Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wíwo Ayé

Wíwo Ayé

Wíwo Ayé

Gbígbọ́ Èdè Ajá Kẹ̀?

Ẹ̀ka Tó Ń Pèsè Ìsọfúnni Nílẹ̀ Japan sọ pé, iléeṣẹ́ kan tó ń ṣe ohun ìṣeré àwọn ọmọdé nílẹ̀ Japan ti ṣe ẹ̀rọ kékeré kan tí wọ́n sọ pé ó lè ṣètumọ̀ gbígbó ajá sí èdè tí ẹ̀dá ènìyàn gbọ́. Ẹ̀rọ náà ní makirofóònù kan tí kò ní wáyà lára tí wọ́n á fi sára bẹ́líìtì ọrùn ajá, èyí tí yóò máa fi ìró ohùn ajá náà ránṣẹ́ sínú ẹ̀rọ agbohùnsílẹ̀ kan. Wọ́n ní ẹ̀rọ agbohùnsílẹ̀ náà máa ń túmọ̀ ìró ohùn ajá, ó sì máa ń pín in sí oríṣi ọ̀nà mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ìyẹn ni ìró ìjákulẹ̀, ìbínú, ìdùnnú, ìbànújẹ́, ohun tó nífẹ̀ẹ́ sí àti ìkanra. Ìtumọ̀ yìí sì máa ń fara hàn lójú ẹ̀rọ agbohùnsílẹ̀ náà, lára àwọn gbólóhùn tó sì máa ń fara hàn làwọn ọ̀rọ̀ bíi “Mò ń gbádùn ara mi gan-an!” “Kò bá mi lára mu rárá!” àti “Ó yá, jẹ́ ká ṣeré jọ̀ọ́!” Àwọn oníléeṣẹ́ náà sọ pé nílẹ̀ Japan, àwọ́n ti ta iye tó tó ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [300,000] lára ẹ̀rọ náà, èyí tí wọ́n ń tà ní ọgọ́rùn-ún dọ́là, àwọ́n sì retí pé àwọ́n á ta iye tó tó mílíọ̀nù kan bí àwọ́n bá gbé e lọ sí orílẹ̀-èdè South Korea àti ilẹ̀ Amẹ́ríkà.

Àwọn Èèyàn Ò Fọkàn Tán Ṣọ́ọ̀ṣì Mọ́

Ìwé ìròyìn Leipziger Volkszeitung sọ pé: “Àwọn èèyàn ilẹ̀ Jámánì fọkàn tán iléeṣẹ́ ọlọ́pàá àti iléeṣẹ́ ológun gan-an, àmọ́ wọn ò fọkàn tán ṣọ́ọ̀ṣì.” Nínú “ìwádìí nípa ìfọkàntánni,” èyí tí Àpérò Lórí Ètò Ọrọ̀ Ajé Àgbáyé ṣètò rẹ̀, wọ́n ṣàkíyèsí pé nínú àwọn ètò pàtàkì mẹ́tàdínlógún tí a dá sílẹ̀ fún àǹfààní àwọn aráàlú, ṣọ́ọ̀ṣì làwọn èèyàn mú gbẹ̀yìn gẹ́gẹ́ bí ohun tí àwọ́n lè fọkàn tán. Armin Nassehi, onímọ̀ nípa ìbágbépọ̀ ẹ̀dá, sọ pé lóde òní tí àìsí ìfọ̀kànbalẹ̀ túbọ̀ ń pọ̀ sí i láàárín àwọn èèyàn, àwọn àjọ tó lè “fìyàtọ̀ sáàárín rere àti búburú,” irú bí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá àti iléeṣẹ́ ológun làwọn ará ilẹ̀ Jámánì fọkàn tán jù. Kí nìdí táwọn aráàlú ò ṣe fọkàn tán ṣọ́ọ̀ṣì? Nassehi sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtara tí àwọn èèyàn ní fún ìsìn ti pọ̀ sí i ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, wọn ò gbà pé ṣọ́ọ̀ṣì lè yanjú àwọn ìṣòro pàtàkì tó ń bá wọn fínra.” Ó sọ pé, àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ilẹ̀ Jámánì “kò ní nǹkan mìíràn láti pèsè ju ààtò ìsìn lásán lọ.”

