Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìdí Tí Orúkọ Jèhófà Fi Gbajúmọ̀ Ní Erékùṣù Pàsífíìkì

Ìdí Tí Orúkọ Jèhófà Fi Gbajúmọ̀ Ní Erékùṣù Pàsífíìkì

Ìdí Tí Orúkọ Jèhófà Fi Gbajúmọ̀ Ní Erékùṣù Pàsífíìkì

LÁTỌWỌ́ ÒǸKỌ̀WÉ JÍ! NÍ FÍJÌ

ÌYÀLẸ́NU gbáà ló jẹ́ fún àwọn èèyàn náà. Àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gúnlẹ̀ sí erékùṣù wọn ní Pàsífíìkì dijú láti gbàdúrà kí wọ́n tó jẹ oúnjẹ tí wọ́n fi ṣe wọ́n lálejò. Àwọn olùgbé erékùṣù náà bi wọ́n pé: “Kí lẹ̀ ń ṣe?”

Wọ́n dáhùn pé: “À ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nítorí ẹ̀bùn tó fún wa ni.”

Àwọn èèyàn náà ṣì fẹ́ mọ̀ sí i, wọ́n wá béèrè pé: “Níbo ni Ọlọ́run yín ń gbé?”

Wọn dá wọn lóhùn pé: “Ọ̀run ni.”

“Kí ni orúkọ Rẹ̀?”

“Jèhófà.”

“Ṣé Ọlọ́run yín máa ń jẹun?”

Àwọn àlejò náà fèsì pé: “Ẹ̀mí ni Ọlọ́run. Kì í ṣe èèyàn bíi tiwa; Ẹni ayérayé ni. Òun ló dá ilẹ̀ ayé, òfuurufú, òkun àti ohun gbogbo. Òun náà ló dá wa.”

Háà ṣe àwọn ará erékùṣù náà láti gbọ́ àlàyé tó rọrùn tó sì yéni yìí, wọ́n sì béèrè ìdí tí àwọn àlejò náà fi wá sí erékùṣù àwọn. Wọ́n rọra fèsì pé: “A wá láti sọ fún yín nípa Jèhófà, Ọlọ́run òtítọ́, àti Ọmọ Rẹ̀ Jésù Olùgbàlà wa ni.”—Látinú ìwé From Darkness to Light in Polynesia.

Ta ni àwọn àlejò wọ̀nyí? Ṣé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní ni? Rárá o. Àwọn ará Tàhítì méjì tí wọ́n jẹ́ olùkọ́ àti ajíhìnrere ni. Wọ́n gúnlẹ̀ sí erékùṣù Mangaia (ní ìhà gúúsù àwọn àgbájọ erékùṣù Cook Islands) ní June 15, 1824. Kí nìdí tí wọ́n fi lo orúkọ náà, Jèhófà? Ṣé ìgbà yẹn nìkan ṣoṣo ni wọ́n lò ó? Ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí á jẹ́ ká lóye ìdí tí orúkọ Jèhófà fi ṣe pàtàkì gan-an títí di òní olónìí nínú àṣà ìbílẹ̀ ọ̀pọ̀ àwọn olùgbé erékùṣù Pàsífíìkì.

Wọ́n Lo Orúkọ Ọlọ́run Jákèjádò Erékùṣù Náà

Ọ̀pọ̀ àwọn míṣọ́nnárì tó ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà lọ sí erékùṣù Pàsífíìkì ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún máa ń lo orúkọ náà, Jèhófà nígbàkigbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ àti nínú àwọn ìwé tí wọ́n kọ. Kódà, òpìtàn kan tiẹ̀ fi àìmọ̀kan sọ pé “ọmọlẹ́yìn Jèhófà” ni àwọn míṣọ́nnárì ìjímìjí náà, “wọn kì í ṣe ọmọlẹ́yìn Kristi.”

Àwọn lẹ́tà tí àwọn míṣọ́nnárì wọ̀nyí kọ sábà máa ń bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn àpólà ọ̀rọ̀ bíi: “Ǹjẹ́ kí Ọlọ́run wa, àní Olúwa wa Jèhófà àti Jésù Kristi ọba àlàáfíà, gbà ọ́ là.” Abájọ nígbà náà tí Albert J. Schütz, gbajúmọ̀ onímọ̀ èdè púpọ̀, fi sọ pé wọ́n tẹ ìwé akọ́mọlédè kan jáde ní erékùṣù Fíjì lọ́dún 1825. Ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo tó tinú èdè Gẹ̀ẹ́sì wá tá a lè rí nínú ìwé náà ni Jehova.

