Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Fífòòró Ẹni—Díẹ̀ Lára Ohun Tó Ń Fà Á Àtàwọn Ohun Tó Ń Yọrí Sí

Fífòòró Ẹni—Díẹ̀ Lára Ohun Tó Ń Fà Á Àtàwọn Ohun Tó Ń Yọrí Sí

Fífòòró Ẹni—Díẹ̀ Lára Ohun Tó Ń Fà Á Àtàwọn Ohun Tó Ń Yọrí Sí

KÍ LÓ lè mú kí ọmọ kan máa fòòró àwọn ẹlòmíràn? Bí ẹnì kan bá ti fòòró rẹ rí, o lè sọ pé, “Kí ni ì báà sọ pé ó ṣẹlẹ̀ ná! Mi ò rídìí tó fi yẹ kó hùwà lọ́nà bẹ́ẹ̀.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bí ọ̀rọ̀ ṣe máa rí lára rẹ nìyẹn lóòótọ́. Àmọ́ o, ìyàtọ̀ ńlá wà láàárín ìdí tí ọmọ kan fi lè di afòòró ẹni àti àwáwí tó lè máa ṣe láti dá irú ìwà bẹ́ẹ̀ láre. Ohun yòówù kó fà á tí ọmọ kan fi di ẹni tí ń fòòró ẹni kò ìwà àìtọ́ tó ń hù náà láre, ó wulẹ̀ lè jẹ́ ká lóye ìdí tó fi ń hùwà bẹ́ẹ̀ ni. Níní irú òye bẹ́ẹ̀ sì lè ṣàǹfààní gidigidi. Báwo nìyẹn ṣe lè rí bẹ́ẹ̀?

Òwe àtijọ́ kan sọ pé: “Ìjìnlẹ̀ òye tí ènìyàn ní máa ń dẹwọ́ ìbínú rẹ̀ dájúdájú.” (Òwe 19:11) Inú tó ń bí wa sí ìwà tí afòòró ẹni náà ń hù lè jẹ́ ká máa fojú tí kò tọ́ wò ó, kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ sú wa tàbí ká tiẹ̀ kórìíra rẹ̀ pàápàá. Àmọ́, lílóye ìwà tó ń hù dáadáa lè mú kí ìbínú wa rọlẹ̀. Ìyẹn, ẹ̀wẹ̀, lè jẹ́ ká túbọ̀ mọ bá a ṣe lè yanjú ìṣòro náà. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára àwọn ohun tó máa ń fa ìwà tí kò bójú mu yìí.

Kí Ló Ń Mú Káwọn Kan Máa Fòòró Àwọn Ẹlòmíràn?

Lọ́pọ̀ ìgbà, ìkùnà àwọn òbí láti fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ tàbí bí wọ́n ṣe mọ̀ọ́mọ̀ pa àwọn ọmọ wọn tì nígbà tí wọ́n wà ní kékeré lè nípa lórí àwọn ọmọ náà. Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ tó di afòòró ẹni ló jẹ́ pé àwọn òbí wọn kò bìkítà nípa wọn, wọn kì í sì í dá sí ọ̀rọ̀ wọn. Ó sì lè jẹ́ pé ìwà tí àwọn òbí wọn ń hù ló mú kí irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ máa ronú pé ìbínú fùfù àti ìwà ipá ló yẹ kéèyàn máa fi yanjú ìṣòro. Àwọn ọmọ tí wọ́n tọ́ nírú ilé bẹ́ẹ̀ lè ṣàì ka bíbú ẹlòmíràn tàbí títọ́ ẹlòmíràn níjà sí fífòòró ẹni; wọ́n tiẹ̀ lè máa rò pé kò sóhun tó burú nínú ìwà tí àwọn ń hù, ó sì bójú mu.

