Ǹjẹ́ Jíjẹ́ Ọlọ́rọ̀ Ló Ń Fi Hàn Pé Èèyàn ní Ìbùkún Ọlọ́run?
Ojú Ìwòye Bíbélì
Ǹjẹ́ Jíjẹ́ Ọlọ́rọ̀ Ló Ń Fi Hàn Pé Èèyàn ní Ìbùkún Ọlọ́run?
“Ìbùkún Jèhófà—èyíinì ni ohun tí ń sọni di ọlọ́rọ̀, kì í sì í fi ìrora kún un.”—ÒWE 10:22.
ṢÉ OHUN tí ẹsẹ Bíbélì tí a mẹ́nu kàn lókè yìí ń sọ ni pé jíjẹ́ ọlọ́rọ̀ ló ń fi hàn pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní ìbùkún rẹ̀? Èrò àwọn kan nìyẹn o. Ronú nípa ohun tí oníwàásù ṣọ́ọ̀ṣì gba-Jésù kan nílẹ̀ Ọsirélíà, tó tún jẹ́ òǹṣèwé sọ, ó ní: “Nínú ìwé [mi], màá jẹ́ kẹ́ ẹ mọ ìdí tẹ́ ẹ fi nílò owó púpọ̀ sí i, àti ọ̀nà tẹ́ ẹ lè gbà ní owó púpọ̀ sí i . . . Bẹ́ ẹ bá lè yí èrò yín padà, tẹ́ ẹ sì ní èrò tó tọ́ nípa owó, mo gbà gbọ́ pé ẹ óò máa rìn nínú ojúure àti aásìkí Ọlọ́run, owó ò sì ní wọ́n yín mọ́ láé.”
Àmọ́, ohun tí irú gbólóhùn báyìí ń fi hàn ni pé Ọlọ́run kò fi ojúure hàn sí àwọn tálákà. Ṣé lóòótọ́ ni ọrọ̀ jẹ́ àmì pé ẹnì kan ní ìbùkún Ọlọ́run?
A Bù Kún Wọn fún Ìdí Pàtàkì Kan
Nínú àkọsílẹ̀ Bíbélì, àwọn àpẹẹrẹ kan wà tó fi hàn bí Ọlọ́run ṣe fi ọrọ̀ bù kún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olùṣòtítọ́. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pá lásán ni Jákọ́bù mú dání nígbà tó máa kúrò nílé, àmọ́ nígbà tó ń padà bọ̀ ní ogún ọdún lẹ́yìn náà, ó ti ní agbo àgùntàn, màlúù àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tó pọ̀ débi pé, wọ́n ṣeé pín sí ọ̀nà méjì. Bíbélì fi hàn pé ẹ̀bùn Ọlọ́run ni aásìkí Jákọ́bù jẹ́. (Jẹ́nẹ́sísì 32:10) Àpẹẹrẹ mìíràn ni ti Jóòbù. Ó pàdánù gbogbo ohun ìní rẹ̀, síbẹ̀ Jèhófà bù kún un lẹ́yìn náà pẹ̀lú “ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlá àgùntàn àti ẹgbàáta ràkúnmí àti ẹgbẹ̀rún àdìpọ̀ méjì-méjì màlúù àti ẹgbẹ̀rún abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.” (Jóòbù 42:12) Jèhófà fún Sólómọ́nì Ọba ní ọrọ̀ tó pọ̀ débi pé òkìkí ọrọ̀ rẹ̀ ṣì ń kàn títí di òní olónìí.—1 Àwọn Ọba 3:13.
Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àkọsílẹ̀ ń bẹ nínú Bíbélì nípa àwọn olùjọsìn Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́ àti onígbọràn, ṣùgbọ́n tí wọ́n jẹ́ tálákà. Dájúdájú, kì í ṣe pé Ọlọ́run ń fi ipò òṣì jẹ àwọn kan níyà, nígbà tó ń fi aásìkí san àwọn kan lẹ́san. Nígbà náà, kí nìdí tí Ọlọ́run ṣe fi ọrọ̀ jíǹkí àwọn kan?
Ìdáhùn sí ìbéèrè yìí yàtọ̀ nínú ọ̀ràn ẹnì kọ̀ọ̀kan. Ọrọ̀ tí Jákọ́bù ní ni Ọlọ́run lò gẹ́gẹ́ bí ìpìlẹ̀ fún kíkó orílẹ̀-èdè kan jọ ní ìmúrasílẹ̀ fún dídé Irú Ọmọ tí a ṣèlérí náà. (Jẹ́nẹ́sísì 22:17, 18) Ọrọ̀ rẹpẹtẹ tí Jóòbù wá ní lẹ́yìn àjálù tó dé bá a jẹ́ ká lóye ní kedere ẹni tó mú àjálù wá bá Jóòbù, èyí sì tipa bẹ́ẹ̀ ya orúkọ Jèhófà sí mímọ́. (Jákọ́bù 5:11) Ní ti Sólómọ́nì, ó lo púpọ̀ lára ọrọ̀ tí Ọlọ́run fún un láti kọ́ tẹ́ńpìlì ńlá ológo kan. (1 Àwọn Ọba 7:47-51) Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, Sólómọ́nì ọ̀hún ni Jèhófà tún lò láti kọ̀wé látinú ìrírí ara rẹ̀ nípa ibi tí agbára ọrọ̀ mọ.—Oníwàásù 2:3-11; 5:10; 7:12.