Lílò tí àwọn míṣọ́nnárì ìjímìjí ń lo orúkọ Jèhófà ní fàlàlà wọ àwọn tó ń gbé ní erékùṣù Pàsífíìkì lọ́kàn ṣinṣin. Díẹ̀ lára àwọn olùgbé erékùṣù náà tí wọ́n fún ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ ni wọ́n wá rán jáde gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì, tàbí olùkọ́, láti lọ fi ẹ̀kọ́ náà kọ́ àwọn èèyàn ní àwọn erékùṣù mìíràn. Nígbà tí ìwé The Covenant Makers—Islander Missionaries in the Pacific ń ṣàlàyé nípa àwọn míṣọ́nnárì ará Tàhítì méjì tá a sọ pé wọ́n gúnlẹ̀ sí erékùṣù Mangaia, ó sọ pé: “Ní ti àwọn olùkọ́ ará Tàhítì yìí o, Jèhófà ni Ọlọ́run òtítọ́ kan ṣoṣo. Òun ló dá gbogbo àgbáyé, ẹ̀dá ènìyàn sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun tó dá. . . . [Wọ́n] sọ pé Jèhófà ni Ọlọ́run òtítọ́ kan ṣoṣo náà àti pé Ọmọkùnrin Rẹ̀, Jésù Kristi, ni Olùgbàlà aráyé.”

Bí díẹ̀ lára àwọn míṣọ́nnárì ìjímìjí náà ṣe ń mú ìhìn Bíbélì lọ láti erékùṣù kan dé òmíràn, wọ́n dojú kọ ewu ńláǹlà, nítorí pé àwọn tó ń gbébẹ̀ máa ń hùwà ẹhànnà nígbà míì. Nígbà tó ń ṣàlàyé ìṣòro tó má ń kojú wọn, ìwé Mission, Church, and Sect in Oceania sọ pé: “Ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Jèhófà sábà máa ń borí ìbẹ̀rù àti àìnírètí.”

A rí àpẹẹrẹ títayọ nípa irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ nínú Jèhófà lọ́dún 1823 nígbà tí wọ́n mú ìhìn Bíbélì wọ erékùṣù Rarotonga, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àgbájọ erékùṣù Cook Islands. Nígbà tí míṣọ́nnárì kan tó tún jẹ́ atukọ̀ òkun, John Williams débẹ̀, ó rán àwọn tọkọtaya méjì pé kí wọ́n lọ kọ́ àwọn olùgbé erékùṣù Rarotonga lẹ́kọ̀ọ́. Àmọ́, èdèkòyédè wáyé láàárín wọn àti ọba wọn tó ti yó bìnàkò, wọ́n sì lu àwọn míṣọ́nnárì náà bí-ẹní-máa-kú. Wọ́n jí gbogbo ohun ìní wọn kó, díẹ̀ ló sì kù kí wọ́n gbẹ̀mí wọn.

Nígbà tí àwọn míṣọ́nnárì náà padà dénú ọkọ̀, wọ́n ṣàlàyé pé àwọn olùgbé erékùṣù Rarotonga ni ẹhànnà tó rorò jù lọ tí àwọ́n tíì bá pàdé rí. Kí ohun tó burú jùyẹn lọ má bàa ṣẹlẹ̀, Williams pinnu láti sá kúrò ní erékùṣù náà, ó kéré tán fún àkókò díẹ̀. Kò tíì ṣíkọ̀ rárá tí Papeiha, ọ̀dọ́kùnrin kan tí òun pẹ̀lú jẹ́ olùkọ́, fi yọ̀ǹda pé òun á dá lọ wàásù fún àwọn olùgbé erékùṣù náà. Ó sọ pé: “Àwọn ẹhànnà náà ì báà pa mí, wọn ì báà dá mi sí, màá lọ bá wọn ṣáá ni.”

