Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Àlùmọ́ọ́nì Ilẹ̀ Ti Fẹ́rẹ̀ẹ́ Run Tán

Àwọn Àlùmọ́ọ́nì Ilẹ̀ Ti Fẹ́rẹ̀ẹ́ Run Tán

Àwọn Àlùmọ́ọ́nì Ilẹ̀ Ti Fẹ́rẹ̀ẹ́ Run Tán

“Bá a bá fa gbùrù, gbùrù a fagbó lọ̀rọ̀ àwọn ìṣẹ̀dá, ìyẹn ni ìwà bàsèjẹ́ tá a ti hù sẹ́yìn ṣe wá ń já jó wa lójú báyìí.”—Ìwé ìròyìn African Wildlife.

BÁ A bá fẹ́ mọ ìwọ̀n ilẹ̀ tó kù tó ṣeé dáko àtèyí tá a lè rí àlùmọ́ọ́nì wà jáde látinú ẹ̀, àfi ká gbéṣirò lé iye gẹdú táráyé ń gé nígbó àti bí wọ́n ṣe ń bààná àwọn àlùmọ́ọ́nì ilẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Àjọ Akówójọ fún Ìdáàbòbò Ohun Alààyè Inú Ìgbẹ́ Lágbàáyé ṣe sọ, látìgbà tá a ti wọ ọdún 1980 ni àpapọ̀ ilẹ̀ tó ṣeé dáko àtèyí táráyé lè rí àlùmọ́ọ́nì wá jáde nínú ẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí dín kù nítorí ìlòkulò táráyé ń lo ilẹ̀. a Àmọ́, àpẹẹrẹ kan ṣoṣo lára bí aráyé ṣe ń ṣàkóbá fún àyíká wa nìyẹn jẹ́ ṣá o.

Òmíràn ni bí àwọn ohun ọ̀gbìn, ẹranko, ẹyẹ àtàwọn ohun alààyè mìíràn, tó fi mọ́ àwọn nǹkan tí ò lẹ́mìí, ṣe máa ń ran ara wọn lọ́wọ́. Àjọ Akówójọ fún Ìdáàbòbò Ohun Alààyè Inú Ìgbẹ́ Lágbàáyé máa ń ṣe àyẹ̀wò kínníkínní nípa bí nǹkan ṣe ń lọ sí láàárín àwọn ìṣẹ̀dá wọ̀nyí. Ìyẹn ni wọ́n sì fi ń mọ bí igi ṣe pọ̀ sí nínú igbó, bí omi ṣe mọ́ tó, àti bí ara àwọn ohun alààyè tó ń gbé nínú omi ṣe dá sí. Nínú àyẹ̀wò tí wọ́n ṣe láàárín ọdún 1970 sí ọdún 2000, wọ́n rí i pé àwọn ẹyẹ, ẹranko, àtàwọn ẹ̀dá afàyàfà tí ń bẹ nínú omi ti fi nǹkan bí ìdá mẹ́tàdínlógójì nínú ọgọ́rùn-ún dín kù sí iye tí wọ́n jẹ́ tẹ́lẹ̀.

Ṣé Àlùmọ́ọ́nì Ilẹ̀ Tó Kù Á Tó Aráyé Lò?

Bó o bá ń gbé ní Ìwọ̀ Oòrùn ayé níbi tí ọjà ti máa ń kún àwọn ilé ìtajà, téèyàn sì ti lè rí ọjà rà tọ̀sán tòru, agbára káká lo fi máa ronú pé àwọn àlùmọ́ọ́nì ilẹ̀ ń dín kù. Síbẹ̀, díẹ̀ lára àwọn èèyàn tó wà láyé ló ń rí ná rí lò. Wàhálà àtijẹ àtimu lọ̀pọ̀ èèyàn ń bá káàkiri lójoojúmọ́. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ti fojú bù ú pé ó ju bílíọ̀nù méjì èèyàn lọ tí wọn kì í rí owó tó tó wọn ná lóòjọ́, àwọn bílíọ̀nù méjì èèyàn sì wà tí wọn ò rí iná mànàmáná lò.

