Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Gbígbé Ìgbésí Ayé Tó Yàtọ̀ Sí Ti Ẹ̀dá—Ǹjẹ́ Ọlọ́run Fọwọ́ Sí I?

Gbígbé Ìgbésí Ayé Tó Yàtọ̀ Sí Ti Ẹ̀dá—Ǹjẹ́ Ọlọ́run Fọwọ́ Sí I?

Ojú Ìwòye Bíbélì

Gbígbé Ìgbésí Ayé Tó Yàtọ̀ Sí Ti Ẹ̀dá—Ǹjẹ́ Ọlọ́run Fọwọ́ Sí I?

“ÌGBÀ wo ni màá tó mọ irú ẹni tí màá máa bá ní ìbálòpọ̀, ṣé ọkùnrin ni tàbí obìnrin?” Ohun tí ọ̀dọ́mọbìnrin ọmọ ọdún mẹ́tàlá kan kọ ránṣẹ́ sí abala tí wọ́n ti ń fún àwọn ọ̀dọ́langba nímọ̀ràn nínú ìwé ìròyìn kan nìyẹn. Ìbéèrè rẹ̀ yìí ṣàgbéyọ èrò ọ̀pọ̀ àwọn tó gbà pé kálukú lómìnira láti lọ́wọ́ sí ìbálòpọ̀ èyíkéyìí tó bá wù ú.

Kò sí iyèméjì pé àwọn èèyàn kan wà tí ìdààmú lè máa bá nítorí èrò oríṣiríṣi nípa ìbálòpọ̀ tó máa ń dìde nínú ọkàn wọn. Àwọn mìíràn kò fi tiwọn bò, ńṣe ni wọ́n ń gbé ìgbésí ayé tó yàtọ̀ sí ti ẹ̀dá, irú bí ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀. Àwọn kan tiẹ̀ láyà débi pé wọ́n ń hùwà wọ́n sì ń múra bí ẹ̀yà òdìkejì, kódà àwọn kan ń ṣe iṣẹ́ abẹ láti fi yí ẹ̀yà ẹ̀dá wọn padà. Àwọn kan sì wà tí wọ́n ń ṣe awuyewuye pé ó yẹ kí wọ́n fàyè gba àwọn àgbàlagbà láti máa ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọdé.

Ṣé lóòótọ́ lẹnì kọ̀ọ̀kan lómìnira láti yan irú ìbálòpọ̀ tó bá wù ú tàbí kẹ̀ kí ọkùnrin sọ ara rẹ̀ di obìnrin tàbí kí obìnrin sọ ara rẹ̀ di ọkùnrin? Kí ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní í sọ lórí àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí?

“Akọ àti Abo Ni Ó Dá Wọn”

Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwé Jẹ́nẹ́sísì nínú Bíbélì sọ, Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló dá àwọn ìyàtọ̀ tó wà láàárín ọkùnrin àti obìnrin. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí dá ènìyàn ní àwòrán rẹ̀ . . . Akọ àti abo ni ó dá wọn. Síwájú sí i, Ọlọ́run súre fún wọn, Ọlọ́run sì wí fún wọn pé: ‘Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀.’”—Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28.

Ọlọ́run dá òmìnira láti ṣe ohun tó wù wọ́n mọ́ ẹ̀dá èèyàn ó sì fún wọn láǹfààní láti gbádùn òmìnira ọ̀hún. (Sáàmù 115:16) Yàtọ̀ sí pé Ọlọ́run gbé ẹrù iṣẹ́ bíbójú tó gbogbo ẹ̀dá alààyè tó kù lórí ilẹ̀ ayé pátá lé èèyàn lọ́wọ́, ó tiẹ̀ tún fún èèyàn láyè láti fún wọn ní orúkọ tó bá tọ́ lójú rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 2:19) Àmọ́ ṣá o, nínú ọ̀ràn ìbálòpọ̀, Ọlọ́run pèsè àwọn ìtọ́sọ́nà tó ṣe pàtó.—Jẹ́nẹ́sísì 2:24.

