Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wíwo Ayé

Wíwo Ayé

Wíwo Ayé

Ewu Tó Wà Nínú Ṣíṣe Ọ̀pọ̀ Nǹkan Lẹ́ẹ̀kan

Ìwé ìròyìn The Wall Street Journal sọ pé, ṣíṣe ohun tó ju ẹyọ kan lọ lẹ́ẹ̀kan náà “kò ní jẹ́ kó o lè ṣiṣẹ́ tó pójú owó, àní, ó tún lè sọ ọ́ di ẹni tí kì í ṣe nǹkan lọ́nà tó dára. Gbígbìyànjú láti ṣe nǹkan méjì tàbí mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lásìkò kan náà tàbí kó o máa mú iṣẹ́ kan mọ́ òmíràn máa gba àkókò tó pọ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn ju kó o máa ṣe wọ́n lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan lọ, kò sì ní jẹ́ kó o lè fi làákàyè ṣe iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ.” Lára àwọn àmì tó lè fi hàn pé ìṣòro ti wà ni: kéèyàn máa tètè gbàgbé nǹkan (irú bíi gbígbàgbé ohun tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe tàbí tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán), àìlè fara balẹ̀ ṣe nǹkan, kéèyàn má lè pọkàn pọ̀ sórí ohun tó ń ṣe, kéèyàn ní àwọn àmì tó ń fi hàn pé èèyàn ní másùnmáwo (irú bí àìlè mí kanlẹ̀ dáadáa) àti kéèyàn má lè ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó dán mọ́rán pẹ̀lú àwọn èèyàn. Àtiṣiṣẹ́ yanjú máa ń ṣòro nígbà tó bá jẹ́ pé apá kan náà nínú ọpọlọ ni wàá lò láti fi ṣe nǹkan ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, irú bíi bíbá ẹnì kan sọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù àti lẹ́sẹ̀ kan náà fífetísí ọmọ kan tó ń pariwo sọ̀rọ̀ látinú iyàrá kejì. Ìgbà téèyàn bá ń wakọ̀ ni ṣíṣe ọ̀pọ̀ nǹkan lẹ́ẹ̀kan náà tiẹ̀ léwu jù. Àwọn ohun bíi jíjẹ tàbí mímu, nínawọ́ mú nǹkan, jíjẹ́ kí ọ̀rọ̀ téèyàn ń sọ pẹ̀lú èrò ọkọ̀ kan tàbí lórí tẹlifóònù gbani lọ́kàn léwu gan-an, àní lílo nǹkan ìṣaralóge tàbí yíyí rédíò tàbí ohun mìíràn nínú mọ́tò pàápàá lè mú kí ọkàn rẹ pínyà fún ìṣẹ́jú àáyá díẹ̀, èyí sì lè yọrí sí jàǹbá ọkọ̀.

Má Ṣe Gbo Ọmọ Ọwọ́ Jìgìjìgì!

Ìwé ìròyìn Toronto Star sọ pé gbígbo ọmọ ọwọ́ jìgìjìgì máa ń fa ìpalára “tó lè mú kí orí ọmọ máa ṣẹ̀jẹ̀ sínú kí ìnira sì bá ọpọlọ, èyí sì lè mú kí ọpọlọ là.” Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn iṣan tó wà nínú ọpọlọ àwọn ọmọ ọwọ́ kò tíì gbó, tí ọpọlọ wọn sì jẹ́ ẹlẹgẹ́, “gbígbo ọmọ ọwọ́ jìgìjìgì fún kìkì ìṣẹ́jú àáyá díẹ̀ lè ṣèpalára fún un jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀. Lára ìpalára tí èyí lè fà ni kí ọpọlọ wú tàbí kó dàrú, kí ọmọ ní àrùn tí kì í jẹ́ kí ọpọlọ lè darí ìséraró àti ìsọ̀rọ̀, kí ọmọdé ya dìndìnrìn, kí ọmọdé rán, ìfọ́jú, etí dídi, àrùn rọpárọsẹ̀ àti ikú.” Dókítà James King, olùtọ́jú àrùn àwọn ọmọdé ní Ilé Ìwòsàn Àwọn Ọmọ Wẹ́wẹ́ ní Ìlà Oòrùn Ontario lórílẹ̀-èdè Kánádà, ti ṣèwádìí lórí àwọn ohun tó lè jẹ́ àbájáde gbígbo ọmọ ọwọ́ jìgìjìgì. Ó sọ pé ó yẹ ká dá àwọn aráàlú lẹ́kọ̀ọ́, nítorí pé lọ́pọ̀ ìgbà àwọn ìpalára náà kì í fi bẹ́ẹ̀ tètè fara hàn, àti pé ó ṣeé ṣe kí wọ́n máa rò pé ibà tàbí otútù àyà lásán ló ń ṣe ọmọ náà. Dókítà King sọ pé: “Ó yẹ ká máa tẹ kókó yìí mọ́ àwọn èèyàn létí, ká sì máa sọ ọ́ gbọnmọgbọnmọ. Àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ gbọ́dọ̀ mọ̀ bẹ́ẹ̀.”