Àwọn kan sọ pé ọ̀nà táwọn ìlú ọlọ́rọ̀ ń gbà ṣòwò ló ń sọ àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń lajú di òtòṣì. Ìwé ìròyìn Vital Signs 2003, sọ pé: “Ní onírúurú ọ̀nà, àwọn òtòṣì ni ètò ọrọ̀ ajé àgbáyé fi ń ṣèfà jẹ.” Ńṣe làwọn àlùmọ́ọ́nì ilẹ̀ túbọ̀ ń dín kù sí i, gegege ni ìwọ̀nba tó kù sì gbówó lórí. Bí ọ̀pọ̀ èèyàn sì ṣe ń du bọ́wọ́ á ṣe tẹ tiwọn lára ìwọ̀nba tó kù náà, ńṣe làwọn tí ò rí towó ṣe rọra jókòó sẹ́gbẹ́ jẹ́gẹ́dẹ́. Bí ìpín tí ì bá jẹ́ tiwọn ṣe ń bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọlọ́rọ̀ tó lè rówó rà wọ́n nìyẹn.

Àwọn Igbó Ti Fẹ́rẹ̀ẹ́ Run Tán

Ó tó ìdámẹ́jọ nínú ìdámẹ́wàá lára àwọn tó ń gbé nílẹ̀ Áfíríkà tí wọ́n ń fi igi dáná. Láfikún sí ìyẹn, ìwé ìròyìn Getaway, ti South Africa, sọ pé: “Bá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ilẹ̀ táwọn èèyàn ti ń pọ̀ sí i jù, táwọn èèyàn ti ń rọ́ wá sígboro jù lágbàáyé, Áfíríkà ni.” Nítorí èyí, wọ́n ti wó gbogbo igi tó wà lórí ilẹ̀ tó fẹ̀ tó ọgọ́rùn-ún kìlómítà níwá lẹ́yìn, lọ́tùn-ún àti lósì lágbègbè àwọn ìlú ńlá kan ní aṣálẹ̀ Sahel, ìyẹn aṣálẹ̀ salalu kan tí òjò kì í ti í sábà rọ̀, tó wà létí gúúsù Aṣálẹ̀ Sàhárà. Wọn ò kàn ṣàdédé gé àwọn igi náà lulẹ̀ o. Ọ̀jọ̀gbọ́n Samuel Nana-Sinkam sọ pé: ‘Ńṣe ni ọ̀pọ̀ yamùrá àwọn ọmọ Áfíríkà ń ba àyíká wọn jẹ́ nítorí àtijẹ àtimu.’

Bí ọ̀ràn ti rí ní Gúúsù Amẹ́ríkà tún wá yàtọ̀ o. Bí àpẹẹrẹ, lórílẹ̀-èdè Brazil, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó egbèjìdínlógójì [7,600] ilé iṣẹ́ agégẹdú tó wà ní igbó tí igi pọ̀ sí níbẹ̀. Àjọ àwọn ilé iṣẹ́ aládàá ńlá tí wọ́n ní ẹ̀ka káàkiri àgbáyé ló ni ọ̀pọ̀ nínú wọn. Ilé iṣẹ́ agégẹdú máa ń pa tó ọgbọ̀n dọ́là owó ilẹ̀ Amẹ́ríkà lórí igi gẹdú kan. Àmọ́ ṣá o, nígbà táwọn alágbàtà, àwọn oníṣòwò, àtàwọn tó ń lo igi á bá fi jèrè tiwọn lórí ẹ̀, iye tí wọ́n á ti pa lórí igi kan náà yẹn á ti kọjá ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádóje [130,000] dọ́là owó ilẹ̀ Amẹ́ríkà, kó tó wá balẹ̀ sínú ṣọ́ọ̀bù. Abájọ táwọn èèyàn fi máa ń sọ pé ìgbẹ́ lowó wà.

