Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ló Ń fa Ìṣòro Tó Ń kojú Àwọn Àgbẹ̀?

Kí Ló Ń fa Ìṣòro Tó Ń kojú Àwọn Àgbẹ̀?

Kí Ló Ń fa Ìṣòro Tó Ń kojú Àwọn Àgbẹ̀?

“A ti dá àwọn òṣìṣẹ́ wa tó ń dáhùn ìbéèrè lórí Ètò Orí Tẹlifóònù Nípa Ìṣòro Àwọn Àgbẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ láti ràn yín lọ́wọ́ kẹ́ ẹ lò kojú àwọn ìṣòro yín. Àgbẹ̀ bíi ti yín ni wá, àwọn kan lára wa sì ti ṣàgbẹ̀ rí, a sì lóye àwọn ìnira tó ń kojú àwọn ìdílé tó ń gbé àrọko. A lè darí yín sọ́dọ̀ àwọn tó lè ràn yín lọ́wọ́. . . . A ò ní jẹ́ kí etí mìíràn gbọ́ ohun tí ẹ bá báwa sọ o.”—Ọ̀rọ̀ yìí wá láti ibi tí ìjọba ilẹ̀ Kánádà ń kó ìsọfúnni sí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.

Ọ̀PỌ̀ àwọn onímọ̀ nípa ìlera ló ti wá mọ̀ báyìí pé iṣẹ́ àgbẹ̀ ń fa másùnmáwo. Láti lè ran àwọn àgbẹ̀ lọ́wọ́ láti kojú ipò yìí, àwọn afìṣemọ̀rònú tó mọ̀ nípa másùnmáwo tó wà nídìí iṣẹ́ àgbẹ̀ wà tí wọ́n ń ṣe àwọn ètò bíi mímú kí àwọn àgbẹ̀ kóra jọ pọ̀ láti jíròrò ìṣòro wọn kí wọ́n sì ṣètìlẹ́yìn fún ara wọn. Bákan náà, ètò orí tẹlifóònù tún wà fún àwọn àgbẹ̀ tó ń dojú kọ másùnmáwo.

Ìyàwó àgbẹ̀ kan tó ń jẹ́ Jane máa ń wá sí ìpàdé kan tí wọ́n máa ń ṣe lálaalẹ́ ọjọ́ Thursday láti gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn. Jane ṣàlàyé pé: “Ohun tó gbé mi wá ni pé ọkọ mi fọwọ́ ara rẹ̀ pa ara rẹ̀. Ó wù ú lọ́kàn pé kó máa dá oko ìdílé wọn lọ, mo sì rò pé ìgbà tí ìyẹn ò ti ṣeé ṣe, kò sí nǹkan mìíràn tó fẹ́ ṣe mọ́.”

Ọ̀pọ̀ ti ṣàkíyèsí pé ńṣe ni iye àwọn àgbẹ̀ tó ń wá ìtura nítorí másùnmáwo ń pọ̀ sí i. Àmọ́, kí ló tiẹ̀ ń fa àwọn ìṣòro tó ń dojú kọ ọ̀pọ̀ àgbẹ̀ ná?

Àwọn Ìṣòro Tí Ipò Ojú Ọjọ́ àti Kòkòrò Ń Fà

Níbi tí ìjọba ilẹ̀ Kánádà ń kó ìsọfúnni sí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tá a fa ọ̀rọ̀ yọ nínú rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀, a kà pé: “Ní ti ọ̀ràn iṣẹ́ oko dídá, ọ̀pọ̀ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nídìí iṣẹ́ náà lójoojúmọ́ ni oò lè ṣe ohunkóhun sí, àwọn nǹkan bí ipò ojú ọjọ́, iye táwọn oníbàárà máa ra irè oko lọ́jà, èlé orí owó tó o yá àti kí irinṣẹ́ dẹnu kọlẹ̀. Kódà, mímọ èyí téèyàn ì bá ṣe láàárín irú irè oko wo ló yẹ kéèyàn gbìn tàbí bóyá kéèyàn ta ilẹ̀ tó fi ń dáko àti bóyá kéèyàn gbé e fún ẹni tó jẹ lówó lè fa másùnmáwo, níwọ̀n bí àbájáde ìpinnu yìí ti lè dára tàbí kó burú.” Nígbà táwọn ohun wọ̀nyí bá tún wá dá kún ìbẹ̀rù ọ̀dá líle koko, kòkòrò ajokorun tàbí pípàdánù oko ẹni, másùnmáwo náà lè kọjá sísọ.

