A Ṣèbẹ̀wò Mánigbàgbé Sínú Ihò Ngorongoro
A Ṣèbẹ̀wò Mánigbàgbé Sínú Ihò Ngorongoro
Látọwọ́ òǹkọ̀wé Jí! ní Tanzania
“KÁ SỌ pé àwọn áńgẹ́lì yà fọ́tò àwọn nǹkan tó wà nínú Ọgbà Édẹ́nì ni, díẹ̀ làwòrán àwọn ẹranko ìgbẹ́ tí wọ́n á yà ì bá fi yàtọ̀ sí èyí téèyàn lè rí yà nínú Ihò Ngorongoro lónìí.” Ohun tí Reinhard Künkel kọ sínú ìwé rẹ̀ nípa ohun àrímáleèlọ tó wà lórílẹ̀-èdè olómìnira Tanzania yìí nìyẹn. Ihò Ngorongoro lẹ́wà gan-an ni, àwọn ẹranko ìgbẹ́ sì pọ̀ níbẹ̀ jabíjabí. Bá wa ka lọ ká jọ lọ fójú lóúnjẹ!
Àwòyanu
Lẹ́yìn tí ọkọ̀ wa ti rin ìrìn wákàtí mẹ́rin lórí títì eléruku, a dé etí Ihò Ngorongoro. À rí i pé ibẹ̀ lẹ́wà jọjọ bá a ṣe bojú wo ìta láti fàráńdà òtẹ́ẹ̀lì tá a dé sí. Ńṣe ni gbogbo ibẹ̀ tẹ́ rẹrẹ bí ojú sánmà, kódà a ò rí irú ẹ̀ rí. Àwọn onímọ̀ nípa ẹranko àti irúgbìn tiẹ̀ sọ pé kò sí méjì irú ibẹ̀ láyé, àwa náà sì rí i pé ohun àgbàyanu ni lóòótọ́.
Kí ló fà á tí wọ́n fi ń pe ihò náà ní Ngorongoro? Kò sẹ́ni tó mọ̀dí ẹ̀ dájú. Gẹ́gẹ́ bí Àjọ Aṣọ́gbó ní Ìlà Oòrùn Áfíríkà ṣe sọ, àwọn kan gbà pé ọkùnrin Masai kan tó ń gbé nínú ihò náà, tó sì máa ń ṣe agogo tí wọ́n ń dè mọ́ màlúù lọ́rùn, ló ń jẹ́ Ngorongoro. Àwọn míì sọ pé látọ̀dọ̀ àwọn jagunjagun ará Datogo tí wọ́n láyà bíi kìnnìún lorúkọ náà ti wá. Àwọn ará Masai ṣẹ́gun wọn lẹ́yìn tí wọ́n bá wọn fìjà pẹẹ́ta nínú ihò náà ní àádọ́jọ [150] ọdún sẹ́yìn. Ńṣe la gbé orúkọ náà tì gẹ́dẹ́ńgbẹ́ lójijì bá a ṣe rí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà mélòó kan tí wọ́n ń jẹ koríko nítòsí ibi tá a gbé ọkọ̀ wa sí. A kó sínú ọkọ̀, a sì túbọ̀ rìn sún mọ́ wọn, ṣùgbọ́n kò dà bíi pé wọ́n rí wa. À ń wakọ̀ lọ sí apá ìsàlẹ̀ ihò náà ká bàa lè rí àwọn ẹranko ìgbẹ́ púpọ̀ sí i.
Gíga ibi tí ojú ihò náà wà
jẹ́ ọ̀ọ́dúnrún lé lẹ́gbàá ó dín mẹ́rìnlélọ́gọ́ta mítà [2,236], ìyẹn ga tó kéèyàn to òpó iná bí igba àti méjìlá sórí ara wọn lóòró. Kò sí òkè ayọnáyèéfín tó fẹ̀ tóyẹn lágbàáyé. Láti ìpẹ̀kun kan dé ìkejì, ẹnu ihò náà fẹ̀ tó kìlómítà mọ́kàndínlógún ó lé díẹ̀, tàbí máìlì méjìlá. Ojú ihò náà lápapọ̀ fẹ̀ tó kìlómítà mẹ́rìnlélọ́ọ̀ọ́dúnrún [304]. Ọkọ̀ wa rọra ń rìn bá a ṣe ń wà á wọ inú ihò náà lọ. Ihò náà jìn tó ẹgbẹ̀ta ó lé mẹ́wàá [610] mítà. À ń yọrí síta látojú fèrèsé ọkọ wa ká bàa lè ya fọ́tò. Nígbà tá a wà létí ihò náà ńṣe ni afẹ́fẹ́ òwúrọ̀ rọra ń fẹ́ lẹlẹ, àmọ́, ó yà wá lẹ́nu pé fofoofo ni inú ẹ̀ lọ́hùn-ún ń gbóná.Nígbà tá a gúnlẹ̀ sínú ihò gbàràmù gbaramu náà tán, dẹ́rẹ́bà wa bẹ̀rẹ̀ sí gbé wa káàkiri, a kọjá adágún omi oníyọ̀ á sì ráwọn ẹyẹ flamingo aláwọ̀ osùn tí wọ́n wà níbẹ̀. Láti ìsàlẹ̀ ihò tá a gúnlẹ̀ sí yìí, téèyàn bá wo ẹnu ihò náà lókè, ńṣe ni ojú ọ̀run tó funfun nini mú kó fara hàn kedere. Bá a sì ṣe ń gbúròó àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà àtàwọn ẹranko bí ìrá kùnnùgbá tí igbe wọn àtàwọn igbe míì láyìíká rinlẹ̀, ńṣe là ń kọ hà tí orí wa sì ń wú. Dájúdájú, ibi yìí mà gbádùn mọ́ni gan-an ni o!
