Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí Àìsàn Ibà Bá Ń ṣe Ọmọ Rẹ

Bí Àìsàn Ibà Bá Ń ṣe Ọmọ Rẹ

Bí Àìsàn Ibà Bá Ń ṣe Ọmọ Rẹ

“Ara mi ò yá!” Bí ọmọ rẹ bá fi ìnira sọ gbólóhùn yìí jáde, ó lè jẹ́ pé ojú ẹsẹ̀ ni wàá ti máa fi ọwọ́ ba ara rẹ̀ wò bóyá ó ń gbóná. Bó bá jẹ́ ibà ló ń ṣe é, láìsí àní-àní ẹ̀rù lè máa bà ọ́.

Ìwádìí kan tí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Àwọn Ọmọ Wẹ́wẹ́ ní Yunifásítì Johns Hopkins, tó wà ní ìlú Baltimore, ní ìpínlẹ̀ Maryland, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ṣe, fi hàn pé ìdá mọ́kànléláàádọ́rùn-ún àwọn òbí ló gbà gbọ́ pé “kódà àìsàn ibà fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ pàápàá lè ní àbájáde búburú kan ó kéré tán, ó lè fa gìrì tàbí kó ṣàkóbá fún ọpọlọ.” Ìwádìí kan náà yẹn fi hàn pé “ìdá mọ́kàndínláàádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn òbí ló fún àwọn ọmọ wọn ní oògùn tó ń dẹwọ́ àìsàn ibà ṣáájú kó tó di pé ara àwọn ọmọ wọn gbóná ju bó ṣe yẹ lọ.”

Báwo gan-an ló ṣe yẹ kí ẹ̀rù bà ọ́ tó bí ibà bá ń ṣe ọmọ rẹ? Àwọn ọ̀nà wo ló sì dára jù lọ láti gbà tọ́jú rẹ̀?

Ipa Pàtàkì Tí Ibà Ń Kó

Kí ló ń fa ibà? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, (bí a bá lo ohun ìdíwọ̀n tí wọ́n ń kì bọ ẹnu) ìwọ̀n mẹ́tàdínlógójì lórí òṣùwọ̀n Celsius (370C) ni ìdíwọ̀n ara tó wà déédéé (ìyẹn ni ìwọ̀n tó ń fi hàn pé ara kò gbóná jù tàbí tutù jù), ìdíwọ̀n ìgbóná ara máa ń yí padà díẹ̀díẹ̀ látàárọ̀ ṣúlẹ̀. a Nípa báyìí, ara rẹ lè má fi bẹ́ẹ̀ gbóná lọ́wọ́ òwúrọ̀, àmọ́ kó máa gbóná sí i bó bá ń di ọwọ́ ìrọ̀lẹ́. Apá kan nínú ọpọlọ, èyí tó ń jẹ́ hypothalamus, ló máa ń díwọ̀n bí ara ṣe ń gbóná sí. Ibà máa ń ṣeni nígbà tí agbára tí ń dènà àrùn nínú ara bá ń mú àwọn èròjà pyrogen jáde nínú ẹ̀jẹ̀, bó bá ti rí i pé àwọn kòkòrò àrùn tó ń fi àrùn ṣeni ti wọnú ara. Èyí ló máa sún hypothalamus láti mú kí ara gbóná.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ibà lè fa àìfararọ àti ìpàdánù omi ara, kì í kúkú wá ṣe ohun tó burú jáì. Àní, ó jọ pé ibà ń kópa pàtàkì nínú ríran ara lọ́wọ́ láti mú àwọn kòkòrò tó ń fi àrùn ṣeni kúrò, gẹ́gẹ́ bí ìsọfúnni tó wá láti Ibùdó Mayo Tó Ń Ṣe Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àti Ìwádìí Nípa Ìlera ṣe fi hàn. “Àwọn kòkòrò fáírọ́ọ̀sì tó ń fa otútù àtàwọn àìsàn mìíràn tí kì í jẹ́ kéèyàn lè mí dáadáa fẹ́ràn ibi tí kò bá gbóná. Nípa fífi ibà fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ ṣe ọ́, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni ara rẹ ń mú àwọn fáírọ́ọ̀sì náà kúrò.” Látàrí èyí, àwọn onímọ̀ nípa ìlera níbi ìṣèwádìí náà wá sọ láfikún pé “kò pọn dandan láti máa tọ́jú àìsàn ibà fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́, àti pé, ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lè ṣèdíwọ́ fún ọ̀nà tó yẹ kí ara ọmọ gbà kọ́fẹ padà fúnra rẹ̀.” Kódà, ilé ìwòsàn kan tiẹ̀ wà ní orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò tó máa ń tọ́jú àwọn àìsàn kan nípa mímú kí ara àwọn aláìsàn gbóná sí i.

