Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

‘Ìwé Ìròyìn Tó Yẹ Kéèyàn Fara Balẹ̀ Kà Ni’

‘Ìwé Ìròyìn Tó Yẹ Kéèyàn Fara Balẹ̀ Kà Ni’

‘Ìwé Ìròyìn Tó Yẹ Kéèyàn Fara Balẹ̀ Kà Ni’

DAVID jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ òfin ní Yunifásítì Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ó kọ̀wé sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé: “Mo máa ń fún ọ̀jọ̀gbọ́n ẹni àádọ́rin ọdún kan tó jẹ́ ògúnnágbòǹgbò ní ẹ̀ka ìmọ̀ òfin ní Yunifásítì wa ní ìwé ìròyìn Jí! lédè Gẹ̀ẹ́sì déédéé. Láàárọ̀ ọjọ́ kan, lẹ́yìn tó gba àwọn ìtẹ̀jáde tó dé kẹ́yìn, ó sọ fún àlejò kan tó wà nínú ọ́fíìsì rẹ̀ pé: ‘Àwọn ìwé kan wà tá a kàn lè tọ́ wò, àwọn mìíràn wà tá a ní láti gbé mì, àwọn díẹ̀ sì wà tá a ní láti jẹ lẹ́nu kó sì dà nínú wa. Ìwé ìròyìn tó yẹ kéèyàn jẹ lẹ́nu kó sì dà nínú ni Jí!’”

Ní àkókò mìíràn, lẹ́yìn tí David jáde nínú ọ́fíìsì ọ̀jọ̀gbọ́n náà, ó sọ pé òún gbọ́ tó ń sọ fún àlejò mìíràn pé ó yẹ kó máa ka Jí! “Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwádìí ni wọ́n máa ń ṣe kí wọ́n tó tẹ Jí! jáde àti pé kì í pọ̀n sápá kan síbẹ̀ ó máa ń sojú abẹ níkòó nígbà tó bá ń jíròrò onírúurú kókó ẹ̀kọ́. Mo gbọ́ tó ń sọ fún ẹni náà pé: ‘Ńṣe ni mo máa ń fara balẹ̀ ka àwọn ìwé ìròyìn náà. Dájúdájú, Ọlọ́run ló ń fún àwọn tó ń kọ ìwé ìròyìn náà ní ọgbọ́n tí wọ́n fi ń kọ irú àwọn àpilẹ̀kọ tó jẹ́ àgbàyanu bẹ́ẹ̀.’”

Jí! ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ó sì ń jíròrò onírúurú nǹkan. Ní pàtàkì jù lọ, ó ń jẹ́ kéèyàn ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìlérí tí Ẹlẹ́dàá ṣe nínú Bíbélì nípa ayé tuntun kan níbi tí àlááfíà máa wà, èyí tí yóò rọ́pò ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 náà, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? jẹ́ ká mọ̀ nípa ète Ọlọ́run yìí, ó sì pèsè àwọn ìsọfúnni nínú Bíbélì láti fi ohun tó yẹ ká ṣe hàn wá ká lè rí ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀. Bó o bá fẹ́ gba ẹ̀dà kan ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 yìí, o lè kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí kí o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sójú ìwé 5 ìwé ìròyìn yìí.

□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.