Ohun Tó Lè Mú Kí Ìgbéyàwó Rẹ Jẹ́ Aláyọ̀
Ohun Tó Lè Mú Kí Ìgbéyàwó Rẹ Jẹ́ Aláyọ̀
Ìwé ìròyìn La Presse sọ pé: “Ẹ̀tàn díẹ̀díẹ̀ lohun tó ń jẹ́ kí àjọṣe lọ́kọ-láya dùn kó sì lárinrin.” Ìwé ìròyìn ilẹ̀ Kánádà yìí ń sọ̀rọ̀ nípa ìwádìí kan tó sọ irọ́ pípa di ohun tó bójú mu. Inú ìwé Journal of Social and Personal Relationships ni wọ́n tẹ àbájáde ìwádìí yìí sí. Ọ̀jọ̀gbọ́n Tim Cole, tó ń ṣiṣẹ́ ní Yunifásítì De Paul, tó wà ní ìlú Chicago lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, sọ pé: “Nípa ṣíṣe ẹ̀tàn [tàbí píparọ́] níwọ̀nba, a lè mú kí àjọṣe [àárín tọkọtaya] máa lárinrin nìṣó kó má sì sí ìṣòro kankan.”
Àmọ́ o, ǹjẹ́ lóòótọ́ ni ẹ̀tàn lè mú kí ìgbéyàwó láyọ̀? Bíbélì gba àwọn Kristẹni níyànjú pé: “Nísinsìnyí tí ẹ ti fi èké ṣíṣe sílẹ̀, kí olúkúlùkù yín máa bá aládùúgbò rẹ̀ sọ òtítọ́.” (Éfésù 4:25) Ǹjẹ́ ìmọ̀ràn yìí gbéṣẹ́? Nígbà tí wọ́n béèrè lọ́wọ́ amòfin kan tó ń rí sí ọ̀ràn ìkọ̀sílẹ̀ pé, Kí ni olórí ohun tó ń fà á tí àwọn tọkọtaya fi ń túká? ó dáhùn pé: “Àìlè bá ara wọn sọ òótọ́, kí wọ́n sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn fún ara wọn, kí wọ́n sì máa bá ara wọn lò bí ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́.”
Nígbà náà, kí ni àṣírí ìgbéyàwó aláyọ̀? Nínú ìwé náà Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé, orí kẹta ní àkọlé yìí: “Kọ́kọ́rọ́ Méjì sí Ìgbéyàwó Wíwà Pẹ́ Títí.” Ó jíròrò ohun méjì pàtàkì tó lè jẹ́ kó ṣeé ṣe fún tọkọtaya láti máa fi ayọ̀ gbé pọ̀, èyí tó máa fún wọn ní ìbùkún yanturu. O lè béèrè fún ẹ̀dà kan ìwé yìí lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí kí o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sójú ìwé 5 ìwé ìròyìn yìí.
□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.