Papeiha sọ gbólóhùn kan tí àwọn èèyàn sábà máa ń fà yọ nínú àkọsílẹ̀ ìgbòkègbodò àwọn míṣọ́nnárì ìjímìjí, ìyẹn ni pé: “Ko Jehova toku tiaki! Tei roto au i tona rima! (Jèhófà ni olùṣọ́ àgùntàn mi! Ọwọ́ Rẹ̀ ni mo fi ẹ̀mí mi lé!)” Bó ti sọ bẹ́ẹ̀ tán, ó gbé aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ kan wọ̀, ó sì mú ìwé kan tó ní àyọkà díẹ̀ látinú Bíbélì èdè Tàhítì, àfi jùà ló bẹ́ sómi, ó sì lúwẹ̀ẹ́ padà sí èbúté erékùṣù náà. Àṣeyọrí tó ṣe kúrò ní kékeré. Nígbà tó débẹ̀, ọ̀pọ̀ lára àwọn tó wà níbẹ̀ ló fetí sí ẹ̀kọ́ tó ń kọ́ wọn.

Olùgbé erékùṣù Rarotonga kan tí òun alára wá di míṣọ́nnárì ni More Ta’unga. Ní ọdún 1842, ó di míṣọ́nnárì àkọ́kọ́ tó kọ́ ilé àwọn míṣọ́nnárì sí erékùṣù New Caledonia. Nígbà tó ń kọ̀wé nípa ọkùnrin kan tó fúnra rẹ̀ kọ́ ní ìwé kíkọ àti ìwé kíkà, ó ṣàlàyé nínú ìwé àkọsílẹ̀ rẹ̀ pé: “Díẹ̀díẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí lóye àwọn nǹkan tí mò ń kọ́ ọ. Kò sì pẹ́ púpọ̀ tó fi sọ fún mi pé, ‘Mo fẹ́ gbàdúrà.’ Ṣùgbọ́n, mo sọ fún un pé kó máà kánjú. Nígbà tó ṣe díẹ̀ sí i, ó tún bi mí pé, ‘Ṣé oò ní jẹ́ kí n gbàdúrà ni?’ Ló bá kúkú béèrè ìdí rẹ̀ ti mi ò fi fẹ́ kí òun gbàdúrà, mo sì sọ fún un pé, ‘Wàá kọ́kọ́ jáwọ́ nínú ìbọ̀rìṣà, ìgbà yẹn ni wàá tó lè gbàdúrà sí Jèhófà. Òun nìkan ló lè gbọ́ àdúrà rẹ.’ Bó ṣe gbé apẹ̀rẹ̀ tó kó àwọn ère òrìṣà rẹ̀ sí wá bá mi nìyẹn o, ó sì sọ fún mi pé, ‘Dáná sún wọn. Láti ìsinsìnyí lọ, Jèhófà ni Ọlọ́run tí màá máa sìn.’ Ó wá mọ àdúrà gbà dáadáa.”

Àwọn Olùgbé Erékùṣù Pàsífíìkì Gba Jèhófà Gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run Wọn

Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ìgbà gbogbo ni àwọn míṣọ́nnárì máa ń lo orúkọ Ọlọ́run, kò yani lẹ́nu pé àwọn tí wọ́n wàásù fún bẹ̀rẹ̀ sí gba Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run wọn. Ìwé náà, Missionary Adventures in the South Pacific, ṣàpèjúwe ìpàdé ńlá kan tó wáyé ní àríwá erékùṣù Pàsífíìkì lẹ́yìn tí ọkọ̀ òkun àwọn míṣọ́nnárì tó ń jẹ́ Morning Star gúnlẹ̀ síbẹ̀. Ìwé náà sọ pé àwọn olùgbé erékùṣù náà “fohùn ṣọ̀kan nípa nínawọ́ sókè, àwọn tó pọ̀ jù lára wọn tiẹ̀ na ọwọ́ wọn méjèèjì wọn ò sì ká ọwọ́ náà sílẹ̀ bọ̀rọ̀, kí wọ́n lè fi hàn pé àwọ́n á kọ ìbọ̀rìṣà sílẹ̀ àwọn á sì sin Jèhófà. Síwájú sí i, wọ́n gbà pé àwọ́n á máa pèsè gbogbo nǹkan tí àwọn olùkọ́ náà bá nílò. Wọ́n wá ya ilẹ̀ kan sọ́tọ̀, èyí tí wọ́n yà sí mímọ́ fún Jèhófà láti fi kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì àti ilé àwọn pásítọ̀.”

