Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Piñata—Àṣà Àtayébáyé

Piñata—Àṣà Àtayébáyé

Piñata—Àṣà Àtayébáyé

LÁTỌWỌ́ ÒǸKỌ̀WÉ JÍ! NÍ MẸ́SÍKÒ

ÀWỌN ọmọdé àdúgbò ń ṣe àjọyọ̀. À ń gbọ́ tí wọ́n ń fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ kígbe pé: “Là á mọ́ ọn! Là á mọ́ ọn! Là á mọ́ ọn!” Nígbà tá a yọjú wo àgbàlá, a rí ère kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí wọ́n fi bébà tí wọ́n ti rẹ sómi àti àtè ṣe, wọ́n kùn ún ní àwọ̀ oríṣiríṣi, wọ́n sì so ó rọ̀ sáàárín igi méjì. Ọmọ kan tí wọ́n fi aṣọ bò lójú ń la igi kan mọ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà, ó sì ń gbìyànjú láti fọ́ ọ. Àwọn àlejò ń hó yèè bí wọ́n ti ń ṣe kóríyá fún un. Níkẹyìn, ère kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà fọ́, àwọn midinmíìdìn, èso àtàwọn ohun ìṣeré tó wà nínú rẹ̀ sì tú dà sílẹ̀. Àwọn ọmọdé náà ń rẹ́rìn-ín kèékèé, gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ sì ń ṣe kìtìkìtì láti ṣa àwọn ohun tó dà sílẹ̀ náà. Bẹ́ẹ̀ ni inú wọn ń dùn ṣìnkìn. Wọ́n sọ fún wa pé orúkọ tí wọ́n ń pe kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà ni piñata, àti pé fífọ́ piñata níbi àjọyọ̀ jẹ́ àṣà àtayébáyé lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò àtàwọn orílẹ̀-èdè Látìn Amẹ́ríkà mìíràn.

A bẹ̀rẹ̀ sí ṣe kàyéfì nípa ìdí tí piñata fi gbajúmọ̀ tó bẹ́ẹ̀. Ibo ló ti bẹ̀rẹ̀? Ǹjẹ́ fífọ́ piñata ní ìtumọ̀ pàtàkì èyíkéyìí? A pinnu láti tú iṣu ọ̀ràn náà dé ìsàlẹ̀ ìkòkò.

Piñata Ṣe Bẹ̀rẹ̀

Èrò kan tó wọ́pọ̀ ni pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn èèyàn ilẹ̀ Ṣáínà ló kọ́kọ́ lo ohun kan bíi piñata gẹ́gẹ́ bí apá kan ayẹyẹ Ọdún Titun wọn, èyí tó tún ń sàmì sí ìbẹ̀rẹ̀ ìgbà ìrúwé. Wọ́n máa ń ṣe àwọn ère màlúù àti ẹfọ̀n, wọ́n á wá lẹ bébà aláwọ̀ mèremère mọ́ wọn lára, wọ́n á sì kó oríṣi kóró irúgbìn márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ kún inú wọn. Àwọn igi tẹ́ẹ́rẹ́ tí wọ́n kùn ni wọ́n máa ń lò láti fi fọ́ àwọn ère náà. Wọ́n á sun bébà aláwọ̀ mèremère tí wọ́n fi ṣe ère náà lọ́ṣọ̀ọ́, wọ́n á sì kó eérú náà pa mọ́ gẹ́gẹ́ bí oògùn oríire fún ọdún tó ń bọ̀.

