Sísanra Jọ̀kọ̀tọ̀ Ǹjẹ́ Kò Ti Ń di Àjàkálẹ̀ Àrùn Tó Kárí Ayé Báyìí?
Sísanra Jọ̀kọ̀tọ̀ Ǹjẹ́ Kò Ti Ń di Àjàkálẹ̀ Àrùn Tó Kárí Ayé Báyìí?
ÌWÉ ìròyìn ìṣègùn ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà, The Lancet sọ pé: “Ó pẹ́ tí a ti ń gbọ́ pé ìgbésí ayé ìdẹ̀rùn tí àwọn èèyàn ń gbé lóde òní láwọn orílẹ̀-èdè ọlọ́rọ̀ tó ti gòkè àgbà ló ń fa sísanra jọ̀kọ̀tọ̀, àmọ́ ní báyìí, ó ti ń dé àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà náà.” Ìròyìn náà sọ pé àwọn onímọ̀ nípa bí oúnjẹ ṣe ń ṣara lóore ti ń ṣe kìlọ̀kìlọ̀ báyìí pé “àjàkálẹ̀ àrùn kárí ayé” kan ń bọ̀ o, ìyẹn ni àwọn àìsàn tí sísanra jọ̀kọ̀tọ̀ ń fà, irú bí àtọ̀gbẹ, ẹ̀jẹ̀ ríru, àrùn jẹjẹrẹ àti àrùn ọkàn.
Látàrí bí iye àwọn ọkùnrin tó sanra jọ̀kọ̀tọ̀ nílẹ̀ Ṣáínà ṣe di ìlọ́po mẹ́ta tí iye àwọn obìnrin tó sanra jọ̀kọ̀tọ̀ sì di ìlọ́po méjì láàárín ọdún mẹ́jọ tó kọjá, iye àwọn tó ní ìṣòro ẹ̀jẹ̀ ríru níbẹ̀ ti pọ̀ tó ti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Nínú gbogbo àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ní àrùn àtọ̀gbẹ lágbàáyé, ó lé ní ìdajì tó jẹ́ pé ilẹ̀ Íńdíà àti ilẹ̀ Ṣáínà ni wọ́n wà. Iye àwọn alárùn àtọ̀gbẹ nílẹ̀ Íjíbítì ti pọ̀ tó iye àwọn alárùn àtọ̀gbẹ tó wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ohun tó sì lé ní ìdajì àwọn obìnrin ilẹ̀ Íjíbítì ló sanra ju bó ṣe yẹ lọ báyìí. Nílẹ̀ Mẹ́síkò, ọ̀pọ̀ èèyàn ló túbọ̀ ń sanra jọ̀kọ̀tọ̀ jákèjádò orílẹ̀-èdè náà, yálà wọ́n jẹ́ olówó tàbí wọ́n jẹ́ tálákà, èyí sì ti mú kí àrùn àtọ̀gbẹ pọ̀ sí i. Àní, láwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní àgbègbè aṣálẹ̀ Sàhárà ní Áfíríkà, tí wọ́n tòṣì gidigidi pàápàá, ńṣe ni sísanra jọ̀kọ̀tọ̀ àti àrùn àtọ̀gbẹ ń pọ̀ sí i.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé jíjẹ àwọn oúnjẹ àyáragbọ́ tó jẹ́ ọlọ́ràá ló mú káwọn èèyàn máa sanra jọ̀kọ̀tọ̀ láwọn orílẹ̀-èdè kan, lájorí ohun tó ń fà á ni pé ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ṣe oúnjẹ jáde túbọ̀ ń fi ṣúgà púpọ̀ sínú oúnjẹ báyìí “kí wọ́n lè ládùn sí i.” Láfikún sí i, òróró ti ń pọ̀ gan-an báyìí nínú oúnjẹ àwọn èèyàn ilẹ̀ Éṣíà àti Áfíríkà, tí èyí sì ń mú kí wọ́n túbọ̀ máa tóbi sí i. Ìtẹ̀síwájú nínú ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ní àwọn iléeṣẹ́ àti nínú iṣẹ́ àgbẹ̀ túmọ̀ sí pé kò pọn dandan mọ́ láti máa lo àwọn èèyàn púpọ̀ fún iṣẹ́ kí wọ́n tó lè mú nǹkan jáde. Àwọn èèyàn ò fẹ́ fi gbogbo ara ṣiṣẹ́ mọ́, wọ́n sì ń fẹ́ àkókò ìgbafàájì púpọ̀ sí i. Ní báyìí tí kọ̀ǹpútà àti tẹlifíṣọ̀n ti gbajúmọ̀ gan-an, àwọn òṣìṣẹ́ kì í fi bẹ́ẹ̀ ṣe eré ìmárale mọ́, “fífi ìsọfúnni ránṣẹ́ lórí kọ̀ǹpútà sì ti fòpin sí lílọ jíṣẹ́ fúnni àti dídìde lórí ìjókòó ẹni láti lọ bá àwọn alábàáṣiṣẹ́ ẹni sọ̀rọ̀.”
Níwọ̀n bí sísanra jọ̀kọ̀tọ̀ ti ń yára gbilẹ̀ sí i láàárín àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ pẹ̀lú, pàápàá láwọn ibi tí kò ti fi bẹ́ẹ̀ sí eré ìtura àti eré ìmárale, ó ṣe pàtàkì gidigidi pé kí àwọn olùkọ́ mọ ipa tí oúnjẹ ń kó lórí ìjáfáfá ọmọ ní ilé ẹ̀kọ́. Gail Harrison, tó ń ṣiṣẹ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Nípa Ìlera Aráàlú, tó wà ní Yunifásítì California, ké gbàjarè pé láfikún sí wíwá nǹkan ṣe lágbègbè kọ̀ọ̀kan láti dènà ìṣòro yìí, “ó pọn dandan láti ní ètò àpawọ́pọ̀ṣe kan tó máa wà fún dídènà ìṣòro yìí kárí ayé, pa pọ̀ pẹ̀lú ṣíṣe àgbékalẹ̀ àwọn ìlànà, àkànṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn àjọ aṣèrànwọ́” láti kojú àjàkálẹ̀ àrùn sísanra jọ̀kọ̀tọ̀ àtàwọn ìṣòro mìíràn tó rọ̀ mọ́ ọn.