Ṣé Ọ̀dẹ̀ Lẹni Tó Bá Jẹ́ Èèyàn Pẹ̀lẹ́?
Ojú Ìwòye Bíbélì
Ṣé Ọ̀dẹ̀ Lẹni Tó Bá Jẹ́ Èèyàn Pẹ̀lẹ́?
“Kò yẹ kí ẹrú Olúwa máa jà, ṣùgbọ́n ó yẹ kí ó jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí gbogbo ènìyàn.”—2 TÍMÓTÌ 2:24.
LÁTINÚ oyún la ti máa ń mọ̀ bí ohun kan bá kàn wá lára. Látìgbà tá a ti dáyé la sì ti máa ń fẹ́ kí ìyá wa máa fọwọ́ pa wá lára. Báwọn òbí wa ṣe máa ń kẹ́ wa, tí wọ́n sì máa ń gẹ̀ wá nígbà ọmọdé ló jẹ́ ká meré ṣe ká sì mọnú rò; òun náà ló sì jẹ́ ká mọ̀rọ̀ sọ dáadáa.
Àmọ́ ṣá o, Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé láwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn èèyàn á jẹ́ “aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá.” Àwọn ànímọ́ bí inú rere àti àánú á wá ṣọ̀wọ́n, nítorí pé àwọn èèyàn á jẹ́ “olùfẹ́ ara wọn,” “òǹrorò” àti “aláìní ìfẹ́ ohun rere.”—2 Tímótì 3:1-3.
Lóde òní, ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń rò pé ńṣe ló yẹ káwọn jẹ́ òǹrorò káwọn sì máa dijú mọ́ agbárí. Lójú tiwọn,
ọ̀dẹ̀ lẹni tó bá jẹ́ èèyàn pẹ̀lẹ́. Àmọ́, ṣé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí lóòótọ́?Àwọn Èèyàn Pẹ̀lẹ́ Tí Wọ́n sì Lágbára
Bíbélì pe Jèhófà Ọlọ́run ní “akin lójú ogun.” (Ẹ́kísódù 15:3) Òun ni Orísun gbogbo agbára. (Sáàmù 62:11; Róòmù 1:20) Síbẹ̀, agbára tí Jèhófà ní ò sọ pé kó máà jẹ́ “oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ gidigidi nínú ìfẹ́ni, [àti] aláàánú” nígbà tó ń san ẹ̀san rere fún Jóòbù tó jẹ́ olóòótọ́. (Jákọ́bù 5:11) Bá a bá sì wo ọ̀nà tí Jèhófà gbà bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lò, a óò rí i pé kò fọwọ́ líle mú wọn, ńṣe ló ń ṣe wọ́n pẹ̀lẹ́ bí abiyamọ tó máa ń ṣojú àánú sí “ọmọ ikùn rẹ̀.”—Aísáyà 49:15.
Jésù tẹ̀ lé àpẹẹrẹ bàbá ẹ̀, ó lágbára ó sì tún jẹ́ èèyàn pẹ̀lẹ́. Ó kégbèé lé àwọn alágàbàgebè aṣáájú ẹ̀sìn tó bá láyé lórí kárakára. (Mátíù 23:1-33) Ó sì tún fi tagbáratagbára lé àwọn tó ń fìwọra ṣe pàṣípààrọ̀ owó kúrò nínú tẹ́ńpìlì. (Mátíù 21:12, 13) Àmọ́, ṣé kíkórìíra tí Jésù kórìíra ìwà ìbàjẹ́ àti ìwọra wá sọ ọ́ di ọ̀dájú ni? Ó tì o! Èèyàn pẹ̀lẹ́ ni gbogbo èèyàn mọ Jésù sí. Kódà, ó tiẹ̀ fira ẹ̀ wé àgbébọ̀ adìyẹ tó “ń kó ọ̀wọ́ àwọn òròmọdìyẹ rẹ̀ sábẹ́ ìyẹ́ apá rẹ̀.”—Lúùkù 13:34.
Ṣé Ẹni Líle Ló Yẹ Ká Jẹ́ àbí Oníwà Pẹ̀lẹ́?
