Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ọdún Bíbélì”

“Ọdún Bíbélì”

“Ọdún Bíbélì”

Ní orílẹ̀-èdè Austria, ilẹ̀ Faransé, ilẹ̀ Jámánì àti orílẹ̀-èdè Switzerland, wọ́n ti sàmì sí ọdún 2003 gẹ́gẹ́ bí “Ọdún Bíbélì.” Ìwé ìròyìn ilẹ̀ Jámánì náà Frankfurter Allgemeine Zeitung sọ pé: “Bíi ti ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n ṣayẹyẹ Ọdún Bíbélì lọ́dún 1992 tó sì tún jẹ́ ìgbà tí wọ́n ṣe é kẹ́yìn, ìdí tí [àwọn ṣọ́ọ̀ṣì] fi ń ṣe ètò yìí jẹ́ nítorí àtilè mú kí àwọn èèyàn túbọ̀ mọ̀ nípa ‘ìwé ìyè’ yìí, àti láti túbọ̀ mú kí wọ́n rí bí Ìwé Mímọ́ ṣe wúlò tó nínú ìgbésí ayé wọn.”

Ìwé Bibelreport ti June 2002 ròyìn pé, wọ́n ti tú Bíbélì sí ọgbọ̀kànlá àti mẹ́tàdínláàádọ́rùn-ún [2,287] èdè—ó kéré tán lápá kan. Bákan náà, wọ́n fojú bù ú pé títí di àkókò yìí, nǹkan bíi bílíọ̀nù márùn-ún ẹ̀dà Bíbélì ni wọ́n ti pín kiri. Irú ìsapá ńláǹlà bẹ́ẹ̀ fi hàn kedere pé àwọn èèyàn ò kóyán ìwé yìí kéré.

Lóde òní, ọ̀pọ̀ èèyàn lè máà gbà pé Bíbélì wúlò. Àní, ńṣe ni ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń wò ó pé àwọn ìlànà inú Bíbélì kò bágbà mu, kò sì bá àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ nínú ayé mu. Àmọ́ o, ohun pàtàkì méjì ló ń sún àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ilẹ̀ Jámánì láti máa sàmì sí àwọn ọdún kan gẹ́gẹ́ bí Ọdún Bíbélì. Àkọ́kọ́, láti fún àwọn èèyàn níṣìírí láti túbọ̀ máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì nínú ìgbésí ayé wọn, àti èkejì, láti ta ìfẹ́ fún Bíbélì jí lọ́kàn àwọn tó ti pa ṣọ́ọ̀ṣì tì.

Kíka Bíbélì láti ìbẹ̀rẹ̀ dópin kì í ṣe iṣẹ́ kékeré o, àmọ́ kò sí àní-àní pé ó jẹ́ ọ̀nà dáradára kan láti lóye àwọn kókó pàtàkì inú Ìwé Mímọ́. Bó ti wù kó rí, ó yẹ kí ẹni tó bá fẹ́ jàǹfààní lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ látinú Bíbélì máa fi ọ̀rọ̀ tó wà nínú 2 Tímótì 3:16, 17 sọ́kàn, èyí tó kà pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo, kí ènìyàn Ọlọ́run lè pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.”

Akéwì ọmọ ilẹ̀ Jámánì nì, Johann Wolfgang von Goethe (1749-1832) sọ pé: “Ó dá mi lójú pé béèyàn bá ṣe ń lóye Bíbélì sí i bẹ́ẹ̀ náà ni yóò túbọ̀ máa gbádùn mọ́ ọn.” Ní tòótọ́, inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nìkan la ti lè rí àlàyé tó mọ́gbọ́n dání nípa ibi tí àwa ẹ̀dá ènìyàn ti ṣẹ̀ wá, ìdí tí Ọlọ́run fi dá wa sí ilẹ̀ ayé àti ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wa ní ọjọ́ ọ̀la!—Aísáyà 46:9, 10.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 29]

Látinú ìwé Bildersaal deutscher Geschichte