Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Lẹ́yìn Tí Ìbúgbàù Náà Wáyé

Lẹ́yìn Tí Ìbúgbàù Náà Wáyé

Lẹ́yìn Tí Ìbúgbàù Náà Wáyé

LÁTỌWỌ́ ÒǸKỌ̀WÉ JÍ! NÍ ECUADOR

ÌLÚ Riobamba lórílẹ̀-èdè Ecuador ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé, lọ́jọ́ kan tí oòrùn ń ta yẹ́ẹ́ ní November 20, 2002. Ojú ọ̀run mọ́ kedere, ojú sánmà sì funfun gbòò níbi tí Ọlọ́run sọ ọ́ lọ́jọ̀ sí. Àwọn òkè tí yìnyín máa ń bò ló yí àgbègbè náà ká, wọ́n sì ti lọ wà jù. Ẹgbàá méjìlélọ́gọ́ta [124,000] èèyàn ló ń gbé ìlú náà, ibi tí àwọn kan sì ń gbé fi ẹgbẹ̀rìnlá ó dín ọgọ́rùn-ún [2,700] mítà ga ju ìtẹ́jú òkun lọ ní Òkè Ńlá Andes. Kálukú wọn ń bá ìgbòkègbodò ojoojúmọ́ wọn lọ, láìmọ̀ pé ohun kan máa tó dabarú àlàáfíà àti ìparọ́rọ́ náà. Ní ọ̀sán tí gbogbo nǹkan parọ́rọ́ náà ni ohun kan ṣàdéédéé bú gbàù, ariwo rẹ̀ sì fẹ́rẹ̀ẹ́ dini létí! Àwọn fèrèsé ilé bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n pẹ̀pẹ̀, ilẹ̀ sì ń mì tìtì. Èéfín tó dúdú kirikiri wá bẹ̀rẹ̀ sí gbára jọ lójú ọ̀run.

Ní nǹkan bí ìṣẹ́jú mẹ́wàá lẹ́yìn èyí, ìbúgbàù kejì tún wáyé, ìmìtìtì ilẹ̀ tó pẹ̀lú rẹ̀ sì pọ̀ débi pé ó fa àwọn fèrèsé ya, ó sì ya àwọn ilẹ̀kùn kúrò lára ògiri. Iná tó ń sọ kẹ̀ù àti èéfín tó gbára jọ lọ́tẹ̀ yìí pọ̀ ju ti ìṣáájú lọ fíìfíì. Lẹ́yìn èyí ni ìbúgbàù tún wá bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹlẹ̀ tẹ̀léra-tẹ̀léra, tí iná sì ń ṣẹ́ yọ lọ́tùn-ún lósì.

Tọkọtaya tó ti lé lọ́mọ ọgọ́ta ọdún ni José àti Ana. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n, ibi tí wọ́n ń gbé sì tó irínwó mítà sí ibi tí ìbúgbàù náà ti wáyé. Ìbúgbàù rírinlẹ̀ náà sọ àwọn méjèèjì mọ́lẹ̀. Ẹ̀gbẹ́ ilẹ̀kùn iwájú ilé ni Ana dúró sí kó tó di pé ó ya kúrò lára ògiri, tí ìbúgbàù yìí sì sọ ilẹ̀kùn náà lu ògiri kan lẹ́yìn ilé. Bí tọkọtaya tí ìpayà ti bá náà ṣe ń sá lọ sí ọ̀nà ẹ̀yìnkùlé, àjà bẹ̀rẹ̀ sí jìn lé wọn lórí. Wọ́n ṣáà rá pálá bọ́ sí àgbàlá wọn lẹ́yìnkùlé, níbi tí àwọn méjèèjì ti so mọ́ ara wọn, tí wọ́n sì ń gbàdúrà. Ọpẹ́lọpẹ́ pé ọmọ wọn ọkùnrin dé ní ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lẹ́yìn náà, tó sì fi ọkọ̀ gbé wọn lọ sí ibi tó láàbò.

Àmọ́ o, kì í ṣe gbogbo èèyàn ló rìnnà kore bẹ́ẹ̀ yẹn. Ńṣe ni jìnnìjìnnì bá tọmọdé tàgbà. Àìlóǹkà èèyàn ló sì fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ. Níbi tí wọ́n ti ń pariwo gèè, tí wọ́n sì ń lọgun tòò, àwọn kan fẹsẹ̀ kọ, wọ́n sì ṣubú yakata sórí àwọn gíláàsì tó ti fọ́n ká sí gbogbo ọ̀nà tí wọ́n ń gbà lẹ́gbẹ̀ẹ́ títì. Eré àsápajúdé làwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, àwọn bọ́ọ̀sì àtàwọn ọkọ̀ akẹ́rù ń sá jáde kúrò nínú ìlú náà, kódà àwọn kan ń wakọ̀ gba ọ̀nà tí kò yẹ kí wọ́n gbà! Ọ̀pọ̀ àwọn tó sá kúrò ní ilé ẹ̀kọ́ tàbí níbi iṣẹ́ ni kò gbọ́ nǹkan kan nípa àwọn ìdílé wọn fún nǹkan bíi wákàtí mẹ́rìnlélógún.

