Jíja Àjàbọ́ Lọ́wọ́ Ìfòòró Ẹni
Jíja Àjàbọ́ Lọ́wọ́ Ìfòòró Ẹni
‘Àṣà téèyàn ń kọ́ ni fífòòró ẹni, béèyàn bá sì kọ́ ohun kan, ó ṣeé ṣe láti jáwọ́ nínú rẹ̀.’—Ọ̀mọ̀wé C. Sally Murphy.
YÁLÀ ẹnì kan jẹ́ afòòró ẹni tàbí ẹni tí à ń fòòró, àwọn méjèèjì ló nílò ìrànlọ́wọ́. Afòòró ẹni ní láti mọ bí òun á ṣe máa bá àwọn ẹlòmíràn gbé pọ̀ láìsí pé ó ń ṣi agbára lò. Àwọn ohun kan sì wà tó yẹ kí ẹni tí à ń fòòró mọ̀ nípa ọ̀nà tó lè gbà kojú ìṣòro náà.
Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ ni pé ẹni tó ń fòòró ẹni kì í mọ bí a ṣe ń bá ẹlòmíràn lò, kò sì ní ìgbatẹnirò kankan fún àwọn tó ń dúnkookò mọ́. Ó pọn dandan pé kí wọ́n máa kíyè sí i lójú méjèèjì, kí wọ́n sì kọ́ ọ láti máa bá ẹlòmíràn lò bí ọmọlúwàbí. Ìwé náà Take Action Against Bullying sọ pé: “Àyàfi bí àwọn afòòró ẹni bá kọ́ àṣà tuntun kí wọ́n sì máa fi ṣèwà hù, láìjẹ́ bẹ́ẹ̀ ńṣe ni wọ́n á máa fòòró àwọn ẹlòmíràn ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn. Wọ́n á máa fòòró àwọn ọkọ tàbí aya wọn, àwọn ọmọ wọn, àní, ó ṣeé ṣe kí wọ́n tún máa fòòró àwọn tí kò tó wọn lẹ́nu iṣẹ́.”
Ríran Àwọn Ọmọdé Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Má Bàa Di Afòòró Ẹni
Kíkọ́ àwọn ọmọdé láti jẹ́ ẹni tó ń gba tẹni rò nígbà tí wọ́n ṣì kéré gan-an lọ́jọ́ orí lè ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n má bàa di afòòró ẹni. Àwọn olùkọ́ láwọn orílẹ̀-èdè kan ń lo ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tuntun kan tí wọ́n ń pè ní ẹ̀kọ́ nípa ìgbatẹnirò. Ìdí tí wọ́n fi gbé ètò yìí kalẹ̀ ni láti kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ọjọ́ orí
wọn bẹ̀rẹ̀ láti ọdún márùn-ún sókè láti máa gba ti àwọn ẹlòmíràn rò àti láti máa fi inú rere bá àwọn èèyàn lò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìsọfúnni díẹ̀ ló ṣì wà nípa bí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe máa ṣàǹfààní fún àwọn ọmọ náà tó, àwọn àbájáde tí wọ́n kọ́kọ́ rí fi hàn pé àwọn ọmọdé tó ti gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà kò fi bẹ́ẹ̀ ya òfínràn bí àwọn tí kò gbà á.Gẹ́gẹ́ bí òbí, kò yẹ kó jẹ́ pé ètò tí ilé ẹ̀kọ́ ṣe nìkan ni wàá gbára lé fún pípèsè irú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ fún àwọn ọmọ rẹ. Bí o kò bá fẹ́ kí ọmọ rẹ di afòòró ẹni, ó ṣe pàtàkì kó o kọ́ ọ, nípa ọ̀rọ̀ ẹnu àti nípa àpẹẹrẹ tìrẹ, béèyàn ṣe lè fi ọ̀wọ̀ àti iyì bá àwọn mìíràn lò. Kí ló lè ràn ọ́ lọ́wọ́? Ó ṣeé ṣe kó o ní ìwé kan, èyí tí ọ̀pọ̀ èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ kà sí, níbi tó o ti lè rí ìsọfúnni tó pójú owó nípa irú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀, ìyẹn ni Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Báwo ló ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́?
Bí àpẹẹrẹ, ó jẹ́ ká ní òye tó ṣe kedere nípa ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ìfòòró ẹni. Ó kórìíra rẹ̀ gidigidi! Bíbélì sọ nípa Ọlọ́run pé: “Dájúdájú, ọkàn Rẹ̀ kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá.” (Sáàmù 11:5) Síwájú sí i, kì í ṣe pé Ọlọ́run kò mọ̀ nípa gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀. Bíbélì ṣe àkọsílẹ̀ nípa bó ṣe dùn ún tó nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń jìyà “nítorí àwọn tí ń ni wọ́n lára àti àwọn tí ń tì wọ́n gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n kiri.” (Onídàájọ́ 2:18) Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Ọlọ́run fìyà jẹ àwọn tó ń ṣi agbára wọn lò, tí wọ́n sì ń fòòró àwọn tí kò lágbára tó wọn, tí wọn kò sì lè gbèjà ara wọn.—Ẹ́kísódù 22:22-24.
