Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣíṣèrànwọ́ Nígbà Ìṣẹ̀lẹ̀ Omíyalé Ní Àgbègbè Caucasus

Ṣíṣèrànwọ́ Nígbà Ìṣẹ̀lẹ̀ Omíyalé Ní Àgbègbè Caucasus

Ṣíṣèrànwọ́ Nígbà Ìṣẹ̀lẹ̀ Omíyalé Ní Àgbègbè Caucasus

LÁTỌWỌ́ ÒǸKỌ̀WÉ JÍ! NÍ RỌ́ṢÍÀ

LỌ́DÚN tó kọjá, ní ìhà àríwá Rọ́ṣíà ní àgbègbè Caucasus, ọjọ́ méjì péré ni òjò tó sábà máa ń rọ̀ láàárín oṣù mẹ́ta fi rọ̀. Ọ̀pọ̀ odò ló kún àkúnya. Àwọn odò kéékèèké pàápàá di ọ̀gbàrá tí ń ya mùúmùú, wọ́n sì ń wọ́ gbogbo nǹkan tó bá wà lọ́nà lọ. Àwọn ìsédò fọ́, àwọn ilé àtàwọn nǹkan mìíràn gbogbo sì wó lulẹ̀ bẹẹrẹbẹ. Bí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn olùgbé ibẹ̀ ṣe pàdánù ilé wọn nìyẹn. Àwọn tí ò lè tètè sá fi ilé wọn sílẹ̀ bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ. Àwọn kan ò tiẹ̀ mọ ohun tí wọ́n lè ṣe bí omi tí ń ru gùdù náà ṣe ń gbé àwọn èèyàn wọn lọ.

Ní ìlú Nevinnomyssk, ìdílé kan gbìyànjú láti kó sínú ọkọ̀ katakata wọn kí wọ́n sì sá lọ. Àmọ́, alagbalúgbú omi ṣàdédé ya lu katakata náà ó sì dojú dé, bí gbogbo wọn ṣe kú nìyẹn. Àwọn mìíràn kàgbákò ikú níbi tí wọ́n ti ń ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́. Ìròyìn fi tóni létí pé nǹkan bí ọ̀kẹ́ mẹ́rìndínlógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàájọ [335,000] èèyàn ni àkúnya omi náà ṣàkóbá fún. Nínú iye yìí, àwọn èèyàn tó kú lé ní igba, ọ̀pọ̀ èèyàn sì ni wọn kò rí.

Omi ya bo ẹgbẹẹgbàárùn-ún ilé. Àwọn páìpù omi àtàwọn kòtò omi ìgbẹ́ sì bà jẹ́. Kódà, alagbalúgbú omi náà hú àwọn òkú tí wọ́n ti sin síta, títí kan òkú àwọn ẹranko tí kòkòrò àrùn anthrax pa. Àwọn oníṣirò fojú díwọ̀n rẹ̀ pé àdánù tí àkúnya náà fà tó nǹkan bíi bílíọ̀nù mẹ́rìndínlógún [16,000,000,000] owó ruble ti ilẹ̀ Rọ́ṣíà tàbí nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta mílíọ̀nù [500,000,000] dọ́là ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà.

Ilẹ̀ rírẹwà tó tún lọ́ràá yìí, tí àwọn olórin àti akéwì sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, wá di ibi àríbọkànjẹ́! Síbẹ̀, ìjábá náà kò ba ìfẹ́ aládùúgbò tòótọ́ jẹ́.

Wọ́n Pèsè Ìrànlọ́wọ́ Láìjáfara

Lákọ̀ọ́kọ́ ná, kò sómi tó mọ́, kò síná, kò sí gáàsì, kò sì ṣeé ṣe láti báni sọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù. Àwọn èèyàn ò gbúròó ara wọn. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń gbé ní àgbègbè ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé ju ẹgbẹ̀ẹ́dógún [3,000] lọ, àwọn tó ń gbé ní ìlú Nevinnomyssk àti itòsí ibẹ̀ sì ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [700] lọ. Nítorí náà, gbàrà tí wọ́n gbọ́ nípa àkúnya náà, àwọn Ẹlẹ́rìí ṣètò àwọn àkànṣe ìgbìmọ̀ tí ń bójú tó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì láti ṣèrànwọ́ fún àwọn tí ọ̀ràn kàn. Àwọn ìgbìmọ̀ wọ̀nyí ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ kó tiẹ̀ tó di pé àwọn òṣìṣẹ̀ ìjọba tó ń pèsè ààbò débẹ̀.

