Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wíwo Ayé

Wíwo Ayé

Wíwo Ayé

Ọkọ̀ Ayọ́kẹ́lẹ́ Tó Ń Lo Pàǹtírí

Ní báyìí, ọkùnrin àgbẹ̀ kan ní orílẹ̀-èdè Finland ti ní ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan tó ń lo gáàsì tó ń jáde látinú pàǹtírí tó ti jẹrà. Ìwé ìròyìn ilẹ̀ Finland náà, Suomen luonto sọ pé: “Gáàsì biogas tó ń jáde látinú àwọn pàǹtírí, tí ẹ̀rọ tó ń yí nǹkan padà ti sọ di mímọ́ níbi tí wọ́n dé e mọ́ nínú ẹ̀rọ tó wà lóko ọkùnrin náà, ni ọkọ̀ yìí ń lò.” Gáàsì tó ń wá látinú pàǹtírí yìí ni epo ọkọ̀ tó mọ́ jù lọ tó wà lónìí, níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé wọ́n lè rí i nígbà tí wọ́n bá ń yí pàǹtírí padà sí nǹkan tó wúlò, kì í ba àyíká jẹ́. Kódà, lára àwọn ohun tí wọ́n ń rí lẹ́yìn tí wọ́n bá ti yọ gáàsì yìí tán nínú pàǹtírí ni ajílẹ̀ tó wúlò gan-an fún iṣẹ́ àgbẹ̀. Àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tó ń lo ògidì gáàsì, tí iye wọn ń lọ sí bíi mílíọ̀nù méjì báyìí jákèjádò ayé, tún lè lo gáàsì yìí. Ní orílẹ̀-èdè Sweden, ọ̀pọ̀ àwọn bọ́ọ̀sì tó wà nígboro ló jẹ́ pé gáàsì yìí ni wọ́n ń lò, àwọn ilé epo kan níbẹ̀ sì ti ń ta gáàsì yìí láfikún sáwọn epo ọkọ̀ mìíràn. Gẹ́gẹ́ bí àpilẹ̀kọ náà ti sọ, pabanbarì rẹ̀ ni pé: “Gáàsì biogas kò wọ́n tó pẹtiróòlù àti dísù rárá.”

Ìdí Tí Ọ̀gbàrá Òjò Kì Í Fi Í Gbé Àwọn Èèrà Lọ

Kí làwọn èèrà máa ń ṣe tí òjò bá ń rọ̀? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo èèrà ló ń gbé inú ihò ilẹ̀, ìwé ìròyìn The New York Times sọ pé àwọn tó ń gbébẹ̀ máa ń ṣe àwọn nǹkan kan tó jẹ́ àgbàyanu kí ọ̀gbàrá òjò má bàa gbé wọn lọ. Àwọn ògbóǹkangí onímọ̀ nípa èèrà, Ọ̀mọ̀wé Edward O. Wilson àti Bert Holldobler, ṣàlàyé pé àwọn èèrà kan tó ń gbé nínú àwọn igbó ilẹ̀ olóoru “máa ń fẹsẹ̀ fẹ́ẹ kódà bó bá jẹ́ ẹ̀kán [omi] kan ṣoṣo lásán ni wọ́n rí lẹ́nu ihò wọn nípa sísáré gba inú ihò náà láti ta àwọn èèrà yòókù lólobó tí wọ́n á sì gba àwọn ẹnu ihò mìíràn jáde. Òórùn ara wọn táwọn èèrà yòókù ń gbọ́ ló máa ń darí wọn lọ sí àwọn ẹnu ihò tí kò tíì dí tàbí kí wọ́n tiẹ̀ kúkú jáde pátápátá nínú ihò náà.” Ká tó ṣẹ́jú pẹ́ẹ́, wọ́n á ti mú kí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èèrà tó wà nínú ihò náà kóra jọ. Ìwé ìròyìn The Times sọ pé, ní apá gúúsù ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti ní ìhà àríwá Gúúsù Amẹ́ríkà sì rèé, àwọn èèrà pupa kan “máa ń rìn wá sẹ́nu ihò wọn, wọ́n á gbára jọ rẹpẹtẹ, àtàwọn tó dàgbà nínú wọn, àtàwọn tó máa ń pamọ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀, wọ́n á wá léfòó lórí omi tó ń ga sí i náà. Ọ̀pọ̀ wọn ló máa ń yè é . . . Níkẹyìn, àwọn èèrà tó ṣù jọ wọ̀nyí á wá toro mọ́ koríko tàbí àwọn ewé igbó, àwọn tó sì là á já lè tún padà sínú ihò náà nígbà tí omi bá lọ sílẹ̀.”