Wọn Ò Ka Ọ̀ràn Ẹ̀sìn Sí Mọ́

Ìwé ìròyìn IHT Asahi Shimbun sọ pé: “Kò dà bíi pé àwọn èèyàn [ilẹ̀ Japan] tún ń fi bẹ́ẹ̀ yíjú sí ìsìn mọ́ láti fi wá ojútùú sí ìṣòro wọn bí wọ́n ṣe ń làkàkà láti kojú àwọn ipò nǹkan tí kò bára dé lóde òní.” Nígbà tí wọ́n béèrè ìbéèrè náà, “Ǹjẹ́ o nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀ràn ẹ̀sìn tàbí ṣé ohun kan wà tó o gbà gbọ́?” lọ́wọ́ àwọn aráàlú, kìkì ìdá mẹ́tàlá nínú ọgọ́rùn-ún wọn ló dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni. Láfikún sí i, ìdá mẹ́sàn-án nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọkùnrin àti ìdá mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn-ún àwọn obìnrin sọ pé àwọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀ràn ẹ̀sìn “lọ́nà kan ṣáá.” Ìwé ìròyìn náà fi kún un pé: “Ó hàn gbangba pé àwọn obìnrin tó ti lé lọ́mọ ogún ọdún kò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ìsìn rárá, nítorí pé wọn kò ju ìdá mẹ́fà lọ.” Ìwádìí ọlọ́dọọdún náà fi hàn pé ìdá mẹ́tàdínlọ́gọ́rin nínú àwọn ọkùnrin nílẹ̀ Japan àti ìdá mẹ́rìndínlọ́gọ́rin nínú àwọn obìnrin sọ pé àwọn kò nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀ràn ẹ̀sìn rárá bẹ́ẹ̀ làwọn ò gba ohunkóhun gbọ́. Tí a bá fi àbájáde ìwádìí yìí wé ti ọdún 1978, kò sí àní-àní pé ńṣe ni iná ìtara àwọn èèyàn ilẹ̀ Japan fún ẹ̀sìn túbọ̀ ń jó àjórẹ̀yìn. Àwọn àgbàlagbà ló dà bíi pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ díẹ̀ sí ọ̀ràn ẹ̀sìn, pàápàá àwọn tó ti lé lọ́mọ ọgọ́ta ọdún.

Àárẹ̀ Ọkàn Ń Dá Kún Àwọn Àìsàn Mìíràn

Ìwé ìròyìn U.S.News & World Report sọ pé: “Àjọ Ìlera Àgbáyé sọ pé bó bá fi máa di ọdún 2020, bí a bá yọwọ́ àrùn ọkàn, olórí ohun tí yóò máa sọ àwọn èèyàn jákèjádò ayé di aláìlera ni àárẹ̀ ọkàn.” Onírúurú ìwádìí ló túbọ̀ ń fi hàn pé ìṣòro bíburú jáì tí ń ṣàkóbá fún ìlera yìí “kì í ṣe ìṣòro ọpọlọ nìkan.” Ọ̀gbẹ́ni Philip Gold, ọ̀gá nínú ìmọ̀ ìṣègùn nípa ètò ìgbékalẹ̀ iṣan ara ní Ilé Ẹ̀kọ́ Tó Ń Rí sí Ìṣiṣẹ́ Ọpọlọ, sọ pé “àárẹ̀ ọkàn nìkan ni àrùn ara tó ń dá kún ọ̀pọ̀ àìsàn mìíràn, kódà, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àwọn àìsàn mìíràn ló lè dá kún.” Àní, àárẹ̀ ọkàn lè dá kún àwọn àìsàn bí àrùn ọkàn àti àtọ̀gbẹ. Bí àpẹẹrẹ, ìwádìí fi hàn pé “ọkàn [àwọn tó ní àárẹ̀ ọkàn] kì í ṣiṣẹ́ dáadáa, nítorí pé kì í lè pèsè ẹ̀jẹ̀ àti afẹ́fẹ́ ọ́síjìn tí ara ń fẹ́” gẹ́gẹ́ bí àpilẹ̀kọ náà ṣe ṣàlàyé. Bákan náà, “ọpọlọ tí ìdààmú ti bá máa ń nílò okun púpọ̀ sí i, èyí sì lè mú kí omi ara tó ń jẹ́ cortisol tú jáde sí i, tí ìyẹn á sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí ìwọ̀n ṣúgà inú ẹ̀jẹ̀ lọ sókè sí i.” Wọ́n tún ti ṣàwárí pé àárẹ̀ ọkàn lè dá kún àrùn àìlágbára egungun àti àrùn jẹjẹrẹ. Ìwádìí ń lọ lọ́wọ́ láti mọ̀ bóyá wíwo àárẹ̀ ọkàn lè mú kí irú àwọn àrùn bẹ́ẹ̀ máà fi bẹ́ẹ̀ lágbára mọ́.

