Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Máa Ṣe Rere”

“Máa Ṣe Rere”

“Máa Ṣe Rere”

“Mo fẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ pé àwọn èèyàn tí ìrísí Ìlú wa jẹ lógún tí wọ́n sì ń fẹ́ kí àwọn arìnrìn-àjò tó ń gba ibẹ̀ kọjá máa fi ojú tó dáa wò ó, kò ṣàì kíyè sí ìsapá àti iṣẹ́ aláápọn yín. Ẹ̀ka iléeṣẹ́ yín fẹ̀rí hàn pé ẹ fojú pàtàkì wo àyíká yín àti Ìlú wa yìí.”

Olórí ìlú Halton Hills, níbi tí ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà lórílẹ̀-èdè Kánádà, ló sọ ọ̀rọ̀ ìgbóríyìn yìí. Lẹ́yìn ìyẹn ló wá gbé àmì ẹ̀yẹ kan fún ẹ̀ka iléeṣẹ́ náà, láti “fi ìmọrírì hàn fún ìsapá àti àníyàn àtọkànwá [wọn] láti mú kí ìgbésí ayé túbọ̀ sunwọ̀n sí i fún gbogbo olùgbé ìlú Halton Hills.”

Irú ọ̀rọ̀ oríyìn bẹ́ẹ̀ látẹnu àwọn aláṣẹ jẹ́rìí sí bí ọ̀rọ̀ Róòmù 13:3 ṣe jẹ́ òtítọ́ tó, ìyẹn ni pé: “Máa ṣe rere, ìwọ yóò sì gba ìyìn láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.” Àmọ́ o, láìsí àní-àní, ẹni tí gbogbo ìyìn àti ọlá yẹ fún ni Jèhófà, Ọba Aláṣẹ ayé òun ọ̀run.