Bí àpẹẹrẹ, bí ọ̀dá bá dá, àkóbá méjì ló lè ṣe. Àgbẹ̀ kan tó ń jẹ́ Howard Paulsen ṣàlàyé pé ọ̀dá tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 2001, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀dá tó tíì burú jù lọ nínú ìtàn ilẹ̀ Kánádà, ṣàkóbá fún àwọn irè oko òun àtàwọn ẹran ọ̀sìn òun. Nígbà tí àwọn ẹran kò bá rí koríko láti jẹ tàbí tí àwọn àgbẹ̀ kò rí irè oko kórè, ó di dandan kí àwọn àgbẹ̀ lọ máa ra oúnjẹ tí wọ́n á fi bọ́ wọn. Ó sọ pé: “Mo ti ná ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá dọ́là lórí ríra oúnjẹ ẹran ọ̀sìn, oúnjẹ tó sì yẹ kí wọ́n jẹ lákòókò òtútù ni mo fi ń bọ́ wọn báyìí. Nígbà tó o bá sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìyẹn, oò lè rí èrè kankan jẹ lórí àwọn ẹran ọ̀sìn náà.” Láwọn àgbègbè mìíràn, àpọ̀jù òjò ti ba ọ̀pọ̀lọpọ̀ oko jẹ́, tí àwọn àgbẹ̀ kò sì rí ohunkóhun kórè níbẹ̀.

Nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ọ̀kan péré ni àrùn tí ń mú màlúù lẹ́nu àti kókósẹ̀ tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 2001 wulẹ̀ jẹ́ lára onírúuru ìṣòro táwọn àgbẹ̀ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ń kojú lákòókò náà, bákan náà ni àrùn dìgbòlugi tó ń ṣe màlúù àti àrùn tó ń ṣe ẹlẹ́dẹ̀ tún wà níbẹ̀. Kì í ṣe gbèsè nìkan làwọn àrùn wọ̀nyí àti ìbẹ̀rù tí wọ́n ń dá sílẹ̀ ń kó àwọn èèyàn sí o. Ìwé ìròyìn kan tó ń jẹ́ Agence France-Presse sọ pé: “Àwọn àgbẹ̀ tó lọ́kàn, tí wọn kì í tètè yọmi lójú pàápàá sunkún bí wọ́n ti ń rí i tí àwọn dókítà ìjọba tó ń tọ́jú ẹranko ń rọ́ àwọn ẹran ọ̀sìn wọn tí wọ́n ti fi gbogbo ọjọ́ ayé wọn tọ́jú dà sínú iná tí wọ́n sì ń sun wọ́n.” Lẹ́yìn tí àrùn tí ń mú màlúù lẹ́nu àti kókósẹ̀ náà bẹ́ sílẹ̀, ńṣe làwọn ọlọ́pàá lọ ń gba ìbọn lọ́wọ́ àwọn àgbẹ̀ tó ṣeé ṣe kí wọ́n gbẹ̀mí ara wọn. Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn àgbẹ̀ tí ìdààmú ti bá ń pe àwọn òṣìṣẹ́ tó ń gbani nímọ̀ràn lápègbà lórí tẹlifóònù.

Ọrọ̀ Ajé Tí Kò Fara Rọ

Ìyípadà ńlá kò ṣàì bá ètò ọrọ̀ ajé gbogbo gbòò pàápàá. Ohun tí èèpo ẹ̀yìn ìwé Broken Heartland sọ ni pé: “Láàárín ọdún 1940 sí agbedeméjì àwọn ọdún 1980, láwọn ibi tí wọ́n ti ń fi oko dídá ṣiṣẹ́ ṣe pẹrẹu ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà, iye tí wọ́n ń ná lórí iṣẹ́ oko wọ ìlọ́po mẹ́ta, owó tí wọ́n fi ń ra àwọn nǹkan èèlò iṣẹ́ oko náà di ìlọ́po mẹ́rin, èlé tí wọ́n ń san lórí owó fò fẹ̀rẹ̀ di ìlọ́po mẹ́wàá, èrè tó ń wọlé fi ìdá mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn-ún já wá sílẹ̀, ìdá méjì nínú mẹ́ta àwọn àgbẹ̀ fi iṣẹ́ oko sílẹ̀, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí àgbègbè kan táwọn àgbẹ̀ wà tí àwọn èèyàn àti onírúurú iṣẹ́ ò ti dín kù, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ ajé kò fara rọ fún wọn.”