Ipa Tí Ìgbéyàwó Ń Ní Lórí Ọkàn

Ìwé ìròyìn The Daily Telegraph ti ìlú London sọ pé: “Ìwádìí ti fi hàn pé bí ìgbéyàwó aláìsàn kan tó ní àrùn ọkàn bá ṣe gbéṣẹ́ sí lè pinnu bí onítọ̀hún á ṣe kọ́fẹ padà sí tí wọ́n bá ṣiṣẹ́ abẹ fún un.” Dókítà James Coyne, tó ń ṣiṣẹ́ ní Yunifásítì Pennsylvania, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé, bí aláìsàn kan bá ní ìgbéyàwó aláyọ̀, èyí lè fún un níṣìírí láti jà fitafita kó lè bọ̀ sípò, àmọ́ “ó máa ṣòro gan-an fún aláìsàn tí ìgbéyàwó rẹ̀ kò láyọ̀ láti kọ́fẹ padà ju aláìsàn tí kò ṣègbéyàwó lọ.” Dókítà Coyne àtàwọn tó wà nínú àwùjọ aṣèwádìí rẹ̀ gba àwòrán àwọn tọkọtaya tó ń ní gbólóhùn asọ̀ nínú ilé sílẹ̀ sórí kásẹ́ẹ̀tì fídíò, wọ́n sì ṣàkíyèsí pé ó ṣeé ṣe kí àwọn alárùn ọkàn tí àjọṣe wọn pẹ̀lú àwọn alábàáṣègbéyàwó wọn kò gún régé tètè kú láàárín ọdún mẹ́rin ní ìfiwéra pẹ̀lú àwọn tí kì í fi bẹ́ẹ̀ sí aáwọ̀ láàárín wọn. Dókítà Linda Waite, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ nípa ìbágbépọ̀ ẹ̀dá ní Yunifásítì Chicago, sọ pé ìgbéyàwó dáradára “la lè fi wé jíjẹ oúnjẹ aṣaralóore, ṣíṣe eré ìmárale àti ṣíṣàì mu sìgá.”

Igi Tí Wọ́n Fi Ń Ṣe Gìtá Violin Ti Ń Tán Lọ Nígbó O

Ìwé ìròyìn kan lórí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì nílẹ̀ Jámánì, ìyẹn natur & kosmos sọ pé: “Igi àkànṣe kan wà tó dára gan-an fún ṣíṣe gìtá violin, àmọ́ igi yìí ti ń tán lọ nígbó.” Igi tí wọ́n ń lò náà ni igi Caesalpinia echinata. A lè rí igi yìí nínú igbó tó wà létíkun orílẹ̀-èdè Brazil. Àmọ́, igbó yìí ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pa run tán o nítorí bí àwọn èèyàn ṣe ń gé igi ibẹ̀ dà nù láti ṣe iṣẹ́ àgbẹ̀. Ìwọ̀nba díẹ̀ ló ṣẹ́ kù lára igi náà nínú igbó yìí, ó sì wà lára àwọn igi tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pa run tán. Ìyẹn nìkan kọ́ o, kìkì àwọn igi tó ti pé ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ló ti máa ń gbó débi pé inú wọn á ní àwọ̀ ìyeyè tàbí àwọ̀ pupa rẹ́súrẹ́sú, èyí tó dára gan-an fún ṣíṣe gìtá violin. Àpilẹ̀kọ náà sọ pé, gẹ́gẹ́ bí ọ̀gbẹ́ni Thomas Gerbeth, àgbà ọ̀jẹ̀ nínú ṣíṣe gìtá violin ṣe sọ, kò sí ohun mìíràn tó ṣeé fi rọ́pò igi yìí nítorí pé “kò tíì sí ohun èlò àtọwọ́dá kan tí wọ́n mú jáde tó dà bí igi yìí.” Ní báyìí, bí àwọn tó ń ṣe ohun èlò ìkọrin violin ṣe ń ké gbàjarè làwọn olórin náà ń ké gbàjarè pé kí wọ́n máà jẹ́ kí igi yìí run o.

