Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

(A lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí. Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdáhùn wọn sì wà ní ojú ìwé 27. Fún àfikún ìsọfúnni, wo ìwé “Insight on the Scriptures,” tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.)

1. Kí ni Jèhófà pàṣẹ pé kò ní kásẹ̀ nílẹ̀ láé? (Jẹ́nẹ́sísì 8:22)

2. Ewé wo ni Jésù sọ pé àwọn Farisí máa ń fi tìṣọ́ratìṣọ́ra san ìdámẹ́wàá rẹ̀, àmọ́ tí wọn ò ní ka “ìdájọ́ òdodo àti ìfẹ́ fún Ọlọ́run” sí? (Lúùkù 11:42)

3. Ọ̀nà wo ni Jésù sọ pé òun yóò gbà padà wá? (Ìṣípayá 16:15)

4. Àwọn ará Filísínì mélòó ni Sámúsìnì fi “egungun páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ tútù kan ti akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́” ṣá balẹ̀? (Onídàájọ́ 15:15)

5. Kí la pe Jésù fún jíjẹ́ tó jẹ́ ẹnì kan ṣoṣo tí Jèhófà dá ní tààràtà? (Jòhánù 3:18)

6. Àwọn ìtọ́ni wo ni Pọ́ọ̀lù fún àwọn ará Tẹsalóníkà nípa àwọn tó jẹ́ ọ̀lẹ? (2 Tẹsalóníkà 3:10, 12)

7. Kí ni Jésù sọ pé gbogbo wa gbọ́dọ̀ ṣe “láti gba ẹnu ọ̀nà tóóró wọlé”? (Lúùkù 13:24)

8. Ìlú wo ló sábà máa ń wá sọ́kàn nígbà tá a bá dárúkọ ìkángun àríwá Ísírẹ́lì? (1 Sámúẹ́lì 3:20)

9. Ọ̀nà wo ni Ọlọ́run gbà kìlọ̀ fún àwọn awòràwọ̀ tó ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ Jésù pé wọn ò gbọ́dọ̀ padà sọ́dọ̀ Ọba Hẹ́rọ́dù apààyàn? (Mátíù 2:12)

10. Kí nìdí tá a fi retí pé kí alábòójútó kan nínú ìjọ “ní gbólóhùn ẹ̀rí tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn lóde”? (1 Tímótì 3:7)

11. Ibo ni Fílípì ti rí ìwẹ̀fà ará Etiópíà náà tó sì kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́? (Ìṣe 8:26)

12. Kí ni ìyà ẹ̀ṣẹ̀ Sọ́ọ̀lù fún ṣíṣàìgbọràn sí àṣẹ Jèhófà pé kó pa gbogbo àwọn ará Ámálékì run pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn agbo ẹran àtàwọn ọ̀wọ́ ẹran wọn? (1 Sámúẹ́lì 15:23, 26)

13. Kí nìdí tí Ábúráhámù fi gbé èyí tó pọ̀ jù nínú ìgbésí ayé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àtìpó ní ilẹ̀ mìíràn? (Hébérù 11:10; 12:22)

14. Àwọn ìwà ọ̀daràn wo ni Bárábà tí Pílátù dá sílẹ̀ dípò Jésù jẹ̀bi rẹ̀? (Lúùkù 23:25; Jòhánù 18:40)

15. Kí lorúkọ ọkùnrin ará Lídà tó ní àrùn ẹ̀gbà tó sì ti “dùbúlẹ̀ gbalaja lórí àkéte rẹ̀ fún ọdún mẹ́jọ” tí Pétérù wò sàn? (Ìṣe 9:32-34)

Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè

1. “Fífún irúgbìn àti ìkórè, àti òtútù àti ooru, àti ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ìgbà òtútù, àti ọ̀sán àti òru”

2. Efinrin àti ewéko rúè

3. “Bí olè”

4. Ẹgbẹ̀rún kan

5. “Ọmọ bíbí kan ṣoṣo ti Ọlọ́run”

6. “Bí ẹnikẹ́ni kò bá fẹ́ ṣiṣẹ́, kí ó má ṣe jẹun.” “Nípa ṣíṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìṣejẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, kí wọ́n máa jẹ oúnjẹ tí àwọn fúnra wọn ṣiṣẹ́ fún”

7. “Ẹ tiraka tokuntokun”

8. Dánì

9. Nípasẹ̀ àlá

10. Kí ó “má bàa ṣubú sínú ẹ̀gàn àti ìdẹkùn Èṣù”

11. Lójú ọ̀nà aṣálẹ̀ tó lọ láti Jerúsálẹ́mù sí Gásà

12. Jèhófà kọ̀ ọ́ “láti máa bá a lọ gẹ́gẹ́ bí ọba lórí Ísírẹ́lì”

13. Nítorí ó ń dúró de “ìlú ńlá tí ó ní àwọn ìpìlẹ̀ tòótọ́,” Jerúsálẹ́mù ti ọ̀run

14. Ìdìtẹ̀ sí ìjọba, ìpànìyàn àti olè jíjà

15. Énéà