Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìṣòro Tó Ń Kojú Àwọn Àgbẹ̀ Yóò Dópin

Ìṣòro Tó Ń Kojú Àwọn Àgbẹ̀ Yóò Dópin

Ìṣòro Tó Ń Kojú Àwọn Àgbẹ̀ Yóò Dópin

“RODNEY, ẹni tó ń dá oko bàbá bàbá rẹ̀ sọ pé: “Àwọn kan tí kò ṣe iṣẹ́ àgbẹ̀ àmọ́ tí wọ́n ń rí nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn àgbẹ̀ lè máa ronú pé pẹ̀lú gbogbo ìṣòro yìí, kí ló dé tẹ́nì kan á ṣì jókòó sídìí iṣẹ́ àgbẹ̀.” Síbẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn káàkiri ayé kò yéé ṣe iṣẹ́ àgbẹ̀. Láwọn orílẹ̀-èdè kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, ó lè má fi bẹ́ẹ̀ sí iṣẹ́; àmọ́ ó ṣe kò ṣe, iṣẹ́ àgbẹ̀ á ṣì jẹ́ kí ìdílé kan rí oúnjẹ fi sẹ́nu lóòjọ́.

Ìyẹn nìkan kọ́ o, ọ̀pọ̀ ìdílé ló gbà pé iṣẹ́ àgbẹ̀ kì í wulẹ̀ ṣe iṣẹ́ tí àwọ́n fi ń wá owó lásán, àmọ́ ó jẹ́ iṣẹ́ kan tí wọn ò lè fi sílẹ̀. Iye àwọn àgbẹ̀ tí wọ́n ṣì ń bá iṣẹ́ àgbẹ̀ lọ lójú ìṣòro ọ̀dá, kòkòrò, ipò ọrọ̀ ajé tó polúkúrúmuṣu àtàwọn ìṣòro mìíràn fi hàn pé wọn ò káàárẹ̀ bẹ́ẹ̀ ló sì tún ń fi ìfẹ́ tí wọ́n ní fún ìgbésí ayé oko hàn. Ká tó gbé bí ìṣòro tó ń kojú iṣẹ́ àgbẹ̀ ṣe máa dópin yẹ̀ wò, ẹ jẹ́ ká wo bí àwọn kan ṣe dẹni tó rí ìrànlọ́wọ́ gbà láti kojú àwọn ìṣòro náà.

Bí Àwọn Kan Ṣe Ń Kojú Ìṣòro Náà

Iṣẹ́ àgbẹ̀ ní àwọn wàhálà kan nínú tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀. A ní láti mọ̀ pé, ipò ojú ọjọ́, ipò ọrọ̀ ajé àti ọ̀pọ̀ àwọn ìṣòro mìíràn tó ń fa ìdààmú ọkàn ni kò ṣeé ṣe nǹkan kan sí. Ìròyìn kan tó wá látọ̀dọ̀ Àjọ Tó Ń Rí sí Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún Àwọn Àgbẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ North Carolina, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Ẹ̀kọ́ kan tó nira tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àgbẹ̀ ti kọ́ ni pé iṣẹ́ ńlá kọ́ lowó ńlá. Ìgbà gbogbo kọ́ ni iṣẹ́ àṣelàágùn tó ti mọ́ àwọn àgbẹ̀ lára máa ń mú èrè tí wọ́n retí wá. Gbogbo àgbẹ̀ pátá ló jẹ́ pé àwọn ipò kan tàbí àwọn nǹkan kan á wà tí wọn ò ní lè ṣe nǹkan kan sí.” Bàbá àgbẹ̀ kan sọ ọgbọ́n tó dá láti rí i pé òun ò gba ìbànújẹ́ láyè, ó sọ pé: “Ohun yòówù tí ì báà ṣẹlẹ̀, mo ti kọ́ láti gba kámú.”

Òwe ayé ọjọ́un kan sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń ṣọ́ ẹ̀fúùfù kì yóò fún irúgbìn; ẹni tí ó bá sì ń wo àwọsánmà kì yóò kárúgbìn.” (Oníwàásù 11:4) Iyèméjì àti àìmọ ohun tó yẹ kéèyàn ṣe lè máà jẹ́ kéèyàn dáwọ́ lé ohunkóhun. Àmọ́, fífi àwọn èrò tó dára rọ́pò àwọn èrò tí kò tọ́ lè dín ìdààmú ọkàn tí kò nídìí kù.