Dókítà Al Sacchetti tó ń ṣiṣẹ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Oníṣègùn Tó Ń Rí sí Ìṣẹ̀lẹ̀ Pàjáwìrì Nílẹ̀ Amẹ́ríkà sọ pé: “Ibà gan-an fúnra rẹ̀ kì í ṣe ìṣòro. Àmọ́, ó jẹ́ àmì pé ó ṣeé ṣe kí kòkòrò àrùn kan ti wà nínú ara. Nítorí náà, nígbà tí ibà bá ń ṣe ọmọ kan, ọmọ náà ló yẹ kí àwọn òbí pe àfiyèsí sí, àti ohun náà gan-an tó ṣeé ṣe kó fa àìsàn náà, kì í ṣe bí ara ọmọ ṣe gbóná sí.” Àjọ Àwọn Oníṣègùn Tó Ń Tọ́jú Àìsàn Àwọn Ọmọdé Nílẹ̀ Amẹ́ríkà sọ pé: “Bí ibà bá ń ṣe ọmọ rẹ, tí ìdíwọ̀n ìgbóná ara rẹ̀ kò sì tíì fi ìwọ̀n kan àti ẹ̀sún mẹ́ta (38.30C) kọjá ìwọ̀n tó wà déédéé, kì í ṣe ohun tó fi bẹ́ẹ̀ pọn dandan láti lo oògùn sí, àyàfi bí ara bá ń ni ín tàbí bí gìrì bá ti máa ń mú un nígbà tí ibà bá ń ṣe é. Àní, bí ara bá tiẹ̀ gbóná gan-an ju ìwọ̀n tó wà déédéé lọ pàápàá, ìyẹn kì í ṣe ohun tó léwu tàbí tó fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì àyàfi bí gìrì bá ti máa ń mú un tẹ́lẹ̀ tàbí tó ní àìsàn bárakú kan. Ohun tó ṣe pàtàkì ni láti wo bí ọmọ rẹ ṣe ń ṣe. Bó bá ń jẹun tó ń sùn dáadáa, tó sì ń ṣeré, ó ṣeé ṣe kó máà nílò ìtọ́jú kankan.”

Bí A Ṣe Lè Ṣètọ́jú Ibà Fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́

Èyí ò wá túmọ̀ sí pé kò sí ohunkóhun tó o lè ṣe láti ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ o. Àwọn ògbógi kan nínú ìmọ̀ ìlera dá àwọn àbá tó wà nísàlẹ̀ wọ̀nyí fún ṣíṣètọ́jú ibà fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́: Má ṣe jẹ́ kí iyàrá ọmọ náà tutù jù tàbí kó móoru jù. Wọ aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ fún un. (Bí ooru bá mú un jù, èyí lè mú kí ibà náà pọ̀ sí i.) Rọ ọmọ náà láti máa mu omi àtàwọn nǹkan olómi bí omi èso tí wọ́n ti fi omi là, àti omi ọbẹ̀, nítorí pé ibà lè fa ìpàdánù omi ara. b (Àwọn ohun mímu tó ní èròjà kaféènì, irú bí ọtí ẹlẹ́rìndòdò tó ní cola nínú tàbí tíì dúdú lè mú kéèyàn máa tọ̀ gan-an, wọ́n sì lè mú kí omi ara túbọ̀ gbẹ.) Kí àwọn ìyá má ṣe ṣíwọ́ fífún àwọn ọmọ ìkókó lọ́mú. Má ṣe fún ọmọ ní àwọn oúnjẹ tí kì í tètè dà, nítorí pé ibà kì í jẹ́ kí oúnjẹ dà dáadáa nínú ikùn.