Ní ìlú kékeré kan tó ń jẹ́ Orbelyanovka, tó fi nǹkan bí ọgọ́ta kìlómítà jìn sí gúúsù ìlà oòrùn Nevinnomyssk, omi náà kàn ń yára ga sí i ni. Èèyàn mẹ́jọ, tó fi mọ́ àwọn obìnrin méjì tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí, wá ibi fara pa mọ́ sí níbi téńté orí òkè kan. Orí òkè yìí kan náà sì làwọn ẹranko kéékèèké mìíràn àti ọ̀pọ̀ ejò sá lọ. Nítorí náa, ní gbogbo òru ọjọ́ náà, ńṣe làwọn èèyàn mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ níláti máa lé àwọn ejò náà dà nù.

Bí ilẹ̀ ọjọ́ kejì ti ń mọ́ ni àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ládùúgbò náà ti bẹ̀rẹ̀ sí wá ọ̀nà tí wọ́n á gbà dé ọ̀dọ̀ àwọn arábinrin wọn méjèèjì náà. Níkẹyìn, ní nǹkan bí ọwọ́ ọ̀sán, wọ́n rí ọkọ̀ òbèlè onírọ́bà. Ṣùgbọ́n, kí wọ́n tó gbé àwọn arábìnrin náà kúrò níbẹ̀, wọ́n kọ́kọ́ fi ọkọ̀ òbèlè náà gbé bàbá àgbàlagbà kan tó jẹ́ arọ. Lẹ́yìn ìyẹn, bí wọ́n ṣe ń gbé àwọn arábìnrin náà lọ, hẹlikópítà kan dé ó sì gbé àwọn èèyàn tó kù lórí òkè náà.

Kí ilẹ̀ ọjọ́ yẹn tó ṣú, àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà nínú ọkọ̀ òbèlè náà tún ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́. Nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí náà bi wọ́n pé: “Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ wá?” àwọn èèyàn náà dáhùn pé: “Òṣìṣẹ́ Ìjọba Tí Ń Rí sí Ọ̀ràn Pàjáwìrì ni yín kẹ̀.” Ó yà wọ́n lẹ́nu nígbà tí wọ́n wá mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí ni wọ́n, wọn kì í ṣe òṣìṣẹ́ ìjọba.

Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní Nevinnomyssk ra ohun ìdáná kan tó ṣeé fi mọ́tò gbé kiri wọ́n sì pèsè oúnjẹ gbígbóná fún àwọn tí ebi ń pa. Yàtọ̀ sí oúnjẹ, wọ́n tún fún wọn ní omi, aṣọ àti egbòogi pẹ̀lú. Àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn tún fọ àwọn ilé mọ́ tónítóní, wọ́n sì palẹ̀ gbogbo pàǹtírí tó wà láyìíká ilé àwọn èèyàn mọ́.

Tọkọtaya Ẹlẹ́rìí kan tí wọ́n ń gbé ní Zelenokumsk, tí wọ́n sì jẹ́ oníṣòwò, fi ọkọ̀ wọn kó omi, oúnjẹ àti aṣọ tí wọ́n rà lọ́pọ̀ rẹpẹtẹ lọ síbẹ̀. Nígbà tí àwọn ojúlùmọ̀ ìyàwó arákùnrin náà bi í pé ta ló ń ra àwọn nǹkan náà lọ fún, ó dáhùn pé àwọn onígbàgbọ́ bíi tòhun tí ìjábá náà ṣẹlẹ̀ sí ni. Ẹ̀mí ìbìkítà rẹ̀ wú wọn lórí gidigidi, ó sì wu àwọn náà láti ṣèrànlọ́wọ́. Odindi àpò ìyẹ̀fùn noodle ńlá kan ni obìnrin oníṣòwò kan gbé fún un. Òmíràn gbé páálí ọṣẹ ńlá kan fún un, àwọn mìíràn sì kó àpò ṣúgà fún un.

Ìrànlọ́wọ́ Láti Ọ̀nà Jíjìn

Níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí ní orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ti fẹ́ láti mọ ọ̀nà tí wọ́n lè gbà ṣèrànwọ́ fún àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ omíyalé ṣàkóbá fún, wọ́n ṣètò owó àkànlò kan tí wọ́n á máa lò láti fi ran àwọn aláìní lọ́wọ́. Kódà, ìrànlọ́wọ́ tún wá látọ̀dọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ olùyọ̀ọ̀da ara ẹni tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà, èyí tó wà nítòsí St. Petersburg. Àwọn kan ra àwọn nǹkan tuntun fún àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ omíyalé náà ṣàkóbá fún. Ọ̀kan lára wọn ṣàlàyé pé: “Mo yọ̀ǹda ohun ìní mi tó dára jù lọ nítorí pé mo ní ohun tí mo lè lò, ṣùgbọ́n àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa ò ní nǹkan kan.”

