Epo Rọ̀bì—Ṣé Ìbùkún òun Ègún Ni?
Epo Rọ̀bì—Ṣé Ìbùkún òun Ègún Ni?
BÁWO ni àwọn orílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀ ṣe gbára lé epo àtàwọn èròjà tó ń wá látinú rẹ̀ tó? Epo rọ̀bì àti ògidì gáàsì ṣe pàtàkì fún wọn gan-an, èyí sì ti sọ wọ́n di “Àwùjọ Tó Gbára Lé Epo Rọ̀bì” gẹ́gẹ́ bí ọ̀gbẹ́ni Daniel Yergin ṣe pè wọ́n nínú ìwé rẹ̀ tó ń jẹ́ The Prize. Ìwọ tiẹ̀ ronú ná nípa epo ẹ̀rọ amúlémóoru, gírísì, àtè, ọ̀dà ásífáàtì tí wọ́n fi ń ṣe títì, àtàwọn nǹkan tí wọ́n ń fi àwọn kẹ́míkà tí wọ́n ń rí látinú epo rọ̀bì ṣe—àwọn nǹkan bí ọkọ̀ òfuurufú, ọkọ̀ ìrìnnà, ọkọ̀ ojú omi, àtè, ọ̀dà, aṣọ onírọ́bà, bàtà káńfáàsì, ohun ìṣiré ọmọdé, aró, oògùn aspirin, lọ́fínńdà, ohun ìṣojúlóge, àwo orin ìgbàlódé, kọ̀ǹpútà, tẹlifíṣọ̀n àti tẹlifóònù. Ojoojúmọ́ ni ọ̀pọ̀ èèyàn ń lò lára àwọn ohun èlò tó ju ẹgbẹ̀rún mẹ́rin lọ tí wọ́n mú jáde látinú epo rọ̀bì, èyí tó ń kópa tí kì í ṣe kékeré lórí ìgbésí ayé òde òní. Àmọ́, ti ìpalára tó ń ṣe fún àwọn ohun alààyè ńkọ́, èyí tó ti jẹ́ apá kan ìtàn epo látìbẹ̀rẹ̀?
Ọba Tí “Ìṣàkóso Rẹ̀ Kò Tu Àwọn Èèyàn Lára”
Nígbà tó fi máa di òpin ọdún 1940, tó ti hàn gbangba pé ogun fẹ́ bẹ́ sílẹ̀ láàárín orílẹ̀-èdè Romania àti Hungary, kíá ni Adolf Hitler, aláṣẹ bóofẹ́bóokọ̀ ìjọba Násì ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe bí apẹ̀tùsíjà. Ṣé lóòótọ́ ló jẹ́ olùlàjà? Ohun tí Hitler ò fẹ́ kó ṣẹlẹ̀ ni pé kí àwọn kànga ìwapo ilẹ̀ Romania bọ́ sábẹ́ àkóso ilẹ̀ Soviet Union. Epo rọ̀bì yìí náà ni olórí ohun tó fà á tí ilẹ̀ Iraq fi lọ kógun ja ilẹ̀ Kuwait lọ́dún 1990 tí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn sì lọ́wọ́ sí ìjà náà. Irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wọ́pọ̀ gan-an ni o. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé ìfẹ́ láti di aláṣẹ epo ló máa ń dá wàhálà àti ìnira sílẹ̀.
Kì í ṣe pé epo ṣe pàtàkì lọ́pọ̀lọpọ̀ fún ìgbésí ayé òde òní nìkan ni àmọ́ òun gan-an tún ni olórí ohun tí ọ̀ràn ìṣèlú dá lé, ó sì tún jẹ́ ohun tí àwọn kan tí agbára wà níkàáwọ́ wọn nífẹ̀ẹ́ sí gidigidi. Gẹ́gẹ́ bí Àjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Tó Ń Ta Epo Sílẹ̀ Òkèèrè (OPEC) ti sọ láìpẹ́ yìí, epo kì í ṣe èròjà lásán, “ìṣúra tí wọ́n fi ń ṣagbára ni.” Àwọn orílẹ̀-èdè kan ti lo epo rọ̀bì láti fàgbà han àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, nípa kíkọ̀ láti bá wọn ra epo. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn kànga ìwapo, iléeṣẹ́ ìfọpo àtàwọn ọkọ̀ òkun agbépo tún jẹ́ ohun tí àwọn apániláyà máa ń dájú sọ, ọ̀pọ̀ ìgbà lèyí sì máa ń ṣe àkóbá ńláǹlà fún àyíká.
Wọ́n ti nàka àbùkù sí àwọn iléeṣẹ́ epo fún bíbà tí wọ́n ń ba àyíká jẹ́ nítorí afẹ́fẹ́ carbon dioxide tó máa ń tú dà sáfẹ́fẹ́, èyí tó lè dá kún ìṣòro ipò ojú ọjọ́ tó ń fi gbogbo ìgbà yí padà. Níbàámu pẹ̀lú ìròyìn kan tó wá látọ̀dọ̀ àjọ PEMEX (Àjọ Elépo Rọ̀bì Ilẹ̀ Mẹ́síkò), tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn iléeṣẹ́ olówò epo tó tóbi jù lọ lágbàáyé, gbogbo ìgbésẹ̀ kọ̀ọ̀kan tí wọ́n fi ń yọ onírúurú èròjà inú epo rọ̀bì jáde ló máa ń fa títú èéfín olóró dà sínú afẹ́fẹ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé epo pẹtiróòlù ti mọ́ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, ní ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún mẹ́fà lẹ́yìn Àpérò Kyoto nígbà tí orílẹ̀-èdè mọ́kànlélọ́gọ́jọ [161] pàdé pọ̀ láti gbé ìgbésẹ̀ lórí dídín ewu gbígbóná tí ayé ń gbóná kù, ọ̀pọ̀ ló ronú pé nǹkan ò tíì fi bẹ́ẹ̀ yí padà. Ní òdìkejì èyí, ohun tí àjọ OPEC sọ ni pé “epo ló mú ọrọ̀ àti aásìkí tí” ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè “ń gbádùn lónìí wá.” Àmọ́, ṣé gbogbo ìgbà lọ̀rọ̀ yìí jẹ́ òótọ́?
Àwọn kan ò ní ṣàì tọ́ka sí àkóbá tí àwọn kànga ìwapo tí wọ́n ń gbẹ́ àtàwọn páìpù tí wọ́n ń rì kiri ti ṣe. Àwọn mìíràn sì lè tọ́ka sí bí àwọn tí kò ríṣẹ́ ṣe ṣe ń fojoojúmọ́ pọ̀ sí i ní orílẹ̀-èdè Saudi Arabia tó jẹ́ orílẹ̀-èdè tó lépo jù lọ lágbàáyé. Alí Rodríguez Araque, ààrẹ àjọ OPEC sọ pé: “Èrè gọbọi làwọn ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà ń rí látinú àwọn nǹkan tí wọ́n ń fagbára mú àwọn iléeṣẹ́ tó ń wa epo, àwọn iléeṣẹ́ tó ń fọ̀ ọ́ àtàwọn tó ń lò ó láti máa san.”
Àjọ CorpWatch, tó ń rí sí mímú kí àwọn àjọ elépo dáhùn fún ipa tí epo ń ní lórí àyíká, sọ pé: “Epo ṣì lọba o. Àmọ́, ọba tí ìṣàkóso rẹ̀ kò tu àwọn èèyàn lára ni.”
Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí epo rọ̀bì lọ́jọ́ iwájú?