Ọmọbìnrin ẹni ọdún mẹ́rìndínlógún kan tí ọkọ ìyá rẹ̀ máa ń fòòró nílé, tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ sì tún máa ń fòòró ní iléèwé, sọ pé òun náà di afòòró ẹni nígbà tó dé ìpele ẹ̀kọ́ keje. Ó sọ pé: “Ńṣe ni inú kàn máa ń bí mi ṣáá, tí màá sì máa fòòró ẹnikẹ́ni tí mo bá rí, láìka irú ẹni tó lè jẹ́ sí. Ohun tí wọ́n ń fojú èèyàn rí kò rọrùn rárá o. Bí wọ́n bá sì ti ń fòòró èèyàn báyìí ńṣe lòun náà á fẹ́ fi ìkanra mọ́ àwọn ẹlòmíràn.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn obìnrin kì í sábà hùwà ipá tí wọ́n bá ń fòòró àwọn ẹlòmíràn, wọ́n máa ń fi ìbínú wọn hàn lọ́nà mìíràn. a

Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ tó wà ní ilé ẹ̀kọ́ ni ọ̀nà tí wọ́n gbà tọ́ wọn dàgbà àti ilé tí wọ́n ti jáde wa yàtọ̀ síra gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ. Ó ṣeni láàánú pé, ìdí tí àwọn ọmọdé kan ò fi mọ̀ ju ìjà lọ ni pé wọ́n ti kọ́ wọn nílé pé, dídún kookò mọ́ àwọn ẹlòmíràn àti sísọ òkò èébú sí wọn ni ọ̀nà tó yá jù lọ láti mú àwọn èèyàn ṣe ohun tí wọ́n bá fẹ́.

Ó dunni pé, bí wọ́n ṣe máa ń fẹ́ kó rí bẹ́ẹ̀ náà ló máa ń rí. Shelley Hymel, igbákejì gíwá ẹ̀ka ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ní Yunifásítì British Columbia, ní orílẹ̀-èdè Kánádà, ti ń ṣèwádìí lórí ìhùwàsí àwọn ọmọdé fún ogún ọdún. Ó sọ pé: “Àwọn ọmọ kan wà tí wọ́n máa ń wá ọ̀nà tí wọ́n lè gbà mú àwọn ẹlòmíràn ṣe ohun tí wọ́n bá fẹ́, àmọ́ ó ṣeni láàánú pé, ńṣe ni wọ́n máa ń fòòró àwọn ẹlòmíràn. Ọwọ́ wọn sì máa ń tẹ ohun tí wọ́n fẹ́, ìyẹn ni agbára, ipò àti àfiyèsí.”

Ohun mìíràn tó máa ń jẹ́ kí ìfòòró ẹni wọ àwọn kan lẹ́wù ni pé wọn ò ní alábàáwí. Ọ̀pọ̀ àwọn tí à ń fòòró ló máa ń ronú pé àwọn ò ní olùgbèjà—ohun tó sì wá burú nínú ọ̀ràn náà ni pé, lọ́pọ̀ ìgbà lóòótọ́, kì í sí ẹnikẹ́ni tí wọ́n lè lọ ké gbàjarè bá. Debra Pepler, olùdarí Ibùdó Ìṣèwádìí LaMarsh Tó Ń Rí sí Ọ̀ràn Ìwà Ipá àti Píparí Aáwọ̀ ní Yunifásítì York, èyí tó wà nílùú Toronto, ní orílẹ̀-èdè Kánádà, ṣe ìwádìí nípa àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nínú ọgbà ilé ẹ̀kọ́ kan, ó sì kíyè sí i pé kìkì ìwọ̀nba kéréje lára ìfòòró ẹni tó ń wáyé làwọn olùkọ́ ń rí tí wọ́n sì ń ṣe nǹkan nípa rẹ̀.

Síbẹ̀, Ọ̀mọ̀wé Pepler gbà gbọ́ pé dídá sí ọ̀ràn náà ṣe pàtàkì. Ó sọ pé: “Àwọn ọmọdé kò lè yanjú ìṣòro náà torí pé ọ̀ràn nípa fífi agbára rẹ́ni jẹ ni, gbogbo ìgbà tí ẹni tí ń fòòró ẹni bá sì ti dún kookò mọ́ ẹnì kan ni agbára rẹ̀ ń pọ̀ sí i.”