Àwọn èèyàn ti kọ̀wé púpọ̀ lórí rírun tí wọ́n ń run igbó lórílẹ̀-èdè Brazil. Àwọn fọ́tò tí wọ́n yà látojú sánmà lórílẹ̀-èdè Brazil fi hàn pé láàárín ọdún 1995 sí ọdún 2000, ọdọọdún làwọn èèyàn ń pa igbó run lórí ilẹ̀ tó fẹ̀ ju ọ̀kẹ́ kan kìlómítà níbùú lóòró. Ìwé ìròyìn Veja, ti ilẹ̀ Brazil, ròyìn pé: “Gígé igi lulẹ̀ bẹẹrẹbẹ, tí ń múni láyà pami yìí túmọ̀ sí pé ilẹ̀ tó fẹ̀ tó pápá ìṣeré bọ́ọ̀lù kan ló ń pòórá láàárín ìṣẹ́jú àáyá mẹ́jọ mẹ́jọ.” Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, bá a bá fi gbogbo igi tí wọ́n gé lórílẹ̀-èdè Brazil lọ́dún 2000 dá ọgọ́rùn-ún, ó ju àádọ́rin lọ nínú ẹ̀ tí wọ́n sọ pé orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà nìkan rà.

Ohun kan náà ló ń ṣẹlẹ̀ láwọn ibòmíràn tí wọ́n ti ń pa igbó run lágbàáyé. Bí àpẹẹrẹ, láti àádọ́ta ọdún sẹ́yìn, wọ́n ti run ìdajì lára aginjù àti igbó tó wà lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò. Èyí tó tún wá burú jù ni ti bí igbó ṣe ń run lórílẹ̀-èdè Philippine. Igbó tó wà lórí ilẹ̀ tó tó ọ̀kẹ́ márùn-ún hẹ́kítà ló ń pa run lọ́dọọdún. Wọ́n sì ti fojú bù ú lọ́dún 1999 pé bí ọ̀ràn bá ń bá a lọ bẹ́ẹ̀, ìdá méjì lára ìdá mẹ́ta igbó tó wà lórílẹ̀-èdè náà lá á ti run láàárín ọdún mẹ́wàá.

Ó máa ń gbà tó ọgọ́ta sí ọgọ́rùn-ún ọdún kí igi tó ṣeé la pákó tó ó gbó dáadáa àmọ́, àtigé e lulẹ̀ ò gbà ju ìṣẹ́jú díẹ̀ lọ. Ṣó wá yẹ kó yà wá lẹ́nu pé igi míì kì í tètè hù dípò èyí tá a bá gé lulẹ̀?

Ilẹ̀ Tó Ṣeé Ṣọ̀gbìn Ń Tán Lọ

Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti pa igbó tó wà lórí ilẹ̀, èèpẹ̀ tó dùn ún gbin nǹkan sí tó wà lókè á gbẹ, afẹ́fẹ́ á sì fẹ́ ẹ dà nù tàbí kí àgbàrá òjò wọ́ ọ lọ.

