Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Yẹra fún Fífi Ẹ̀gbọ́n Mi Ṣe Àwòkọ́ṣe Nínú Gbogbo Nǹkan?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Yẹra fún Fífi Ẹ̀gbọ́n Mi Ṣe Àwòkọ́ṣe Nínú Gbogbo Nǹkan?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Yẹra fún Fífi Ẹ̀gbọ́n Mi Ṣe Àwòkọ́ṣe Nínú Gbogbo Nǹkan?

“Mo fẹ́ máa ṣe nǹkan bí Ọlọ́run ṣe dá mi, àmọ́ mo sábà máa ń wò ó pé mo ní láti máa ṣe bíi ti àwọn ẹ̀gbọ́n mi obìnrin. Mo máa ń ronú pé èmi ò lè ṣe àwọn ohun ribiribi tí àwọn arábìnrin mi ti ṣe.”—Clare.

ǸJẸ́ o ní arákùnrin tàbí arábìnrin kan tó dà bíi pé kò sóhun tó dáwọ́ lé tí kò ṣe yọrí? Ǹjẹ́ àwọn òbí rẹ máa ń fi ìgbà gbogbo rọ̀ ọ́ láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹ̀gbọ́n rẹ náà? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, o lè máa bẹ̀rù pé òun lo gbọ́dọ̀ máa fi ṣe àwòkọ́ṣe nígbà gbogbo ṣáá, ìyẹn ni pé àyàfi ìgbà tó o bá tó ṣe nǹkan láṣeyọrí bíi ti ẹ̀gbọ́n rẹ làwọn èèyàn á tó mọ bó o ṣe wúlò sí.

Àwọn arákùnrin Barry a méjèèjì ló ti lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́, b èyí tó jẹ́ ilé ẹ̀kọ́ kan tí kò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn, gbogbo èèyàn ló sì kà wọ́n sí Kristẹni àwòfiṣàpẹẹrẹ. Barry sọ pé: “Mo bẹ̀rẹ̀ sí ro ara mi pin níwọ̀n bí mo ti rò pé n ò lè mọ iṣẹ́ ìwàásù ṣe tó wọn tàbí kí n mọ ọ̀rọ̀ sọ níwájú àwùjọ bíi tiwọn. Ó nira fún mi láti ní àwọn ọ̀rẹ́ tèmi nítorí pé ńṣe ni mo kàn máa ń tẹ̀ lé àwọn arákùnrin mi nígbà tí wọ́n bá pè wọ́n síbì kan. Mo wò ó pé ó dà bíi pé nítorí tàwọn ẹ̀gbọ́n mi làwọn èèyàn fi ń ṣe ọ̀yàyà sí mi.”

Kò sí àní-àní pé o lè máa di kùnrùngbùn bó o bá ní ẹ̀gbọ́n (tàbí àbúrò) kan tí àwọn èèyàn sábà máa ń gbóríyìn fún ṣáá. Nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, Jósẹ́fù ọ̀dọ́ jẹ́ ẹni tó yọrí ọlá láàárín àwọn arákùnrin rẹ̀. Báwo lèyí ṣe nípa lórí àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀? “Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kórìíra rẹ̀, wọn kò sì lè bá a sọ̀rọ̀ lọ́nà àlàáfíà.” (Jẹ́nẹ́sísì 37:1-4) Ṣùgbọ́n o, Jósẹ́fù kì í ṣe onígbèéraga ẹ̀dá. Àmọ́, ẹ̀gbọ́n (tàbí àbúrò) rẹ lè sún ọ láti máa bá òun figa gbága tàbí láti máa jowú bó bá jẹ́ pé gbogbo ìgbà ló ń sọ àwọn àṣeyọrí tó ti ṣe létí rẹ.

Ńṣe làwọn ọ̀dọ́ kan máa ń hùwà ọ̀tẹ̀ láti fi bí èyí ṣe rí lára wọn hàn. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè máa mọ̀ọ́mọ̀ gbòdo níléèwé, kí wọ́n má fi bẹ́ẹ̀ kópa nínú ìgbòkègbodò Kristẹni mọ́ tàbí kí wọ́n máa hu àwọn ìwà tí kò bójú mu. Wọ́n lè máa ronú pé bí àwọn kò bá lè ṣe dáadáa bíi tàwọn ẹ̀gbọ́n àwọn, kò pọn dandan pé kí àwọn ṣe ìsapá èyíkéyìí. Àmọ́ o, bópẹ́ bóyá, ọ̀tẹ̀ ṣíṣe á wulẹ̀ kó ọ sí yọ́ọ́yọ́ọ́ ni. Báwo lo ṣe lè yẹra fún fífi ẹ̀gbọ́n rẹ ṣe àwòkọ́ṣe nínú gbogbo nǹkan, tí o kò sì ní máa ro ara rẹ pin?