Nígbà náà, kí nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn kì í fi í sọ nípa bí wọ́n ṣe ń fòòró wọn? Ìdí ni pé, ó dá àwọn tí à ń fòòró lójú pé bí àwọn bá fi ẹjọ́ ẹni tó ń fòòró àwọn sùn pẹ́nrẹ́n, ńṣe ni ìṣòro náà máa pọ̀ sí i. Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn èwe ló jẹ́ pé, dé ìwọ̀n àyè kan, inú fu àyà fu ni wọ́n fi máa ń lo àwọn ọdún wọn ní ilé ẹ̀kọ́. Kí làwọn ohun tí gbígbé ayé nírú ọ̀nà bẹ́ẹ̀ lè yọrí sí?

Ipa Tó Ń Ní Lórí Ìlera àti Ìmí Ẹ̀dùn

Ìròyìn kan tó wá látọ̀dọ̀ Ẹgbẹ́ Àwọn Afìṣemọ̀rònú ní Ilé Ẹ̀kọ́ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé lójoojúmọ́, ó lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́jọ [160,000] ọmọdé tó ń pa iléèwé jẹ nítorí ìbẹ̀rù pé wọ́n á fòòró àwọn. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí à ń fòòró kì í fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ilé ẹ̀kọ́ rárá, wọ́n sì lè máà fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ nípa àwùjọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan tàbí ìgbòkègbodò ilé ẹ̀kọ́ kan ní pàtó sétí. Wọ́n lè máa mọ̀ọ́mọ̀ pẹ́ dé ilé ẹ̀kọ́ lójoojúmọ́ tàbí kí wọ́n máa pa kíláàsì jẹ tàbí kí wọ́n tiẹ̀ máa ṣàwáwí kí wọ́n má bàa lọ sí ilé ẹ̀kọ́ rárá.

Kí la lè fi dá àwọn ọmọdé tí wọ́n ń fòòró mọ̀? Irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ lè máa kanra, kí ojú wọn kọ́rẹ́ lọ́wọ́, tàbí kó dà bíi pé ayé sú wọn, wọ́n sì fẹ́ dá wà ní àwọn nìkan. Wọ́n lè di ẹni tí yóò máa kanra mọ́ àwọn aráalé wọn tàbí àwọn ojúgbà wọn àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn. Àwọn tí ò tiẹ̀ mọwọ́ mẹsẹ̀ pàápàá máa ń fara gbá lára ohun tó jẹ́ àbájáde fífòòró ẹni. Ohun tí wọ́n ń rí lè gbin ìbẹ̀rù púpọ̀ sí wọn lọ́kàn, èyí kò sì ní jẹ́ kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ bó ṣe yẹ.

Àmọ́ ṣá o, ìwé ìròyìn Pediatrics in Review sọ pé: “Ìwà ipá ni ohun tó burú jù lọ tí fífòòró ẹni lè yọrí sí fún àwọn tí à ń fòòró àtàwọn èèyàn láwùjọ. Kódà, ó tún lè yọrí sí pípa ara ẹni tàbí pípa ẹlòmíràn. Nítorí pé àwọn ọmọdé tí wọ́n ń fòòró yìí kò lè dá gbèjà ara wọn, ìṣòro náà máa ń ni àwọn kan lára débi pé wọ́n á ṣe ara wọn léṣe tàbí kí wọ́n gbẹ̀san lọ́nà tó lè pa afòòró ẹni náà lára tàbí tó lè ṣekú pa á pàápàá.”

Ọ̀mọ̀wé Ed Adlaf, onímọ̀ ìjìnlẹ̀ tó ń ṣèwádìí, tó sì tún jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nípa ìmọ̀ ìlera ní Yunifásítì Toronto, fi bí ọ̀ràn náà ṣe ká a lára tó hàn nípa sísọ pé “ó ṣeé ṣe kí àwọn tí wọ́n ń fòòró ẹni àtàwọn tí à ń fòòró ní ìdààmú ọkàn àti àìsí ìbàlẹ̀ ọkàn nísinsìnyí àti lọ́jọ́ iwájú.” Ní sáà ilé ẹ̀kọ́ ti ọdún 2001, ó lé ní ọ̀kẹ́ mọ́kànlá àti ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [225,000] akẹ́kọ̀ọ́ ní àgbègbè Ontario nílẹ̀ Kánádà tí àwọn olùṣèwádìí fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò, nǹkan bí ìdajì lára wọn ló ti nírìírí ìfòòró ẹni lọ́nà kan tàbí òmíràn, yálà àwọn kan ń fòòró wọn tàbí àwọn ni wọ́n ń fòòró àwọn ẹlòmíràn. Nínú àwùjọ yìí kan náà, ẹyọ kan nínú mẹ́wàá wọn ló ti gbèrò láti fọwọ́ ara wọn pa ara wọn.