Nítorí àìgbọ́ràn Ádámù, gbogbo wa pátá la ti jogún àìpé. Nípa bẹ́ẹ̀, ó di dandan ká máa bá àwọn àìlera ẹran ara àtàwọn ìfẹ́ ọkàn lílágbára tí kò bá ète Ọlọ́run mu, èyí tó máa ń dìde nígbà gbogbo nínú wa wọ̀yá ìjà. Fún ìdí yìí, nínú àwọn òfin tí Ọlọ́run pèsè nípasẹ̀ Mósè, ó la àwọn ìbálòpọ̀ tó jẹ́ ìríra fún un lẹ́sẹẹsẹ, àwọn bíi panṣágà, ìbálòpọ̀ láàárín ìbátan, bíbá ẹ̀yà kan náà lòpọ̀ àti bíbá ẹranko lòpọ̀. (Léfítíkù 18:6-23) Ọlọ́run tún dìídì ka fífi ara ẹni hàn lọ́nà téèyàn á fi jọ ẹ̀yà kejì nítorí ìṣekúṣe léèwọ̀. (Diutarónómì 22:5) Lemọ́lemọ́ ni Bíbélì fi ń kọ́ni pé ìbálòpọ̀ kan ṣoṣo tí Ọlọ́run fọwọ́ sí ni èyí tó ń wáyé láàárín ọkùnrin àti obìnrin táwọn méjèèjì jọ ṣègbéyàwó. (Jẹ́nẹ́sísì 20:1-5, 14; 39:7-9; Òwe 5:15-19; Hébérù 13:4) Ǹjẹ́ irú àwọn ìlànà wọ̀nyí tiẹ̀ bọ́gbọ́n mu?

Ṣé Kálukú Lè Yan Ohun Tó Fẹ́?

Bíbélì fi bí èèyàn ṣe rí lọ́wọ́ Ẹlẹ́dàá rẹ̀ wé amọ̀ lọ́wọ́ amọ̀kòkò. Ó sọ pé: “Ìwọ ènìyàn, ta wá ni ọ́ ní ti gidi, tí o fi ń ṣú Ọlọ́run lóhùn? Ǹjẹ́ ohun tí a mọ yóò ha sọ fún ẹni tí ó mọ ọ́n pé, ‘Èé ṣe tí o fi ṣe mí lọ́nà yìí?’” (Róòmù 9:20) Ó hàn gbangba látinú ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà dá ọkùnrin àti obìnrin pé ó bá ìwà ẹ̀dá mu pé kí wọ́n ní òòfà ìbálòpọ̀ sí ara wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, níní òòfà ìbálòpọ̀ sí ẹnì kan tó jẹ́ ẹ̀yà kan náà bíi tẹni, sí ẹranko, tàbí sí ọmọ kékeré ta ko ìṣètò Ẹlẹ́dàá.—Róòmù 1:26, 27, 32.

Fún ìdí yìí, ńṣe làwọn tó bá ń lọ́wọ́ nínú irú àwọn ìbálòpọ̀ tí kò bá ìṣètò Ọlọ́run mu yìí ń gbéjà ko Ọlọ́run. Ìkìlọ̀ kan rèé tó wà nínú Bíbélì: “Ègbé ni fún ẹni tí ń bá Aṣẹ̀dá rẹ̀ fà á, gẹ́gẹ́ bí àpáàdì kan pẹ̀lú àwọn àpáàdì mìíràn lórí ilẹ̀! Ǹjẹ́ ó yẹ kí amọ̀ sọ fún ẹni tí ó mọ ọ́n pé: ‘Kí ni ìwọ ṣe?’” (Aísáyà 45:9) Dájúdájú ó bọ́gbọ́n mu pé kí Ẹlẹ́dàá èèyàn pèsè ìtọ́ni lórí àwọn ọ̀ràn tó jẹ mọ́ ìbálòpọ̀. Ǹjẹ́ kò bọ́gbọ́n mu pé kí àwọn èèyàn pẹ̀lú tẹ̀ lé irú ìtọ́ni bẹ́ẹ̀?

Bí Kálukú Ṣe Lè Ṣèkáwọ́ Ohun Èlò Rẹ̀

Irú àpèjúwe yìí kan náà ni òǹkọ̀wé Bíbélì náà, Pọ́ọ̀lù lò, nígbà tó ń fún àwọn Kristẹni ní ìtọ́sọ́nà lórí ọ̀ràn ìbálòpọ̀. Ó sọ pé: “Kí olúkúlùkù yín mọ bí yóò ti ṣèkáwọ́ ohun èlò tirẹ̀ nínú ìsọdimímọ́ àti ọlá, kì í ṣe nínú ìdálọ́rùn olójúkòkòrò fún ìbálòpọ̀ takọtabo.” (1 Tẹsalóníkà 4:4, 5) Pọ́ọ̀lù fi ara èèyàn wé ohun èlò. Ṣíṣèkáwọ́ ohun èlò yẹn túmọ̀ sí mímú kí èrò ọkàn ẹni àtàwọn ìfẹ́ ọkàn ẹni wà níbàámu pẹ̀lú àwọn òfin Ọlọ́run lórí ìwà rere.