Kí ló fà á tí èrè táwọn àgbẹ̀ ń rí kò fi kájú iye tí wọ́n ń ná àmọ́ tó jẹ́ pé ńṣe ni iye náà túbọ̀ ń lọ sókè? Nínú ayé òde òní tó ti lu jára, ètò káràkátà àgbáyé kò ṣàì kan àwọn àgbẹ̀ náà. Èyí ló mú kó di pé káwọn àgbẹ̀ máa fẹsẹ̀ wọnsẹ̀ pẹ̀lú àwọn àgbẹ̀ mìíràn táwọn náà ń mú oúnjẹ jáde láwọn orílẹ̀-èdè mìíràn tó jìnnà sí wọn. Lóòótọ́, ètò ìṣòwò láàárín orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè ti ṣí àwọn ọ̀nà tuntun tí àwọn àgbẹ̀ fi lè máa ta ọjà wọn, àmọ́ ewu tó wà níbẹ̀ ni pé ọjà àgbáyé kì í dúró sójú kan. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1998, àwọn àgbẹ̀ tó ń ṣọ̀gbìn oúnjẹ oníhóró àtàwọn tó ń sin ẹlẹ́dẹ̀ ní Kánádà wọko gbèsè nígbà tí ọrọ̀ ajé àwọn oníbàárà wọn ní Éṣíà dẹnu kọlẹ̀.

Kò Séèyàn Mọ́ Lóko

Ọ̀jọ̀gbọ́n Mike Jacobsen tó ń ṣiṣẹ́ ní Yunifásítì Iowa, ẹni tó mọ̀ nípa àwọn ọ̀ràn tó jẹ mọ́ ìgbèríko dáadáa sọ pé, kò sí bí ìṣòro á ṣe bá iṣẹ́ àgbẹ̀ tí kò ní kan àwọn tó ń gbé ní ìgbèríko. Ó sọ pé: “Ojú táwọn èèyàn fi máa ń wo ìgbèríko ni pé ó jẹ́ ibi tí àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ pọ̀ sí, tó mọ́ tónítóní, ibi téèyàn á ti fẹ́ gbéyàwó kó sì máa tọ́mọ. Tí àwọn ilé ìwé tó wà níbẹ̀ dára gan-an, tí ìwà ipá kò sì sí níbẹ̀. Ojú táwọn èèyàn fi ń wo àwọn àgbègbè ìgbèríko nìyẹn, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Àmọ́ o, oko tí àwọn ìdílé kéékèèké tó wà lágbègbè náà ń dá ni ipò ọrọ̀ ajé àwọn ìlú tó wà ní ìgbèríko wọ̀nyí sinmi lé pátápátá.” Nípa bẹ́ẹ̀, ńṣe làwọn ọsibítù, ilé ìwé, ilé oúnjẹ, àwọn ṣọ́ọ̀bù àtàwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó ti di títì pa láwọn ìgbèríko ń fi hàn pé wàhálà ńlá ló ń bá àwọn àgbẹ̀ fínra. Ọ̀kan lára àwọn nǹkan tó máa ń fani mọ́ra jù lọ nínú ìgbésí ayé oko ni bí àwọn èèyàn ṣe máa ń wà pa pọ̀ tímọ́tímọ́, èyí tó ti ń pòórá báyìí.

Kò yani lẹ́nu nígbà náà pé, gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwé ìròyìn Newsweek sọ, nǹkan bí ìdá mẹ́rìndínlógún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ará Amẹ́ríkà tó ń gbé ìgbèríko ni ìṣẹ́ ń bá fínra. Nínú ìròyìn kan tí ọ̀gbẹ́ni Geoffrey Lawrence kọ, tó pe àkọlé rẹ̀ ní “Ìṣòro Tó Ń Kojú Àwọn Àgbẹ̀ Ilẹ̀ Ọsirélíà,” ó kọ̀wé pé “àìníṣẹ́lọ́wọ́, àìrí iṣẹ́ gidi ṣe àti ipò òṣì wọ́pọ̀ gan-an láàárín àwọn tó ń gbé ní ìgbèríko ju àwọn tó ń gbé nígboro lọ.” Ipò ọrọ̀ ajé tí kò dúró sójú kan ti sọ ọ́ di dandan fún ọ̀pọ̀ ìdílé—pàápàá jù lọ àwọn ọ̀dọ́—láti ṣí lọ sí ìgboro. Sheila, tí òun àti ìdílé rẹ̀ jọ ń dáko sọ pé: “Ìgbà mélòó ló kù tá ò fi ní rí èèyàn mọ́ tó máa fẹ́ láti dáko?”

