Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kí N Fín Ara?

Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kí N Fín Ara?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kí N Fín Ara?

“Ohun táwọn kan ń fín sára ti lọ wà jù. Wọ́n máa ń lẹ́wà gan-an ni.”—Jalene. a

“Kí n tó lọ fín ara nígbà àkọ́kọ́, ọdún méjì gbáko ni mo fi ń ronú ṣáá nípa rẹ̀.”—Michelle.

Ó FẸ́RẸ̀Ẹ́ jẹ́ pé kò sí ibi tá ò ti lè rí àṣà ara fínfín. Àwọn gbajúmọ̀ olórin rọ́ọ̀kì, àwọn àgbà ọ̀jẹ̀ nínú eré ìdárayá, àwọn afìmúra polówó àtàwọn gbajúgbajà òṣèré máa ń fi yangàn. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́langba náà ti bẹ̀rẹ̀ sí káṣà wọn, nípa fífi ohun tí wọ́n fín sí èjìká, ọwọ́, ìbàdí àti kókósẹ̀ wọn ṣakọ. Andrew sọ pé: “Ohun téèyàn bá fín sára máa ń lẹ́wà gan-an. Àmọ́, ọwọ́ kálukú ló wà bóyá kí òun fín ara tàbí kí òun máà fín ara.”

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ World Book Encyclopedia sọ pé: “Ara fínfín ni àṣà kéèyàn máa fín àmì tó máa wà títí lọ gbére sára. Bí wọ́n ṣe ń ṣe é ni pé wọ́n á lo igi tàbí egungun tàbí abẹ́rẹ́ ẹlẹ́nu ṣóńṣó tí wọ́n ti kì bọ inú àwọn èròjà aláwọ̀ oríṣiríṣi láti máa fi dá ihò tó-tò-tó sí awọ ara.”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn láti mọ iye àwọn tó fín ara nílẹ̀ Amẹ́ríkà, ìwé ìròyìn kan sọ pé ìdá kan nínú mẹ́rin gbogbo àwọn ọmọ ọlọ́dún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ló fín ara. Sandy sọ pé: “Àṣà tó wà lòde báyìí nìyẹn o.” Kí nìdí tí àwọn ọ̀dọ́ kan fi nífẹ̀ẹ́ sí ara fínfín?

Kí Nìdí Tó Fi Gbajúmọ̀ Tó Bẹ́ẹ̀?

Lójú àwọn kan, ara fínfín jẹ́ ọ̀nà kan láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé wọ́n ń fẹ́ ọmọge kan tàbí ọ̀dọ́kùnrin kan ní pàtó. Michelle sọ pé: “Ẹ̀gbọ́n mi fín orúkọ ọmọbìnrin tó ń bá ròde sí kókósẹ̀ rẹ̀.” Ìṣòro wo ló jẹ yọ nídìí ara fínfín náà? Michelle dáhùn pé: “Ó mà ti já a sílẹ̀ báyìí o.” Ìwé ìròyìn Teen sọ pé, “àwọn dókítà fojú bù ú pé ó lé ní ìdá mẹ́ta nínú mẹ́wàá gbogbo iṣẹ́ mímú ara fínfín kúrò tí wọ́n ń ṣe tó jẹ́ pé àwọn ọ̀dọ́bìnrin tí wọ́n fẹ́ láti mú orúkọ ọmọkùnrin tí wọ́n ń fẹ́ tẹ́lẹ̀ kúrò lára ni àwọ́n ń ṣe é fún.”