Lóòótọ́, èyí lè má rọrùn. A sì lè lóye ìdí tí ẹnì kan á fi ní ìṣòro tí wọ́n bá ti fi ìbálòpọ̀ fìtínà rẹ̀ nígbà tó wà lọ́mọdé tàbí tó ní àwọn òbí tàbí alágbàtọ́ mìíràn tí wọ́n fi àpẹẹrẹ búburú lélẹ̀ nípa jíjẹ́ ọkùnrin tàbí jíjẹ́ obìnrin, tàbí tó bá ti máa ń wo àwòrán ìṣekúṣe látìgbà tó ti wà lọ́mọdé. Àwọn nǹkan tó ní í ṣe pẹ̀lú apilẹ̀ àbùdá, omi ara tó máa ń súnni ṣe nǹkan àti ìrònú òun ìhùwà ẹnì kan tún lè kópa nínú mímú kí ẹni náà máa ní èrò tó lòdì nípa ìbálòpọ̀. Àmọ́, ohun ìtùnú ló jẹ́ láti mọ̀ pé Ẹlẹ́dàá wa lè pèsè ìrànwọ́ kó sì ṣètìlẹ́yìn fún àwọn tó nílò rẹ̀.—Sáàmù 33:20; Hébérù 4:16.

Jẹ́ Kí Amọ̀kòkò Títóbi Jù Lọ Náà Mọ Ọ́

Amọ̀kòkò máa ń kọ́kọ́ bu amọ̀ tútù sọ́wọ́ yóò sì wá bẹ̀rẹ̀ sí mọ̀ ọ́n títí yóò fi rí bó ṣe ń fẹ́. Bí amọ̀kòkò náà ṣe ń mọ ọ́n lọ, yóò máa fi àwọn ìka rẹ̀ dán ara ìkòkò náà ní pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ títí tí yóò fi rí bó ṣe ń fẹ́. Ká tó lè di ẹni tí Ọlọ́run mọ títí tí a óò fi di ẹni yíyẹ lójú rẹ̀, a gbọ́dọ̀ máa gbé níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà àti òfin rẹ̀ tí kì í yí padà. Gbàrà tá a bá ti bẹ̀rẹ̀ sí sa ipá wa, Ọlọ́run á wá máa fi ìfẹ́ mọ wá pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ nípasẹ̀ Bíbélì, ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ àti ẹgbẹ́ àwọn ará tó jẹ́ Kristẹni. Nígbà náà, èèyàn á wá bẹ̀rẹ̀ sí rí àbójútó Ọlọ́run fúnra rẹ̀ nínú ìgbésí ayé rẹ̀.

Àmọ́ ṣá o, a gbọ́dọ̀ ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ọgbọ́n Ẹlẹ́dàá ká sì gbà dájúdájú pé ó mọ ohun tó dára fún wa. Nípasẹ̀ àdúrà àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì aláápọn lèèyàn fi máa ń ní irú ìgbọ́kànlé yìí. Bí ẹnì kan bá fi ìgbọ́kànlé nínú Ọlọ́run kojú ìṣòro èrò ìṣekúṣe tó ń wá sí i lọ́kàn, yóò di ẹni tó ṣe é mọ lọ́wọ́ Ẹlẹ́dàá. Ìwé 1 Pétérù 5:6, 7 sọ pé: “Nítorí náà, ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára ńlá Ọlọ́run, kí ó lè gbé yín ga ní àkókò yíyẹ; bí ẹ ti ń kó gbogbo àníyàn yín lé e, nítorí ó bìkítà fún yín.”

Kíka Bíbélì déédéé ń jẹ́ ká mọ̀ nípa ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ olóòótọ́ Ọlọ́run tí wọ́n gbógun ti àwọn ìfẹ́ ọkàn ẹran ara àmọ́ tí wọn ò juwọ́ sílẹ̀. Irú àwọn àpẹẹrẹ báwọ̀nyí mà ń fúnni níṣìírí o! A lè finú wòye ìjákulẹ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní pẹ̀lú ara rẹ̀ nígbà tó kígbe jáde pé: “Èmi abòṣì ènìyàn! Ta ni yóò gbà mí lọ́wọ́ ara tí ń kú ikú yìí?” Síbẹ̀, ó tún darí wa sí ibi tí a ti lè dìídì rí ìrànlọ́wọ́ gbà nígbà tó fúnra rẹ̀ dáhùn ìbéèrè ara rẹ̀ pé: “Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi Olúwa wa!”—Róòmù 7:24, 25.

