Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Igi Tẹ́ẹ́rẹ́ Tó Ń Fọ Eyín Mọ́

Igi Tẹ́ẹ́rẹ́ Tó Ń Fọ Eyín Mọ́

Igi Tẹ́ẹ́rẹ́ Tó Ń Fọ Eyín Mọ́

LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ZAMBIA

ILẸ̀ ÁFÍRÍKÀ—ilẹ̀ táwọn èèyàn ti ń ní eyín funfun kinniwin, síbẹ̀ tó jẹ́ pé ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ ló ń lo búrọ́ọ̀ṣì ìfọyín! Ọgbọ́n wo ni wọ́n ń dá sí i? Ohun tó fà á tí eyín ọ̀pọ̀ lára wọn fi máa ń funfun kinniwin kò ṣẹ̀yìn igi tẹ́ẹ́rẹ́ kan tí wọ́n máa ń lò, èyí tí wọ́n ń pè ní pákò!

Àwọn ará Bábílónì ló ti kọ́kọ́ ń lo pákò nígbà láéláé, lẹ́yìn náà làwọn ará Íjíbítì, àwọn Gíríìkì, àtàwọn ará Róòmù náà wá bẹ̀rẹ̀ sí lò ó. Igi tẹ́ẹ́rẹ́ tí wọ́n ń lò bíi búrọ́ọ̀ṣì yìí tún wọ́pọ̀ nílẹ̀ Arébíà ṣáájú kí ẹ̀sìn Ìsìláàmù tó débẹ̀. Nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrún ọdún sẹ́yìn ni pákò lílò di ohun tí kò wọ́pọ̀ mọ́ nílẹ̀ Yúróòpù, àmọ́ ṣá, wọ́n ṣì ń lò ó gan-an láwọn apá ibì kan ní ilẹ̀ Áfíríkà, Éṣíà àti Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn Ayé.

Igi saltbush ni wọ́n sábà máa ń lò fún pákò ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn Ayé. Ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà, igi ọsàn wẹ́wẹ́ àti igi òroǹbó ni wọ́n máa ń lò, nígbà tó jẹ́ pé igi dóńgóyárò ló wọ́pọ̀ tí wọ́n máa ń lò jù láwọn àgbègbè kan nílẹ̀ Íńdíà. Ní Ìlà Oòrùn Áfíríkà, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọ̀ọ́dúnrún igi àti egbò igi tí wọ́n ń lò fún pákò. Báwo ni igi yìí ṣe máa ń fọ eyín mọ́?

Béèyàn bá ń jẹ pákò lẹ́nu, bó bá yá ibi tó ń jẹ náà á kúnná, á sì dà bíi búrọ́ọ̀ṣì ìfọyín. Bó ti ń jẹ pákò náà lọ, á máa yọ àwọn èérún oúnjẹ tó ti há sí i léyín, á sì tún jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ túbọ̀ máa ṣàn kiri nínú erìgì. Jíjẹ pákò tún máa ń jẹ́ kí ẹnu rú itọ́ dáadáa, itọ́ yìí sì máa ń fọ àwọn kòkòrò àrùn tó sá pa mọ́ sínú ẹnu kúrò, kò sì ní jẹ́ kí wọ́n ráyè gbilẹ̀. a

Àmọ́, iṣẹ́ tí pákò ń ṣe ju kìkìdá fífọ eyín lọ. Ẹ̀ka tàbí egbò àwọn igi kan máa ń ní àwọn èròjà tí kì í jẹ́ kí eyín dípẹtà. Ẹ̀rí sì ti fi hàn pé oje inú àwọn pákò kan ní àwọn èròjà apakòkòrò. Àní, ẹ̀ka igi saltbush, tá a mẹ́nu kàn lókè, kì í tiẹ̀ jẹ́ kéèyàn ní egbò ẹnu. Ní orílẹ̀-èdè Nàmíbíà, pákò tí wọ́n máa ń rí láti ara igi kan tí wọ́n ń pè ní muthala kì í jẹ́ kí àwọn kòkòrò ẹnu tó máa ń fa eyín jíjẹrà, erìgì wíwú àti ọgbẹ́ ọ̀nà ọ̀fun gbilẹ̀. Ohun ìfọyín tó ń wá láti ara igi yìí kì í jẹ́ kí eyín dáhò, bẹ́ẹ̀ ló sì máa ń jẹ́ kí ìdí eyín àti erìgì lágbára. Àwọn iléeṣẹ́ kan ti ń ṣe àwọn ọṣẹ ìfọyín kan báyìí tó ní àwọn egbò àti oje tí wọ́n mú láti ara irú àwọn igi bẹ́ẹ̀ nínú.

Lóòótọ́, búrọ́ọ̀ṣì làwọn kan nífẹ̀ẹ́ sí láti máa fi fọ eyín. Àmọ́, yálà búrọ́ọ̀ṣì lo yàn láàyò tàbí pákò, bíi tàwọn èèyàn ayé ìgbàanì, ohun kan dájú: Ìtọ́jú eyín ṣe pàtàkì fún ìlera ara.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àmọ́ ṣá o, irú oúnjẹ téèyàn ń jẹ náà tún ṣe pàtàkì o. Àwọn tó ń gbé lábúlé ní ilẹ̀ Áfíríkà sábà máa ń jẹ oúnjẹ oníhóró àti ewébẹ̀ ju àwọn tó ń gbé ní ìgboro lọ. Bákan náà ni wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ jẹ ṣúgà, oúnjẹ alágolo tàbí kí wọ́n máa mu ọtí ẹlẹ́rìndòdò—àwọn ohun tó sábà máa ń mú kí eyín jẹrà.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Igi dóńgóyárò wà lára ohun tí wọ́n máa ń lò fún pákò

[Credit Line]

William M. Ciesla, Forest Health Management International, www.forestryimages.org