Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí Ẹ̀sìn Rẹ àti Tàwọn Ìbátan Rẹ Ò Bá Dọ́gba

Bí Ẹ̀sìn Rẹ àti Tàwọn Ìbátan Rẹ Ò Bá Dọ́gba

Ojú Ìwòye Bíbélì

Bí Ẹ̀sìn Rẹ àti Tàwọn Ìbátan Rẹ Ò Bá Dọ́gba

ÌWÁDÌÍ kan fi hàn pé, àwọn ìsìn àti ẹ̀ya ìsìn tó wà láyé lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá. Ní orílẹ̀-èdè kan, nǹkan bí ìdá mẹ́rìndínlógún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn àgbàlagbà tó wà níbẹ̀ ló ti yí ìsìn wọn padà lákòókò kan nígbèésí ayé wọn. Abájọ nígbà náà tí àìgbọ́ra-ẹni-yé nípa ìsìn fi máa ń wáyé láàárín àwọn ìbátan àti ọ̀rẹ́. Nígbà míì, èyí máa ń dá ìṣòro sílẹ̀ láàárín wọn. Èyí ló wá fa ìbéèrè náà pé, Báwo ló ṣe yẹ kí àwọn Kristẹni máa hùwà sí àwọn ìbátan wọn tí wọn ò jọ ṣe ẹ̀sìn kan náà?

Àjọṣe Àrà Ọ̀tọ̀

Bí àpẹẹrẹ, gbé ohun tí Bíbélì sọ nípa àjọṣe àrà ọ̀tọ̀ tó wà láàárín àwọn òbí àtàwọn ọmọ wọn yẹ̀ wò. Bíbélì kò sọ pé ìgbà kan ní pàtó ni ìwúlò àṣẹ tó wà ní Ẹ́kísódù 20:12 láti “bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ” mọ. Àní, nínú ìjíròrò Jésù lórí àṣẹ yìí, tí àkọsílẹ̀ rẹ̀ wà ní Mátíù 15:4-6, ó hàn gbangba pé ọ̀wọ̀ tó yẹ kí àwọn ọmọ tó ti dàgbà máa fún àwọn òbí wọn ló ń sọ nípa rẹ̀.

Nínú Bíbélì, ìwé Òwe kìlọ̀ pé kí àwọn ọmọ má ṣe hùwà àfojúdi sí àwọn òbí wọn. Ìmọ̀ràn inú ìwé Òwe 23:22 ni pé má ṣe “tẹ́ńbẹ́lú ìyá rẹ kìkì nítorí pé ó ti darúgbó.” Ní ṣàkó, Òwe 19:26 kìlọ̀ pé ẹni tí “ń ṣe baba níkà tí ó sì lé ìyá lọ, jẹ́ ọmọ tí ń hùwà lọ́nà tí ń tini lójú àti lọ́nà tí ń dójú tini.”

Gẹ́gẹ́ bí a ti rí i nínú Ìwé Mímọ́, ó hàn gbangba pé a kò gbọ́dọ̀ pa àwọn òbí wa tì. Pé àwọn òbí wa kò fara mọ́ ìsìn wa kò fagi lé àjọṣe tó wà láàárín àwa pẹ̀lú wọn. Àwọn ìlànà Bíbélì yìí tún kan àwọn ẹbí wa mìíràn, bákan náà ló sì tún kan aya tàbí ọkọ ẹni. Ó ṣe kedere pé ojúṣe àwọn Kristẹni ni láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ìbátan wọn èyí sì tún bá Ìwé Mímọ́ mu pẹ̀lú.

Fífòye Bá Wọn Lò Ṣe Pàtàkì

Àmọ́ ṣá o, Bíbélì kì wá nílọ̀ nípa ẹgbẹ́ búburú, àwọn tá a jọ jẹ́ ara ìdílé kan náà sì lè jẹ́ irú ẹgbẹ́ búburú bẹ́ẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 15:33) Ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó jẹ́ olóòótọ́ láyé ọjọ́un ló rọ̀ mọ́ ṣíṣe ohun tó tọ́ bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí wọn kò fara mọ́ ọn. Èyí gan-an lohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ọ̀ràn àwọn ọmọkùnrin Kórà. (Númérì 16:32, 33; 26:10, 11) Àwọn Kristẹni tòótọ́ kò gbọ́dọ̀ juwọ́ sílẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ wọn kí wọ́n lè tẹ́ àwọn ẹlòmíràn lọ́rùn, kódà bó tiẹ̀ jẹ́ àwọn ìbátan wọn pàápàá.—Ìṣe 5:29.