Má Ṣe Gbé Wọn Pọ́n Ju Bó Ṣe Yẹ Lọ

Bó o bá ń rí gbogbo bí àwọn èèyàn ṣe ń kan sáárá sí ẹ̀gbọ́n rẹ, o lè máa ronú pé ẹni pípé ni àti pé o ò lè ṣe bíi tirẹ̀ láéláé. Àmọ́, ṣé bí ọ̀rọ̀ ṣe rí nìyẹn lóòótọ́? Bíbélì ò pẹ́ ọ̀rọ̀ sọ rárá nígbà tó sọ pé: “Gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.”—Róòmù 3:23.

Bẹ́ẹ̀ ni o, ohun yòówù kí ẹ̀bùn àbínibí àwọn ẹ̀gbọ́n wa jẹ́, “ẹ̀dá ènìyàn tí ó ní àwọn àìlera kan náà” bíi tiwa ni wọ́n ṣì jẹ́. (Ìṣe 14:15) Kò sídìí láti máa gbé wọn gẹ̀gẹ̀ láìnídìí tàbí kó o kà wọ́n sí pàtàkì ju bó ṣe yẹ lọ. Jésù Kristi ni ẹ̀dá ènìyàn kan ṣoṣo tó tíì fi àpẹẹrẹ pípé lélẹ̀.—1 Pétérù 2:21.

Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Wọn!

Ìgbésẹ̀ tó kàn ni pé kó o gbìyànjú láti wo ipò tó o bá ara rẹ yìí gẹ́gẹ́ bí àǹfààní kan fún ọ láti kẹ́kọ̀ọ́. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa àwọn àbúrò Jésù Kristi lọ́kùnrin àti lóbìnrin. (Mátíù 13:55, 56) Ronú nípa ohun tí wọn ì bá ti kọ́ látọ̀dọ̀ ẹ̀gbọ́n wọn tó jẹ́ ẹni pípé! Síbẹ̀síbẹ̀, “ní ti tòótọ́, àwọn arákùnrin rẹ̀ kì í lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀.” (Jòhánù 7:5) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbéraga àti owú ni kò jẹ́ kí wọ́n ní ìgbàgbọ́. Àwọn tó jẹ́ arákùnrin Jésù nípa tẹ̀mí, ìyẹn àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ló dáhùn ìkésíni rẹ̀ pé: “Ẹ . . . kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi.” (Mátíù 11:29) Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde làwọn tó jẹ́ ọmọ ìyá rẹ̀ gan-gan ṣẹ̀ṣẹ̀ tó mọyì rẹ̀. (Ìṣe 1:14) Kó tó di àkókò yẹn, wọ́n ti pàdánù ọ̀pọ̀ àǹfààní ṣíṣeyebíye láti kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ arákùnrin wọn tó jẹ́ ẹni títayọ.

Kéènì ṣe irú àṣìṣe kan náà. Àbúrò rẹ̀ Ébẹ́lì jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó tayọ. Bíbélì sọ pé “Jèhófà fi ojú rere wo Ébẹ́lì àti ọrẹ ẹbọ rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 4:4) Àmọ́ ṣá o, nítorí àwọn ìdí kan, Ọlọ́run “kò fi ojú rere kankan wo Kéènì àti ọrẹ ẹbọ rẹ̀.” Kéènì ì bá ti fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn, kó sì ti kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ arákùnrin rẹ̀. Dípò ìyẹn, ńṣe ni “ìbínú Kéènì . . . gbóná gidigidi,” ó sì pa Ébẹ́lì lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.—Jẹ́nẹ́sísì 4:5-8.

Láìsí àní-àní, o ò ní bínú débi tí wàá fi ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ yẹn sí ẹ̀gbọ́n (tàbí àbúrò) rẹ. Àmọ́, ìwọ náà lè pàdánù ọ̀pọ̀ àǹfààní ṣíṣeyebíye bó o bá jẹ́ kí ìgbéraga àti owú nípa lórí rẹ. Bó o bá ní ẹ̀gbọ́n kan tó mọ ẹ̀kọ́ ìṣirò dáadáa, tí kò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nínú ẹ̀kọ́ nípa ìtàn, tó mọ eré ìdárayá tó o fẹ́ràn gan-an jù ọ́ lọ, tí Ìwé Mímọ́ ń hó lórí rẹ̀ tàbí tí kò kẹ̀rẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ sísọ níwájú àwùjọ, o gbọ́dọ̀ yàgò fún owú jíjẹ o! Ó ṣe tán, “owú jẹ́ ìjẹrà fún àwọn egungun,” ìpalára ni yóò sì ṣe fún ọ. (Òwe 14:30; 27:4) Dípò tí wàá fi máa di kùnrùngbùn, gbìyànjú láti kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ. Gbà pé ó ní àwọn ẹ̀bùn àbínibí kan tí ìwọ kò ní tàbí pé ó mọ àwọn nǹkan kan tí ìwọ ò mọ̀. Máa kíyè sí bí ẹ̀gbọ́n rẹ ṣe ń ṣe nǹkan, tàbí kó o tiẹ̀ kúkú béèrè fún ìrànlọ́wọ́ látọ̀dọ̀ rẹ̀.