Bíbélì tún ṣàkọsílẹ̀ ìtọ́ni kan tó ṣeé ṣe kó jẹ́ èyí tó lókìkí jù lọ nípa béèyàn ṣe lè fi ìgbatẹnirò hàn. Jésù sọ pé: “Nítorí náà, gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.” (Mátíù 7:12) Kò rọrùn rárá láti kọ́ àwọn ọmọdé láti tẹ̀ lé Òfin Pàtàkì yìí, ìyẹn ni pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ kí wọ́n sì máa fi í sílò nínú ìgbésí ayé wọn; ó ń béèrè pé kí àwọn òbí fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀, kí wọ́n máa tẹ̀ ẹ́ mọ́ wọn létí gbọnmọgbọnmọ, kí wọ́n sì sapá gidigidi, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn ọmọdé sábà máa ń ní ẹ̀mí tinú-mi-ni-màá-ṣe. Àmọ́, gbogbo ìsapá wọ̀nyẹn ló ṣe pàtàkì. Bí àwọn ọmọ rẹ bá kọ́ láti jẹ́ onínúure àti agbatẹnirò, wọn kò ní fẹ́ láti di afòòró ẹni.
Ìrànwọ́ fún Àwọn Tí À Ń Fòòró
Ohun kan wà tó máa ń nira láti ṣe fún àwọn tí à ń fòòró, pàápàá àwọn èwe, ìyẹn ni jíjẹ́ ẹni tí ara rẹ̀ balẹ̀ tó sì lè ṣe ohun tó tọ́ lásìkò tí ìfòòró ẹni náà bá ń wáyé. Nígbà tí ẹnì kan bá fòòró rẹ, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ló ń fẹ́ láti kó ọ láyà jẹ. Ó ń retí pé kó o bínú rangbandan tàbí kó o fi hàn pé jìnnìjìnnì ti bò ọ́. Bó o bá fa ìbínú yọ tàbí tó o bú sẹ́kún tó o sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé ohun tí afòòró ẹni náà ń ṣe dùn ọ́ wọra tàbí pé ẹ̀rù ń bà ọ́, ńṣe ni á túbọ̀ máa ṣẹ̀rù bà ọ́ torí pé ò ń ṣe ohun tó retí pé kó o ṣe. Nípa bẹ́ẹ̀, ó lè máa ṣe ohun kan náà sí ọ léraléra láti mú ọ bínú.
Kí lo lè ṣe? Gbé àwọn àbá tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí yẹ̀ wò. Àwọn ọmọdé la dìídì kọ ìsọfúnni náà fún,
àmọ́ àwọn ìlànà ibẹ̀ tún lè wúlò fún àwọn àgbàlagbà tí àwọn kan ń fòòró.◼ Fara balẹ̀. Má ṣe fa ìbínú yọ. Bíbélì fún wa ní ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n yìí pé: “Jáwọ́ nínú ìbínú, kí o sì fi ìhónú sílẹ̀.” (Sáàmù 37:8) Bó o bá bínú kọjá bó ṣe yẹ, ńṣe lò ń fún afòòró ẹni náà lágbára láti máa ṣe ọ́ bó ṣe fẹ́, ó sì ṣeé ṣe kó o ṣe ohun tí wàá kábàámọ̀ rẹ̀.—Òwe 25:28.
◼ Má ṣe ní in lọ́kàn láti gbẹ̀san. Ńṣe ni gbígbẹ̀san sábà máa ń dá kún ìṣòro, kì í yanjú rẹ̀. Bó ti lè wù kó rí, gbígbẹ̀san kì í ṣe ohun tó dára rárá. Ọmọbìnrin kan tí àwọn ọ̀dọ́ márùn-ún lù bí ẹní máa kú nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìndínlógún sọ pé: “Mo pinnu lọ́kàn mi pé, ‘Màá gbẹ̀san ohun tí wọ́n ṣe sí mi.’ Nípa bẹ́ẹ̀, mo ké sí àwọn ọ̀rẹ́ mi méjì láti ràn mí lọ́wọ́, wọ́n sì bá mi gbẹ̀san lára méjì nínú àwọn tó fìyà jẹ mí.” Kí lohun tí èyí yọrí sí? Ó sọ pé: “Ńṣe ni gbogbo nǹkan tojú sú mi.” Ohun tí ọmọbìnrin náà ṣe yìí wá mú kí ìwà rẹ̀ túbọ̀ burú sí i. Rántí ọ̀rọ̀ Bíbélì tó sọ pé: “Ẹ má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnì kankan.”—Róòmù 12:17.