Èrò àwọn kan ni pé ní ọ̀rúndún kẹtàlá, Marco Polo, arìnrìn-àjò kan tó jẹ́ ará ìlú Venice nílẹ̀ Ítálì, ló mú àṣà yìí wá láti ilẹ̀ Ṣáínà sí orílẹ̀-èdè Ítálì. Ibẹ̀ ni àṣà náà ti gba orúkọ tí wọ́n ń pè é báyìí, ìyẹn látinú ọ̀rọ̀ ilẹ̀ Ítálì náà pignatta, tó túmọ̀ sí ìkòkò ẹlẹgẹ́; wọ́n á sì kó onírúurú ohun ọ̀ṣọ́ tàbí midinmíìdìn sínú piñata náà dípò kóró irúgbìn. Lẹ́yìn náà ni àṣà yìí tàn kálẹ̀ lọ sí orílẹ̀-èdè Sípéènì. Fífọ́ piñata wá di àṣà ní gbogbo Sunday àkọ́kọ́ nígbà Lẹ́ǹtì. a Ó dà bíi pé ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kẹrìndínlógún làwọn míṣọ́nnárì ará Sípéènì mú àṣà yìí wá sí ilẹ̀ Mẹ́síkò.

Àmọ́ o, àfàìmọ̀ ni ẹnu ò ní ya àwọn míṣọ́nnárì ará Sípéènì náà (gẹ́gẹ́ bí ẹnu ṣe ya àwa náà) láti rí i pé àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Mẹ́síkò ti ní irú àṣà yìí tẹ́lẹ̀. Àwọn ẹ̀yà Aztec máa ń ṣàjọyọ̀ ọjọ́ ìbí Huitzilopochtli, ìyẹn ọlọ́run oòrùn àti ogun, nípa gbígbé ìkòkò amọ̀ kan sórí òpó kan nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀ ní ìparí ọdún. Wọ́n á fi àwọn ìyẹ́ ẹyẹ tó ní onírúurú àwọ̀ ṣe ìkòkò náà lọ́ṣọ̀ọ́, wọ́n á sì kó àwọn ohun ọ̀ṣọ́ kéékèèké kúnnú rẹ̀. Wọ́n á wá la igi mọ́ ọn, wọ́n á sì fi àwọn ìṣúra tó bá dà sílẹ̀ látinú rẹ̀ rúbọ sí ère ọlọ́run wọn. Àwọn ẹ̀yà Maya náà máa ń ṣe eré kan nínú èyí tí àwọn tí wọ́n fi aṣọ bò lójú ti máa ń la igi mọ́ ìkòkò amọ̀ kan tí wọ́n so rọ̀.

Ọgbọ́n kan tí àwọn míṣọ́nnárì ará Sípéènì náà máa ń dá láti yí àwọn ẹ̀yà Íńdíà náà lọ́kàn padà ni lílo piñata. Wọ́n máa ń kọ́ wọn pé ọ̀kan lára ohun tí piñata náà dúró fún ni bí àwọn Kristẹni ṣe ń jìjàkadì láti borí Èṣù àti ẹ̀ṣẹ̀. Ohun tí wọ́n fi ń ṣe piñata láyé àtijọ́ ni ìkòkò amọ̀ tí wọ́n lẹ bébà aláwọ̀ mèremère mọ́ lára, èyí tí wọ́n máa ń ṣe ní ìrísí ìràwọ̀ onígun méje, tí wọ́n sì máa ń ṣe wajawaja sí àwọn igun rẹ̀ méjèèje yíká. Wọ́n ní àwọn igun méje wọ̀nyí dúró fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ méje tó lè yọrí sí ikú, ìyẹn ni ìwọra, àjẹkì, ìmẹ́lẹ́, ìgbéraga, ìlara, ìrunú àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́. Líla tí ẹni tó da nǹkan bojú máa ń la igi mọ́ piñata túmọ̀ sí bí ìgbàgbọ́ gbà-láìjanpata àti ìpinnu lílágbára ṣe ń borí àdánwò tàbí ibi. Àwọn ohun tó wà nínú piñata náà ni èrè téèyàn á gbà.