Jíjẹ oúnjẹ tó ń ṣara lóore àti sísinmi dáadáa tún lè mú àwọn àbájáde tó dára wá. Ìwé ìròyìn orí Íńtánẹ́ẹ̀tì kan tó ń jẹ́ The Western Producer ròyìn pé, àwọn àgbẹ̀ tí ara wọn bá le “máa ń lè ṣe àwọn ìpinnu tó dára.” Àgbẹ̀ kan tó ń jẹ́ Eugene àti ìyàwó rẹ̀, Candace sọ fún aṣojú ìwé ìròyìn Jí! pé: “Sísinmi dáadáa máa ń jẹ́ ká lè fara da ìdààmú ọkàn. Àwọn ìṣòro wa kì í fi bẹ́ẹ̀ ṣe bàbàrà mọ́ nígbà tá a bá sinmi. Oúnjẹ tó ń ṣara lóore náà tún máa ń ṣèrànwọ́, àgàgà tó bá jẹ́ pé gbogbo ìdílé ló jọ ń jẹ ẹ́ pa pọ̀.” Ìmọ̀ràn yìí ṣe rẹ́gí pẹ̀lú ohun tí Bíbélì sọ pé: “Kí olúkúlùkù ènìyàn máa jẹ, kí ó sì máa mu ní tòótọ́, kí ó sì rí ohun rere nítorí gbogbo iṣẹ́ àṣekára rẹ̀. Ẹ̀bùn Ọlọ́run ni.”—Oníwàásù 3:13.

Pípèsè Ìṣírí Tí Ìdílé Nílò

Àgbẹ̀ kan sọ fún aṣojú ìwé ìròyìn Jí! pé: “Ọ̀pọ̀ ìdílé tó ń ṣiṣẹ́ oko ló ti di dandan fún láti máa fi iṣẹ́ mìíràn gbe iṣẹ́ oko lẹ́sẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé torí àtidín ìṣòro ìnáwó kù ló mú kí wọ́n máa ṣe èyí, àwọn ìṣòro mìíràn tó jẹ mọ́ ti ìdílé tún lè yọjú. Àwọn ìdílé kan tó ń ṣiṣẹ́ oko tí wọ́n sì wà pa pọ̀ tímọ́tímọ́ nígbà kan rí kò tún fi bẹ́ẹ̀ wà pa pọ̀ mọ́.” Báwo làwọn ìdílé ṣe lè kojú èyí?

Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [2,700] sẹ́yìn, Bíbélì fún àwọn olórí ìdílé ní ìṣílétí yìí pé: “Múra iṣẹ́ rẹ sílẹ̀ lóde, kí o sì pèsè rẹ̀ sílẹ̀ fún ara rẹ ní pápá. Lẹ́yìn ìgbà náà, kí o gbé agbo ilé rẹ ró pẹ̀lú.” (Òwe 24:27) Randy, baálé ilé kan tó ń dá oko àwọn bàbá bàbá rẹ̀ sọ pé: “Wíwá àkókò láti fi ìmọrírì hàn fún àwọn tó wà nínú ìdílé pọn dandan. Ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé ló nílò ìṣírí àti ìfẹ́. Sísọ àwọn ọ̀rọ̀ tó dùn mọ́ni àti ṣíṣe nǹkan tó dára fún wọn máa ń jẹ́ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan gbà pé a fẹ́ràn òun a sì mọyì òun.”

Àwọn ọmọ ní pàtàkì nílò pé ká dá wọn lọ́kàn le nígbà táwọn ìyípadà ńlá bá ṣẹlẹ̀. Ẹ̀dùn ọkàn tó máa ń bá àwọn ọmọdé nígbà tí oko ìdílé wọn bá bọ́ sọ́wọ́ ẹlòmíì la lè fi wé ti àwọn ọmọ tí àwọn òbí wọn kọra wọn sílẹ̀ tàbí tí òbí wọn kú. Ó yẹ kí àwọn òbí jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ìṣòro náà kì í ṣe ẹ̀bi wọn àti pé ìdílé náà kò ní torí ẹ̀ tú ká.

Bí Àwọn Mìíràn Ṣe Lè Ṣèrànwọ́

Àwọn àgbẹ̀ tí ìdààmú bá lè dẹni tí kì í fẹ́ dá sí ẹnikẹ́ni mọ́, kódà wọ́n lè máa yẹra fún àwọn tó jẹ́ ọ̀rẹ́ wọn pàápàá. (Òwe 18:1) Àmọ́, àkókò wàhálà gan-an lèèyàn nílò ìtìlẹ́yìn àwọn ẹlòmíràn ju ìgbàkígbà mìíràn lọ!

Ǹjẹ́ o ní àwọn ọ̀rẹ́ kan tàbí àwọn aládùúgbò kan tí nǹkan ò dẹrùn fún nítorí ìṣòro iṣẹ́ oko? Kìkì bíbá irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kẹ́dùn lè ṣèrànwọ́ fún wọn. Àgbẹ̀ kan tó ń jẹ́ Ron sọ pé: “Ìtùnú ló jẹ́ lọ́tọ̀lọ́tọ̀ láti mọ̀ pé àwọn ọ̀rẹ́ wa mọ ìnira tí à ń kojú.” Bẹ́ẹ̀ ni o, lo ìdánúṣe láti bẹ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ wò kó o sì tẹ́tí sí wọn bí wọ́n ti ń tú ọkàn wọn jáde.