Bí ibà bá ń ṣe ọmọ kan, tí ìdíwọ̀n ìgbóná ara rẹ̀ sì fi ìwọ̀n kan àti ẹ̀sún mẹ́sàn-án (38.90C) kọjá ìwọ̀n tó wà déédéé, àwọn oògùn tó ń dẹwọ́ ibà, èyí téèyàn lè rà lórí àtẹ ni wọ́n sábà máa ń fún un, irú bí acetaminophen (ìyẹn ni parasitamọ́ọ̀) tàbí ibuprofen. Àmọ́ o, ó ṣe pàtàkì láti fún ọmọ náà ní ìwọ̀n oògùn tí ìwé ìtọ́ni tó bá oògùn náà wá sọ pé kéèyàn lò. (Kí a má ṣe fún àwọn ọmọ tí kò bá tíì pé ọdún méjì ní oògùn èyíkéyìí láìjẹ́ pé dókítà sọ bẹ́ẹ̀.) Àwọn oògùn tó ń dẹwọ́ ibà kì í gbógun ti kòkòrò àrùn. Nípa bẹ́ẹ̀, wọn kì í mú kí ara ọmọ tètè kọ́fẹ padà bí otútù tàbí irú àwọn àìlera bẹ́ẹ̀ bá ń ṣe é, àmọ́ wọ́n lè mú kí ara tù ú. Àwọn ògbógi kan dábàá pé láti dẹwọ́ àìsàn ibà, kí a má ṣe fún àwọn ọmọ tí kò bá tíì pé ọdún mẹ́rìndínlógún ní oògùn asipiríìnì, nítorí pé ìwádìí ti fi hàn pé ó lè fa àìsàn Reye—àìsàn kan tó lè gbẹ̀mí ẹni. c

A tún lè dẹwọ́ ibà nípa fífi kànrìnkàn wẹ̀ fún ọmọ. Jẹ́ kí ọmọ náà jókòó sínú agbada ìwẹ̀ tí omi lílọ́wọ́ọ́rọ́ díẹ̀ wà nínú rẹ̀, kí o sì máa fi kànrìnkàn ṣí ara fún un. (Má ṣe lo ògógóró, nítorí pé ó lè ṣèpalára fún ọmọ.)

Àpótí tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí ní àwọn ìsọfúnni díẹ̀ tó lè ṣèrànwọ́ fúnni nípa ìgbà téèyàn lè ṣètò láti lọ rí dókítà. Gbígba ìtọ́jú lọ́dọ̀ àwọn oníṣègùn ṣe pàtàkì gan-an fún ẹnì kan tó bá ń gbé ní àgbègbè tí irú àwọn àrùn ibà lílégbá kan bí ibà dengue, àrùn Ebola, ibà jẹ̀funjẹ̀fun tàbí ibà pọ́njú ti gbòde kan.

Nígbà náà, ju gbogbo rẹ̀ lọ, ohun tó dára jù pé kó o ṣe ni pé kó o mú kí ara túbọ̀ tu ọmọ rẹ. Rántí pé kì í sábà ṣẹlẹ̀ pé kí ibà kan le títí kó wá ṣàkóbá fún ọpọlọ tàbí kó yọrí sí ikú. Kódà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé gìrì tí ibà ń fà lè bani lẹ́rù, kì í sábà ní àbájáde pípẹ́títí kan lórí ẹni.