Ìkọ̀sílẹ̀ Ọ̀sán Gangan

Ìwé ìròyìn Berliner Morgenpost sọ pé nílẹ̀ Jámánì, “ńṣe làwọn tọkọtaya tó ti ń bára wọn bọ̀ tipẹ́ àmọ́ tí wọ́n ń tú ká túbọ̀ ń pọ̀ sí i ṣáá.” Gina Kästele, agbọ̀ràndùn kan lórí ọ̀ràn ìgbéyàwó ní ìlú Munich, lórílẹ̀-èdè Jámánì, sọ pé bí ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin ò ṣe gbára lé àwọn ọkùnrin mọ́, pàápàá lórí ọ̀ràn ìnáwó, jẹ́ ohun pàtàkì kan tó ń dá ìṣòro yìí sílẹ̀. Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Kì í tún ṣe àwọn ọkùnrin ló ń gbọ́ bùkátà ìdílé mọ́ bíi ti ìgbà àtijọ́.” Ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn rò pé ó ń fà á tó fi ń pẹ́ kí àwọn tọkọtaya tó já ara wọn jù sílẹ̀ ni pé wọ́n ń dúró kí àwọn ọmọ wọn kúrò nílé. Kästele sọ pé, àmọ́ o, lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tó sábà máa ń fa ìkọ̀sílẹ̀ ọ̀sán gangan yìí ni kí àwọn ọkùnrin máa lójú lóde.

Ẹ̀rín Músẹ́ Ṣàǹfààní

“Àwọn èèyàn tó tó ìdá mẹ́rìnléláàádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ló sọ pé àwọn kì í fẹ́ láti bá àwọn èèyàn tó máa ń sorí kọ́ nígbà gbogbo ṣòwò pọ̀, àwọn tó tó ìdá mọ́kàndínláàádọ́rùn-ún sì sọ pé àwọn ò lè bá wọn ṣọ̀rẹ́.” Èyí ni ohun tí ìwé ìròyìn Wprost sọ nípa ìwádìí kan tí Ẹ̀ka Ìmọ̀ Nípa Ìbágbépọ̀ Ẹ̀dá ní Yunifásítì Jagiellonian tó wà ní ìlú Kraków, lórílẹ̀-èdè Poland, ṣe. Ohun kan tí wọ́n sọ pé ó fà á ni pé àwọn èèyàn sábà máa ń wò ó pé àwọn tó máa ń sorí kọ́ nígbà gbogbo ní nǹkan nínú sáwọn ẹlòmíràn tí wọn kò fẹ́ kí wọ́n mọ̀. Àwọn tí iléeṣẹ́ ìròyìn sábà máa ń gbé sójú táyé ti mọ èyí tipẹ́, ìdí nìyẹn tí “àwọn olóṣèlú, àwọn oníṣòwò ńláńlá, àwọn gbajúgbajà olórin, àwọn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ orí tẹlifíṣọ̀n, àwọn aṣojú iléeṣẹ́ àtàwọn ọlọ́jà fi máa ń rẹ́rìn-ín” gan-an, bí ìwé ìròyìn Wprost ṣe sọ ọ́. Àwọn olùṣèwádìí tún ṣàkíyèsí pé nígbà tá a bá rẹ́rìn-ín músẹ́, ẹ̀jẹ̀ máa ń túbọ̀ ṣàn lọ sí ọpọlọ wa, èyí á sì jẹ́ kí ara wa yá gágá sí i. Obìnrin oníṣòwò kan sọ pé: “Mo máa ń gbìyànjú láti rẹ́rìn-ín músẹ́ kódà nígbà tí ẹ̀rín ò bá pa mí. Nígbà tí mo bá rẹ́rìn-ín, mo máa ń rí ìyàtọ̀ lára mi, ó sì máa ń mú kí ara mi túbọ̀ yá gágá sí i.”