Látọjọ́ táláyé ti dáyé ni ọ̀gbàrá ti ń wọ́ iyẹ̀pẹ̀ lọ, ìyẹn kì í sì í ṣe ìṣòro kan dà bí alárà, àyàfi báwọn èèyàn bá dá tiwọn kún un nípa ṣíṣàìlo ilẹ̀ bó ṣe yẹ. Bí àpẹẹrẹ, ìwé ìròyìn China Today sọ pé ìjì tó máa ń fẹ́ iyẹ̀pẹ̀, àtàwọn nǹkan míì bíi pípa igbó run àti fífi ẹran jẹko ju bó ṣe yẹ lọ ti “ń yára sọ ibi tó pọ̀ sí i” di aṣálẹ̀. Láti bí ọdún mélòó kan báyìí tí ilẹ̀ ti ṣàdédé bẹ̀rẹ̀ sí gbẹ táútáú lórílẹ̀-èdè Ṣáínà, àwọn àgbègbè ìwọ oòrùn àti àríwá ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè náà ti bẹ̀rẹ̀ sí tutù rinrin bí afẹ́fẹ́ tó ń bì wá láti ẹkùn Siberia ṣe ń fẹ́ gba ibẹ̀ kọjá. Àìmọye tọ́ọ̀nù iyanrìn àti eruku lẹ́búlẹ́bú ni ìjì ti fẹ́ lọ, wọ́n sì fẹ́ dé ìyànníyàn orílẹ̀-èdè Korea àti Japan. Nǹkan bí ìdámẹ́rin lára gbogbo ilẹ̀ tó wà lórílẹ̀-èdè Ṣáínà báyìí lo ti di aṣálẹ̀.

Ohun tó fà á tí ilẹ̀ fi ń bàjẹ́ nílẹ̀ Áfíríkà náà ò ṣẹ̀yìn gbogbo ohun tá a ti ń sọ bọ̀ yìí. Ìwé ìròyìn Africa Geographic sọ pé: “Bí àwọn àgbẹ̀ ṣe ń gégi tí wọ́n sì ń roko nítorí àtigbin àwọn irúgbìn oníkóró, ńṣe ni wọ́n ń dín agbára ilẹ̀ kù.” Wọ́n ti fojú bù ú pé lẹ́yìn tí wọ́n bá ti ro abá ilẹ̀ kan láti fi ṣọ̀gbìn, lọ́dún mẹ́ta lẹ́yìn náà, ilẹ̀ yẹn á ti pàdánù ìdajì agbára tó ní láti mú kí irúgbìn dáa. Ìdí nìyẹn tí ìwé ìròyìn náà fi sọ síwájú sí i pé: “Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ hẹ́kítà ilẹ̀ ni wọ́n ti lò ṣá, wọ́n sì máa tó lo àràádọ́ta ọ̀kẹ́ mìíràn ṣá níwọ̀n bí irè oko ti ń dín kù sí i láwọn ibì kan lọ́dọọdún.”

Wọ́n sọ pé erùpẹ̀ tí àgbàrá ń wọ́ lọ lọ́dọọdún lórílẹ̀-èdè Brazil nìkan lè kún inú ọkọ̀ akóyọyọ bíi mílíọ̀nù mẹ́rìnlélọ́gọ́rin. Lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò, Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Àyíká àti Àlùmọ́ọ́nì Ilẹ̀ sọ pé ìdá mẹ́tàléláàádọ́ta lára ilẹ̀ tí wọ́n gbin àwọn irúgbìn sí, ìdá mọ́kàndínlọ́gọ́ta lára igbó àti ìdá méjìléláàádọ́rin lára aginjù ni àgbàrá ti wọ́ lọ. Ìròyìn kan látọ̀dọ̀ Ètò Ìdàgbàsókè Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sọ pé lójú gbogbo ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ yìí, “lára ìdá mẹ́ta ilẹ̀ tó ṣeé ṣọ̀gbìn, àgbàrá ti ba ìdá méjì jẹ́. Nítorí èyí, irè oko kàn ń dín kú ṣáá ni, bẹ́ẹ̀ sì ni iye ẹnu tó yẹ ka foúnjẹ bọ́ ń pọ̀ sí i.”

