Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

(A lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí. Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdáhùn wọn sì wà ní ojú ìwé 24. Fún àfikún ìsọfúnni, wo ìwé “Insight on the Scriptures,” tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.)

1. Nínú àkọsílẹ̀ Bíbélì, tọkọtaya wo ni wọ́n kọ́kọ́ sin sínú hòrò Mákípẹ́là nítòsí Hébúrónì, àwọn wo la sì tún mọ̀ tí wọ́n sin síbẹ̀? (Jẹ́nẹ́sísì 49:29-33; 50:13)

2. Ọmọkùnrin Dáfídì wo ló lẹ́wà débi pé ẹwà rẹ̀ kò láfijọ? (2 Sámúẹ́lì 14:25)

3. Ẹ̀tọ́ jíjẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ ibo ni Pọ́ọ̀lù ti ní látìgbà ìbí rẹ̀? (Ìṣe 22:25-28)

4. Ìkìlọ̀ wo ni Ọlọ́run fún Ádámù nípa èso tá a kà léèwọ̀ náà? (Jẹ́nẹ́sísì 2:17)

5. Lẹ́yìn tí Ọba Rèhóbóámù kọ̀ láti ṣe ohun táwọn èèyàn béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, ọkùnrin wo ni Rèhóbóámù rán sí àwọn ẹ̀yà àríwá tó ṣọ̀tẹ̀, kí ló sì ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin náà? (2 Kíróníkà 10:18)

6. Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé “kò sí ẹnì kan tí ó lè sìnrú fún ọ̀gá méjì”? (Mátíù 6:24)

7. Nígbà tí Jèhófà pèsè mánà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti jẹ, kí ló ń ṣẹlẹ̀ sí èyí tí wọn ò bá kó? (Ẹ́kísódù 16:21)

8. Ta ló da Jésù? (Lúùkù 6:16)

9. Òrìṣà wo làwọn ọmọ Ámónì kà sí pàtàkì jù lọ? (2 Sámúẹ́lì 12:30)

10. Ẹ̀yà ara wo la sábà máa ń lò lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ nínú Bíbélì láti dúró fún lílo okun tàbí agbára ńlá? (Jeremáyà 32:17)

11. Ta ló sọ fún Ọba Ahasuwérúsì pé kí wọ́n yọ Fáṣítì nípò kí wọ́n sì fi ayaba mìíràn rọ́pò rẹ̀? (Ẹ́sítérì 1:14-20)

12. Báwo ni Mósè ṣe sọ omi Márà kíkorò di omi dídùn? (Ẹ́kísódù 15:23-25)

13. Ibo ni ìrìn àjò àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì ti bẹ̀rẹ̀? (Ẹ́kísódù 12:37)

14. Ta ló ń fún Jòsáyà ní ìròyìn bí iṣẹ́ àtúnṣe tẹ́ńpìlì ṣe ń lọ sí tó sì ń kà látinú “ìwé òfin” tí wọ́n rí níbẹ̀ sí etígbọ̀ọ́ ọba? (2 Ọba 22:8-10)

15. Kí ni àwọ̀ àwọn ẹṣin mẹ́rin tí Jòhánù rí gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú ìwé Ìṣípayá, kí ni wọ́n sì dúró fún? (Ìṣípayá 6:2-8)

Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè

1. Ábúráhámù àti Sárà; bákan náà, Ísákì, Rèbékà, Léà àti Jékọ́bù

2. Ábúsálómù

3. Ti Róòmù

4. “Ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ nínú rẹ̀, dájúdájú, ìwọ yóò kú”

5. Hádórámù, olórí àwọn tó ń ṣiṣẹ́ àfipámúniṣe. Wọ́n sọ ọ́ lókùúta pa

6. “Ẹ kò lè sìnrú fún Ọlọ́run àti fún Ọrọ̀”

7. “Nígbà tí oòrùn mú, ó yọ́”

8. Júdásì Ísíkáríótù

9. Málíkámù

10. Apá

11. Mémúkánì, agbọ̀rọ̀sọ fún àwọn ọmọ aládé méje ti Mídíà òun Páṣíà

12. “Jèhófà darí rẹ̀ sí igi kan, ó sì sọ ọ́ sínú omi náà”

13. Rámésésì

14. Ṣáfánì, akọ̀wé ọba

15. Àwọ̀ funfun—ogun òdodo; àwọ̀ iná—ogun ẹ̀dá èèyàn; àwọ̀ dúdú—ìyàn; àwọ̀ ràndánràndán—ikú