Iná Ibi Ìpàgọ́ Gba Ìṣọ́ra O

Ìwé àtìgbàdégbà náà, Medical Journal of Australia (MJA) sọ pé, ohun tó lé ní àádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún ìṣẹ̀lẹ̀ iná tó máa ń jó àwọn ọmọdé níbi tí àwọn èèyàn ti ń lọ pàgọ́ lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà ló jẹ́ pé “ẹ̀ṣẹ́ná ló ń fà á dípò tí ì bá fi jẹ́ ọwọ́ iná gan-an fúnra rẹ̀.” Síwájú sí i, ní orílẹ̀-èdè Ọsirélíà, èyí tó pọ̀ jù nínú ìpalára tí iná ibi ìpàgọ́ ń fà ló ń wáyé “ní òwúrọ̀ tó tẹ̀ lé ọjọ́ tí àwọn tó ń gbafẹ́ bá ti rò pé iná ọ̀hún ti kú tán.” Báwo lèyí ṣe rí bẹ́ẹ̀? Àwọn olùṣèwádìí ṣàkíyèsí pé tí wọ́n bá fi omi pa iná ibi ìpàgọ́, ẹ̀ṣẹ́ná á ti fẹ́rẹ̀ẹ́ jó di eérú lẹ́yìn wákàtí mẹ́jọ. Àmọ́, ní ìfiwéra, àwọn iná ibi ìpàgọ́ tí wọ́n fi iyẹ̀pẹ̀ pa ṣì máa ń kẹ̀ gan-an lẹ́yìn wákàtí mẹ́jọ—èyí sì lè jó ara ní àjóbàjẹ́ gbàrà tó bá ti kanni lára. Ìwé àtìgbàdégbà MJA tún sọ pé: “Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ńṣe ni fífi iyẹ̀pẹ̀ paná máa ń jẹ́ kó jọ bí ẹni pé iná náà ti kú, nígbà tó jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ́ná àti eérú rẹ̀ ṣì gbóná gan-an, ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbà pa iná ibi ìpàgọ́ fin-ín fin-ín ni lílo omi.”

Kókó Oníjẹjẹrẹ

Ọ̀pọ̀ àwọn kókó tó ń lé sára ni kò léwu rárá. Síbẹ̀, ó dára láti máa kíyè sí àwọn kókó oníjẹjẹrẹ. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwé ìròyìn Milenio ti ìlú Mexico City sọ, àwọn ohun tó wà nísàlẹ̀ wọ̀nyí ni àmì tó ń fi hàn pé ó yẹ kó o lọ ṣàyẹ̀wò rẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn oníṣègùn: Kókó náà kò rí rogodo délẹ̀, eteetí rẹ̀ ò sì bára dọ́gba. Àwọ̀ àti ìtóbi rẹ̀ máa ń yí padà, fífẹ̀ rẹ̀ tóbi ju kóró ọsàn lọ, tàbí kí kókó náà máa ṣẹ̀jẹ̀ tàbí kó máa yúnni. Dókítà Nancy Pulido Díaz, tó ń ṣiṣẹ́ ní Ibùdó Ìṣègùn Ìjọba ti La Raza, sọ pé: “Àwọn kókó tó yẹ kéèyàn kíyè sí gan-an ni àwọn tí wọ́n bí mọ́ni àtàwọn tó wà ní àtẹ́lẹwọ́ tàbí àtẹ́lẹsẹ̀ ẹni.”

Kíkọ́ Èdè Àjèjì

Ṣé wàá fẹ́ láti kọ́ èdè àjèjì? Ìwé ìròyìn ilẹ̀ Poland náà, Poradnik Domowy fúnni láwọn àmọ̀ràn tó wà nísàlẹ̀ yìí. “Ohun kan tí kò lè ṣe kó máà wáyé bí èèyàn bá ń kọ́ èdè ni ṣíṣe àṣìṣe. Mímọ̀ bẹ́ẹ̀ ni ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ bí a óò bá ṣàṣeyọrí.” Ohun pàtàkì mìíràn ni “mímúra tán láti gbìyànjú rẹ̀ wò.” Bí a ò bá mọ bí a ṣe lè sọ ohun kan, “nígbà míì a ní láti sọ ohun tó bá ti wá sí wa lọ́kàn, tàbí ká kàn wulẹ̀ méfò ṣáá,” èyí tó dára ju kéèyàn máa lọ́ra láti sọ̀rọ̀ lọ. Ìwé ìròyìn náà sọ pé: “A kì í sábà mọ̀ rárá pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìbẹ̀rù tàbí ìtìjú gan-an ni olórí ìṣòro wa. Bí a bá gbìyànjú láti borí àwọn ìṣòro wọ̀nyí, kò sí àní-àní pé ìtẹ̀síwájú wa á yá kánkán.” Olùkọ́ tó dáńgájíá tún lè ranni lọ́wọ́ láti borí ìbẹ̀rù àti láti tètè mọ̀ ọ́n sọ.