Nínú àwọn ọ̀ràn kan, àwọn òbí tàbí àwọn mọ̀lẹ́bí mìíràn lè fi taratara gbéjà ko ohun tí Kristẹni kan gbà gbọ́. Kódà, àwọn kan tiẹ̀ lè di ọ̀tá ìsìn Kristẹni tòótọ́. Bọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn Kristẹni ní láti gbé àwọn ìgbésẹ̀ bíbọ́gbọ́nmu láti pa àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà mọ́. Jésù tọ̀nà nígbà tó sọ pé: “Àwọn ọ̀tá ènìyàn yóò jẹ́ àwọn ènìyàn agbo ilé òun fúnra rẹ̀. Ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ni tí ó pọ̀ fún baba tàbí ìyá ju èyí tí ó ní fún mi, kò yẹ fún mi; ẹni tí ó bá sì ní ìfẹ́ni tí ó pọ̀ fún ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin ju èyí tí ó ní fún mi, kò yẹ fún mi.”—Mátíù 10:36, 37.

Àmọ́ ṣá o, lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn Kristẹni kì í dojú kọ àtakò gbígbóná janjan látọ̀dọ̀ àwọn ìbátan wọn. Àwọn èèyàn wọn ò kàn fara mọ́ ọ̀nà tí wọ́n gbà lóye àwọn ẹ̀kọ́ inú Bíbélì ni. Ìwé Mímọ́ rọ àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi láti máa bá àwọn aláìgbàgbọ́ lò “pẹ̀lú ìwà tútù” àti “ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.” (2 Tímótì 2:25; 1 Pétérù 3:15) Lọ́nà yíyẹ, Bíbélì gbà wá nímọ̀ràn pé: “Kò yẹ kí ẹrú Olúwa máa jà, ṣùgbọ́n ó yẹ kí ó jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí gbogbo ènìyàn.” (2 Tímótì 2:24) Bákan náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni “láti má sọ̀rọ̀ ẹnì kankan lọ́nà ìbàjẹ́, láti má ṣe jẹ́ aríjàgbá, láti jẹ́ afòyebánilò, kí wọ́n máa fi gbogbo ìwà tútù hàn sí ènìyàn gbogbo.”—Títù 3:2.

Máa Kàn sí Wọn sì Máa Fi Ìfẹ́ Hàn sí Wọn

Nínú 1 Pétérù 2:12, a fún àwọn Kristẹni ní ìṣírí yìí pé: “Ẹ tọ́jú ìwà yín kí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè [àwọn aláìgbàgbọ́] pé . . . kí wọ́n lè tipa àwọn iṣẹ́ yín àtàtà tí wọ́n fojú rí, yin Ọlọ́run lógo.” Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ìbátan wa tí kò fara mọ́ ìsìn wa máa ń rí àwọn ìyípadà tí fífi ìlànà Bíbélì sílò ti sún wa ṣe nínú ìgbésí ayé wa. Rántí pé ọ̀pọ̀ àwọn tí kò fìfẹ́ hàn tẹ́lẹ̀ tàbí tí wọ́n tiẹ̀ ti ṣàtakò sí òtítọ́ Bíbélì nígbà kan ti yí èrò wọn padà nígbà tó yá. Ó lè jẹ́ pé lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí àwọn kan ti ń fara balẹ̀ kíyè sí ìwà rere ọkọ tàbí aya tàbí ọmọ kan ni wọ́n á tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí wádìí ohun tó mú ẹni náà máà hùwà lọ́nà bẹ́ẹ̀. Bí àwọn èèyàn ò bá tiẹ̀ tẹ́wọ́ gba òtítọ́ tí Bíbélì fi kọ́ni, kò yẹ kó jẹ́ nítorí pé èèyàn wọn kan tó jẹ́ Kristẹni pa wọ́n tì.

Lóòótọ́, ipò kálukú yàtọ̀ síra, ibi tí àwọn Kristẹni Ẹlẹ́rìí kan ń gbé sì jìnnà gan-an sí ibi tí àwọn òbí wọn ń gbé. Ó lè má ṣeé ṣe fún wọn láti lọ máa bẹ̀ wọ́n wò déédéé bí wọ́n ṣe fẹ́. Àmọ́, kíkọ lẹ́tà sí wọn, pípè wọ́n lórí tẹlifóònù, tàbí kíkàn sí wọn déédéé láwọn ọ̀nà mìíràn á mú un dá àwọn ìbátan wa lójú pé a nífẹ̀ẹ́ wọn. Ọ̀pọ̀ àwọn tí kì í ṣe Kristẹni tòótọ́ ló nífẹ̀ẹ́ àwọn òbí wọn àtàwọn ìbátan wọn mìíràn, tí wọ́n sì máa ń bá wọn sọ̀rọ̀ látìgbàdégbà láìka ìsìn tí wọ́n lè máa ṣe sí. Ǹjẹ́ ó wá yẹ kí àwọn Kristẹni Ẹlẹ́rìí ṣe ohun tó dín kù síyẹn?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Kíkàn sí àwọn ìbátan rẹ déédéé yóò mú un dá wọn lójú pé o nífẹ̀ẹ́ wọn