Ọ̀fẹ́ Lomi, Síbẹ̀ A Ò Rí I Lò

Béèyàn ò bá jẹun fún nǹkan bí oṣù kan, á kú, ṣùgbọ́n bí ò bá sómi, á kú ní nǹkan bí ọ̀sẹ̀ kan. Nítorí náà, àwọn ògbógi sọ pé tó bá fi máa tó ọdún mélòó kan sí àkókò tá a wà yìí, àìrí omi tó dáa mu máa dá ìjàngbọ̀n sílẹ̀ fáwọn èèyàn. Gẹ́gẹ́ bí ìsọfúnni tí ìwé ìròyìn Time gbé jáde lọ́dún 2002 ṣe sọ, ó lé ní èèyàn bílíọ̀nù kan kárí ayé tí wọn ò rómi tó dáa mu.

Ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń fa ọ̀dá omi. Lórílẹ̀-èdè Faransé, ọ̀kan lára wọn ni bíba àyíká jẹ́, ọkàn àwọn èèyàn ò sì balẹ̀ mọ́ nítorí pé ṣe ló ń lágbára sí i. Ìwé ìròyìn Le Figaro sọ pé: “Àwọn odò tó wà lórílẹ̀-èdè Faransé ti dọ̀tí kọjá wẹ́rẹwẹ̀rẹ.” Nínú ìwádìí táwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ṣe, wọ́n ti wá rí i pé omiró ajílẹ̀ tí wọ́n ń lò fún ohun ọ̀gbìn, èyí tó ń sun gba abẹ́ ilẹ̀ kọjá ló ń fà á. Ìwé ìròyìn náà tún sọ pé: “Omiró tó gba inú àwọn odò ilẹ̀ Faransé kọjá sínú agbami òkun Àtìláńtíìkì lọ́dún 1999 jẹ́ ọ̀kẹ́ méjìdínlógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàájọ tọ́ọ̀nù, ìyẹn sì tó ìlọ́po méjì iye omiró tó wọnú odò náà lọ́dún 1985.”

Ọ̀rọ̀ ti ilẹ̀ Japan náà fẹ́ẹ̀ rí bẹ́ẹ̀. Yutaka Une, ọ̀gá iléeṣẹ́ àṣesìnlú tó ń rí sọ́ràn ààbò iṣẹ́ àgbẹ̀ lórílẹ̀-èdè náà sọ pé kí jíjẹ mímu má bàa dáwọ́ dúró lórílẹ̀-èdè yẹn, “kò sí ohun táwọn àgbẹ̀ lè ṣe ju kí wọ́n máa lo ajílẹ̀ àtàwọn oògùn apakòkòrò tó ní kẹ́míkà nínú kí wọ́n lè róúnjẹ tó pọ̀ tó fi bọ àwọn aráàlú.” Èyí ló fà á tí omiró onímájèlé fi ń sun lọ sábẹ́ ilẹ̀ tó sì fi ń bá omi jẹ́. Ìyẹn ni ìwé ìròyìn IHT Asahi Shimbun tí wọ́n ń tẹ̀ ní ìlú Tokyo sọ pó jẹ́ “olórí ìṣòro tó wà jákèjádò ilẹ̀ Japan.”

Lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò, ìwé ìròyìn Reforma sọ pé ìdá márùndínlógójì nínú ọgọ́rùn-ún àìsàn tó ń ṣe wọ́n “ló jẹ́ nítorí bí àyíká wọn ṣe rí.” Láfikún sí i, ìwádìí kan tí akọ̀wé ìlera ṣe fi hàn pé “ẹnì kan nínú ẹni mẹ́rin tó ń gbé níbẹ̀ ò ní ṣáláńgá; inú kànga, odò, adágún, tàbí ìṣàn omi làwọn tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́jọ ti ń rómi mu; àwọn ọkọ̀ tó ń ta omi ló sì ń já omi fáwọn tó lé ní mílíọ̀nù kan.” Abájọ tó jẹ́ pé nínú ẹni mẹ́wàá lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò, omi tí ò dáa ló ń fà á tí ẹni mẹ́sàn-án fi ń yàgbẹ́ gbuuru!