Àrùn Ògbólógbòó Tí Kò Tíì Kásẹ̀ Ńlẹ̀

Ìwé ìròyìn El País ti ilẹ̀ Sípéènì sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí ìsọfúnni tó wá látọ̀dọ̀ Àjọ Ìlera Àgbáyé ṣe fi hàn, ó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [700,000] èèyàn tí àwọn oníṣègùn ṣàwárí jákèjádò ayé lọ́dún 2002 pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ní àrùn ẹ̀tẹ̀.” Látìgbà tí wọ́n ti ń kọ Bíbélì ni àrùn ẹ̀tẹ̀ ti jẹ́ àrùn bíbanilẹ́rù. Lóde òní, irú àrùn ẹ̀tẹ̀ tó ń ṣe àwọn èèyàn ṣeé wò. Àní, nǹkan bíi mílíọ̀nù méjìlá èèyàn ni àrùn ẹ̀tẹ̀ wọn ti sàn láàárín ogún ọdún tó kọjá. Àmọ́ ṣá o, “a ò tíì lè fọwọ́ sọ̀yà pé àrùn ẹ̀tẹ̀ ti kásẹ̀ ńlẹ̀ pátápátá,” ni ohun tí olùṣèwádìí Jeanette Farrell sọ. Kò tíì ṣeé ṣe fún àwọn oníṣègùn láti mú àìsàn náà kúrò, bẹ́ẹ̀ ni kò sì yé mú àwọn èèyàn. Títí di báyìí, àwọn orílẹ̀-èdè tí àrùn náà ti ń jà jù ni ilẹ̀ Brazil, Burma, Íńdíà, Madagascar, Mòsáńbíìkì àti Nepal. Látàrí pé òye tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ń ní nípa apilẹ̀ àbùdá túbọ̀ ń pọ̀ sí i, wọ́n retí pé àwọ́n á rí abẹ́rẹ́ àjẹsára tó lè gbọ́ àrùn yìí.

Bí Ọkùnrin Ṣe Pọ̀ Ju Obìnrin Lọ ní Ilẹ̀ Ṣáínà Ń Kọni Lóminú

Ìwé ìròyìn China Today sọ pé: “Àbájáde ètò ìkànìyàn ẹlẹ́ẹ̀karùn-ún tó wáyé nílẹ̀ Ṣáínà fi hàn pé, iye ọmọkùnrin tí wọ́n ń bí báyìí pọ̀ ju ọmọbìnrin lọ, nítorí pé ní ìpíndọ́gba, bí a bá kó ọgọ́rùn-ún ọmọbìnrin jọ, a óò rí nǹkan bí ẹ̀tàdínlọ́gọ́fà [117] ọmọkùnrin, àmọ́ ní ìfiwéra pẹ̀lú ìṣirò ọdún 1990, bí a bá kó ọgọ́rùn-ún ọmọbìnrin jọ nígbà yẹn a ò lè rí ju nǹkan bí ọmọkùnrin mẹ́rìnléláàádọ́fà [114] lọ. Ìṣirò méjèèjì yìí ju iye tí a sábà máa ń rí kárí ayé lọ fíìfíì, ìyẹn ni pé bí a bá kó ọgọ́rùn-ún ọmọbìnrin jọ iye ọmọkùnrin tá a máa ń rí kì í ju márùnlélọ́gọ́rùn-ún [105] lọ, èyí sì fi hàn pé ńṣe ni ọ̀ràn bí ọkùnrin ṣe ń pọ̀ ju obìnrin lọ nílẹ̀ Ṣáínà túbọ̀ ń burú sí i.” Wọ́n fojú bù ú pé lọ́jọ́ iwájú, nǹkan bí àádọ́ta mílíọ̀nù ọkùnrin lórílẹ̀-èdè Ṣáínà ni kò ní ṣeé ṣe fún láti rí ìyàwó fẹ́ bí wọ́n bá tó ẹni tó ń láya. Àpilẹ̀kọ náà fi kún un pé: “Zheng Zizhen, ọ̀gá àgbà Àjọ Tó Ń Rí sí Ìbágbépọ̀ Ẹ̀dá àti Iye Èèyàn Tó Wà ní Àgbègbè Guangdong, ni wọ́n fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ pé, bí ọmọkùnrin ṣe ń pọ̀ ju ọmọbìnrin lọ láìdáwọ́dúró yìí yóò ṣàkóbá fún iye èèyàn tó wà nílẹ̀ Ṣáínà, fún àwùjọ àti fún ìlànà ìwà híhù.”