Kí lohun tó fa gbogbo ìkọlùkọgbà yìí? Iná kan tó ṣẹ́ yọ níbi tí àwọn ológun ń kó ohun ìjà ogun pa mọ́ sí lábẹ́ ilẹ̀ ló fà á, tí èyí sì mú kí àwọn bọ́ǹbù àfọwọ́jù àtàwọn ohun ìjà mìíràn bẹ̀rẹ̀ sí bú gbàù. Bí ìbúgbàù náà ṣe ń bá a nìṣó, àwọn mọ́tò ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ sí lo gbohùngbohùn láti fi kìlọ̀ fún àwọn èèyàn pé kí gbogbo wọn fi ìlú náà sílẹ̀ lọ sí ibi tó jìnnà tó kìlómítà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ.

Ká tó ṣẹ́jú pẹ́ẹ́, ìlú Riobamba ti mọ́ foo. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn aráàlú kún ojú títì márosẹ̀ tó wà lẹ́yìn òde ìlú náà fọ́fọ́. Gbogbo wọn kóra jọ síbẹ̀ nínú otútù alẹ́ náà, ọ̀pọ̀ lára wọn ni kò sì wọ aṣọ nínípọn èyíkéyìí. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ wákàtí, ìbúgbàù náà bẹ̀rẹ̀ sí rọlẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Nígbà tí wọn ò lè fara gba ojú ọjọ́ tó tutù nini ọ̀hún mọ́, àwọn olùgbé ìlú náà bẹ̀rẹ̀ sí rọra rìn padà lọ sínú ìlú. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́ dáadáa lọ́jọ́ kejì, ọ̀pọ̀ lára wọn rí i pé ìbúgbàù náà ti ba àwọn fèrèsé, ilẹ̀kùn, òrùlé, àjà ilé àti ògiri ilé wọn jẹ́ kọjá wẹ́rẹwẹ̀rẹ. Ìdílé kan rí àwọn àfọ́kù gíláàsì ẹlẹ́nu ṣóṣóró tó ti wọlé ṣinṣin sára bẹ́ẹ̀dì wọn nínú iyàrá. Àwọn mìíràn rí àwọn àfọ́kù bọ́ǹbù nínú ilé àti láyìíká ilé wọn.

Àwọn ìròyìn tó kọ́kọ́ jáde fi hàn pé èèyàn méje ló kú, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta àti méjìdínlógójì [538] èèyàn ló fara pa, ẹgbàásàn-án [18,000] ilé ló sì bà jẹ́. Kò sí èyíkéyìí lára àádọ́ta dín lẹ́gbẹ̀rún [950] Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lágbègbè náà tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ní láti ṣètọ́jú àwọn méjì tó fara pa yánnayànna.

Ṣíṣèrànwọ́ fún Àwọn Tí Ìṣẹ̀lẹ̀ Náà Ṣàkóbá Fún

Lówùúrọ̀ ọjọ́ tó tẹ̀ lé ìbúgbàù náà, àwọn alàgbà ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lágbègbè náà bẹ̀rẹ̀ sí ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ará wọn láti mọ ipò tí wọ́n wà. Nígbà tó ṣe díẹ̀ lọ́jọ́ kan náà yẹn, òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan bá àwọn alàgbà tó wà nínú ìjọ mẹ́tàlá ní ìlú Riobamba àti àgbègbè rẹ̀ ṣèpàdé láti mọ bí ohun tó bà jẹ́ àtàwọn tó fara pa ṣe pọ̀ tó. Ó rọ àwọn alàgbà náà láti ṣaájò àwọn èèyàn náà, kí wọ́n sì bójú tó wọn nípa tẹ̀mí. Pípésẹ̀ sí àwọn ìpàdé Kristẹni, kódà lábẹ́ irú àwọn ipò lílekoko bí èyí, ṣe pàtàkì gidigidi! (Hébérù 10:24, 25) Látàrí èyí, àwọn ìjọ àdúgbò ṣe àwọn ìpàdé tí wọ́n ti máa ń ṣe déédéé tẹ́lẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ tó tẹ̀ lé ìjábá náà.