Ìwé ìròyìn Veja ti orílẹ̀-èdè Brazil sọ pé: “Láwọn etíkun ìlú Rio de Janeiro èèyàn lè gbádùn oòrùn tó ń ta yẹ́ẹ́, iyanrìn funfun àti omi tó dúdú bí aró. Èèyàn sì tún lè kàgbákò aràn inú ìgbẹ́ àti epo tó máa ń tú sómi níbẹ̀.” Ìdí tọ́ràn sì fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé èyí tó ju ìdajì lọ lára ẹ̀gbin ilé ìgbọ̀nsẹ̀ nílẹ̀ Brazil ló máa ń ṣàn tààràtà lọ sínú àwọn odò, adágún àtàwọn agbami òkun, láìsí pé ẹni kẹ́ni ń tọ́jú àwọn odò náà. Ìyẹn ló fà á tí omi mímu fi wọ́n bí ojú níbẹ̀. Ẹ̀gbin tó wà nínú àwọn odò tó yí ìlú tó tóbi jù lọ lórílẹ̀-èdè Brazil, São Paulo ká, pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tó fi jẹ́ pé níbi tó jìn tó ọgọ́rùn-ún kìlómítà lomi tí wọ́n ń mu ti ń wá.

Nílẹ̀ Ọsirélíà, àpọ̀jù iyọ̀ nínú omi ló fà á tí wọn ò fi rómi mu. Láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ni wọ́n ti sọ fáwọn tó nílẹ̀ pé kí wọ́n ro ilẹ̀ wọn kí wọ́n bàa lè gbin àwọn nǹkan sórí ẹ̀. Nítorí pé ilẹ̀ tí wọ́n ro kò jẹ́ kí igi pọ̀ mọ́, kò sí ohun tó máa fa omi tó wà lábẹ́ ilẹ̀ mu, bí omi tó wà lábẹ́ ilẹ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀ sì wá sókè nìyẹn, tí iyọ̀ tó lè kún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àpò, èyí tó wà lábẹ́ ilẹ̀, sì ń sun jáde. Àjọ Kájọlà, ti Ilẹ̀ Ọsirélíà Tó Ń Ṣèwádìí Nípa Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀ àti Ilé Iṣẹ́ Tó Ń Lo Ẹ̀rọ sọ pé: “Nǹkan bíi mílíọ̀nù méjì ààbọ̀ hẹ́kítà ilẹ̀ [mílíọ̀nù mẹ́fà àti ọ̀kẹ́ mẹ́wàá éékà] ni omi náà ti sọ dí oníyọ̀ báyìí. Èyí tó pọ̀ jù lára wọn ló jẹ́ ilẹ̀ tó dáa jù lọ fún iṣẹ́ àgbẹ̀ ní Ọsirélíà.”

Àwọn kan gbà gbọ́ pé bí kì í bá ṣe towó tó ká àwọn aṣòfin ilẹ̀ Ọsirélíà lára ju ìrọ̀rùn aráàlú lọ, ìṣòro iyọ̀ tó ń ba ilẹ̀ jẹ́ náà ì bá tí wáyé. Hugo Bekle ti ilé ìwé gíga Edith Cowan University, tó wà nílùú Perth, nílẹ̀ Ọsirélíà sọ pé: “Wọ́n ti sọ fún ìjọba láti ọdún 1917 pé omi oníyọ̀ lè ba ibi tí wọ́n ń gbin àlìkámà sí jẹ́. Láàárín ọdún 1920 sí 1929, àtẹ̀jáde kan ṣàlàyé bí gígé gbogbo igi tó wà nígbó ṣe lè mú kí iyọ̀ pọ̀ sí i nínú àwọn odò tó ń ṣàn. Nígbà tó sì di àárín ọdún 1930 sí 1939, Ẹ̀ka Tó Ń Rí sí Iṣẹ́ Àgbẹ̀ fara mọ́ àlàyé tí wọ́n ṣe nípa bí gígé tí wọ́n ń gé igi yìí ṣe lè mú kí omi tó wà lábẹ́ ilẹ̀ máa sun wá sókè. Àjọ Kájọlà, ti Ilẹ̀ Ọsirélíà Tó Ń Ṣèwádìí Nípa Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀ àti Ilé Iṣẹ́ Tó Ń Lo Ẹ̀rọ wá fìn-ín ìdí kókò ọ̀ràn náà lọ́dún 1950, . . . síbẹ̀ ìjọba ò yé kọtí ikún sáwọn ìkìlọ̀ wọ̀nyí, wọ́n wulẹ̀ ṣe bí kántankàntan làwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ náà ń sọ.”