Láìsí àní-àní, dídènà àrùn lohun tó dára jù lọ láti ṣe, ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tó sì gbéṣẹ́ jù lọ láti gbà dáàbò bo ọmọ rẹ lọ́wọ́ àìsàn ni fífi ìmọ́tótó kọ́ ọ. Ó yẹ ká kọ́ àwọn ọmọ láti máa fọ ọwọ́ wọn déédéé—pàápàá ṣáájú kí wọ́n tó jẹun, lẹ́yìn tí wọ́n bá lo ilé ìgbọ̀nsẹ̀ tán, lẹ́yìn tí wọ́n bá ti lọ síbi tí àwọn èèyàn máa ń pọ̀ sí tàbí lẹ́yìn tí wọ́n bá gbé ẹran ọ̀sìn mọ́ra. Àmọ́ o, lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ìsapá, bí ọmọ rẹ bá ṣì ń ní ibà fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́, má ṣe jáyà jù. Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe jíròrò rẹ̀, ọ̀pọ̀ nǹkan lo lè ṣe láti ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ kí ara rẹ̀ lè kọ́fẹ padà.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Mímọ bí ìgbóná tàbí ìtutù ara á ṣe máa yí padà tó sinmi lórí ibi tí a bá fi ohun tí wọ́n fi ń díwọ̀n ìgbóná tàbí ìtutù ara sí nínú ara tàbí irú ohun èlò ìṣèdíwọ̀n tí a bá lò.

b Wo ìtẹ̀jáde Jí! ti April 8, 1995, ojú ìwé 11, láti mọ̀ nípa ìlànà ìdápadà omi ara, èyí tó o lè ṣàmúlò bí àìsàn ibà bá ń ṣe ẹnì kan, tí ìgbẹ́ gbuuru sì tún ń yọ ọ́ lẹ́nu tàbí tó tún ń bì lọ́wọ́ kan náà.

c Àìsàn Reye jẹ́ àìsàn tó lè ṣàkóbá tí kì í ṣe kékeré fún ọpọlọ, èyí tó lè ṣe àwọn ọmọdé lẹ́yìn tí kòkòrò fáírọ́ọ̀sì bá ti wọ ara wọn.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 27]

Lọ Rí Dókítà Bí Ibà Bá Ń Ṣe Ọmọ Rẹ, Tí Àwọn Ohun Tó Wà Nísàlẹ̀ Wọ̀nyí sì Ń Ṣẹlẹ̀ Sí I . . .

◼ Ó jẹ́ ọmọ oṣù mẹ́ta tàbí kò tó bẹ́ẹ̀, ìdíwọ̀n ìgbóná ẹnu ihò ìdí rẹ̀ sì fi ìwọ̀n kan (380C) tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ kọjá ìwọ̀n tó wà déédéé

◼ Ó jẹ́ ọmọ oṣù mẹ́ta sí oṣù mẹ́fà, ìdíwọ̀n ìgbóná ara rẹ̀ sì fi ìwọ̀n kan àti ẹ̀sún mẹ́ta (38.30C) tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ kọjá ìwọ̀n tó wà déédéé

◼ Ó ti lé lọ́mọ oṣù mẹ́fà, ìdíwọ̀n ìgbóná ara rẹ̀ sì fi ìwọ̀n mẹ́ta (400C) tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ kọjá ìwọ̀n tó wà déédéé

◼ Kò fẹ́ gba àwọn nǹkan olómi, ó sì jọ pé ó ní ìṣòro ìpàdánù omi ara

◼ Gìrì ń mú un tàbí ara rẹ̀ ń rọ jọwọrọ

◼ Ó hàn lára rẹ̀ pé ó ṣì ní ibà lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta

◼ Ó ń ké ṣáá tàbí ó jọ pé ó ní ìṣòro iyè ríra

◼ Àwọn ohun kan sú sí i lára, kò lè mí dáadáa, ìgbẹ́ gbuuru ń yọ ọ́ lẹ́nu tàbí pé ó ń bì léraléra

◼ Kò lè yí ọrùn dáadáa tàbí ó ń ní akọ ẹ̀fọ́rí láìròtẹ́lẹ̀

[Credit Line]

Ibi tí ìsọfúnni yìí ti wá: Àjọ Àwọn Oníṣègùn Tó Ń Tọ́jú Àìsàn Àwọn Ọmọdé Nílẹ̀ Amẹ́ríkà