Àwọn Ẹranko Ìgbẹ́ Tó Ń Gbénú Ihò Náà
A ti ń ronú pé a máa rí àwọn ẹranko bí ẹfọ̀n, erin, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà, ìrá kùnnùgbá, àgbàlàǹgbó, àgbáǹréré dúdú, àtàwọn ọ̀bọ nínú Ihò Ngorongoro, gbogbo wọn pátá la sì rí. Àwọn ẹranko apẹranjẹ bíi cheetah, ìkookò, ajáko, àtàwọn kìnnìún onígọ̀gọ̀ dúdú sì tún máa ń jẹ̀ níbẹ̀. Níbi adágún kékeré kan báyìí, a ráwọn erinmi tí wọ́n ń wẹ̀. Gbogbo bá a ṣe ń yà wọ́n ní fọ́tò, wọ́n kàn ń wẹ̀ lọ ní tiwọn ni.
Àfi ṣìí tí dírẹ́bà wa dúró lójijì! Ó ní ká wo àgbáǹréré
dúdú tó ń sọdá ní nǹkan bí ẹsẹ̀ bàtà díẹ̀ síbi tá a wà. Ó kàn ń dá gbàgọ̀ lọ ní tiẹ̀ ni, a sì fẹ́rẹ̀ẹ́ lè fọwọ́ kàn án níbi tó sún mọ́ wa dé. A ò mọyì àǹfààní tá a jẹ láti rí i níbi tí Ọlọ́run dá a sí. Wọ́n ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pa àwọn ẹranko fọ̀ngbàdì yìí tán ṣá o; bóyá lèyí tó kù nínú ihò náà fi tó ogún. Wọ́n ti mú àwọn èèyàn kan tó ń pẹran láìgbàṣẹ níbi tí wọ́n ti n pa àwọn àgbáǹréré náà kí wọ́n bàa lè yọ ìwo wọn. Wọ́n á wá lọ ta ìwo náà fáwọn tá á fi wọ́n ṣe èèkù ọ̀bẹ àti egbòogi, èyí tí ò sì bófin mu. Lemọ́lemọ́ làwọn aṣọ́gbó máa ń pààrà inú ihò náà kí wọ́n lè lé àwọn tó ń jí ẹran pa jìnnà síbẹ̀.Ẹni bá fẹ́ràn ẹyẹ ò jayò pa bó bá retí pé kóun rí ọ̀kan-ò-jọ̀kan ẹyẹ rírẹwà níbẹ̀, àwọn bí ògòǹgò, ẹyẹ kori bustard, àgùfọn ológbe, lékeléke, ẹyẹ àkọ̀, àṣáǹwéwé, ẹyẹ alágòógó pupa tó máa ń ṣa kòkòrò jẹ lára ẹran, àti àìlóǹkà ẹyẹ flamingo kékeré. Oríṣiríṣi ẹyẹ tó finú ihò náà ṣe ibùgbé lé ní ọgọ́rùn-ún. Èèyàn ò sì lè rí irú àwọn ẹyẹ bẹ́ẹ̀ ní Ọgbà Ẹranko Ìlú ti Serengeti tó wà ládùúgbò ibẹ̀. Àwọn ẹyẹ àkókó onírùngbọ̀n yẹ́úkẹ́, ọ̀gẹṣinlẹ́ṣin, yanjayanja, àtàwọn ọ̀pẹ́ẹ̀rẹ́ ọlọ́pọ̀ ẹwà náà wà níbẹ̀. Àwọn ẹyẹ rosy-breasted eléèékánná ṣàgìlà rọra ba mọ́nú koríko, wọ́n sì ti rí kannakánná tó wọ́n bí ojú rí níbẹ̀.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí tó pọ̀ lára àwọn ẹranko tó wà níbẹ̀ ò kíyè sí wa, a ò tó ẹrú tó ń kúrò nínú ọkọ̀ wa. Àmọ́ ṣá o, àwọn Masai, tí wọ́n ń gbé nínú ilé alámọ̀ tí wọ́n fi koríko bò nínú ihò náà, máa ń rìn fàlàlà bí wọ́n ti ń da ẹran káàkiri. Ó dà bí ẹni pé àwọn àtàwọn ẹran ìgbẹ́ náà ti mọwọ́ ara wọn.
Ìparọ́rọ́ àti ẹwà tó wà nínú Ihò Ngorongoro kọjá àfẹnusọ, ó sì mú ká gbà pé Ọlọ́run tóbi lọ́ba. Mánigbàgbé gbáà ni ìbẹ̀wò tá a ṣe síbi ihò náà jẹ́.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Àgbáǹréré
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Àwọn Masai tí wọ́n ń daran létí ihò náà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Obìnrin Masai kan
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Ẹranko “Cheetah”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Àgùfọn ológbe
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Ẹyẹ “Flamingo”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Erinmi
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30, 31]
Ihò Ngorongoro
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Ẹfọ̀n
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Erin
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Ọ̀bọ