Aráyé Wà Ní Bèbè Ìparun

Ó dájú pé èrò tó dáa ló sún àwọn èèyàn dédìí ọ̀pọ̀ ohun tí wọ́n ń ṣe. Àmọ́, bó ti sábà máa ń rí, òye tá a ní nípa àyíká wa ò kún débi tá a fi lè mọ ibi táwọn nǹkan tá a bá ṣe máa já sí ní pàtó. Wàhálà tíyẹn sì ń dá sílẹ̀, ò kéré. Olùdarí Ibi Àkójọ Ohun Ìṣẹ̀ǹbáyé Ìpínlẹ̀ South Australia, Tim Flannery, sọ pé: “Àwa èèyàn ti kọwọ́ bọ iṣẹ́ Ọlọ́run lójú débi pé a ti fẹ́rẹ̀ẹ́ ba ilẹ̀ tá a fi ń ṣọ̀gbìn jẹ́ pátápátá, a sì wá ń rìn ní bèbè ìparun.”

Èwo wá ni ṣíṣe báyìí o? Ǹjẹ́ aráyé á kọ́ láti máa lo àwọn àlùmọ́ọ́nì ilẹ̀ lọ́nà tí wọn ò fi ní máa ba àyíká jẹ́, tí ohun kan ò sì ní máa pa òmíràn lára? Àní, ṣé bíbà táwọn èèyàn ń ba ilé ayé jẹ́ á dópin?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bí àpẹẹrẹ, wọ́n fojú bù ú pé lọ́dún 1999 ìdá kan nínú márùn-ún lára ilẹ̀ tó ṣeé ṣọ̀gbìn téèyàn sì lè rí àlùmọ́ọ́nì wà jáde látinú ẹ̀ laráyé ti bà jẹ́. Èyí túmọ̀ sí pé ó gba ju odidi ọdún kan àtoṣù méjì lọ kí ilẹ̀ tó jẹ bò lẹ́yìn àlùmọ́ọ́nì táráyé wá jáde látinú ẹ̀ lọ́dún yẹn nìkan ṣoṣo.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

Má Fomi Kankan Ṣòfò

Àwọn nǹkan díẹ̀ wà tó lè mú kó o dín omi tó ò ń lò kù.

● Tún ẹnu ẹ̀rọ tó bá ń jò ṣe.

● Má máa pẹ́ jù lábẹ́ ẹ̀rọ alásẹ́.

● Má ṣe ṣí omi sílẹ̀ bó o bá ń fárùngbọ̀n tàbí bó o bá ń fọyín lọ́wọ́.

● Máa tún aṣọ ìnura lò bí ìgbà méjì sí mẹ́ta kó o tó fọ̀ ọ́.

● Jẹ́ kó dìgbà tí aṣọ púpọ̀ bá wà láti fọ̀ kó o tó lo ẹ̀rọ ìfọṣọ. (Ìlànà kan náà ni kó o tẹ̀ lé bó o bá ń lo ẹ̀rọ tó ń fọ abọ́.)