Ọṣẹ́ Ńlá Tí Ọtí Àmujù Ń Ṣe

Ìwé ìròyìn The Independent ti ìlú London sọ pé: “Bí àwọn obìnrin àtàwọn ọ̀dọ́ ṣe ń mutí lámujù ti mú kí àwọn tí ọtí líle ń pa nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì pọ̀ gan-an. Àwọn tó ń kú nítorí mímu ọtí nímukúmu ti di ìlọ́po méjì láàárín ogún ọdún, àrùn ìwúlé ẹ̀dọ̀ tó le koko àti ìsúnkì ẹ̀dọ̀ ló sì ń pa èyí tó pọ̀ jù nínú wọn.” Rèwerèwe làwọn tó ń mutí àmujù náà wá ń kú báyìí. Ìròyìn náà sọ pé: “Lọ́dún mẹ́wàá sẹ́yìn, tọkùnrin tobìnrin tó máa ń mu ọtí àmujù máa ń lé láàádọ́rin ọdún kí wọ́n tó kú. Iye tí wọ́n gbé síta kẹ́yìn nípa àwọn tí ọtí àmujù pa láàárín ọdún 1998 sí 2000 fi hàn pé wọn kì í pé ọgọ́ta ọdún mọ́.” Àmọ́, àbájáde ọtí ìmukúmu kò mọ sórí àìsàn nìkan o. Nílẹ̀ Faransé, ìwé ìròyìn Le Monde sọ pé “kò sí tàbí-ṣùgbọ́n pé ọtí líle ló ń fa ìdá mẹ́wàá sí ìdá ogún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn jàǹbá tó ń wáyé lẹ́nu iṣẹ́.” Kò tán síbẹ̀ o, lọ́dọọdún nílẹ̀ Faransé, ẹgbẹ̀tàlá ààbọ̀ [2,700] èèyàn ló ń kú, tí ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún [24,000] sì ń fara pa yánnayànna nínú àwọn jàǹbá tó ń ṣẹlẹ̀ lójú pópó nítorí ọtí àmujù, bẹ́ẹ̀ ni ọtí líle kò ṣẹ̀yìn ìdá mẹ́ta nínú mẹ́wàá ìwà ọ̀daràn tó ń ṣẹlẹ̀. Bákan náà ni ọtí ìmukúmu tún ń kó orílẹ̀-èdè náà sí gbèsè rẹpẹtẹ. Ìwé ìròyìn Le Monde sọ pé nílẹ̀ Faransé lọ́dún 1996, mímu ọtí lámujù fa àdánù owó tí wọ́n fojú bù pé ó lé ní bílíọ̀nù mọ́kàndínlógún dọ́là.

Ìdààmú Ọkàn Ń Dá Àìsàn Síni Lára

Ìwádìí kan wáyé ní orílẹ̀-èdè Netherlands nípa àwọn òṣìṣẹ́ tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ. Ìròyìn tí Àjọ Tó Ń Ṣèwádìí Lórí Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì ní Orílẹ̀-Èdè Netherlands gbé jáde nípa ìwádìí náà sọ pé: “Ìdààmú ọkàn lẹ́nu iṣẹ́ àti àárẹ̀ máa ń jẹ́ kéèyàn tètè ní àkóràn líle irú bí ọ̀fìnkìn, àwọn àìsàn tó jẹ mọ́ òtútù, àti àrùn inú àti ti ìfun. Ìwádìí náà jẹ́ kó hàn kedere pé àwọn òṣìṣẹ́ tí iṣẹ́ wọn kì í fún wọn ní ìsinmi rárá máa ń ní ọ̀fìnkìn ju àwọn òṣìṣẹ́ tí iṣẹ́ wọn kò fi bẹ́ẹ̀ kó wọn láyà sókè lọ.” Àwọn nǹkan mìíràn tí wọ́n tún rí i pé ó ń jẹ́ kéèyàn tètè ní àkóràn ni ṣíṣe iṣẹ́ alẹ́ àti àìsí ìfọ̀kànbalẹ̀ nítorí àtúntò tó máa ń wáyé láwọn iléeṣẹ́. Ìròyìn náà sọ pé: “Àwọn òṣìṣẹ́ alẹ́ lè tètè ní àkóràn ju àwọn tó ń ṣiṣẹ́ lójú mọmọ lọ.”