Àwọn ọ̀dọ́ kan ka ara fínfín sí iṣẹ́ ọnà. Àwọn mìíràn máa ń wò ó gẹ́gẹ́ bí ohun tó ń fi hàn pé àwọ́n lè ṣe ohun tó bá wù àwọn. Josie sọ pé: “Bó bá ṣe wù mí ni mo ṣe lè lo ìgbésí ayé mi.” Ó tún fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ara fínfín ni “ìpinnu tó ṣe pàtàkì jù lọ tí mo tíì ṣe nínú ìgbésí ayé mi.” Ara fínfín máa ń fún àwọn ọ̀dọ́ kan láǹfààní láti dán ohun tuntun wò, ìyẹn ni pé wọ́n á máa ronú pé àwọ́n lè ṣe ohun tó bá wù àwọn sí ara àwọn. Ó tún lè jẹ́ àmì tó ń fi hàn pé ẹnì kan jẹ́ ẹlẹ́mìí ọ̀tẹ̀ tàbí pé ìgbésí ayé tó ń gbé kò bá ti àwùjọ mu. Ìdí nìyí tí àwọn ara fínfín kan fi máa ń ní ọ̀rọ̀ rírùn, àwòránkáwòrán tàbí ọ̀rọ̀ tí ń ru ìwà pálapàla sókè.

Àmọ́ o, ohun tó ń sún ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ dédìí àṣà yìí kò ṣẹ̀yìn fífẹ́ láti tẹ̀ lé àṣà tó wà lóde. Ṣùgbọ́n, ṣé bí o ṣe dà bíi pé gbogbo èèyàn ló ń fín ara wá túmọ̀ sí pé ìwọ náà gbọ́dọ̀ fín ara?

Ara Fínfín—Iṣẹ́ Ọnà Àtayébáyé

Ara fínfín kì í ṣe àṣà tuntun o. Àwọn olùṣèwádìí ti rí àwọn òkú tí wọ́n kùn lọ́ṣẹ nílẹ̀ Íjíbítì àti ilẹ̀ Líbíà tí wọ́n fín ara fún, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé wọ́n ti gbé ayé ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ṣáájú kí Kristi tó wá sáyé. Wọ́n tún ti rí àwọn òkú tí wọ́n kùn lọ́ṣẹ tí wọ́n sì fín ara fún ní Gúúsù Amẹ́ríkà. Ọ̀pọ̀ àwọn àwòrán tí wọ́n fín sára wọn ló jẹ mọ́ ìjọsìn àwọn ọlọ́run kèfèrí. Olùṣèwádìí Steve Gilbert sọ pé: “Ara fínfín tó tíì pẹ́ jù lọ tó jẹ́ àwòrán ohun kan ní pàtó dípò tí ì bá fi jẹ́ àwòrán bọrọgidi kan lásán ni ti ọlọ́run èké tó ń jẹ́ Bes. Nínú ìtàn ìwáṣẹ̀ ilẹ̀ Íjíbítì, Bes yìí ni ọlọ́run àríyá, oníwà pálapàla sì ni.”

Láìfọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀, Òfin Mósè ka ara fínfín léèwọ̀ fún àwọn èèyàn Ọlọ́run. Léfítíkù 19:28 sọ pé: “Ẹ kò . . . gbọ́dọ̀ kọ ara yín lábẹ nítorí ọkàn tí ó ti di olóògbé, ẹ kò sì gbọ́dọ̀ fín àmì sí ara yín. Èmi ni Jèhófà.” Àwọn abọ̀rìṣà, irú bí àwọn èèyàn ilẹ̀ Íjíbítì, máa ń fín orúkọ àwọn ọlọ́run èké wọn tàbí àwòrán wọn sórí ọmú wọn tàbí sí apá wọn. Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá pa àṣẹ Jèhófà mọ́ lórí fínfín àmì sára, yóò jẹ́ kí wọ́n lè yàtọ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn.—Diutarónómì 14:1, 2.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni òde òní kò sí lábẹ́ Òfin Mósè, kíkà tó ka ara fínfín léèwọ̀ jẹ́ ohun tó gbàrònú. (Éfésù 2:15; Kólósè 2:14, 15) Bó o bá jẹ́ Kristẹni, kò sí àní-àní pé o ò ní fẹ́ ya àwòrán èyíkéyìí sára tàbí kó o kọ ohunkóhun sára tó lè máa fi hàn pé ò ń gbé ìbọ̀rìṣà tàbí ìjọsìn èké lárugẹ—àní fúngbà díẹ̀ pàápàá.—2 Kọ́ríńtì 6:15-18.