Àṣà Piñata Lóde Òní

Nígbà tó yá, piñata wá di apá kan ayẹyẹ posadas b tí wọ́n máa ń ṣe nígbà Kérésìmesì, wọ́n sì ń ṣe é títí di òní olónìí. (Wọ́n máa ń lo piñata onírìísí ìràwọ̀ láti ṣàpẹẹrẹ ìràwọ̀ tó darí àwọn awòràwọ̀ lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.) Bákan náà, wọn ò lè ṣe kí wọ́n máà fọ́ piñata níbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí. Àní, àṣà piñata ti fìdí múlẹ̀ nílẹ̀ Mẹ́síkò débi pé wọ́n máa ń kó ère rẹ̀ lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn.

A ṣàkíyèsí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ilẹ̀ Mẹ́síkò kò wo piñata bí apá kan ìjọsìn mọ́, ohun ṣeréṣeré lásán sì ni ọ̀pọ̀ kà á sí. Ká sọ tòótọ́, wọ́n máa ń fọ́ piñata níbi ọ̀pọ̀ ayẹyẹ nílẹ̀ Mẹ́síkò, kì í ṣe nígbà ayẹyẹ posadas tàbí nígbà ọjọ́ ìbí nìkan. Oríṣiríṣi piñata lèèyàn sì lè rí rà yàtọ̀ sí bí wọ́n ṣe ń ṣe é bí ìràwọ̀ nígbà àtijọ́. Wọ́n lè ṣe é kó rí bí ẹranko, òdòdó tàbí ọmọlangidi.

Bí àwọn Kristẹni bá ń wò ó bóyá kí àwọ́n lọ́wọ́ nínú àṣà piñata níbi àpèjẹ kan, ó yẹ kí wọ́n ronú nípa bí èyí kò ṣe ní kó ìdààmú bá ẹ̀rí ọkàn àwọn ẹlòmíràn. (1 Kọ́ríńtì 10:31-33) Kì í ṣe ohun tí àṣà yìí túmọ̀ sí ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn ló ṣe pàtàkì jù àmọ́ ojú táwọn èèyàn fi ń wò ó lóde òní ní àgbègbè rẹ. Láìsí àní-àní, èrò tí àwọn èèyàn ní nípa rẹ̀ lè yàtọ̀ láti àgbègbè kan sí òmíràn. Nípa báyìí, ó bọ́gbọ́n mu láti ṣọ́ra fún sísọ irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ di nǹkan ńlá. Bíbélì sọ pé: “Kí olúkúlùkù má ṣe máa wá àǹfààní ti ara rẹ̀, bí kò ṣe ti ẹnì kejì.”—1 Kọ́ríńtì 10:24.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Nínú àwọn ìsìn kan, irú bí ẹ̀sìn Kátólíìkì, Lẹ́ǹtì ni ogójì ọjọ́ ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, ohun tó sì máa ń tẹ̀ lé e ni ayẹyẹ Ọ̀sẹ̀ Mímọ́ nígbà Ọdún Àjíǹde.

b Nílẹ̀ Mẹ́síkò, ayẹyẹ posadas jẹ́ ayẹyẹ ọlọ́jọ́ mẹ́sàn-án kan tí wọ́n máa ń ṣe ṣáájú Kérésìmesì, láti fi ṣàṣefihàn bí Jósẹ́fù àti Màríà ṣe ń wá posada tàbí ibùwọ̀. Wọ́n máa ń fọ́ piñata láti fi ṣe àṣekágbá ayẹyẹ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ní gbogbo alẹ́ ọjọ́ mẹ́sàn-án náà.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Bó o bá ń wò ó bóyá kó o lo lọ́wọ́ nínú àṣà “piñata” níbi àpèjẹ kan, ó yẹ kó o ronú nípa bí èyí kò ṣe ní kó ìdààmú bá ẹ̀rí ọkàn àwọn ẹlòmíràn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Onírúurú ọ̀nà ni wọ́n ń gbà ṣe “piñata,” ó sì máa ń tóbi ju ara wọn lọ