◼ Bí ọ̀ràn náà bá ti ń kọjá bó ṣe yẹ, tètè fi ibẹ̀ sílẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Kí aáwọ̀ tó bẹ́, fi ibẹ̀ sílẹ̀.” (Òwe 17:14) Ohun tó ti dáa jù ni pé, kó o gbìyànjú láti yàgò pátápátá fún àwọn afòòró ẹni. Òwe 22:3 sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́, ṣùgbọ́n aláìní ìrírí gba ibẹ̀ kọjá, yóò sì jìyà àbájáde rẹ̀.”
◼ Bí ìfòòró ẹni náà ò bá dáwọ́ dúró, á dáa kí ìwọ fúnra rẹ bá onítọ̀hún sọ́rọ̀. Lọ bá a ní àkókò tí ara rẹ balẹ̀, máa wo ojú rẹ̀ nígbà tó o bá ń bá a sọ̀rọ̀, kó o sì sọ ojú abẹ níkòó, láìsí pé ò ń pariwo. Sọ fún un pé o ò Òwe 15:1.
fẹ́ ohun tó ń ṣe, sì jẹ́ kó mọ̀ pé kì í ṣe ọ̀rọ̀ eré rárá àti pé ó máa ń dùn ọ́ gan-an ni. Má ṣe àfojúdi sí onítọ̀hún o, má sì sọ̀rọ̀ tó máa bí i nínú.—◼ Bá àgbàlagbà kan tó mọ ọ̀rọ̀ gbọ́, tó sì jẹ́ agbatẹnirò sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro náà. Sọ bí ọ̀rọ̀ náà bá ṣe jẹ́ gan-an fún un, kó o sì béèrè nípa bó o ṣe lè bójú tó ìṣòro náà. Bákan náà, sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ ní pàtó bó o bá ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, èyí lè jẹ́ ìrànwọ́ àti ìtùnú ńlá gan-an fún ọ.—1 Tẹsalóníkà 5:17.
◼ Rántí pé o kì í ṣe ẹ̀dá yẹpẹrẹ. Afòòró ẹni náà lè fẹ́ kó o máa ronú pé ẹni yẹpẹrẹ ni ọ́, pé o yẹ lẹ́ni tí wọ́n ń hùwà tí kò dára sí. Àmọ́ kì í ṣe òun ni onídàájọ́ rẹ. Ọlọ́run ni onídàájọ́, ànímọ́ rere tí gbogbo wa ní lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ló sì ń wò mọ́ wa lára. Afòòró ẹni náà gan-an ló sọ ara rẹ̀ di ẹni yẹpẹrẹ nítorí ìwà tó ń hù.
Ẹ̀yin Òbí—Ẹ Dáàbò Bo Àwọn Ọmọ Yín
Àwọn òbí pẹ̀lú lè tètè bẹ̀rẹ̀ sí dá àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ nípa bí wọ́n ṣe lè fi ọgbọ́n bá àwọn afòòró ẹni lò. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè máa ṣàlàyé fún wọn nípa onírúurú ọ̀nà tí wọ́n lè gbà kojú ìfòòró ẹni.
Àní dídúró láìdẹranù pàápàá, lè fi hàn pé ẹni tí à ń fòòró ní ìgboyà, ìyẹn sì lè lé ẹni tí ń fòòró rẹ̀ sá. Wíwo ẹni náà lójú ní tààràtà, ṣíṣàì dẹra nù àti ṣíṣàì jẹ́ kí ohùn ẹni gbọ̀n nígbà tá a bá ń sọ̀rọ̀ tún lè ranni lọ́wọ́. A rọ àwọn òbí láti kọ́ àwọn ọmọ wọn pé kí wọ́n má ṣe máa wà ní sàkáání àwọn afòòró ẹni, kí wọ́n máa yẹra fún wọn, kí wọ́n sì máa fọ̀ràn lọ àgbàlagbà kan tó ṣeé finú hàn, irú bí olùkọ́.
Inú ilé ló ti yẹ kí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nípa fífòpin sí ìfòòró ẹni bẹ̀rẹ̀. Àwọn òbí tó bá ń fàyè sílẹ̀ láti gbọ́ tàwọn ọmọ, tí wọ́n ń fi sùúrù àti ìgbatẹnirò tẹ́tí sí àníyàn wọn, yóò ran irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ láti mọ̀ pé a mọyì wọn nínú ìdílé náà, a ṣe tán láti tì wọ́n lẹ́yìn, a sì nífẹ̀ẹ́ wọn. Ọ̀pọ̀ àwọn ògbógi tó jẹ́ olùgbaninímọ̀ràn nípa ọmọ títọ́ àti ìṣòro àwọn ọ̀dọ́ máa ń gba àwọn òbí níyànjú láti máa kọ́ àwọn ọmọ wọn pé kí wọ́n má ka ara wọn sí ẹni yẹpẹrẹ. Ṣíṣàì ka ara wọn sí ẹni yẹpẹrẹ kò ní jẹ́ kí wọ́n fàyè gba àwọn afòòró ẹni láti máa rí wọn bí ẹni tí wọ́n lè kó láyà jẹ.
Àmọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan ló ṣì wà láti ṣe yàtọ̀ sí wíwulẹ̀ bá àwọn ọmọ sọ̀rọ̀. Ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé ló yẹ kó mọ bí a ṣe ń fi ọ̀wọ̀ àti iyì bá àwọn ẹlòmíràn lò, kí kálukú wọn sì kọ́ ìgbatẹnirò. Nítorí náà, má ṣe gba ìfòòró ẹni láyè lọ́nàkọnà nínú agboolé rẹ. Jẹ́ kí ilé rẹ jẹ́ ibi títunilára, ibi tí ọ̀wọ̀ àti ìfẹ́ á ti jọba.
Ìgbà Tí Òpin Yóò Dé Bá Ìfòòró Ẹni
“Ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.” (Oníwàásù 8:9) Ọ̀nà tí Bíbélì gbà sọ̀rọ̀ nípa ìtàn ẹ̀dá ènìyàn nìyẹn. Ká sòótọ́, ìfòòró ẹni ti ń yọ aráyé lẹ́nu láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Òǹkọ̀wé Bíbélì kan sọ pé: “Èmi alára . . . padà, kí n lè rí gbogbo ìwà ìninilára tí a ń hù lábẹ́ oòrùn, sì wò ó! omijé àwọn tí a ń ni lára, ṣùgbọ́n wọn kò ní olùtùnú; ọ̀dọ̀ àwọn tí ń ni wọ́n lára sì ni agbára wà, tí ó fi jẹ́ pé wọn kò ní olùtùnú.”—Oníwàásù 4:1.
Àmọ́ o, ó dájú pé Ọlọ́run ń rí gbogbo ìfòòró ẹni tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé, àánú àwọn tí à ń ni lára sì ń ṣe é. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ ó tiẹ̀ máa ṣe ohunkóhun nípa rẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni, yóò ṣe bẹ́ẹ̀! Kíyè sí ìlérí tó ṣe nínú ìwé Míkà 4:4: “Wọn yóò . . . jókòó ní ti tòótọ́, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, kì yóò sì sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì; nítorí ẹnu Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ti sọ ọ́.”
Ronú nípa bí ayé ṣe máa rí nígbà tí ìlérí yẹn bá ní ìmúṣẹ. Kò ní sí ẹnikẹ́ni tí yóò máa ṣẹ̀rù ba ẹlòmíràn—bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn afòòró ẹni á ti wábi gbà! Ǹjẹ́ ìyẹn ò dùn gbọ́ létí? Àmọ́, kì í wulẹ̀ ṣe pé Ọlọ́run ti ṣèlérí irú ọjọ́ ọ̀la bẹ́ẹ̀ nìkan ni, ní báyìí, ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan ń lọ lọ́wọ́ kárí ayé. Ó ń ṣe àwọn èèyàn láǹfààní gidigidi. Àwọn tó bá ń kópa nínú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà máa ń gba ìtọ́ni láti yí ìwà òfínràn wọn padà, kí wọ́n wà lálàáfíà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, kí wọ́n sì máa fi ọ̀wọ̀ àti iyì bá àwọn ẹlòmíràn lò. (Éfésù 4:22-24) Láìpẹ́ jọjọ, gbogbo olùgbé ayé yóò jàǹfààní ìtọ́ni tó ju ìtọ́ni lọ yìí, ìṣòro ìfòòró ẹni kì yóò sì sí mọ́. Àwọn ìlérí Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì á di ohun tó ní ìmúṣẹ. Gbogbo ẹni tó bá wà láàyè nígbà náà ni yóò gbádùn gbígbé nínú ayé kan níbi tí kò ti ní sí àwọn afòòró ẹni mọ́!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Kò sí ìtìjú nínú rírìn kúrò ní sàkáání afòòró ẹni
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Nínú ìdílé tí nǹkan ti ń lọ bó ṣe yẹ, wọ́n máa ń kọ́ àwọn ọmọ nípa bí wọ́n ṣe lè kojú onírúurú ìṣòro ìfòòró ẹni
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Kọ́ ọmọ rẹ pé kí òun fúnra rẹ̀ bá onítọ̀hún sọ̀rọ̀, kó sọ ojú abẹ níkòó, kó sì sọ̀rọ̀ lọ́nà tó mọ́gbọ́n dání