Àwọn Èwe àti Orin Kíkọ

Orin kíkọ jẹ́ “ọ̀nà pàtàkì kan láti fi ìmọ̀lára hàn ó sì ń jẹ́ kí àwọn ọmọ ní ìwà tó dáa,” gẹ́gẹ́ bí Dókítà Michael Fuchs tó jẹ́ ògbóǹtagí onímọ̀ nípa ìtọ́jú etí, imú àti ọ̀nà ọ̀fun ní Yunifásítì Leipzig, ṣe sọ nínú ìwé ìròyìn ilẹ̀ Jámánì náà, Gesundheit. Àmọ́, Fuchs dárò pé “láti bí ogún ọdún sẹ́yìn, ó hàn gbangba pé ohùn àwọn ọmọdé ò fi bẹ́ẹ̀ ròkè mọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀. Bákan náà ló jẹ́ pé ìró ohùn wọn pàápàá ti yí padà.” Fuchs wá sọ àwọn nǹkan méjì tó ṣeé ṣe kó fa èyí. Àkọ́kọ́, “àwọn èwe òde ìwòyí kì í fi bẹ́ẹ̀ kọrin nílé mọ́. Nígbà tó jẹ́ pé láyé àtijọ́ àwọn ìdílé máa ń lo àkókò tí wọn ò bá ṣe nǹkan kan láti kọrin tàbí láti fi àwọn ohun èlò ìkọrin ṣeré, lákòókò yìí, iwájú tẹlifíṣọ̀n ni gbogbo wọn máa ń jókòó sí, etí nìkan ni wọ́n sì fi ń gbọ́ orin báyìí.” Èkejì, nígbà táwọn ọmọdé bá tiẹ̀ ń kọrin pàápàá, wọ́n máa ń fẹ́ láti lo irú ohùn kíkẹ̀ táwọn akọrin jìn-jin-jìn àtàwọn olórin gbígbajúmọ̀ ń lò. Fuchs kọ̀wé pé: “Ìnira táwọn èwe máa ń kó bá ohùn wọn ti pọ̀ jù níbi tí wọ́n bá ti ń gbìyànjú láti fara wé irú àwọn gbajúmọ̀ olórin bẹ́ẹ̀.” Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lè mú kí gògóńgò àti iṣan ọrùn wọn le tantan. Ìnira tí wọ́n ń kó bá ohùn wọn yìí lè mú kí àwọn kókó tín-tìn-tín máa fara hàn nínú tán-án-ná ọ̀nà ọ̀fun wọn, tí èyí á sì túbọ̀ máa sọ ohùn wọn dìdàkudà sí i.

Títún Yàrá Ṣe Lọ́ṣọ̀ọ́ Lè Mú Kí Ọmọ Tuntun Ṣàìsàn

Ìwé ìròyìn ilẹ̀ Jámánì náà, Medi-Netz sọ pé: “Bí àwọn èèyàn bá tún yàrá wọn ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ nígbà tí obìnrin wà nínú oyún tàbí ní kété tí wọ́n bá bí ọmọ náà tán, ọ̀nà ọ̀fun lè máa dun ọmọ náà tàbí kó tiẹ̀ máa ní ìṣòro mímí láwọn oṣù àkọ́kọ́ tó dáyé. Ní báyìí, wọ́n tún ti ṣàwárí pé èyí tún ń nípa lórí agbára tí ń dènà àrùn lára ọmọ, kódà nígbà tó ṣì wà nínú oyún pàápàá, tí ọmọ á sì tètè máa kó àìsàn tí yóò sì tún máa ní èèwọ̀ ara.” Àwọn olùṣèwádìí láwọn ilé ìwòsàn àtàwọn ibùdó ìwádìí bíi mélòó kan ní orílẹ̀-èdè Jámánì ti ṣàkíyèsí pé lára àwọn kẹ́míkà tó ń dá ìṣòro ọ̀hún sílẹ̀ làwọn tó ń tú jáde látinú àtè, kápẹ́ẹ̀tì, ọ̀dà tí kò tíì gbẹ àtàwọn àga inú ilé tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe. Ìwé ìròyìn Medi-Netz tún sọ pé: “Àwọn sẹ́ẹ̀lì pàtàkì tó lè dáàbò bò wá lọ́wọ́ àwọn èèwọ̀ ara ni àwọn kẹ́míkà tó léwu yìí máa ń sọ di aláìlágbára.” Ìròyìn kan tó fara jọ èyí nínú ìwé ìròyìn GEO dámọ̀ràn pé kí àwọn òbí sún títún ilé ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ síwájú “títí dìgbà tí ìkókó á fi pé ọmọ ọdún méjì,” nígbà tí agbára ìdènà àrùn ara rẹ̀ á ti lágbára sí i.