Ẹ̀ka Ọ́fíìsì náà tún fi lẹ́tà ránṣẹ́ sí nǹkan bí àádọ́jọ [150] ìjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní St. Petersburg àti Moscow, wọ́n sì ṣàlàyé ọ̀nà tí àwọn ará lè gbà dá owó, oúnjẹ àti aṣọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ètò ọrọ̀ ajé ò fi bẹ́ẹ̀ lọ déédéé ní orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, tí ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí ò sì fi bẹ́ẹ̀ ní púpọ̀ nípa tara, àwọn ohun tí wọ́n fi ṣèrànwọ́ fi hàn bí wọ́n ti jẹ́ ọ̀làwọ́ tó. Ìwà ọ̀làwọ́ wọn rí gẹ́lẹ́ bí èyí tí àwọn Kristẹni ará Makedóníà tí iṣẹ́ ń ṣẹ́ fi hàn sí àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọn ní Jùdíà.—2 Kọ́ríńtì 8:1-4.

Lẹ́yìn tí wọ́n ti yanjú ohun táwọn ará dá jọ sọ́tọ̀ọ̀tọ̀ níbi tí wọ́n ń dá wọn jọ sí, wọ́n kó wọn sọ́kọ̀ wọ́n sì wà wọ́n lọ síbi tí ìjábá náà ti ṣẹlẹ̀. Yàtọ̀ sí ohun táwọn èèyàn dá jọ yìí, Ẹ̀ka Ọ́fíìsì tún ra tọ́ọ̀nù mẹ́wàá oúnjẹ (èyí tó lè kún inú ọkọ̀ akóyọyọ bíi méjì), ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta aṣọ bẹ́ẹ̀dì àtàwọn ohun èlò ìmọ́tótó. Wọ́n sì tún ra àwọn irinṣẹ́ àti aṣọ iṣẹ́ tí wọ́n á lò láti palẹ̀ ìdọ̀tí mọ́ níbi tí ìjábá ti ṣẹlẹ̀. Lápapọ̀, ọkọ̀ akẹ́rù ńláńlá mẹ́fà ni wọ́n fi kó àwọn ohun àfiṣèrànwọ́ lọ sí ìhà àríwá àgbègbè Caucasus.

Ìwà Ọ̀làwọ́ Wọn Ṣí Àǹfààní Sílẹ̀ fún Ìjẹ́rìí

Gbogbo iṣẹ́ táwọn Ẹlẹ́rìí ṣe nígbà tí wọ́n ń sọ ibi tí ìjábá náà ti ṣẹlẹ̀ di mímọ́ tónítóní làwọn èèyàn kíyè sí. Àpẹẹrẹ kan ni ti ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ìlú Kislovodsk rírẹwà táwọn èèyàn ti ń gbafẹ́, níbi tí àwọn Ẹlẹ́rìí tó tó ọ̀ọ́dúnrún [300] wà. Wọ́n yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ lọ́dọ̀ ẹ̀ka ìjọba tí ń rí sí àbójútó ìlú, wọ́n sì yan àgbègbè kan fún wọn láti tún ṣe.

Ní agogo mẹ́jọ òwúrọ̀ ní June 28, nǹkan bí àádọ́jọ [150] àwọn Ẹlẹ́rìí, tó fi mọ́ gbogbo ìdílé, kó àwọn irinṣẹ́ wá wọ́n sì pé jọ fún iṣẹ́ náà. Àwọn kan lára wọn gba àkókò ìsinmi tí wọn ò ní sanwó rẹ̀ fún wọn níbi iṣẹ́ nítorí àtilọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìpalẹ̀-ìdọ̀tí-mọ́ náà. Láìpẹ́, lẹ́yìn tí wọ́n bẹ̀rẹ̀, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan dé, igbákejì olórí ìlú sì bọ́ sílẹ̀ látinú ọkọ̀ náà. Ó béèrè pé: “Àwọn wo nìyí?”

Wọ́n dá a lóhùn pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni. Wọ́n wá síbí láti palẹ̀ ìdọ̀tí tí ìjábá náà dá sílẹ̀ mọ́ ni.”