Nítorí báwọn èwe ṣe ń ya lọ sígboro, kìkìdá àwọn arúgbó ló ń kù báyìí lọ́pọ̀ ìgbèríko. Kì í ṣe pé kò sí àwọn ọ̀dọ́ tó lókun láti ṣiṣẹ́ mọ́ nìkan ni, àmọ́ kò tún sí ẹni tó máa bójú tó àwọn àgbàlagbà náà, èyí sì tún wá jẹ́ nígbà táwọn àgbàlagbà yìí nílò rẹ̀ jù lọ. Abájọ tí gbogbo rẹ̀ fi tojú sú wọn tí àwọn ìyípadà náà sì ń kó ìpayà bá wọn.

Láìsí àní-àní, àdánù ńlá ni ìṣòro tó ń kojú àwọn àgbẹ̀ yìí, kì í sì ṣe àwọn nìkan ló ń fara gbá a. Ó kan ará ilé ó kan ará oko. Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àpilẹ̀kọ wa tó tẹ̀ lé e yóò ti fi hàn, ìdí wà tá a fi lè gbà gbọ́ pé ìṣòro àwọn àgbẹ̀ yóò dópin.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]

Nínú ayé òde òní tó ti lu jára, ètò káràkátà àgbáyé ló ń pinnu iye tí àwọn àgbẹ̀ á ta ọjà wọn

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]

“Ìgbà mélòó ló kù tá ò fi ní rí èèyàn mọ́ tó máa fẹ́ láti dáko?”

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

ÀWỌN OÚNJẸ TÍ WỌN Ò FI KẸ́MÍKÀ GBÌN

Ńṣe làwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí oúnjẹ tí wọn ò fi kẹ́míkà gbìn túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Ní ilẹ̀ Kánádà, ìdá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún nínú ọgọ́rùn-ún ni iye àwọn tó ń ra oúnjẹ tí wọn ò fi kẹ́míkà gbìn fi ń pọ̀ sí i lọ́dọọdún.

Èwo ni wọ́n ń pè ní oúnjẹ tí wọn ò fi kẹ́míkà gbìn? Ìròyìn kan tó wá látọ̀dọ̀ Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Àgbẹ̀, Ìpèsè Oúnjẹ àti Ìdàgbàsókè Ìgbèríko ní Ìpínlẹ̀ Alberta, ní ilẹ̀ Kánádà sọ pé ó jẹ́ “oúnjẹ tí wọ́n gbìn lábẹ́ ètò kan, tó jẹ́ pé, yàtọ̀ sí pé wọn ò lo kẹ́míkà rárá, ètò yìí tún máa ń ṣiṣẹ́ láti fún ilẹ̀ lọ́ràá, ó máa ń jẹ́ kí àwọn àgbẹ̀ lè gbin onírúurú nǹkan, bákan náà kì í jẹ́ kí wọ́n máa lo àwọn ẹranko tàbí ilẹ̀ nílòkulò.”

Àwọn àgbẹ̀ tí kì í lo kẹ́míkà sọ pé irú iṣẹ́ àgbẹ̀ yìí yàtọ̀ gédégbé sí ti àwọn iléeṣẹ́ aládàáńlá tí wọ́n máa ń fi ẹ̀rọ ṣe ọ̀gbìn oúnjẹ. Nínú ìwé ìròyìn Canadian Geographic, Katharine Vansittart sọ pé: “Oríṣi irè oko kan làwọn tó máa ń dá oko rẹpẹtẹ máa ń fẹ́ láti gbìn lọ́pọ̀ jaburata, ohun tó sì ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wọn láti mú ọ̀pọ̀ irè jáde ni lílo ẹ̀rọ, oògùn apakòkòrò àti ajílẹ̀. Yàtọ̀ sí pé ràlẹ̀rálẹ̀ irú àwọn kẹ́míkà bẹ́ẹ̀ lè wà nínú oúnjẹ, ó tún máa ń dín àwọn èròjà aṣaralóore inú oúnjẹ kù bí wọ́n bá kórè wọn láìgbó, èyí tó pọn dandan bó bá jẹ́ ọ̀nà jíjìn ni wọ́n ti máa lọ tà wọ́n. Láti rí i dájú pé irè oko dé ibi tí wọ́n ń kó wọn lọ láìbàjẹ́, wọ́n lè fọ́n kẹ́míkà sí wọn lára, wọ́n sì lè kó wọn sínú nǹkan tí wọ́n ti fi àtè pa inú rẹ̀ tàbí kí wọ́n kó wọn sábẹ́ ìtànṣán.”