Ohun Kan Tó Lè Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Yí Padà

A tún lè rí ìrànlọ́wọ́ gbà nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run. Èyí jẹ́ ohun alágbára kan tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti yí padà. Ẹ̀mí mímọ́ lè ràn wá lọ́wọ́ láti “bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀” kí a sì “gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin.” (Éfésù 4:22-24) Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ kì í kùnà láé láti dáhùn nígbà tí a bá fi tọkàntọkàn béèrè fún ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ìyípadà yìí. Jésù fi dá wa lójú pé Bàbá yóò “fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!” (Lúùkù 11:13) Àmọ́, gbígbàdúrà lemọ́lemọ́ ṣe pàtàkì o, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ ti fi hàn, èyí tó sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní bíbéèrè, a ó sì fi í fún yín.” (Mátíù 7:7) Èyí túbọ̀ ṣe pàtàkì gan-an nígbà tí ẹnì kan bá ń tiraka láti kápá ìfẹ́ lílágbára fún ìbálòpọ̀.

Ọlọ́run tún máa ń ràn wá lọ́wọ́ nípasẹ̀ ojúlówó ẹgbẹ́ àwọn ará, èyí tó ní onírúurú èèyàn nínú. Àwọn Kristẹni kan nínú ìjọ Kọ́ríńtì ti ọ̀rúndún kìíní náà ti jẹ́ irú “àwọn ọkùnrin tí a pa mọ́ fún àwọn ète tí ó lòdì sí ti ẹ̀dá” àtàwọn “ọkùnrin tí ń bá ọkùnrin dà pọ̀” nígbà kan rí. Síbẹ̀, wọ́n yí padà. Ẹ̀jẹ̀ Kristi wẹ̀ wọ́n mọ́, wọ́n sì di ẹni ìtẹ́wọ́gbà lójú Ọlọ́run. (1 Kọ́ríńtì 6:9-11) Ó pọn dandan kí àwọn kan lónìí ṣe irú àwọn ìyípadà bẹ́ẹ̀. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ sì lè rí ìtìlẹ́yìn gbà nínú ìjọ Kristẹni bí wọ́n ti ń sapá láti gbógun ti èrò tí kò tọ́.

Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé dídi Kristẹni á ṣàdéédéé mú gbogbo èròkérò àti èrò òdì nípa irú ẹ̀yà tẹ́nì kan fẹ́ láti jẹ́ kúrò lọ́kàn ni? Kò fi dandan jẹ́ bẹ́ẹ̀. Fífi àwọn ìlànà Bíbélì sílò nígbà gbogbo ti mú kó ṣeé ṣe fún àwọn kan láti máa gbé ìgbésí ayé tó bójú mu. Síbẹ̀, lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn Kristẹni wọ̀nyí ní láti máa ja ìjàkadì ojoojúmọ́ pẹ̀lú àwọn èrò tó lòdì. Nípa bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ láti máa sin Ọlọ́run bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ní ‘ẹ̀gún ìṣàpẹẹrẹ nínú ẹran ara’ wọn. (2 Kọ́ríńtì 12:7) Níwọ̀n ìgbà tí wọn ò bá jáwọ́ láti máa mú àwọn èrò tí kò tọ́ kúrò lọ́kàn tí wọ́n sì ń bá a nìṣó láti máa hùwà òdodo, Ọlọ́run kà wọ́n sí ìránṣẹ́ olóòótọ́ àti ẹni tó mọ́ lójú rẹ̀. Wọ́n lè máa wọ̀nà de àkókó náà nígbà tí gbogbo ìran èèyàn yóò di ẹni tí a “dá . . . sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́, [tí wọn] yóò sì ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.”—Róòmù 8:21.

Ní báyìí ná, gbogbo àwọn tó bá fẹ́ mú inú Ọlọ́run dùn gbọ́dọ̀ máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà òdodo rẹ̀. Àwọn Kristẹni tòótọ́ yàn láti sin Ọlọ́run kì í ṣe láti máa tẹ̀ lé àwọn èrò onímọtara-ẹni-nìkan tó lè máa wá sọ́kàn wọn. Àwọn tó bá fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run nínú gbogbo apá ìgbésí ayé wọn yóò di ẹni tí Ọlọ́run fi ayọ̀ àti ìdùnnú ayérayé jíǹkí.—Sáàmù 128:1; Jòhánù 17:3.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 26]

Ọlọ́run pèsè àwọn ìtọ́sọ́nà tó ṣe pàtó lórí ọ̀ràn ìbálòpọ̀

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 26]

Àwọn Kristẹni kan nínú ìjọ Kọ́ríńtì ti ọ̀rúndún kìíní náà ti jẹ́ irú “àwọn ọkùnrin tí a pa mọ́ fún àwọn ète tí ó lòdì sí ti ẹ̀dá” àtàwọn “ọkùnrin tí ń bá ọkùnrin dà pọ̀” nígbà kan rí. Síbẹ̀, wọ́n yí padà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ń ranni lọ́wọ́ láti ní àwọn ìlànà ìwà rere tó ga