Ó ya olórí ìlú yìí lẹ́nu láti rí bí àwọn Ẹlẹ́rìí náà ṣe pọ̀ tó, ó wá sọ pé: “Ohun tí wọ́n ṣe yìí mà dára gan-an o! Ẹ ṣeun o! Èyí ga jù!”

Lẹ́yìn náà, kí ó tó tó àkókò oúnjẹ ọ̀sán, aláṣẹ ìlú míì tún ń wakọ̀ kọjá lọ. Ó dúró, ó sọ̀ kalẹ̀ látinú ọkọ̀, ó sì sún mọ́ ibi tí àwọn Ẹlẹ́rìí náà wà. Ó wá sọ pé: “A ti ń kíyè sí iṣẹ́ tí ẹ̀ ń ṣe, ìyàlẹ́nu gbáà ló sì jẹ́ fún wa. A ó tíì rí i káwọn èèyàn ṣiṣẹ́ bí èyí rí. Iṣẹ́ kékeré kọ́ lẹ ti ṣe o!”

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà tíì sọ̀rọ̀ tán tí obìnrin àgbàlagbà kan tí ń kọjá lọ fi yà síbẹ̀ tó sì béèrè pé: “Kí ló fà á tí àwọn èèyàn wọ̀nyí fi ń fi gbogbo ara ṣiṣẹ́ báyìí?” Nígbà tí wọ́n sọ fún un pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wá ṣèrànwọ́ láti tún ìlú ṣe ni wọ́n, omi lé ròrò lójú rẹ̀. Ó sì sọ pé: “Ojúlówó onígbàgbọ́ ni yín. Dájúdájú, ìgbà ìpọ́njú làá mọ̀rẹ́.” Obìnrin mìíràn sọ pé: “Ẹ̀gàn ni hẹ̀ẹ̀, wọ́n ṣe bẹbẹ! Ó pẹ́ tí mo ti rí irú èyí kẹ́yìn.”

Nígbà tó di ọjọ́ kejì, ìwé ìròyìn Na Vodakh gbóṣùbà fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì ṣàlàyé pé wọ́n ti kó ẹrẹ̀ tó tó ọgọ́rùn-ún tọ́ọ̀nù (èyí tó lè kún inú ọkọ̀ akóyọyọ bíi mẹ́tàdínlógún) kúrò nínú ìlú náà. Àwọn aláṣẹ ìlú Kislovodsk kọ̀wé ìdúpẹ́ sáwọn Ẹlẹ́rìí náà, wọ́n sọ pé: “Ìrànlọ́wọ́ ńláǹlà tí ẹ ṣe ló dá ẹwà ìlú yìí padà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀ . . . Kò sí iyèméjì pé ọ̀rọ̀ ìmọrírì tó bá ń tẹnu ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn tó ń bẹ ìlú wa yìí wò jáde ni yóò jẹ́ èrè dídára jù lọ tí ẹ lè rí gbà.”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjábá tó wáyé ní ìhà àríwá àgbègbè Caucasus fa àdánù àti pákáǹleke tí kò ṣeé fẹnu sọ, inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dùn láti fìfẹ́ hàn sí àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ àtàwọn aládùúgbò wọn. Ohun tó mú inú wọn dùn jù lọ ni mímọ̀ tí wọ́n mọ̀ pé fífi ìfẹ́ hàn lọ́nà bẹ́ẹ̀ ń fògo fún Jèhófà, Ẹlẹ́dàá wa.

[Àwọn àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 20]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Òkun Dúdú

ÀWỌN ÒKÈ CAUCASUS

Nevinnomyssk

Orbelyanovka

Zelenokumsk

Kislovodsk

Òkun Caspian

[Credit Line]

Àgbáyé: Mountain High Maps® Copyright © 1997 Digital Wisdom, Inc.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Àwọn Ẹlẹ́rìí ra ohun ìdáná tó ṣeé fi mọ́tò gbé kiri yìí wọ́n sì pèsè oúnjẹ fún àwọn tí ebi ń pa

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Ẹlẹ́rìí yìí lo mọ́tò ìdílé rẹ̀ láti fi kó oúnjẹ àtàwọn ohun èlò mìíràn lọ fún àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ omíyalé ṣàkóbá fún

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

Àwọn aláṣẹ ìlú Kislovodsk gbóríyìn fún àwọn Ẹlẹ́rìí nítorí pé wọ́n ṣèrànwọ́ láti tún ìlú wọn ṣe