Nígbà tí ìwé Wiliamu—Mariner-Missionary—The Story of John Williams ń ṣàlàyé bí Malietoa, olóyè pàtàkì kan ní erékùṣù Samoa ṣe yí padà, ó sọ pé: “Malietoa bá àwọn èèyàn rẹ̀ sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀, ó sì ṣèlérí ní gbangba pé òun á di olùjọ́sìn Jèhófà, òun á sì kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì kan fún ìjọsìn Rẹ̀. Ó wá pàṣẹ pé kí àwọn tó bá kù nílé bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà àti Jésù Kristi.”

Gbogbo ìgbòkègbodò àwọn míṣọ́nnárì yìí ní ipa tó wà títí gbére lórí ìgbésí ayé ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbé ní erékùṣù Pàsífíìkì. Kódà, lóde òní, ní àwọn orílẹ̀-èdè bíi Fíjì àti Samoa, kò ṣàjèjì láti gbọ́ orúkọ Jèhófà lórí rédíò tàbí kéèyàn rí i nínú ìwé ìròyìn.

Ṣùgbọ́n ipa tí ìgbòkègbodò náà ní kò mọ síbẹ̀ o. Nínú ìwé rẹ̀, Treasure Islands, tí wọ́n kọ́kọ́ tẹ̀ jáde ní ọdún 1977, Pearl Binder ṣàlàyé bí orúkọ Jèhófà ti ṣe pàtàkì tó fún àwọn ará Banaba. Erékùṣù Kiribati ni àwọn èèyàn náà kọ́kọ́ ń gbé, lẹ́yìn tí wọ́n ṣí kúrò níbẹ̀ ni wọ́n wá tẹ̀ dó sí erékùṣù Rabi, ní Fíjì. Binder kọ̀wé pé: “Àwọn míṣọ́nnárì tó wá sí Banaba ti fún àwọn ará Banaba ní ohun tó ṣeyebíye ju bí wọ́n ti rò lọ. . . . Ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú Jèhófà ló kó ipa pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé wọn. Ó ti mú kí wọ́n wà ní ìṣọ̀kan. Kò tún sí ohun mìíràn tó lè sọ wọ́n dọ̀kan bẹ́ẹ̀ ní gbogbo àádọ́rin ọdún tó kún fún ìpọ́njú tó ń peléke sí i, síbẹ̀ kó ṣì tún gbé wọn ró nípa tẹ̀mí di òní olónìí. Bí kì í bá ṣe ẹ̀kọ́ nípa Jèhófà tí àwọn aláwọ̀ funfun fi kọ́ àwọn ará Banaba ni, (èyí tí àwọn aláwọ̀ funfun fúnra wọn ò kà sí páàpáà) àwọn ará Banaba ì bá tí ní ìrètí kankan.”

Orúkọ Ọlọ́run Nínú Àwọn Ìtumọ̀ Bíbélì

Ọ̀kan lára àwọn ohun tó jẹ àwọn míṣọ́nnárì ìjímìjí náà lọ́kàn jù lọ ni pé kí wọ́n tú Bíbélì lọ́nà tó máa rọrùn láti lóye sí àwọn èdè táwọn èèyàn ń sọ ní erékùṣù Pàsífíìkì. Nítorí bí wọ́n ṣe sapá gidigidi láìkáàárẹ̀, ó ṣeé ṣe fún wọn láti túmọ̀ Bíbélì sí ọ̀pọ̀ lára àwọn èdè táwọn èèyàn ń sọ jákèjádò àgbègbè Pàsífíìkì. Ó bọ́gbọ́n mú lójú àwọn atúmọ̀ náà láti má ṣe yí bí a ṣe ń kọ orúkọ Jèhófà padà, bí wọ́n ti ṣe g̣ẹ́lẹ́ nígbà tí wọ́n ń kọ àwọn orúkọ míì tó wà nínú Bíbélì.