Lọ́jọ́ Thursday àti Friday, wọ́n ṣàkójọ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìsọfúnni nípa ilé àwọn Ẹlẹ́rìí tó bà jẹ́ wọ́n sì fi ránṣẹ́ sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ecuador, èyí tó wà ní ìlú Guayaquil. Ìròyìn náà sọ pé ó jẹ́ kánjúkánjú láti fi nǹkan dí ojú ọ̀pọ̀lọpọ̀ fèrèsé tí gíláàsì wọn ti fọ́ nítorí otútù. Láàárín wákàtí díẹ̀, ẹ̀ka iléeṣẹ́ náà ti ra ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rá nínípọn, ohun tó ṣeé fi lẹ nǹkan àti ìṣó tó ṣeé kàn mọ́ kọnkéré, kí wọ́n lè fi àwọn ohun wọ̀nyí ṣe àtúnṣe onígbà díẹ̀.

Aago mẹ́sàn-án òwúrọ̀ ni ọkọ̀ akẹ́rù tó kó àwọn ẹrù wọ̀nyí wá láti ẹ̀ka iléeṣẹ́ dé lọ́jọ́ Sátidé. Ṣáájú àkókò yìí, àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n pín sí àwùjọ-àwùjọ ti ń báṣẹ́ lọ ní pẹrẹu ní ríran àwọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹ́gbẹ́ wọn lọ́wọ́ láti palẹ̀ gbogbo àwọn àfọ́kù gíláàsì tó wà nínú ilé wọn mọ́ kí iṣẹ́ lílẹ ọ̀rá mọ́ ojú fèrèsé náà lè bẹ̀rẹ̀. Gbọ̀ngàn Ìjọba àdúgbò kan ni wọ́n lò gẹ́gẹ́ bí ojúkò ìgbòkègbodò. Kó bàa lè rọrùn láti gé ọ̀rá náà, wọ́n fa àwọn ìlà sórí ilẹ̀ láti fi ṣe ìdiwọ̀n, wọ́n sì ń gé àwọn ọ̀rá náà níbàámu pẹ̀lú àwọn ìdiwọ̀n náà. Èyí jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wọn láti gé ọ̀rá náà bó ṣe yẹ kó má bàa tóbi jù tàbí kéré jù, lẹ́yìn èyí ni wọ́n á wá kó wọn fún àwọn òṣìṣẹ́ tó ń lẹ̀ wọ́n mọ́ ojú fèrèsé.

José, tí a dárúkọ níṣàájú, sọ pé: “Nígbà tá a máa délé wa lọ́sàn-án ọjọ́ tó tẹ̀ lé ọjọ́ tí ìbúgbàù náà wáyé, àwọn ará ti wà níbẹ̀ tí wọ́n ń bá wa palẹ̀ pàǹtírí mọ́. Lọ́jọ́ Sátidé, alámùúlégbè mi kan wá bá mi, ó kan sáárá sí iṣẹ́ ribiribi tí àwọn ará ṣe ní fífi àwọn ọ̀rá náà sí ilé mi, ó sì béèrè pé, ‘Èló ni gbogbo èyí ná ọ?’” Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún un pé ọ̀fẹ́ làwọn ará ṣe iṣẹ́ náà!

Nígbà tó fi máa di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Sátidé, nǹkan bí igba [200] olùyọ̀ǹda-ara-ẹni láti àwọn ìjọ tó wà lágbègbè náà ti fi nǹkan bo fèrèsé ilé àwọn Ẹlẹ́rìí mọ́kànléláàádọ́rùn-ún. Ọ̀pọ̀ àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí náà tún jàǹfààní. Ìwé ìròyìn àdúgbò kan gbé àwòrán ilé kan tí àwọn Ẹlẹ́rìí tún ṣe jáde, ó sì sọ pé ẹnì kan ṣoṣo lára àwọn mẹ́jọ tó ń gbé ilé náà ni Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Pípèsè Ìṣírí

Ìbúgbàù náà ò ṣàì kó ìdààmú ọkàn ńláǹlà bá àwọn èèyàn. Láti lè pèsè ìtùnú fún àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà lágbègbè náà, wọ́n ṣètò àkànṣe ìpàdé kan lọ́jọ́ Monday, November 25, ní aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́. Àwọn aṣojú láti ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Ecuador ni wọ́n rán wá láti wá darí ìpàdé náà. Nítorí pé kò sí iná mànàmáná, wọn ò lè sún àkókò ìpàdé náà sí àkókò mìíràn lọ́wọ́ alẹ́. Níwọ̀n bó ti jọ pé àkókò tí wọ́n fi ìpàdé náà sí kò ní fi bẹ́ẹ̀ rọ ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́rùn, nǹkan bí ẹgbẹ̀ta èèyàn ni wọ́n retí láti pésẹ̀. Síbẹ̀, egbèje àti mọ́kànlélógún [1,421] èèyàn ló pésẹ̀, lára wọn sì ni àwọn aládùúgbò kan tí wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí, tí gbogbo wọ́n kún inú Gbọ̀ngàn Àpéjọ ìlú Riobamba! Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ pàtàkì tí wọ́n jíròrò nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ni Sáàmù 4:8: “Àlàáfíà ni èmi yóò dùbúlẹ̀, tí èmi yóò sì sùn, nítorí pé ìwọ tìkára rẹ, Jèhófà, nìkan ṣoṣo ni ó mú kí n máa gbé nínú ààbò.” Gbogbo àwọn tó pésẹ̀ ló fi ìmọrírì ńláǹlà hàn fún ìtòlẹ́sẹẹsẹ tẹ̀mí tó ń tuni nínú náà.

Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ẹ̀dà àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn Jí!, ìyẹn àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Ìjábá Àdánidá—Ríran Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Láti Kojú Wọn” (June 22, 1996) ni wọ́n pín fún àwọn òbí nígbà tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà parí. Ìpínrọ̀ kan nínú àpilẹ̀kọ náà kà pé:

“Ẹ̀ka Àbójútó Ìṣẹ̀lẹ̀ Àìròtẹ́lẹ̀ ti Ìjọba Àpapọ̀ United States (FEMA) sọ pé, kété lẹ́yìn ìjábá kan, gẹ́gẹ́ bí ìwà ẹ̀dá, àwọn ọmọdé máa ń bẹ̀rù pé (1) a óò fi wọ́n sílẹ̀ láwọn nìkan, (2) a óò yà wọ́n nípa kúrò lọ́dọ̀ ìdílé wọn, (3) ìṣẹ̀lẹ̀ náà yóò tún ṣẹlẹ̀, (4) ẹnì kan yóò sì fara pa tàbí kú.” Níbàámu pẹ̀lú àpilẹ̀kọ yìí, wọ́n rọ àwọn òbí láti ṣe àwọn ohun tó tẹ̀ lé e yìí:

1. Gbìyànjú láti mú ìdílé wà pa pọ̀.

2. Fara balẹ̀ ṣàlàyé bí ọ̀ràn ṣe rí.

3. Fún àwọn ọmọ níṣìírí láti sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn.

4. Jẹ́ kí àwọn ọmọ pẹ̀lú kópa nínú iṣẹ́ pípalẹ̀ pàǹtírí mọ́.

Lẹ́yìn èyí, àwọn Ẹlẹ́rìí tún ṣe ọ̀pọ̀ ẹ̀dà àpilẹ̀kọ Jí! yìí, wọ́n sì ṣàjọpín rẹ̀ pẹ̀lú àwọn aládùúgbò wọn àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn.

Ní ọ̀sẹ̀ mẹ́ta lẹ́yìn ìbúgbàù náà, wọ́n ṣì ń ra àwọn ohun èlò ìkọ́lé láti fi ṣe iṣẹ́ àtúnṣe àwọn ilé náà kó lè dúró sán-ún, títí kan ṣíṣe àwọn fèrèsé, àjà ilé àti òrùlé tuntun. Láàárín ọ̀sẹ̀ mẹ́ta tó tún tẹ̀ lé e, wọ́n ti parí gbogbo iṣẹ́ ìkọ́lé náà, pa pọ̀ pẹ̀lú títún Gbọ̀ngàn Ìjọba méjì kọ́. Ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ìmọrírì làwọn èèyàn sọ nítorí àwọn iṣẹ́ àfiṣèrànwọ́ onífẹ̀ẹ́ wọ̀nyí.

Onírúurú ìjábá wọ́pọ̀ gan-an ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” wọ̀nyí. (2 Tímótì 3:1-5) Àmọ́ ṣá o, ìtìlẹyìn tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe fún ara wọn lẹ́nì kínní-kejì àti fún àwọn aládùúgbò wọn fẹ̀rí hàn pé ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́ lágbára gan-an. Bí ọ̀rọ̀ ṣe rí gan-an ni José sọ nígbà tó sọ pé: “Ètò àjọ Jèhófà kì í fi nǹkan falẹ̀ bó bá di pé kí wọ́n pèsè ìrànwọ́ fún wa nígbà tí a bá nílò rẹ̀.”

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Àwọn Ẹlẹ́rìí bí igba [200] ló yọ̀ǹda ara wọn láti palẹ̀ pàǹtírí mọ́. Wọ́n díwọ̀n àwọn fèrèsé tuntun, wọ́n gé wọn, wọ́n sì lẹ̀ wọ́n mọ́ ojú fèrèsé. Wọ́n ṣe àwọn òrùlé tuntun láti fi pààrọ̀ ti tẹ́lẹ̀