Barry, tí a mẹ́nu kàn níṣàájú, jàǹfààní nígbà tó yá látinú àpẹẹrẹ rere tí àwọn arákùnrin rẹ̀ fi lélẹ̀. Ó sọ pé: “Mo rí bí àwọn ẹ̀gbọ́n mi ṣe jẹ́ aláyọ̀ tó nítorí pé wọ́n múra tán láti ṣèrànwọ́ fún àwọn èèyàn nínú ìjọ àti nínú iṣẹ́ ìwàásù. Nítorí náà, mo pinnu láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn arákùnrin mi, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba àti Ẹ̀ka Ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìrírí tí mo ní ti mú kó ṣeé ṣe fún mi láti má ṣe ro ara mi pin, ó sì ti ràn mí lọ́wọ́ láti mú kí àjọṣe mi pẹ̀lú Jèhófà sunwọ̀n sí i.”

Lílo Ẹ̀bùn Tó O Ní Dáadáa

Ó ṣeé ṣe kó o máa bẹ̀rù pé fífara wé àwọn ànímọ́ rere ẹ̀gbọ́n (tàbí àbúrò) rẹ kò ní jẹ́ kó o lè ṣe nǹkan bí Ọlọ́run ṣe dá ọ. Àmọ́, kò pọn dandan kí ìyẹn ṣẹlẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní pé: “Ẹ di aláfarawé mi.” (1 Kọ́ríńtì 4:16) Ǹjẹ́ èyí túmọ̀ sí pé Pọ́ọ̀lù ò fẹ́ kí wọ́n hùwà bí Ọlọ́run ṣe dá wọn ni? Rárá o. Kálukú ló láǹfààní láti lo ànímọ́ tirẹ̀. Bóò bá mọ ẹ̀kọ́ ìṣirò tó ẹ̀gbọ́n rẹ, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé o ní àbùkù kan ni. Ohun tí èyí wulẹ̀ túmọ̀ sí ni pé irú ẹ̀dá tìrẹ yàtọ̀.

Pọ́ọ̀lù fún wa ní ìmọ̀ràn gbígbéṣẹ́ yìí pé: “Kí olúkúlùkù máa wádìí ohun tí iṣẹ́ tirẹ̀ jẹ́, nígbà náà ni yóò ní ìdí fún ayọ̀ ńláǹlà ní ti ara rẹ̀ nìkan, kì í sì í ṣe ní ìfiwéra pẹ̀lú ẹlòmíràn.” (Gálátíà 6:4) O ò ṣe sapá láti túbọ̀ lo àwọn ẹ̀bùn àdánidá rẹ dáadáa, kó o sì gbìyànjú láti túbọ̀ di ọ̀jáfáfá sí i nínú àwọn ohun tó o mọ̀? Kíkọ́ láti sọ èdè àjèjì, láti mọ ohun èlò ìkọrin kan lò dáadáa tàbí láti mọ kọ̀ǹpútà lò lè jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ọ láti máa fi ojú tó tọ́ wo ara rẹ, ó sì lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ní òye tí yóò wúlò fún ọ nípa onírúurú nǹkan. Má ṣe ṣàníyàn nípa ṣíṣe nǹkan lọ́nà tí kò fi ní sí àléébù kankan! Fi kọ́ra láti máa ṣe nǹkan lọ́nà tó dára, tọkàntọkàn àti lọ́nà jíjáfáfá. (Òwe 22:29) O lè má fi bẹ́ẹ̀ já fáfá nínú ṣíṣe nǹkan kan, àmọ́ “ọwọ́ àwọn ẹni aláápọn ni yóò ṣàkóso,” gẹ́gẹ́ bí Òwe 12:24 ṣe sọ.