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Béèyàn Ò Bá Fomi Ṣòfò, Ọ̀dá Omi Ò Ní Dá A

● Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ibi tó gbẹ táútáú bí ilẹ̀ Ọsirélíà, èyí tó ju ìdámẹ́sàn-án nínú mẹ́wàá lára omi tí wọ́n fi ń ṣọ̀gbìn “ni wọ́n máa ń bù rinlẹ̀ lọ́nà tá á mú ko lọ sídìí irúgbìn ní tààràtà,” gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn The Canberra Times ṣe sọ. Irú “ọgbọ́n ìbómirinlẹ̀ yìí náà làwọn Fáráò lò nígbà tí wọ́n ń kọ́ àwọn ilé olórí-ṣóńṣó-bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀.”

● Kárí ayé, ìwọ̀n omi tẹ́nì kọ̀ọ̀kan ń lò lọ́dún (tó fi mọ́ omi tí wọ́n fi ń ṣọ̀gbìn àtèyí táwọn ilé iṣẹ́ ń lò) jẹ́ nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ààbọ̀ [550,000] jáálá. Àmọ́ ṣá, ní Àríwá Amẹ́ríkà, ẹnì kan ń lò tó mílíọ̀nù kan àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀ta [1,600,000] jáálá omi lọ́dún. Orílẹ̀-èdè kan ní Soviet Union àtijọ́ ni wọ́n ti ń lo omi tó pọ̀ jù, ẹnì kan ń lò ju mílíọ̀nù márùn-ún àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún [5,300,000] jáálá omi lọ lọ́dún.

● Ibi tá a lè kà sí ilẹ̀ ọ̀gbìn ní orílẹ̀-èdè kan ni fífẹ̀ ilẹ̀ tí wọ́n nílò láti gbin gbogbo ohun tí wọ́n ń jẹ sí. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Africa Geographic, ṣe sọ, “bá a bá yọ ọ́ síra wọn, ó ń gbà tó hẹ́kítà ilẹ̀ mẹ́rin láti ṣọ̀gbìn oúnjẹ tí ará South Africa kọ̀ọ̀kan máa jẹ lọ́dún, bẹ́ẹ̀ sì rèé kò ju hẹ́kítà ilẹ̀ méjì ó lé díẹ̀ lọ tí orílẹ̀-èdè náà ní láti fi ṣọ̀gbìn oúnjẹ tí ẹnì kan á jẹ lọ́dún.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Ilẹ̀ Sahel, lórílẹ̀-èdè Burkina Faso tí wọ́n gé igi àti igbó tó wà níbẹ̀ kúrò. Igi kún ibẹ̀ fọ́fọ́ lọ́dún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sẹ́yìn

[Credit Line]

© Fọ́tò tí Jeremy Hartley/Panos yà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Àwọn àgbẹ̀ tó ń dáná sungbó kí wọ́n tó gbin nǹkan sí i ń ba aginjù tó wà nílẹ̀ Cameroon jẹ́

[Credit Line]

© Fọ́tò tí Fred Hoogervorst/Panos yà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Ọ̀ràn ńlá ni èéfín ọkọ̀ tó ń ba afẹ́fẹ́ jẹ́ ṣì jẹ́ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

Láàárín ọdún 1995 sí ọdún 2000, ọdọọdún làwọn èèyàn ń pa igbó run lórí ilẹ̀ tó fẹ̀ tó ẹgbẹ̀rún méjìdínlógún kìlómítà níbùú lóòró run lórílẹ̀-èdè Brazil

[Credit Line]

© Ricardo Funari/SocialPhotos.com

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Ó ju bílíọ̀nù méjì èèyàn lọ tí wọn kì í rí owó tó tó wọn ná lóòjọ́

[Credit Line]

© Fọ́tò tí Giacomo Pirozzi/Panos yà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Àwọn tó ń sin edé létí odò táwọn ará abúlé kan lórílẹ̀-èdè Íńdíà ń mu ti ba omi náà jẹ́

[Credit Line]

© Fọ́tò tí Caroline Penn/Panos yà