Fífòòró ẹni lemọ́lemọ́ lè sọni di ẹni tí a kó láyà jẹ, ó lè dá àìsàn ńlá síni lára, kódà ó tún lè ṣàkóbá fún ohunkóhun téèyàn bá dáwọ́ lé. Àwọn tí à ń fòòró lè máa ní ìṣòro bí ẹ̀fọ́rí, àìróorunsùn, àníyàn àti ìdààmú ọkàn. Àwọn kan máa ń ní ìpayà nítorí àwọn nǹkan bíbanilẹ́rù tí wọ́n ti nírìírí rẹ̀. Bí wọ́n bá fìyà jẹ ẹnì kan, àwọn tó rí i lè bá a kẹ́dùn, àmọ́ kì í rí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ẹni tó ń jìyà ní ti ìmí ẹ̀dùn. Ìpalára tí wọ́n ń ṣe fún onítọ̀hún kì í hàn síta rárá. Nípa bẹ́ẹ̀, dípò kí àwọn ọ̀rẹ́ àti ìdílé onítọ̀hún máa bá a kẹ́dùn, àròyé tó ń ṣe nígbà gbogbo lè sú wọn.

Ìfòòró ẹni tún máa ń nípa búburú lórí àwọn afòòró ẹni náà fúnra wọn. Bí wọn ò bá kápá ìwàkiwà yìí nígbà èwe, àfàìmọ̀ ni wọn ò ní di ẹni tí yóò máa fòòró àwọn ẹlòmíràn níbi iṣẹ́. Àní, àwọn ìwádìí kan fi hàn pé àwọn tó jẹ́ afòòró ẹni nígbà ọmọdé máa ń hu àwọn ìwà kan tó lè bá wọn dàgbà. Wọ́n sì lè di ẹni tí àwọn agbófinró á máa wá kiri nítorí ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn ní ìfiwéra pẹ̀lú àwọn tí kì í ṣe afòòró ẹni.

Ipa Tó Ń Ní Lórí Ìdílé

Ìfòòró ẹni níbi iṣẹ́ lè nípa lórí àlàáfíà àti ìrẹ́pọ̀ ìdílé. Ó lè sún ẹni tí wọ́n dájú sọ náà láti máa fi ìkanra mọ́ àwọn aráalé láìnídìí. Síwájú sí i, ó lè sún ọkọ tàbí aya onítọ̀hún tàbí ẹnì kan nínú ìdílé rẹ̀ láti máa jìjà ẹ̀bi pẹ̀lú afòòró ẹni náà, níbi tó ti ń gbèjà aráalé rẹ̀. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ọkọ tàbí aya kan lè máa dá ẹnì kejì rẹ̀ tí wọ́n ń fòòró lẹ́bi pé òun ló fa ìṣòro náà. Bí irú àwọn ọ̀ràn ìfòòró ẹni bẹ́ẹ̀ bá ń bá a lọ láìsí ojútùú èyíkéyìí, àní ọ̀rọ̀ náà lè sú ọkọ tàbí aya onítọ̀hún tó ti ń gbèjà rẹ̀ tẹ́lẹ̀. Bí ọdún ti ń gorí ọdún, àfàìmọ̀ ni ìdílé náà kò ní tú ká.

