Epo Rọ̀bì—Ṣé Wọ́n Lè Wà Á Gbẹ?
Epo Rọ̀bì—Ṣé Wọ́n Lè Wà Á Gbẹ?
“Láìsí [ohun àmúṣagbára] iṣẹ́ ò lè ṣeé ṣe láwọn iléeṣẹ́ ńláńlá . . . Wọn ò ní lè ṣe ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, ọkọ̀ akẹ́rù, ọkọ̀ ojú irin, ọkọ̀ òkun tàbí ọkọ̀ òfuurufú jáde . . . Láìsí ohun àmúṣagbára, ńṣe ni ilé máa tutù nini kò sì ní sí ìmọ́lẹ̀ nínú ilé, bẹ́ẹ̀ la ò ní lè se oúnjẹ. . . . Láìsí àwọn ohun àmúṣagbára, ńṣe la máa bá ara wa ní Sànmánì Ojú Dúdú padà.”—Látinú “Àyẹ̀wò Lórí Epo Rọ̀bì Àgbáyé ti Ọdún 2000 Látọwọ́ Àjọ Ilẹ̀ Amẹ́ríkà Tó Ń Ṣèwádìí Nípa Ilẹ̀ Ayé Àtàwọn Ohun Tó Wà Nínú Rẹ̀.”
ÀWỌN ògbógi nípa ohun àmúṣagbára sọ pé epo rọ̀bì lè di ohun tí wọ́n á wà gbẹ bí àkókò ti ń lọ. Àwọn kan fojú bù ú pé epo tó wà láyé kò lè lò ju ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́ta sí márùndínlọ́gọ́rùn-ún lọ mọ́ tí yóò fi tán. Ní báyìí ná, wọ́n ti ń ṣàmúlò àwọn ohun àmúṣagbára mìíràn, èyí tó jẹ́ pé láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ni wọ́n ti ń lo àwọn kan lára wọn. Lára àwọn ohun àmúṣagbára tí kò lè tán wọ̀nyí ni: oòrùn, ẹ̀fúùfù, ìgbì òkun, lílo omi fún iná mànàmáná àti ooru tó ń tinú òkun wá. Àmọ́, lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, àwọn ìṣòro ńláǹlà ṣì wà nípa bí wọ́n á ṣe máa mú wọn jáde àti bí wọ́n á ṣe máa pín wọn kiri.
Ríronú pé ká kọ́kọ́ lo àwọn ohun àmúṣagbára tó lè tètè tán lẹ́yìn náà ká wá bẹ̀rẹ̀ sí lo àwọn tí kò lè tán kò fi bẹ́ẹ̀ dára tó. Àwọn iléeṣẹ́ epo sì ti wà ní sẹpẹ́ láti lo ìwọ̀nba àkókò tí wọ́n ṣírò pé ó kù kí epo tán láti máa wa epo nìṣó. Àmọ́, ó dunni pé bí àkókò tí epo rọ̀bì fi máa wà bá ṣe pẹ́ tó náà ni àwọn ìṣòro tó ń fà bá àwùjọ àti àyíká náà á ṣe máa bá a lọ tó. Àmọ́, ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, kì í ṣe epo fúnra rẹ̀ ló ń fa ìṣòro yìí. Ojúkòkòrò ọmọ ẹ̀dá àti ìfẹ́ láti jẹgàba lé àwọn mìíràn lórí ló sọ epo ní orúkọ burúkú tó ń jẹ́.
Ó dùn mọ́ni pé kì í ṣe ọwọ́ àwọn orílẹ̀-èdè ni ọjọ́ iwájú epo rọ̀bì àti gbogbo àwọn ohun àmúṣagbára wà. Ọwọ́ Jèhófà Ọlọ́run, Ẹni tó dá ayé tó sì tún jẹ́ Alábòójútó rẹ̀, ló wà. Ó sì ti ṣèlérí pé láìpẹ́, gbogbo ìṣòro àyíká àti ti àwùjọ tó jẹ mọ́ bí wọ́n ṣe ń lo àwọn ohun àmúṣọrọ̀ ilẹ̀ ayé àti bí wọ́n ṣe ń ṣe wọ́n níṣekúṣe máa dàwátì. (Ìṣípayá 4:11) Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, àkókò ti sún mọ́lé báyìí tí Ọlọ́run yóò “run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé.” Ìṣàkóso òdodo látọwọ́ Ọlọ́run yóò mú “ọ̀run tuntun kan àti ilẹ̀ ayé tuntun kan” wá, ìyẹn ayé tí kò ní sí ìwà ìnìkànjọpọ́n àti ìrẹ́jẹ níbẹ̀, níbi tí àwọn nǹkan àmúṣọrọ̀ ilẹ̀ ayé á ti jẹ́ èyí táwọn èèyàn yóò máa lò láìsí ìmọtara-ẹni-nìkan fún àǹfààní gbogbo èèyàn tó jẹ́ onígbọràn.—Ìṣípayá 11:18; 21:1-4.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Àwọn orísun mìíràn tí a gbà ń rí agbára ni lílo ohun èlò tí ń lo ìtànṣán láti fa agbára oòrùn àtàwọn ẹ̀rọ ayíbírí láti fa agbára látinú ẹ̀fúùfù