Bó ti wù kó rí, ohun tó yẹ kó o fẹ́ láti ṣiṣẹ́ lé lórí gan-an ni ìtẹ̀síwájú rẹ nípa tẹ̀mí. Òye téèyàn bá ní nípa àwọn nǹkan tẹ̀mí ṣeyebíye gidigidi ju ẹ̀bùn àbínibí èyíkéyìí táwọn èèyàn lè tètè rí lọ. Ronú nípa àwọn arákùnrin tó jẹ́ ìbejì náà, Ísọ̀ àti Jékọ́bù. Bàbá wọn máa ń kan sáárá sí Ísọ̀ gan-an nítorí pé ó jẹ́ “ọkùnrin tí ó mọ bí a ti ṣé ń ṣọdẹ, ọkùnrin inú pápá.” Nígbà tí wọ́n ṣì kéré, ó ṣeé ṣe kí àwọn èèyàn má ka Jékọ́bù, arákùnrin rẹ̀ sí nítorí pé ó jẹ́ “ọkùnrin aláìlẹ́gàn, tí ń gbé inú àwọn àgọ́.” (Jẹ́nẹ́sísì 25:27) Ísọ̀ kùnà láti mú kí ipò tẹ̀mí rẹ̀ jinlẹ̀ sí i, ó sì pàdánù ọ̀pọ̀ ìbùkún. Jékọ́bù ní tirẹ̀ jẹ́ ẹni tó nífẹ̀ẹ́ sí àwọn nǹkan tẹ̀mí, Jèhófà sì bù kún un lọ́pọ̀lọpọ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 27:28, 29; Hébérù 12:16, 17) Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú èyí? Mú kí ipò tẹ̀mí rẹ sunwọ̀n sí i, ‘jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ rẹ máa tàn,’ “ìlọsíwájú [rẹ yóò sì] fara hàn kedere fún gbogbo ènìyàn.”—Mátíù 5:16; 1 Tímótì 4:15.

Clare, tí a mẹ́nu kàn níṣàájú, sọ pé: “Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, àwọn ẹ̀gbọ́n mi obìnrin ni mo máa ń wò kọ́ṣe ní gbogbo ìgbà ṣáá. Àmọ́, nígbà tó yá, mo pinnu láti tẹ̀ lé àmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ náà pé kí n mú kí ìfẹ́ mi ‘gbòòrò síwájú.’ Mo bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ẹni ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú ìjọ wa ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí, mo sì wá onírúurú ọ̀nà tí mo lè gbà ṣèrànwọ́ fún àwọn tó ṣaláìní nínú ìjọ. Mo tún máa ń ké sí àwọn arákùnrin àti arábìnrin lọ́mọdé lágbà wá sí ilé wa, màá sì gbọ́únjẹ fún wọn. Ní báyìí, mo ti ní àwọn ọ̀rẹ́ púpọ̀ sí i, mo sì ti dá ara mi lójú ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.”—2 Kọ́ríńtì 6:13.

Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn òbí rẹ lè gbàgbéra, kí wọ́n sì máa rọ̀ ọ́ pé kó o gbìyànjú láti máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ arákùnrin tàbí arábìnrin rẹ. Ṣùgbọ́n, mímọ̀ pé ńṣe làwọn òbí rẹ ń fẹ́ kó o ṣe dáadáa kò ní jẹ́ kí èyí dùn ọ́ wọra jù. (Òwe 19:11) Àmọ́ o, ó bọ́gbọ́n mu pé kó o fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ sọ fún àwọn òbí rẹ pé bí wọ́n ṣe ń fi ọ́ wé ẹlòmíràn kò bá ọ lára mu. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n wá àwọn ọ̀nà mìíràn láti máa gbà sọ ohun tí wọ́n bá fẹ́ kó o ṣe fún ọ.

Má ṣe gbàgbé láé pé Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò kíyè sí ọ bó o bá ń sìn ín. (1 Kọ́ríńtì 8:3) Barry ṣàkópọ̀ gbogbo rẹ̀ nípa sísọ pé: “Mo rí i pé bí àkókò tí mò ń lò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ṣe ń pọ̀ sí i ni mo ṣe ń láyọ̀ sí i. Nísinsìnyí, àwọn èèyàn ti ń fi ọ̀wọ̀ tèmi wọ̀ mí níbàámu pẹ̀lú irú ẹ̀dá tí mo jẹ́, wọ́n sì mọyì mi bí wọ́n ṣe mọyì àwọn arákùnrin mi.”

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí lára àwọn orúkọ tí a lò padà.

b Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń bójú tó ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Ṣé ẹ̀gbọ́n rẹ làwọn èèyàn sábà máa ń gbóríyìn fún ṣáá?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Sapá láti lo ẹ̀bùn tó o ní dáadáa, kó o sì túbọ̀ di ọ̀jáfáfá sí i nínú àwọn ohun tó o mọ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

‘Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ rẹ máa tàn’ nípa mímú kí òye tó o ní nípa àwọn nǹkan tẹ̀mí jinlẹ̀ sí i