Bíbélì rọ àwọn Kristẹni tòótọ́ pé kí wọ́n máa ṣe àfarawé Kristi nípa gbígbé “àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run.” (Éfésù 4:20-24) Alákàn máa ń bọ́ igbá ẹ̀yìn rẹ̀ sílẹ̀ kí òmíràn lè hù dípò rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ gan-an ló ṣe yẹ ká “bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn àṣà rẹ̀.” (Kólósè 3:9) Àmọ́ ṣá o, kì í pẹ́ tí ẹ̀yìn alákàn tún fi máa ń le kakaraka lẹ́yìn tó bá ti bọ́ igbá ẹ̀yìn ẹ̀ sílẹ̀ tán. Ọ̀ràn tiwa ò gbọ́dọ̀ rí bẹ́ẹ̀, Bíbélì pàṣẹ fún wa pé lẹ́yìn tá bá ti bọ́ ògbólógbòó ìwà sílẹ̀, á gbọ́dọ̀ fi “ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inú rere, . . . àti ìpamọ́ra” wọ ara wa láṣọ títí lọ gbére. (Kólósè 3:12) Nítorí náà, oníwà pẹ̀lẹ́ ló yẹ ká jẹ́.
Ọ̀dẹ̀ kọ́ ni wá bá a bá fi ìwà pẹ̀lẹ́ wọ ara wa láṣọ o. A ní láti “di alágbára ńlá nínú ẹni tí [a] jẹ́ ní inú pẹ̀lú agbára nípasẹ̀ ẹ̀mí [Jèhófà] ká tó lè fi ìwà pẹ̀lẹ́ wọ ara wa láṣọ.” (Éfésù 3:16) Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Lee sọ pé: “Ìgbà kan wà tí mo jẹ́ òǹrorò, àti elèṣù èèyàn. Àkòtagìrì ni mí, nítorí pé mo dáhò sí ara mi mo sì ki nǹkan ọ̀ṣọ́ bọ̀ ọ́. Kò sì sí ohun tí mi ò ṣe tán láti dolówó, kò sí ọ̀rọ̀ burúkú tí mi ò lè sọ kọ́wọ́ mi lè tẹ́ ohun tí mo fẹ́, mo sì tún máa ń jà. Kódà, ojú àánú mi ti fọ́.” Nígbà tó yá, ọkùnrin kan tóun àti Lee jọ ń ṣiṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí fi Bíbélì kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́. Bó ṣe mọ Jèhófà Ọlọ́run tó sì wá nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ nìyẹn o. Ó ti fi ìwà rẹ̀ àtijọ́ sílẹ̀ ó sì ti kọ́ bá a ṣe máa lo ìkóra ẹni níjàánu. Ní báyìí, ó ń fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn nípa fifi àkókò rẹ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà ti fìgbà kan rí jẹ́ “aláfojúdi,” tìpátìkúùkù ló sì fi máa ń ṣe ìfẹ́ inú ara rẹ̀. (1 Tímótì 1:13; Ìṣe 9:1, 2) Síbẹ̀, nígbà tí Pọ́ọ̀lù rí bí Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi ṣe fi àánú àti ìfẹ́ hàn sí òun, ò bẹ̀rẹ̀ sí fara wé wọn. (1 Kọ́ríńtì 11:1) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù dúró lórí àwọn ìlànà táwọn Kristẹni ń tẹ̀ lé, kò fọwọ́ líle mú àwọn ẹlòmíì, pẹ̀lẹ́ ló ń ṣe wọ́n. Kódà, Pọ́ọ̀lù fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn sáwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin.—Ìṣe 20:31, 36-38; Fílémónì 12.
Ohun Tá Á Mú Ká Jẹ́ Èèyàn Pẹ̀lẹ́
Bá a ṣe rí i nínú àpẹẹrẹ Lee àti ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, kò dìgbà téèyàn bá sọ ara ẹ̀ di ọ̀dẹ̀ kó tó lè dẹni tó ń hùwà pẹ̀lẹ́ sáwọn míì. Ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Kéèyàn tó lè di oníwà pẹ̀lẹ́, ó gbọ́dọ̀ lágbára láti yí ìrònú rẹ̀ àti ìwà rẹ̀ padà, kó má sì ṣe gbà fún ẹran ara tá á fẹ́ kó “fi ibi san ibi.”—Róòmù 12:2, 17.
Àwa náà lè kọ́ béèyàn ṣe ń fi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn nípa kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé àti ṣíṣàṣàrò lórí ìfẹ́ àti àánú tí Jèhófà Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi fi hàn sí wa. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, a óò jẹ́ kí agbára Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú kí ọkàn wa rọ̀. (2 Kíróníkà 34:26, 27; Hébérù 4:12) Ibi yòówù kí wọ́n ti tọ́ wa dàgbà tàbí ìṣòro yòówù ká ti bá pàdé látìgbà tá a ti dáyé, a lè kọ́ béèyàn ṣe lè jẹ́ “ẹni pẹ̀lẹ́ sí gbogbo ènìyàn.”—2 Tímótì 2:24.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Baba rere kì í fọwọ́ líle koko mú àwọn ọmọ rẹ̀