Ewu Tó Ń Ṣe fún Ìlera

Àwọn ìpalára tó lè ṣe fún ìlera tún wà tó yẹ kó o ronú nípa rẹ̀. Dókítà Robert Tomsick, igbákejì ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ẹ̀kọ́ nípa awọ ara, sọ pé: “Ẹ rántí o, pé awọ ara yín lẹ̀ ń ki nǹkan bọ̀, tẹ́ ẹ sì ń fi èròjà aláwọ̀ oríṣiríṣi sí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé abẹ́rẹ́ náà kì í fi bẹ́ẹ̀ wọnú ara jù, síbẹ̀ nígbàkigbà tẹ́ ẹ bá fi nǹkan gún ara yín ó ṣeé ṣe kí kòkòrò àrùn wọ ojú ibẹ̀. Mo gbà pé [ara fínfín] jẹ́ nǹkan eléwu.” Dókítà Tomsick ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Gbàrà téèyàn bá ti fi èròjà aláwọ̀ oríṣiríṣi náà sára tán, kódà bí kòkòrò àrùn ò bá tiẹ̀ wọbẹ̀, ìgbàkigbà ni ara fínfín náà lè bẹ̀rẹ̀ sí dani láàmú, ó sì ṣeé ṣe kí awọ ara máa pọ́n, kó máa wú, kó máa dá èépá, kó sì máa yúnni.”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó ń fín àmì sára ò retí pé yóò kúrò, onírúurú ọ̀nà làwọn oníṣègùn ń gbà láti mú un kúrò. Wọ́n máa ń ṣe àwọn nǹkan bíi lílo ẹ̀rọ tí ń tan ìtànṣán láti fi mú un kúrò, ṣíṣe iṣẹ́ abẹ láti gé ibi tí wọ́n fín náà kúrò, fífi búrọ́ọ̀ṣì oníwáyà gbo ojú ibi tí àmì náà wà, fífi omi oníyọ̀ rẹ ojú ibẹ̀, àti fífi ásíìdì mú un kúrò, tí èyí yóò sì dá àpá sí ojú ibẹ̀. Àwọn ohun wọ̀nyí ń náni lówó gan-an, ìrora téèyàn á jẹ kì í sì í ṣe kékeré. Ìwé ìròyìn Teen sọ pé: “Ìrora téèyàn ń jẹ nígbà tó bá ń mú ohun tó fín sára kúrò pọ̀ ju ti ìgbà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń fín in sára lọ.”

Kí Làwọn Èèyàn Á Máa Rò?

Ó tún yẹ kó o ronú dáadáa nípa ohun táwọn ẹlòmíràn lè máa rò nípa bó o ṣe fín ara, nítorí pé ọ̀pọ̀ èèyàn kì í fi ojú tó dára wo àṣà yìí. (1 Kọ́ríńtì 10:29-33) Obìnrin kan tó ń jẹ́ Li lórílẹ̀-èdè Taiwan kò ronú jinlẹ̀ kó tó fín ara nígbà tó wà ní ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún. Ní báyìí, ó ti pé ọmọ ọdún mọ́kànlélógún, ọ́fíìsì ló sì ti ń ṣiṣẹ́. Li sọ pé: “Kì í bá mi lára mu rárá láti rí bí àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ ṣe máa ń tẹjú mọ́ ohun tí mo fín sára.” Theodore Dalrymple, oníṣègùn ọpọlọ kan ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, sọ pé lójú ọ̀pọ̀ èèyàn, ara fínfín “sábà máa ń jẹ́ àmì tó ń fi hàn pé ẹnì kan . . . wà lára àwọn oníwà ipá, ewèlè ẹ̀dá, ọmọ ìta tàbí ẹgbẹ́ ọ̀daràn.”

Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn American Demographics náà sọ ohun tó fara jọ kókó yìí, ó ní: “Ó hàn gbangba pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ará Amẹ́ríkà ka ara fínfín tàbí dídá ara lu sí ohun eléwu. Ìdá márùndínláàádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún [àwọn ọ̀dọ́] ló gbà pé òótọ́ ni gbólóhùn náà, ‘àwọn èèyàn tó fín ara . . . ní láti mọ̀ pé ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe ohun tó wà lọ́kàn wọn yìí lè ṣàkóbá fún wọn nínú iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wọn tàbí nínú àjọṣe wọn pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.’”

Tún rò ó wò ná bóyá ara fínfín á buyì kún jíjẹ́ tó o jẹ́ Kristẹni tàbí yóò tàbùkù sí i. Ǹjẹ́ kò lè ‘jẹ́ okùnfà fún ìkọ̀sẹ̀’ fún àwọn ẹlòmíràn? (2 Kọ́ríńtì 6:3) Lóòótọ́ o, àwọn ibi tó fara sin lára làwọn ọ̀dọ́ kan ń fín àmì sí. Àwọn òbí wọn pàápàá lè má mọ̀ nípa ara tí wọ́n yọ lọ fín yìí. Àmọ́ ṣọ́ra o! Bó bá ṣẹlẹ̀ pé o ní láti lọ rí dókítà ní pàjáwìrì tàbí pé o ní láti lo yàrá tí wọ́n ti ń wẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́, èyí lè mú kó o bọ́ aṣọ rẹ kí àwọn ẹlòmíràn sì rí nǹkan àṣírí tó ò ń fi pa mọ́! Ó sàn láti máa “hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo,” nípa yíyẹra fún ẹ̀tàn tí kò mọ́gbọ́n dání.—Hébérù 13:18.

Bíi ti gbogbo àṣà ìgbàlódé, ara fínfín lè di ohun tí kò gbayì mọ́ bí àkókò ṣe ń lọ. Ó dára ná, ǹjẹ́ o ní aṣọ èyíkéyìí, ì báà jẹ́ ṣòkòtò jíǹsì, ṣẹ́ẹ̀tì tàbí bàtà, tó o fẹ́ràn débi pé òun ni wàá máa fi gbogbo ọjọ́ ayé rẹ wọ̀? Kò dájú! Irú aṣọ tí à ń wọ̀, ọ̀nà tí wọ́n ń gbà rán an àti àwọ̀ aṣọ máa ń yí padà. Àmọ́, ara fínfín ò dà bí aṣọ, nítorí pé ó máa ń ṣòro láti mú kúrò. Yàtọ̀ síyẹn, ohun tó ò ń wò bí “ohun tó gbayì” nígbà tó o wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìndínlógún lè máà fi bẹ́ẹ̀ wù ọ́ mọ́ bó o bá di ọmọ ọgbọ̀n ọdún.

Ọ̀pọ̀ ló ń kábàámọ̀ pé àwọ́n ti ṣe ohun tí kò ṣeé pa rẹ́ sí ara wọn. Amy sọ pé: “Kí n tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà ni mo ti fín ara. Mo máa ń gbìyànjú láti fi nǹkan bò ó. Àmọ́, bí àwọn ẹlòmíràn nínú ìjọ bá rí i, ńṣe lojú máa ń tì mí.” Ẹ̀kọ́ wo lo lè rí kọ́ nínú èyí? Rò ó dáadáa kó o tó fín ara. Má ṣe ohun tí wàá máa kábàámọ̀ bó bá yá.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Àwọn èèyàn sábà máa ń ka ẹni tó bá fín ara sí ọmọ ìta

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Bí àkókò ti ń lọ, ọ̀pọ̀ ló máa ń kábàámọ̀ pé àwọn fín ara

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Rò ó dáadáa kó o tó fín ara