Bíba Ilé Ayé Jẹ́ Máa Dópin!
Bíba Ilé Ayé Jẹ́ Máa Dópin!
ÀWỌN àpilẹ̀kọ méjì tó ṣáájú mú kó ṣe kedere pé kò sí báwọn èèyàn ṣe lè máa bá a nìṣó láti máa lo àwọn àlùmọ́ọ́nì ilẹ̀ ayé nílòkulò bí wọ́n ṣe ń ṣe yìí. Lóòótọ́ làwọn aṣáájú ayé ń ṣe gudugudu méje láti mú kí bíba àyíká jẹ́, dídáná sun igbó, àtàwọn ìṣòro míì dín kù. Látìgbà Àpérò Ìparapọ̀
Orílẹ̀-Èdè Lórí Ibùgbé Ẹ̀dá tó wáyé lọ́dún 1972, àtàwọn àpérò mìíràn tó ń wáyé wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ lẹ́yìn náà, ó ti tó orílẹ̀-èdè mẹ́tàlélọ́gọ́jọ [163] tó ti pé àpérò kí wọ́n lè fọwọ́ sí àwọn àbá lóríṣiríṣi. Ibo wá ni gbogbo àpérò náà já sí? Ọ̀gá àgbà ní Ibùdó Tó Ń Rí sí Òfin Tó Jẹ Mọ́ Àyíká Lágbàáyé, David Hunter, sọ pé: “Ó ṣeni láàánú pé àwọn àdéhùn rẹpẹtẹ, àwọn àbá lóríṣiríṣi àtàwọn nǹkan míì tí wọ́n ti kọ sílẹ̀ láti ṣe kò tíì yí bí àyíká wa ṣe ń bàjẹ́ padà.” Kódà, ọ̀gá àgbà náà fi kún un pé, “gbogbo ohun tá à ń rí láyìíká fi hàn pé ńṣe ni bí àyíká wa ṣe rí lónìí wá ń burú sí i ju bó ṣe rí nígbà Àpérò Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè tó wáyé lọ́dún 1992.”Kí ló wá fà á tó fi jẹ́ pé léyìí tó ti lè lọ́gbọ̀n ọdún tí wọ́n ti ń gbìyànjú láti yanjú ìṣòro àyíká, àṣeyọrí díẹ̀ ni wọ́n tíì ṣe? Ọ̀kan lára ohun tó fà á ni ètò ọrọ̀ ajé tó búrẹ́kẹ́. Báwọn èèyàn bá ṣe ń rajà sí ni ètò ọ̀rọ̀ ajé àwọn orílẹ̀-èdè sinmi lé. Ìyẹn túmọ̀ sí pé àwọn iléeṣẹ́ gbọ́dọ̀ máa ṣe àwọn nǹkan jáde, iléeṣẹ́ náà sì gbọ́dọ̀ rí àwọn ohun èlò tí wọ́n á fi ṣiṣẹ́. Díẹ̀ níbí, díẹ̀ lọ́hùn-ún lọ̀rọ̀ ọ̀hún wá dà, àyíká ló sì máa pàpà jẹ̀rán ẹ̀. Èwo gan-an wá ni ṣíṣe báyìí?
Asán Lórí Asán
Bíbélì ṣàlàyé ìdí tí gbogbo ìlàkàkà ẹ̀dá láti ṣàkóso ara wọn fi ń já sí òtúbáńtẹ́. Wòlíì Jeremáyà sọ pé: “Mo mọ̀ dáadáa, Jèhófà, pé ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Jeremáyà 10:23) Òótọ́ gbáà làwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí já sí!
Ṣé o ti lọ síbi ọgbà ìtura kan rí? Àwọn igi, igbó ṣúúrú, àtàwọn òdòdó rírẹwà tó gún régé téèyàn máa ń rí níbẹ̀ mà máa ń dùn ún wò o! Àmọ́, ọgbà òdòdó tó gún régé kì í ṣàdédé wà o. Àwọn tó mọ̀ nípa òdòdó ti ní láti lo ọ̀pọ̀ wákàtí láti gé orí àti ọwọ́ àwọn igi òdòdó dọ́gba, wọ́n á tún gé àwọn koríko dọ́gba, wọ́n á sì bu ìlẹ̀dú sídìí àwọn òdòdó kí wọ́n bàa lè dùn wó bí wọ́n ṣe ń dàgbà. Wá wo bí gbogbo ilẹ̀ ayé wa ì bá ṣe rí ká sọ pé bí ọgbà kan ṣe ń rí ìtọ́jú onífẹ̀ẹ́ náà ni ayé wa yìí ṣe ń rí ìtọ́jú.
