Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Epo Rọ̀bì—Bí Ó Ṣe Wúlò fún Ọ

Epo Rọ̀bì—Bí Ó Ṣe Wúlò fún Ọ

Epo Rọ̀bì—Bí Ó Ṣe Wúlò fún Ọ

ǸJẸ́ o tiẹ̀ ti fìgbà kan ronú nípa bí ìgbésí ayé á ṣe rí fún ọ̀pọ̀ èèyàn ká ní kò sí epo rọ̀bì àtàwọn ohun tí wọ́n ń rí nínú rẹ̀? a Látinú epo rọ̀bì la ti ń rí ọ́ìlì tí à ń lò fún ẹ́ńjìnnì ọkọ̀, kẹ̀kẹ́, kẹ̀kẹ́ ọmọdé àti àwọn nǹkan mìíràn tí wọ́n ní àwọn ẹ̀ya ara tó ń yí. Ọ́ìlì kì í jẹ́ kí àwọn ẹ̀ya ara maṣíìnì jẹ, nípa bẹ́ẹ̀ wọn ò ní tètè dẹnu kọlẹ̀. Àmọ́, àwọn ohun mìíràn tún wà tí wọ́n ń lo ọ́ìlì fún o.

Látinú epo rọ̀bì ni wọ́n ti ń rí epo tí ọkọ̀ òfuurufú, ọkọ̀ ìrìnnà àti ẹ̀rọ amúlémóoru ń lò. Àwọn èròjà tó wá láti inú epo rọ̀bì ni wọ́n fi ń ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun ìṣaralóge, ọ̀dà ìkunlé, yíǹkì, oògùn, ajílẹ̀, ike àti àìlóǹkà àwọn nǹkan mìíràn. Ká ní kò sí epo rọ̀bì ni, ìgbésí ayé ì bá yàtọ̀ pátápátá fún ọ̀pọ̀ èèyàn. Abájọ tí orísun ìsọfúnni kan fi sọ pé, epo rọ̀bì àtàwọn nǹkan tí wọ́n ń rí nínú rẹ̀ wúlò “fún ṣíṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan débi pé bóyá ni èròjà èyíkéyìí mìíràn tún wà lórí ilẹ̀ ayé tó wúlò jù ú lọ.” Báwo la ṣe ń rí epo rọ̀bì? Ibo ló ti ń wá? Báwo ló ṣe pẹ́ tó tí ẹ̀dá èèyàn ti ń lò ó?

Bíbélì sọ fún wa pé, ní ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún ọdún méjì ṣáájú kí Kristi tó wá sáyé, Nóà tẹ̀ lé ìtọ́ni tí Ọlọ́run fún un láti kan ọkọ̀ gìrìwò kan ó sì lo ọ̀dà bítúmẹ́nì, èyí tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èròjà tó wá látinú epo rọ̀bì, kí omi má bàa ráyè wọnú ọkọ̀ náà. (Jẹ́nẹ́sísì 6:14) Àwọn ará Bábílónì máa ń lo àwọn nǹkan tó wá látinú epo rọ̀bì fún ṣíṣe bíríkì sísun, àwọn ará Íjíbítì máa ń lò ó nígbà tí wọ́n bá ń kun òkú lọ́ṣẹ, bẹ́ẹ̀ sì làwọn èèyàn ayé ọjọ́un mìíràn lò ó fún ìtọ́jú àìsàn.

Ta ló lè ronú pé ohun èlò yìí lè wá di ohun tó ṣe pàtàkì báyìí lóde òní? Kò sẹ́ni tó lè jiyàn rẹ̀ pé ọ̀làjú tí àwọn iléeṣẹ́ ẹ̀rọ òde òní mú bá ayé kò ṣẹ̀yìn epo rọ̀bì.

Lílò tí wọ́n ń lo epo tí wọ́n ń rí látinú epo rọ̀bì fún títan iná ló túbọ̀ wá sọ ọ́ di ìlúmọ̀ọ́ká. Láti ọ̀rúndún kẹẹ̀ẹ́dógún ni wọ́n ti ń lo epo tó ń sun jáde látinú ilẹ̀ fún títan àtùpà ní ìlú Baku, tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè Azerbaijan lónìí. Lọ́dún 1650, wọ́n gbẹ́ àwọn kòtò tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìn ní orílẹ̀-èdè Romania, níbi tí wọ́n ti lo epo tí wọ́n rí níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi kẹrosíìnì fún títan iná. Nígbà tó fi máa di ìdajì ọ̀rúndún kọkàndínlógún, orílẹ̀-èdè yìí àtàwọn mìíràn ní Ìlà Oòrùn Yúróòpù ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣòwò epo, òwò náà sì búrẹ́kẹ́.

Ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, rírí ohun amúnáwá tó jẹ́ ojúlówó ni olórí ohun tó sún àwùjọ àwọn ọkùnrin kan láti bẹ̀rẹ̀ sí í wá epo láwọn ọdún 1800. Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí gbà pé kí epo kẹrosíìnì tí yóò tó tà lọ́jà tó lè wà, àwọ́n ní láti gbẹ́lẹ̀ láti wa epo rọ̀bì jáde, èrò wọn sì tọ̀nà. Nípa bẹ́ẹ̀, lọ́dún 1859, ó ṣeé ṣe fún wọn láti wa epo jáde ní ìlú Pennsylvania. Bí kìràkìtà lórí epo rọ̀bì ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn o. Kí ló wá ṣẹlẹ̀ tẹ̀ lé èyí?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ọ̀rọ̀ náà “epo rọ̀bì” dúró fún ohun méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀—epo rọ̀bì fúnra rẹ̀ àti èròjà kan tí wọ́n jọ ń wá láti abẹ́ ilẹ̀, ìyẹn ògidì gáàsì, tí wọ́n tún ń pè ní mẹtéènì. Nígbà míì, àwọn èròjà méjèèjì yìí máa ń sun jáde láti abẹ́ ilẹ̀. Ní ti epo rọ̀bì, ó lè ṣàn bí omi tàbí kó rí bí ọ̀dà ásífáàtì tí wọ́n fi ń ṣe títì, bí ọ̀dà bítúmẹ́nì rírọ̀ tàbí líle, tàbí bí ọ̀dà tar.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 3]

KÍ LÓ Ń JẸ́ EPO RỌ̀BÌ?

Epo rọ̀bì jẹ́ nǹkan kíki, tó lè tètè gbiná, tó ní àwọ̀ ìyeyè òun àwọ̀ dúdú tó sì jẹ́ àpapọ̀ àwọn èròjà gáàsì, èròjà olómi, àtàwọn èròjà líle, abẹ́ ilẹ̀ ló sì ti ń wá. Wọ́n lè mú oríṣiríṣi nǹkan jáde látinú rẹ̀, àwọn nǹkan bí ògidì gáàsì, epo pẹtiróòlù, èròjà náfútà, kẹrosíìnì, epo ọkọ̀, ọ́ìlì tí wọ́n ń lò fún àwọn ẹ̀ya ara ẹ̀rọ, àtè àti ọ̀dà ásífáàtì tí wọ́n fi ń ṣe títì, wọ́n sì tún ń lò ó fún mímú ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan mìíràn jáde.