ̀ tí ń dẹ́rù bani ránṣẹ́. Àwọn ọ̀dọ́ tún máa ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì láti fi kọ ọ̀rọ̀ ìkórìíra nípa ẹni tí wọ́n ń fòòró, àní wọ́n tún máa ń kọ àwọn ọ̀rọ̀ àṣírí onítọ̀hún síbẹ̀. Ọ̀mọ̀wé Wendy Craig tó ń ṣiṣẹ́ ní Queen’s University, ní orílẹ̀-èdè Kánádà sọ pé, fífòòró ẹni lọ́nà yìí “máa ń ṣe ìpalára tí kì í ṣe kékeré fún ọmọ tí wọ́n ń ṣe é sí.”

Níbi Iṣẹ́

Fífòòró ẹni níbi iṣẹ́ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn sábà máa ń ṣàròyé nípa rẹ̀ pé ó ń fa ìwà ipá tó ń ṣẹlẹ̀ níbi iṣẹ́. Àní, àwọn orílẹ̀-èdè kan ròyìn pé, àṣà yìí wọ́pọ̀ ju ìṣòro kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà tàbí fífi ọ̀ranyàn báni tage lọ. Lọ́dọọdún, òṣìṣẹ́ kan nínú márùn-ún ni wọ́n ń fòòró níbi iṣẹ́ ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

Nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ìròyìn kan tí Ẹ̀ka Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì àti Ìmọ̀ Iṣẹ́ Ẹ̀rọ ní Yunifásítì Manchester gbé jáde lọ́dún 2000 sọ pé nínú àwọn ẹgbẹ̀rún márùn-ún ó lé ọ̀ọ́dúnrún [5,300] òṣìṣẹ́ tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ ní iléeṣẹ́ àádọ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdajì lára wọn tó sọ pé àwọn ti rí i tí wọ́n ń fòòró àwọn èèyàn láàárín ọdún márùn-ún sẹ́yìn. Ìwádìí kan tí Àjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù ṣe lọ́dún 1996, èyí tí wọ́n gbé ka ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tí wọ́n ṣe pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógún ó dín igba [15,800] èèyàn láti orílẹ̀-èdè mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, fi hàn pé ìdá mẹ́jọ nínú ọgọ́rùn-ún wọn—ìyẹn nǹkan bíi mílíọ̀nù méjìlá òṣìṣẹ́—ni àwọn kan yọ lẹ́nu tàbí tí wọ́n fòòró níbi iṣẹ́.

Yálà inú ọgbà ilé ẹ̀kọ́ ni ìfòòró ẹni ti ń wáyé tàbí níbi iṣẹ́, ohun kan náà ni gbogbo ìfòòró ẹni dá lé—ìyẹn ni lílo agbára láti pa ẹlòmíràn lára tàbí láti kàn án lábùkù. Àmọ́ o, kí nìdí táwọn èèyàn kan fi máa ń fòòró àwọn ẹlòmíràn? Àwọn nǹkan wo ni ìwà yìí máa ń yọrí sí? Kí la sì lè ṣe nípa rẹ̀?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 12]

Onírúurú Ọ̀nà Tí Ìfòòró-Ẹni Pín Sí

Àwọn Tí Ń Tọ́ni Níjà: Àwọn wọ̀nyí ló rọrùn jù lọ láti dá mọ̀. Wọ́n máa ń fi ìbínú wọn hàn nípa gbígbá ẹni tí wọ́n dájú sọ, títì í gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n, gbígbá a nípàá—tàbí bíba nǹkan rẹ̀ jẹ́.

Àwọn Tí Ń Fi Ọ̀rọ̀ Fòòró: Wọ́n máa ń sọ ọ̀rọ̀ tó máa dunni wọra, wọ́n sì máa ń pẹ̀gàn ẹni tí wọ́n bá ń fòòró, yálà nípa pípè é ní orúkọkórúkọ, sísọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ sí i tàbí nípa sísọ ọ̀rọ̀ tó máa mú inú bí i ṣáá.

Àwọn Tí Ń Bani Jẹ́ Lójú Àwọn Ẹlòmíràn: Wọ́n máa ń fi ọ̀rọ̀ èké ba àwọn tí wọ́n ń fòòró lórúkọ jẹ́. Àwọn obìnrin tó máa ń fòòró ẹni ló sábà máa ń hu irú ìwà yìí jù.

Àwọn Tí Ń Fi Ìkanra Mọ́ Àwọn Ẹlòmíràn: Àwọn wọ̀nyí làwọn tí à ń fòòró, tí wọ́n wá ń padà fòòró àwọn ẹlòmíràn. Lóòótọ́, fífòòró tí wọ́n fòòró wọn kò dá irú ìwà tí wọ́n ń hù náà láre; ńṣe ló wulẹ̀ jẹ́ kéèyàn mọ ohun tó sọ wọ́n di afòòró ẹni.

[Credit Line]

Ibi tí a ti mú ìsọfúnni yìí: Ìwé Take Action Against Bullying, látọwọ́ Gesele Lajoie, Alyson McLellan àti Cindi Seddon