Fítámì D Ṣe Pàtàkì Gan-an Nígbà Òtútù

Ìwé àtìgbàdégbà náà, Tufts University Health & Nutrition Letter ṣàlàyé pé: “Ara nílò fítámì D kó bàa lè gba èròjà calcium sínú, kí èròjà yìí lè dé inú egungun, kó sì ṣèrànwọ́ fún àwọn egungun ara kí wọ́n má bàa kán. Awọ ara wa ló sábà máa ń mú ìdá àádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún èròjà fítámì D jáde nígbà tí oòrùn bá ta sí wa lára. Àmọ́, láwọn àgbègbè tó máa ń tutù nini, ìtànṣán oòrùn kì í lágbára tó láti mú kí ara mú èròjà fítámì D jáde láwọn oṣù ìgbà òtútù. Èyí tó tún wá burú níbẹ̀ ni pé, ṣàṣà làwọn tó jẹ́ ẹni àádọ́ta ọdún tàbí tí wọ́n dàgbà jù bẹ́ẹ̀ lọ tí wọ́n ń jẹ àwọn oúnjẹ tó ń fún ara ní ìdá mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn-ún èròjà fítámì D tí ara nílò.” Fún ìdí èyí, Ilé Ẹ̀kọ́ Nípa Ìlera ti Ìjọba Àpapọ̀ Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà dámọ̀ràn pé, tó bá ti di ìgbà òtútù láwọn àgbègbè tó máa ń tutù nini, kí àwọn tó ti lé ní àádọ́ta ọdún, ní pàtàkì, ṣàfikún èròjà fítámì D tí wọ́n ń gbà sára nípa jíjẹ àwọn oúnjẹ bí ẹja ọlọ́ràá kí wọ́n sì máa lo oògùn tí wọ́n fi epo ẹja ṣe tàbí kí wọ́n máa lo oògùn tó ń ṣàlékún fítámì D nínú ara, àmọ́ ṣá kó má pọ̀ ju bó ṣe yẹ lọ. Kó má ju ìwọ̀n ẹgbàá tí a fọwọ́ sí lágbàáyé, ìyẹn ìwọ̀n àádọ́ta máíkírógíráàmù lójúmọ́.

Àwọn Ọ̀dọ́mọdé Ọ̀mùtí ní Gúúsù Áfíríkà

Ìwé ìròyìn The Star ti ìlú Johannesburg kìlọ̀ pé: “Gúúsù Áfíríkà lè di orílẹ̀-èdè àwọn ọ̀mùtí paraku, nítorí bí àwọn ọmọdé ṣe ń dẹni tó ń mu ọtí ìmukúmu nígbà tọ́jọ́ orí wọn ṣì kéré gan-an.” Wọ́n sọ pé láwọn iléèwé kan, àwọn ọmọdé tí ọjọ́ orí wọn kò ju ọdún mẹ́sàn-án lọ ni ràbọ̀ràbọ̀ ọtí ṣì máa ń wà lára wọn nígbà tí wọ́n bá fi máa dé iléèwé, ńṣe ni àṣàkaṣà náà sì ń burú sí i. Kí ló fà á táwọn ọmọ fi ń mu ọtí nímukúmu bẹ́ẹ̀? Àwọn ọlọ́pàá nàka àbùkù sí “àwọn ìpolówó [tó] ń ṣàfihàn irú ìgbésí ayé tí àwọn ọ̀dọ́langba nífẹ̀ẹ́ sí.” Àwọn ìdí mìíràn tí ìwé ìròyìn náà tún mẹ́nu kàn ni bó ṣe rọrùn fún wọn láti rí ọtí, bó ṣe jẹ́ ohun ìtẹ́wọ́gbà láwùjọ, bí àwọn òbí ṣe ń gba ìgbàkugbà láyè àti bí àwọn ọmọ ṣe wá ń lómìnira tí wọ́n sì ń lówó lọ́wọ́ báyìí. Ẹnì kan tó jẹ́ afìṣemọ̀rònú sọ pé: “Bákan náà, àwọn òbí kì í ṣàkóso àwọn ọmọ wọn mọ́, àwọn ọmọ ò sì bọ̀wọ̀ fún àṣẹ kankan mọ́—èyí tó jẹ́ olórí ohun tó sọ àwùjọ dìdàkudà pátápátá.”