Ó máa dùn mọ́ ẹni tó bá jẹ́ ọ̀jáfáfá akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú láti mọ̀ pé kì í ṣe nínú ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù nìkan ni àwọn atúmọ̀ Bíbélì nígbà ìjímìjí yìí ti lo orúkọ Jèhófà, àmọ́ wọ́n tún lò ó nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì táwọn èèyàn mọ̀ sí Májẹ̀mú Tuntun. Ìwádìí kan nípa méje lára àwọn èdè tí wọ́n ń sọ ní erékùṣù Pàsífíìkì fi hàn pé nínú ẹsẹ Bíbélì méjìléláàádọ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ti lo orúkọ Jèhófà nínú àwọn ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì. Àwọn Ìwé Mímọ́ wọ̀nyí kì í ṣe èyí tí wọ́n túmọ̀ ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún nìkan o. Ìtumọ̀ òde òní kan lédè Rotuman, tí wọ́n tẹ̀ jáde lọ́dún 1999, náà wà lára wọn. Bíbélì náà lo orúkọ Jèhófà ní ẹsẹ méjìdínláàádọ́ta nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì.

Ní òpin ọ̀rúndún kọkàndínlógún, míṣọ́nnárì kan tó ti pẹ́ ní erékùṣù Pàsífíìkì, William Wyatt Gill, kọ̀wé nípa ọ̀kan lára àwọn ìtumọ̀ ìjímìjí náà pé: “Lẹ́yìn tí mo ti lo Bíbélì èdè Rarotonga fún ọdún méjìlélógójì, ẹ jọ̀wọ́ ẹ forí jì mí bí mo bá sọ pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà yàtọ̀ sí èyí tí wọ́n lò láti tú u. . . . Bíi ti gbogbo àwọn ìtumọ̀ mìíràn tó wà lédè àwọn ará Pàsífíìkì àti New Guinea, wọn ò yí bí wọ́n ṣe kọ orúkọ mímọ́ náà ‘Jèhófà’ padà, wọn ò sì tú u sí nǹkan mìíràn. Èyí mú kí ìyàtọ̀ tó wà láàárín Ọlọ́run ayérayé àti òrìṣà táwọn abọ̀rìṣà ń forí balẹ̀ fún túbọ̀ fara hàn kedere kèdèrè.”

Ìdí Tí Wọ́n Fi Lo Orúkọ Ọlọ́run

Kí ló fà á tí àwọn míṣọ́nnárì, àwọn atúmọ̀ Bíbélì àtàwọn olùkọ́ fi kúndùn àtimáa lo orúkọ Ọlọ́run, Jèhófà? Ní pàtàkì jù lọ, ó jẹ́ nítorí pé wọ́n rí i bí ohun tó pọn dandan láti fìyàtọ̀ sáàárín Jèhófà, Ọlọ́run òtítọ́ kan ṣoṣo náà, àti ogunlọ́gọ̀ àwọn ọlọ́run èké tí àwọn olùgbé erékùṣù Pàsífíìkì ń sìn. (Jòhánù 17:3; 1 Kọ́ríńtì 8:5, 6) Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọlọ́run wọ̀nyí ló ní orúkọ tiẹ̀, bí àwọn tó ń sìn wọ́n bá sì fẹ́ béèrè, wọ́n á ní, “Ta ni Ọlọ́run rẹ? Kí lorúkọ rẹ̀?” Bó bá jẹ́ èdè àdúgbò ni wọ́n fi túmọ̀ orúkọ “ọlọ́run,” àwọn tó ń béèrè ò ní mọ èwo lèwo, wọ́n sì lè bẹ̀rẹ̀ sí ronú pé Olódùmarè wulẹ̀ jẹ́ ọlọ́run mìíràn kan tí kò yàtọ̀ sí àwọn òrìṣà àkúnlẹ̀bọ tí wọ́n kà sí ọlọ́run. Nítorí náà, kò yani lẹ́nu láti rí ìdí tí àwọn míṣọ́nnárì ìjímìjí wọ̀nyí fi kúndùn àtimáa lo orúkọ Jèhófà.