Ohun tí Ẹlẹ́dàá wa dìídì fẹ́ ni pé kí ilẹ̀ ayé wa lódindi rí irú ìtọ́jú bẹ́ẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ nípa ìṣẹ̀dá ti sọ nínú Ọ̀rọ̀ onímìísí Ọlọ́run, “Jèhófà Ọlọ́run sì ń bá a lọ láti mú ọkùnrin náà, ó sì mú un tẹ̀ dó sínú ọgbà Édẹ́nì láti máa ro ó àti láti máa bójú tó o.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:15) Láfikún sí ìyẹn, Ọlọ́run tún pàṣẹ fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn náà pé yàtọ̀ sí pé kí wọ́n bójú tó ọgbà Édẹ́nì, kí wọ́n tún mú kí Párádísè ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà gbòòrò títí tá á fi kárí gbogbo ilẹ̀ ayé pátá.—Jẹ́nẹ́sísì 1:28.
Ó mà ṣe o, Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn wọ́n sì di aláìpé. Bí àǹfààní tí wọ́n ní láti máa bójú tó Párádísè kí wọ́n sì jẹ́ kó gbòòrò sí i ṣe bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́ nìyẹn. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6, 23) Nítorí pé irú ọmọ tọkọtaya tí Ọlọ́run kọ́kọ́ dá yìí ni wá, a ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé wọn. (Róòmù 5:12) Lílo àwọn àlùmọ́ọ́nì ilẹ̀ nílòkulò wulẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ kan lára ìsapá asán táráyé ti ṣe láti dá ṣàkóso ara wọn. Ṣáká ló dájú pé ìṣòro tó ń bá aráyé fínra ti kọjá ohun tí wọ́n lè dá yanjú. Àfi káráyé yáa wá ìrànlọ́wọ́ síbòmíràn.
Ohun Tó Máa Yanjú Ìṣòro Aráyé
Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti máa gbàdúrà pé: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mátíù 6:10) Bíbélì kọ́ni pé lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run lókè ọ̀run, Ọlọ́run á sọ ayé di Párádísè. (Sáàmù 37:10, 11) Nígbà yẹn àwọn igi àtàwọn ohun ọ̀gbìn á máa hù dáadáa nínú àyíká tó mọ́ tónítóní. (Sáàmù 72:16) Bí aráyé bá ṣe ń tẹ̀ lé ìtọ́ni Ọlọ́run, ilẹ̀ ayé á di mímọ́ tónítóní, aráyé á sì mọ béèyàn ṣe ń gbé ìgbésí ayé láìba àyíká jẹ́. Báwo ló ṣe lè dá wa lójú pé ọ̀rọ̀ á rí bẹ́ẹ̀?
Bíbélì sọ pé ilẹ̀ ayé ò ní “ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n fún àkókò tí ó lọ kánrin, tàbí títí láé.” (Sáàmù 104:5) Nígbà tí àkókò bá tó lójú Ọlọ́run, gbogbo ẹ̀dá alààyè á gbádùn ìbùkún ayérayé, ara wọn á dá ṣáṣá, oúnjẹ á pọ̀ rẹpẹtẹ, wọ́n á sì rílé tó dáa gbé. Ṣé wàá fẹ́ láti mọ̀ sí i nípa àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ń fẹ́ fún aráyé? Bá èyíkéyìí lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ̀rọ̀. Inú wọn á dùn láti fi hàn ọ́ nínú Bíbélì rẹ pé Ọlọ́run máa fòpin sí bíba ilẹ̀ ayé jẹ́, wọ́n á sì ṣàlàyé ọ̀nà tó máa gbà ṣe bẹ́ẹ̀ fún ọ!
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Bí aráyé bá ṣe ń tẹ̀ lé ìtọ́ni Ọlọ́run, wọ́n á mọ béèyàn ṣe ń gbé ìgbésí ayé láìba àyíká jẹ́
[Credit Line]
Ọmọbìnrin kan àti àgbẹ̀ kan: © Àwòrán tí Jeremy Horner/Panos yà