Ọ̀nà Tí Ọlọ́run Ń Gbà Bù Kún Wa
Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti ní èrò tó tọ́ nípa owó nígbà tó sọ fún wọn pé kí wọ́n “dẹ́kun ṣíṣàníyàn” nípa ohun ìní. Ó jẹ́ kó yé wọn pé kódà Sólómọ́nì pàápàá, pẹ̀lú gbogbo ògo tó ní, ni a kò wọ̀ láṣọ bíi ti àwọn òdòdó lílì pápá. Síbẹ̀, Jésù sọ pé: “Wàyí o, bí Ọlọ́run bá wọ ewéko pápá láṣọ báyìí, . . . òun kì yóò ha kúkú wọ̀ yín láṣọ jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ̀yin tí ẹ ní ìgbàgbọ́ kíkéré?” Jésù fi àwọn Kristẹni lọ́kàn balẹ̀ pé bí àwọn ọmọlẹ́yìn òun bá wá Ìjọba náà àti òdodo Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́, nígbà náà a óò fi oúnjẹ, aṣọ àti ibùgbé kún un fún wọn. (Mátíù 6:25, 28-33) Báwo ni Ọlọ́run ṣe ń mú ìlérí yìí ṣẹ?
Bí àwọn Kristẹni bá fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò, èyí á fún wọn ní ìbùkún yanturu, pàápàá ìbùkún tẹ̀mí. (Òwe 10:22) Àmọ́ o, ó tún lè ṣe wọ́n láǹfààní láwọn ọ̀nà mìíràn. Bí àpẹẹrẹ, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pàṣẹ fún àwọn Kristẹni pé: “Kí ẹni tí ń jalè má jalè mọ́, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, kí ó máa ṣe iṣẹ́ àṣekára.” (Éfésù 4:28) Ó tún sọ pé “ẹni tí ń fi ọwọ́ dẹngbẹrẹ ṣiṣẹ́ yóò jẹ́ aláìnílọ́wọ́, ṣùgbọ́n ọwọ́ ẹni aláápọn ni yóò sọni di ọlọ́rọ̀.” (Òwe 10:4) Àwọn Kristẹni tó jẹ́ olóòótọ́ àti òṣìṣẹ́ kára, tó ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí, làwọn agbanisíṣẹ́ sábà máa ń gbà síṣẹ́. Ìbùkún sì lèyí jẹ́.
Bíbélì tún kọ́ àwọn Kristẹni láti yẹra fún àwọn àṣàkaṣà, irú bíi tẹ́tẹ́ títa táwọn oníwọra fi ń ṣeré ìnàjú, sìgá mímu tó ń sọni di ẹlẹ́gbin, àti ìmutípara tí ń sọni di akúrẹtẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 6:9, 10; 2 Kọ́ríńtì 7:1; Éfésù 5:5) Àwọn tó ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí ti rí i pé owó tí àwọ́n ń ná ti dín kù, ìlera àwọn sì ti dára sí i.
Ohun Tó Níye Lórí Ju Fàdákà Tàbí Wúrà Lọ
Síbẹ̀síbẹ̀, a ò lè gbára lé ọrọ̀ gẹ́gẹ́ bí lájorí ohun kan ṣoṣo tó ń fi hàn pé èèyàn ní ìtẹ́wọ́gbà àti ìbùkún Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, Jésù ṣí ipò tẹ̀mí àwọn Kristẹni kan ní ìlú Laodíkíà payá nígbà tó sọ fún wọn pé: “Ìwọ wí pé: ‘Ọlọ́rọ̀ ni mí, mo sì ti kó ọrọ̀ jọ, èmi kò sì nílò ohunkóhun rárá,’ ṣùgbọ́n o kò mọ̀ pé akúùṣẹ́ ni ọ́ àti ẹni ìkáàánú fún àti òtòṣì àti afọ́jú àti ẹni ìhòòhò.” (Ìṣípayá 3:17) Ní ìyàtọ̀ pátápátá síyẹn, Jésù sọ fún àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ tálákà àmọ́ tí wọ́n dúró sán-ún nípa tẹ̀mí ní ìlú Símínà pé: “Mo mọ ìpọ́njú àti ipò òṣì rẹ—ṣùgbọ́n ọlọ́rọ̀ ni ọ́.” (Ìṣípayá 2:9) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé nítorí ìṣòtítọ́ àwọn Kristẹni wọ̀nyí ni àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí wọn fi mú kí ipò ìṣúnná owó le koko fún wọn, síbẹ̀ wọ́n ní ọrọ̀ tó níye lórí gan-an ju fàdákà tàbí wúrà lọ.—Òwe 22:1; Hébérù 10:34.
Jèhófà Ọlọ́run máa ń bù kún ìsapá àwọn tó bá ń tiraka láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (Sáàmù 1:2, 3) Ó ń fún wọn lókun, ó sì tún ń pèsè àwọn ohun tí wọ́n nílò láti fara da àdánwò, láti pèsè àwọn ohun kòṣeémánìí fún àwọn ìdílé wọn, àti láti wá Ìjọba rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́. (Sáàmù 37:25; Mátíù 6:31-33; Fílípì 4:12, 13) Nítorí náà, dípò kí àwọn Kristẹni tòótọ́ máa wo ọrọ̀ gẹ́gẹ́ bí lájorí ohun tó ń fi hàn pé èèyàn ní ìbùkún Ọlọ́run, ńṣe ni wọ́n ń làkàkà láti jẹ́ “ọlọ́rọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ àtàtà.” Nípa jíjẹ́ kí àjọṣe wọn pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá dán mọ́rán, àwọn Kristẹni ń fi “àìséwu to ìṣúra ìpìlẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ jọ fún ara wọn de ẹ̀yìn ọ̀la.”—1 Tímótì 6:17-19; Máàkù 12:42-44.