Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìṣòro Tó Ń kojú Àwọn Àgbẹ̀

Ìṣòro Tó Ń kojú Àwọn Àgbẹ̀

Ìṣòro Tó Ń kojú Àwọn Àgbẹ̀

ILẸ̀ táwọn baba ńlá Richard ti fi dáko ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn ni òun náà fi ń dáko. Àmọ́, lọ́dún 2001, ọkùnrin àgbẹ̀ tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Kánádà yìí lẹni àkọ́kọ́ nínú ìdílé wọn tí kò rí nǹkan kan mú jáde nínú oko yìí. Ọ̀dá kan tó dá ló ba àwọn irè oko rẹ̀ jẹ́. Owó irè oko tó lọ sílẹ̀ lọ́dún tó ṣáájú àti owó táwọn àgbẹ̀ ń ná lórí iṣẹ́ àgbẹ̀, èyí tó túbọ̀ ń ga sí i, wà lára ohun tó tún dá kún ìṣòro rẹ̀. Richard figbe bọnu pé: “Ńṣe ni ìṣòro náà ń fẹjú sí i, kò sì sí ọ̀nà àbáyọ kankan.”

Lágbègbè tí wọ́n ti ń ṣọ̀gbìn àgbàdo gan-an lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, Larry ní oko kan tó ti jẹ́ ti ìdílé rẹ̀ láti ọdún márùndínlọ́gọ́fà sẹ́yìn. Ó sọ pé: “Èrò mi ni pé ó ti di ẹrù iṣẹ́ tèmi náà láti máa rí i pé oko náà ń pawó wọlé . . . , àmọ́ kò ṣeé ṣe fún mi rárá.” Larry àti ìyàwó rẹ̀ pàdánù oko wọn yìí ni.

Larry àti Richard nìkan kọ́ làgbẹ̀ tó ń dojú kọ ìṣòro o. Nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, nígbà tí àrùn tó ń mú màlúù lẹ́nu àti kókósẹ̀ bẹ́ sílẹ̀ láwọn oko tí wọ́n ti ń sin ẹran, ẹ̀dùn ọkàn kékeré kọ́ lèyí kó bá àwọn àgbẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni gbèsè tí wọ́n bá ara wọn nínú ẹ̀ kúrò ní díẹ̀. Ìròyìn kan sọ pé: “Inú fu àyà fu ni àwọn àgbẹ̀ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì máa ń wà lójoojúmọ́, kódà láwọn ibi tí àìsàn náà kò tíì tàn dé pàápàá. Ńṣe ni wọ́n máa ń fẹ́ dá wà, tí wọ́n á sì máa ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe láti rí owó àwọn tí wọ́n jẹ ní gbèsè san.” Láwọn orílẹ̀-èdè kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, ogun, ọ̀dá, pípọ̀ tí iye èèyàn ń yára pọ̀ sí i àti onírúurú àwọn ìṣòro mìíràn kò jẹ́ kí wàhálà àwọn àgbẹ̀ yọ rárá. Ó ti wá di dandan fún àwọn ìjọba ilẹ̀ wọ̀nyí láti máa ra oúnjẹ wọlé láti orílẹ̀-èdè mìíràn, oúnjẹ tó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìdílé ni agbára wọn kò ká a láti rà.

Nípa bẹ́ẹ̀, ìṣòro àwọn àgbẹ̀ délé ó dóko. Síbẹ̀, ìwọ̀nba díẹ̀ lára àwọn tó ń gbé nígboro ló ń ronú nípa ohun tójú àwọn àgbẹ̀ ń rí. Ó ń lọ sí bí àádọ́ta ọdún báyìí tí Ààrẹ Dwight D. Eisenhower ti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, sọ láìfọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀ pé: “Bó bá jẹ́ gègé ìkọ̀wé ni ọkọ́ àti àdá rẹ, tóò sì gbé nítòsí oko àgbàdo, iṣẹ́ àgbẹ̀ á rọrùn gan-an lójú rẹ.” Àwọn àgbẹ̀ òde òní náà gbà pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn, pé ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ni kò mọ̀ nípa iṣẹ́ àgbẹ̀ àti ipa pàtàkì táwọn àgbẹ̀ ń kó. Àgbẹ̀ kan ní orílẹ̀-èdè Kánádà dárò pé: “Àwọn èèyàn ò fẹ́ mọ̀ nípa ibi tí oúnjẹ tí à ń jẹ ti ń wá. Kí oúnjẹ tó di èyí tí wọ́n dì sínú ọ̀rá kó sì tó dé orí àtẹ ní ṣọ́ọ̀bù, àìmọye èèyàn ló ti máa ṣiṣẹ́ lórí rẹ̀.”

Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé iṣẹ́ àgbẹ̀ ni gbogbo wa gbára lé, a ò lè dágunlá sí ìṣòro tó ń kojú àwọn àgbẹ̀. Àwọn onímọ̀ nípa ìbágbépọ̀ ẹ̀dá méjì, Don A. Dillman àti Daryl J. Hobbs kìlọ̀ pé: “Láyé òde òní, kíákíá ni ohun tó bá kan ará oko máa ń kan ará ilé tí ohun tó bá kan ará ilé sì máa ń kan ará oko. Àti ilé o, àti oko o, kò sí ọ̀kankan tó lè ní ìlọsíwájú kan lọ títí bí ọ̀kan yòókù bá ń lálàṣí.” Bákan náà, nínú ayé tó ti lu jára lónìí, bí ọrọ̀ ajé bá dẹnu kọlẹ̀ lórílẹ̀-èdè kan, èyí lè ṣàkóbá ńlá fún iye tí wọ́n ń ta irè oko àti iye táwọn àgbẹ̀ á ná lórí iṣẹ́ oko ní orílẹ̀-èdè mìíràn.

Abájọ tí Ibùdó Ìtọ́jú Nǹkan Ọ̀gbìn àti Ẹran Ọ̀sìn ní ìlú New York fi ròyìn pé: “Iṣẹ́ àgbẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára iṣẹ́ mẹ́wàá tó ń dáni lágara jù lọ ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.” Kí ni díẹ̀ lára ohun tó ń fa ìṣòro tó ń kojú àwọn àgbẹ̀? Ọ̀nà wo làwọn àgbẹ̀ lè gbà kojú àwọn ìṣòro wọ̀nyí? Ǹjẹ́ ìdí kankan wà láti gbà gbọ́ pé àwọn ìṣòro náà á níyanjú?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]

“Bó bá jẹ́ gègé ìkọ̀wé ni ọkọ́ àti àdá rẹ̀, tóò sì gbé nítòsí oko àgbàdo, iṣẹ́ àgbẹ̀ á rọrùn gan-an lójú rẹ”