Jack jàǹfààní látinú irú ìbẹ̀wò bẹ́ẹ̀. Ó sọ pé: “Ńṣe ni inú mi máa ń dùn bí mo bá rántí ìgbà táwọn ọ̀rẹ́ mi kíyè sí i pé mo wà nínú ìnira tí wọ́n sì ṣèbẹ̀wò onífẹ̀ẹ́ sọ́dọ̀ mi.” Kò ṣẹ̀ṣẹ̀ dìgbà téèyàn bá mọ tinú-tòde iṣẹ́ àgbẹ̀ kó tó lè ṣèrànwọ́. Rodney, tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ níbẹ̀rẹ̀ sọ pé: “Kìkì mímọ̀ pé àwọn ọ̀rẹ́ mi mọ̀ pé mo ní iṣẹ́ ńláǹlà láti ṣe máa ń fún mi ní okun àti ìfẹ́ ọkàn láti ṣe ohun tí mo bá lè ṣe.” Èyí rán wa létí òwe Bíbélì tó sọ pé: “Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.”—Òwe 17:17.

Bí Ìṣòro Náà Á Ṣe Kásẹ̀ Nílẹ̀ Pátápátá

Àwọn ìṣòro tó wà nídìí iṣẹ́ àgbẹ̀ wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀rí tó ń fi hàn pé ẹ̀dá èèyàn kò ní agbára láti bójú tó ilẹ̀ ayé àtàwọn ohun tó wà nínú rẹ̀ kí wọ́n sì ṣàṣeyọrí. Wòlíì Jeremáyà sọ pé: “Mo mọ̀ dáadáa, Jèhófà, pé ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Jeremáyà 10:23) Ó hàn gbangba pé aráyé nílò ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run. Bákan náà, jẹ́ kó dá ọ lójú pé irú ìrànlọ́wọ́ yìí kò ní pẹ́ dé mọ́.

Àkọsílẹ̀ Bíbélì sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run sì ń bá a lọ láti mú ọkùnrin náà, ó sì mú un tẹ̀ dó sínú ọgbà Édẹ́nì láti máa ro ó àti láti máa bójú tó o.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:15) Bẹ́ẹ̀ ni, látìgbà tí Ẹlẹ́dàá wa ti pa àṣẹ yìí ni iṣẹ́ àgbẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀! Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn náà, Ọlọ́run mú àwọn èèyàn rẹ̀ wá sí ilẹ̀ Kénáánì. Nígbà tí àkọsílẹ̀ tí a mí sí ń sọ nípa ilẹ̀ náà, ó sọ pé: “Láti inú òjò ojú ọ̀run ni ó ti ń mu omi; ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń bójú tó. Ojú Jèhófà Ọlọ́run rẹ wà lára rẹ̀ nígbà gbogbo, láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ọdún dé òpin ọdún.” (Diutarónómì 11:11, 12) Jèhófà tún pèsè àwọn òfin tí kò ní jẹ́ kí wọ́n lo Ilẹ̀ Ìlérí náà nílòkulò. Bí àpẹẹrẹ, ní òpin ọdún méje méje, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní láti fún àwọn pápá wọn, ọgbà àjàrà wọn àti oko ólífì wọn nísinmi. (Ẹ́kísódù 23:10, 11) Nípa bẹ́ẹ̀, ilẹ̀ náà kò ṣá.

A lè fọkàn balẹ̀ pé, lọ́jọ́ iwájú, lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run—ìyẹn ìṣàkóso kan látòkè ọ̀run tí Jésù Kristi máa jẹ́ olórí rẹ̀—ilẹ̀ ayé á máa mú ọ̀pọ̀ yanturu irè tí aráyé kò tíì rírú rẹ̀ rí jáde. (Aísáyà 35:1-7) Nígbà tí Jésù Kristi, ẹni tó jẹ́ Alákòóso tí Ọlọ́run ti yàn fún Ìjọba yìí wà lórí ilẹ̀ ayé, ó fi hàn pé òun lágbára láti kápá ìjì, ọ̀dá àtàwọn ohun mìíràn tó máa ń ṣàkóbá fún iṣẹ́ àgbẹ̀. (Máàkù 4:37-41) Sáàmù kejìléláàádọ́rin sọ bí ipò nǹkan ṣe máa rí nígbà tó bá bẹ̀rẹ̀ sí lo agbára rẹ̀ láti mú ayé àtàwọn ohun tó wà nínú rẹ̀ bọ̀ sípò. Ó fi dá wa lójú pé: “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀; àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà ní orí àwọn òkè ńlá. Èso rẹ̀ yóò rí bí ti Lẹ́bánónì, àwọn èyí tí ó sì ti inú ìlú ńlá wá yóò yọ ìtànná bí ewéko ilẹ̀.” (Sáàmù 72:16) Àwọn irè tó pọ̀ débi pé a ò rírú rẹ̀ rí, téèyàn á fi tayọ̀tayọ̀ kó, ló ń dúró de àwọn èèyàn Ọlọ́run nínú ayé tuntun tó ṣèlérí rẹ̀ náà.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 9]

“Ẹ̀kọ́ kan tó nira tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àgbẹ̀ ti kọ́ ni pé iṣẹ́ ńlá kọ́ lowó ńlá”

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Bíbìkítà fún ìdílé nípa ti ìmí ẹ̀dùn àti nípa tẹ̀mí lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fara da ipò wọn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Lábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run, ilẹ̀ ayé yóò máa mú oúnjẹ jáde lọ́pọ̀ yanturu

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 9]

Garo Nalbandian