Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wọ́n Rí I Pé Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Wọn

Wọ́n Rí I Pé Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Wọn

Wọ́n Rí I Pé Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Wọn

Ó máa ń ṣòro fún àwọn kan láti gbà gbọ́ pé ẹnikẹ́ni—kódà Ọlọ́run pàápàá—lè nífẹ̀ẹ́ àwọn gan-an. Nítorí náà, lẹ́yìn kíka ìwé náà, Sún Mọ́ Jèhófà, ọ̀pọ̀ ló kọ lẹ́tà láti fi ẹ̀mí ìmoore wọn hàn fún ìdánilójú tí ìwé náà fún wọn pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wọn. Obìnrin kan láti ìlú Decatur, ní ìpínlẹ̀ Illinois, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà kọ̀wé pé: “Ó jọ mí lójú gan-an láti mọ bó ṣe nífẹ̀ẹ́ mi tó, kódà pẹ̀lú gbogbo àwọn ìkùdíẹ̀-káàtó mi.”

Lẹ́tà rẹ̀ ń bá a lọ pé: “Ńṣe ni omijé ayọ̀ ń bọ́ lójú mi nígbà tí mo ka gbólóhùn [ojú ìwé 117] tó sọ pé: ‘Òótọ́ ni pé Jèhófà jẹ́ Baba olódodo tí kì í ṣègbè, tí kì í yẹ̀ rárá lórí ohun tó tọ́, síbẹ̀ ó máa ń fi ìyọ́nú hàn sí àwọn ọmọ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé tó bá ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ àti ìdáríjì rẹ̀.’”

Ọkùnrin kan láti ìlú Ripon, ní ìpínlẹ̀ California, kọ̀wé pé: “Mo dúpẹ́ gan-an lọ́wọ́ yín tẹ́ ẹ jẹ́ kí n rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ mi. Ó bìkítà lóòótọ́. N kì í kàn ṣe èèyàn kan lásán ṣáá.” Obìnrin kan láti ìpínlẹ̀ New Hampshire sọ pé: “Nígbà míì, ńṣe ló máa ń dà bíi pé kí n máà gbé ìwé náà sílẹ̀, kí n kàn máa kà á lọ ṣáá.” Ó ṣàlàyé pé: “Ó ṣòro gan-an fún mi tẹ́lẹ̀ láti gbà lóòótọ́ pé Jèhófà lè nífẹ̀ẹ́ mi.” Nípa bẹ́ẹ̀, ìwé yẹn gan-an lohun tó nílò.

A gbà pé kíka ìwé yìí á ṣe ìwọ náà láǹfààní. Lẹ́yìn àwọn orí mẹ́ta tó ṣáájú, a pín ìwé náà sí ìsọ̀rí mẹ́rin, tí wọ́n ní àwọn àkòrí náà, “Ó ‘Ní Agbára Ńlá’,” “Olùfẹ́ Ìdájọ́ Òdodo,” “Ọlọ́gbọ́n ní Ọkàn-Àyà” àti “Ọlọ́run Jẹ́ Ìfẹ́.” Ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan dá lórí ànímọ́ pàtàkì kan tí Ọlọ́run ní. Orí náà, “Ẹ Sún Mọ́ Ọlọ́run, Yóò sì Sún Mọ́ Yín” ló kádìí ìwé tí ń tani jí yìí.

Bó o bá fẹ́ láti gba ẹ̀dà kan ìwé olójú ewé 320 tó ní èèpo ẹ̀yìn fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ yìí, jọ̀wọ́ kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí kí o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sójú ìwé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.

□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.