Àwọn wo ló ń ra àwọn oúnjẹ tí wọn ò fi kẹ́míkà gbìn? Ìròyìn tó wá láti ìpínlẹ̀ Alberta, nílẹ̀ Kánádà tá a mẹ́nu kàn lókè sọ pé “ó bẹ̀rẹ̀ látorí àwọn ọ̀dọ́langba tí ìlera wọn jẹ lógún lọ dórí àwọn ìyá tí kò fi ìlera àwọn ọmọ wọn ṣeré, títí lọ dórí àwọn èèyàn tí wọ́n bí lẹ́yìn ogun àgbáyé kejì àmọ́ tí wọ́n ti ń dàgbà báyìí. . . . Kò mọ sọ́dọ̀ àwọn táwọn èèyàn mọ̀ sáwọn tó ń ṣagbátẹrù àlááfíà ní nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún sí ogójì ọdún sẹ́yìn.”

Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe gbogbo èèyàn ló gbà pé oúnjẹ tí wọn ò fi kẹ́míkà gbìn ló dára jù o. Ìwé ìròyìn Canadian Geographic sọ pé: “Àwọn tó ń ṣiyèméjì nípa oúnjẹ tí wọn ò fi kẹ́míkà gbìn ń ṣe awuyewuye nítorí bó ṣe máa ń gbówó lórí gan-an, tí kò sì sí ẹ̀rí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì kankan tó fi hàn pé òun ló dára jù. Ohun tó sì ń kó ìdààmú bá àwọn kan ni bá a ṣe ní ìlànà méjì fún gbígbin oúnjẹ, èyí tí kò fi ti àwọn akúṣẹ̀ẹ́ ṣe.” Àwọn tó fara mọ́ ọn náà kò ṣàì fèsì o, wọ́n ní táwọn èèyàn bá yí oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ padà, tí ìyàtọ̀ dé bá iye tí wọ́n ń tà wọ́n àti bí wọ́n ṣe ń kó wọn ṣọwọ́, èyí lè mú kí agbára gbogbo èèyàn ká a, láìka bí ipò ìṣúnná owó wọn ṣe rí sí. Pẹ̀lú èrò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ yìí àti ìsọfúnni ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, kò dájú pé awuyewuye tó ń lọ lórí oúnjẹ tí wọn ò fi kẹ́míkà gbìn yóò dópin bọ̀rọ̀.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

OÒGÙN APAKÒKÒRÒ ÌDÀÀMÚ ÀWỌN ÀGBẸ̀

Àwọn kòkòrò àtàwọn àrùn tó ń bá irúgbìn jà láwọn apá ibì kan láyé ti ba ìdá mẹ́ta nínú mẹ́rin àwọn irè oko tó yẹ káwọn àgbẹ̀ kórè jẹ́. Ọgbọ́n kan tó jọ pé wọ́n lè dá sí i ni gbígbin ọ̀pọ̀lọpọ̀ irúgbìn. Ìwé ìròyìn Globe and Mail sọ pé: “Àwọn àgbẹ̀ ilẹ̀ Kánádà ti gbìyànjú láti borí ìṣòro yìí nípa lílo àwọn ọ̀nà kan tá a mú kí irè oko wọn pọ̀ sí i, tí wọ́n á sì lè rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ tà.” Síbẹ̀, ọ̀gbẹ́ni Terence McRae, tó ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka tó wà fún ètò àyíká ní ilẹ̀ Kánádà kìlọ̀ pé: “Ọ̀pọ̀ lára àwọn ìyípadà tí wọ́n ṣe yìí ti mú kí àwọn ewu tí iṣẹ́ àgbẹ̀ lè fà bá àyíká pọ̀ sí i.”

Lílo oògùn apakòkòrò ń kọ́? Eléyìí náà ń kó ìdààmú bá àwọn àgbẹ̀, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé iyàn jíjà ṣì ń lọ ní pẹrẹu lórí bí lílo oògùn apakòkòrò ṣe gbéṣẹ́ sí àtàwọn ìpalára tó lè ṣe fún ìlera. Ìròyìn kan tó wá látọ̀dọ̀ Àjọ Ìlera Àgbáyé gbà pé òye ò tíì kún tó nípa bí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn oògùn apakòkòrò ṣe ní májèlé nínú sí àtàwọn ewu mìíràn tó so mọ́ ọn. Àwọn ewu tó lè ti fara sin tẹ́lẹ̀ sì lè le sí i bí àwọn májèlé inú wọn ṣe ń gba ara ewéko kọjá sára àwọn ẹranko. Àwọn ẹranko ń jẹ ewéko tí wọ́n ti fọ́n oògùn apakòkòrò sí. Lẹ́yìn náà, àwọn èèyàn á sì wá jẹ àwọn ẹran náà.

[Credit Line]

Fọ́tò USDA tí Doug Wilson yà