“Ìwà Ipá Gbẹ̀mí Àwọn Èèyàn Tó Lé Ní Mílíọ̀nù Kan Ààbọ̀”

Ìwé ìròyìn The Wall Street Journal sọ pé: “Àbọ̀ ìwádìí tí Àjọ Ìlera Àgbáyé gbé jáde, nínú èyí tí wọ́n ti gbìdánwò fún ìgbà àkọ́kọ́ láti mọ bí onírúurú ìwà òǹrorò ṣe ń gbẹ̀mí àwọn èèyàn tó, fi hàn pé ìwà ipá gbẹ̀mí àwọn èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù kan ààbọ̀ lọ́dún 2000. Iye yìí dọ́gba pẹ̀lú àwọn tí ikọ́ ẹ̀gbẹ pa, ó sì tún ju iye àwọn tí àrùn ibà pa lọ.” Ohun tí wọ́n gbé ìṣirò yìí kà ni ìsọfúnni tí wọ́n kó jọ láti àádọ́rin orílẹ̀-èdè, lára èyí tí ogun, ìwà jàgídíjàgan, ìpara-ẹni àti ìbọn yíyìn wà. Àpilẹ̀kọ náà fi kún un pé: “Àwọn olùṣèwádìí ṣàkíyèsí pé ikú tí ìwà ipá ń fà jẹ́ nǹkan bí ìdá mẹ́ta nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo ikú tó ń pa àwọn èèyàn lágbàáyé. Bí ìwà ipá sí àwọn obìnrin, àwọn ọmọdé, àwọn àgbàlagbà, àwọn ọ̀dọ́kùnrin àti sí gbogbo aráàlú lápapọ̀ ṣe pọ̀ tó ju ohun tí wọ́n retí lọ fíìfíì. Àwọn olùṣèwádìí náà sọ pé, ohun kan tó fa ìyẹn ni pé àwọn èèyàn kì í sábà fi ìwà ipá tó àwọn agbófinró létí.” Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa bí ìwà ipá ṣe ń gbẹ̀mí àwọn èèyàn rèé: Ìpara-ẹni—ìdá àádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún, ìpànìyàn—ìdá ọgbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún, àti ogun—ìdá ogún nínú ọgọ́rùn-ún. Ìlà Oòrùn Yúróòpù ni ìpara-ẹni ti wọ́pọ̀ jù lọ, orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà àti Lithuania ló sì ti máa ń ṣẹlẹ̀ jù. Bákan náà, orílẹ̀-èdè Albania làwọn èèyàn ti ń kú ikú ìbọn jù lọ, nítorí pé bí a bá kó ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000] èèyàn jọ, èèyàn méjìlélógún ni èyí ń ṣẹlẹ̀ sí. Ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, bí a bá kó ọ̀kẹ́ márùn-ún èèyàn jọ, àwọn èèyàn tó lé ní mọ́kànlá ló ń kú ikú ìbọn, nígbà tó jẹ́ pé ní ìfiwéra, nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti orílẹ̀-èdè Japan, kò tó èèyàn kan tó ń kú ikú ìbọn.

Fífi Ariwo Rédíò Ọkọ̀ Díje

Báwo ni ariwo rédíò ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ẹnì kan ṣe ròkè tó ju ti ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ẹlòmíràn lọ? Wíwá ìdáhùn sí ìbéèrè yìí ló fa ìdíje tuntun kan tó kárí ayé báyìí, èyí tí wọ́n ń pè ní fífi ariwo ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ díje, tó ń wáyé ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, gẹ́gẹ́ bí ìwé National Public Radio ṣe sọ. Ní àwọn ibi tí wọ́n ti ṣètò láti pé jọ sí, wọ́n máa ń fi àwọn ohun èlò tí wọ́n ti fi sínú àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà díwọ̀n bí ariwo rédíò ọkọ̀ kọ̀ọ̀kan ṣe ròkè sí—nípa lílo ìdíwọ̀n decibel, tàbí dB ní ìkékúrú. Wọn kì í díwọ̀n ìró ohùn tí wọ́n bá gbọ́ lẹ́yìn òde ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, nípa bẹ́ẹ̀ àwọn tó ń kópa nínú ìdíje náà máa ń fi nǹkan dí gbogbo ibi tí ariwo lè gbà jáde nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wọn. Olùdíje kan tó ń jẹ́ Wayne Harris sọ pé: “Nínú àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tí wọ́n ti ṣiṣẹ́ sí lára gan-an débi pé ariwo ò lè jáde látinú wọn, . . . àwọn fèrèsé máa ń nípọn pìpìrì, wọ́n sì máa ń lo kọnkéré àti irin láti fi mú kí àwọn ilẹ̀kùn túbọ̀ nípọn sí i.” Àwọn tó ń fi ariwo ọkọ̀ díje náà kì í jókòó sínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wọn nígbà tí wọ́n bá yí rédíò wọn sókè pátápátá—èyí sì jẹ́ fún àǹfààní ara wọn.