Nínú àwọn ọ̀ràn kan, ìfòòró ẹni lè mú kí iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ èèyàn tàbí kí ọ̀nà àtijẹ àtimu dí, ó lè fa kí ọkọ àti aya pínyà tàbí kí wọ́n kọ ara wọn sílẹ̀, kódà ó lè mú kí ẹni tí wọ́n ń fòòró pa ara rẹ̀. Ó lé ní ìdajì àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n ń fòòró níbi iṣẹ́ ní orílẹ̀-èdè Ọsirélíà tó sọ pé, ìṣòro náà ń nípa lórí àjọṣe àwọn pẹ̀lú àwọn ìbátan tímọ́tímọ́, irú bí àwọn ẹni tí wọ́n ń bá gbé láìṣègbéyàwó, àwọn ọkọ tàbí aya wọn, tàbí ìdílé wọn.

Ìpalára Tí Ìfòòró Ẹni Ń Ṣe Kò Kéré Rárá

Ìfòòró ẹni níbi iṣẹ́ tún lè ná àwọn agbanisíṣẹ́ ní owó gọbọi. Ẹni tó ń fòòró ẹni níbi iṣẹ́ lè jẹ́ ọ̀gá ẹlẹ́ẹ̀kẹ́ èébú tàbí òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ ẹni kan tó ń gbèrò ibi síni, ó sì lè jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè máa jẹ gàba lé àwọn ẹlòmíràn lórí, kó máa wá fìn-ín ìdí kókò, kó sì máa bẹnu àtẹ́ lù wọ́n nípa sísọ̀rọ̀ àlùfààṣá sí wọn àti ṣíṣe lámèyítọ́ wọn ṣáá. Wọ́n tún sábà máa ń kan ẹni tí wọ́n dájú sọ lábùkù níṣojú àwọn ẹlòmíràn. Àwọn afòòró ẹni kì í fẹ́ gbà pé àwọn kì í ṣe ọmọlúwàbí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í tọrọ àforíjì nítorí àìmọ̀wàáhù wọn. Wọ́n sábà máa ń dúnkookò mọ́ àwọn òṣìṣẹ́ tó dáńgájíá, tó jẹ́ olóòótọ́, tí àwọn òṣìṣẹ́ míì sì fẹ́ràn.

Àwọn òṣìṣẹ́ tí àwọn afòòró ẹni ń yọ lẹ́nu kì í lè ṣiṣẹ́ dáadáa. Èyí tún máa ń nípa lórí bí àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wọn tó ń rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ á ṣe ṣiṣẹ́ tó pójú owó sí. Ìfòòró ẹni lè sún àwọn òṣìṣẹ́ láti máa ronú pé àwọn ń ja ẹni tó gbà àwọn síṣẹ́ lólè àti pé àwọn ò fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́. Ìròyìn kan sọ pé, iye tí àwọn iléeṣẹ́ tó wà nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ń ná lọ́dọọdún láti fi yanjú àwọn ìṣòro tó ń jẹ yọ látàrí ìfòòró ẹni níbi iṣẹ́ tó bílíọ̀nù mẹ́ta owó dọ́là. Bákan náà, wọ́n sọ pé ìfòòró ẹni ló ń fa ohun tó ju ìdá ọgbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún àwọn àìsàn tó ní í ṣe pẹ̀lú másùnmáwo.

Láìsí àní-àní, jákèjádò ayé ni ìfòòró ẹni ti ń nípa lórí àwọn èèyàn tó wà láwùjọ. Ìbéèrè ibẹ̀ wá ni pé, Ǹjẹ́ ohunkóhun wà tá a lè ṣe láti kápá ìṣòro yìí àti láti fòpin sí i?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn obìnrin tó ń fòòró ẹni sábà máa ń dá àwọn ọgbọ́n kan láti fi fòòró ẹlòmíràn, irú bíi pípa ẹni tí wọ́n dájú sọ tì àti títan àhesọ kálẹ̀ nípa onítọ̀hún. Àmọ́, ní báyìí o, ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin ló ti ń hùwà ipá.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Ìfòòró ẹni níbi iṣẹ́ ti wọ́pọ̀ gan-an báyìí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Àwọn tí à ń fòòró lè di ẹni tí ayé sú kí wọ́n sì fẹ́ dá wà ní àwọn nìkan