Ṣé ó wá túmọ̀ sí pé gbogbo ẹni tó bá ṣáà ti ń lo orúkọ náà Jèhófà, ló mọ ẹni tí Jèhófà jẹ́ nítòótọ́? Bẹ́ẹ̀ kọ́. Míṣọ́nnárì kan tó jẹ́ ògbufọ̀, Hiram Bingham, tó jẹ́ ọmọ míṣọ́nnárì olókìkí kan báyìí nílùú Hawaii, tóun náà ń jẹ́ Hiram Bingham, rí i tí àwọn olùgbé erékùṣù Abaiang (ní Kiribati) ń lọgun pé “Ọlọ́run kan ṣoṣo ló wà, ìyẹn ni Jèhófà” bí wọ́n ti ń wó ère wọn lulẹ̀. Ṣùgbọ́n, èyí ni ohun tí ìwé Missionary Adventures in the South Pacific sọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà:

“Àmọ́ ṣá o, Bingham mọ̀ pé wíwó tí wọ́n wó ère náà lulẹ̀ kò túmọ̀ sí pé lóòótọ́ làwọn èèyàn náà tẹ́wọ́ gba ẹ̀sìn Kristẹni. Ó kéré tán, kì í ṣe lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ yẹn. Wọn ò tíì mọ ìjẹ́pàtàkì ìhìn rere tí wọ́n ń wàásù rẹ̀ fún wọn, wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí gbọ́ ọ ni.” Dájúdájú, wọ́n ṣì ní púpọ̀ sí i láti mọ̀ ju wíwulẹ̀ gbà pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. Ó yẹ kí àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan kí wọ́n sì máa bọ̀wọ̀ fún un ní gbogbo ọ̀nà.—Róòmù 10:13-17.

Kódà, Mósè ọkùnrin olóòótọ́ nì, tó mọ orúkọ Jèhófà tó sì lò ó, ṣì ní púpọ̀ sí i láti mọ̀. Ó gbàdúrà pé: “Wàyí o, jọ̀wọ́, bí mo bá rí ojú rere lójú rẹ, jọ̀wọ́, jẹ́ kí n mọ àwọn ọ̀nà rẹ, kí n lè mọ̀ ọ́, kí n lè rí ojú rere lójú rẹ.” (Ẹ́kísódù 33:13) Bẹ́ẹ̀ ni o, kì í ṣe orúkọ Jèhófà nìkan ni Mósè fẹ́ mọ̀. Ó fẹ́ láti mọ àwọn ànímọ́ Jèhófà àti ọ̀nà tó lè gbà mú inú rẹ̀ dùn. Nítorí ohun tó béèrè yìí, Ọlọ́run fún un ni àǹfààní àgbàyanu ti rírí ìran kan tó wé mọ́ ìtumọ̀ orúkọ Jèhófà.—Ẹ́kísódù 33:19; 34:5-7.

Bákan náà lónìí, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò erékùṣù Pàsífíìkì ń lo Bíbélì tí àwọn míṣọ́nnárì ìjímìjí túmọ̀ láti ran àwọn aláìlábòsí ọkàn lọ́wọ́, kì í wulẹ̀ ṣe láti lóye ìtumọ̀ orúkọ náà Jèhófà bí kò ṣe láti mọ ohun tó ń béèrè lọ́wọ́ àwọn tí yóò bá sìn ín “ní ẹ̀mí àti òtítọ́.” (Jòhánù 4:23, 24) Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn èèyàn ń yin orúkọ Jèhófà lógo ní “àwọn erékùṣù òkun.” Ìyẹn ló fà á tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn fi ń gbé ìrètí wọn ka orúkọ rẹ̀ títóbilọ́lá.—Aísáyà 24:15; 42:12; 51:5; Òwe 18:10.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Àwọn olùgbé erékùṣù Pàsífíìkì tí àwọn míṣọ́nnárì Kirisẹ́ńdọ̀mù ìgbà ìjímìjí kọ́ ní orúkọ Ọlọ́run sọ ọ́ di mímọ̀ fún àwọn ẹlòmíràn

[Credit Line]

Igi ọ̀pẹ àti fọ́tò apá òsì: Látinú ìwé Gems From the Coral Islands

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

John Williams

[Credit Line]

Culver Pictures

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Papeiha

[Credit Line]

Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda Institute of Pacific Studies, látinú ìwé Mission Life in the Islands of the Pacific, látọwọ́ Aaron Buzacott

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ̀ kárí ayé