Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bó Bá Lóun Ò Lè Fẹ́ Mi Ńkọ́?

Bó Bá Lóun Ò Lè Fẹ́ Mi Ńkọ́?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Bó Bá Lóun Ò Lè Fẹ́ Mi Ńkọ́?

Ọ̀RẸ́ lẹ̀ ń pera yín. O kàn wá rí i pé ọkàn ẹ̀ ṣáà ń fà ẹ́ ni. Ó lè jẹ́ pé bó ṣe níwà ló fà ẹ́ mọ́ra, tàbí bó ṣe máa ń fẹyín sí ẹ nígbà tó bá ń sọ̀rọ̀. Ohun yòówù tí ì báà fà á, ó ti ń tọ́jọ́ mẹ́tà báyìí, kò sì ṣe bí ẹni tó fẹ́ kẹ́ ẹ máa fẹ́ra. Lo bá ní kó o kúkú lọ bi í bóyá ó ní in lọ́kàn pé kẹ́ ẹ máa fẹ́ra. Ó dùn ẹ́ kọjá sísọ nígbà tó sọ fún ọ wẹ́rẹ́ pé kò lè ṣeé ṣe. a

Kò sí kó má dùn ẹ́ ná. Ṣùgbọ́n má bara jẹ́ jù; jẹ́ kí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yé ẹ dáadáa. Òótọ́ ni pé ọ̀dọ́kùnrin kan sọ pé òun ò nífẹ̀ẹ́ sí kí ìwọ àti òun máa fẹ́ra. Rántí o, ìpinnu tó ṣe ò sọ ẹ́ dẹni yẹ̀yẹ́, ìyẹn ò sì ní káwọn míì máà fẹ́ràn rẹ tàbí kí wọ́n má bọ̀wọ̀ fún ẹ mọ́. Kódà, ó lè jẹ́ pé ohun tó ń lé nísinsìnyí àti ohun tọ́rọ̀ ẹ̀ kàn báyìí ló rò ni ò fi gbà, ó lè máà ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú irú ẹni tó fi ẹ́ pè.

Àgàgà tó o bá jẹ́ Kristẹni, rántí pé “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ [rẹ] àti ìfẹ́ tí [o] fi hàn fún orúkọ rẹ̀.” (Hébérù 6:10) Sonja b sọ pé: “Èèyàn pàtàkì ṣì ni ẹ́. O ṣì wúlò gan-an fún Jèhófà gẹ́gẹ́ bí àpọ́n.” Níwọ̀n bí Ọlọ́run tó jẹ́ Ẹni Gíga Ju Lọ àtàwọn ẹlòmíì ti ń fojú pàtàkì wò ẹ́, kí ló wá dé tí wàá wá pa iyì náà mọ́ra ẹ lára?

O ṣì lè máa rò ó pé ó ti tán fún ẹ àti pé bóyá ló máa rẹ́ni tó lè fi ẹ́ ṣaya. Ṣùgbọ́n, bó bá tiẹ̀ dà bíi pé o ò “ṣe wẹ́kú” lójú ọ̀dọ́kùnrin yìí lákòókò yìí, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé o ò ní “ṣe wẹ́kú” lójú ẹlòmíì. (Onídàájọ́ 14:3) Nítorí náà, dípò tí wàá fi rò pé pàbó ni akitiyan ẹ láti rọ́kọ fẹ́ já sí, gbà pé àǹfààní kan ti tìdí ìgbésẹ̀ tó o gbé wá, ìyẹn ni pé o ti mọ̀ pé ọmọkùnrin yìí kì í ṣe tìẹ. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?

Ṣé Òun Ló Yẹ Kó O Fẹ́?

Bíbélì pàṣẹ fáwọn ọkọ pé kí wọ́n “máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnra wọn.” (Éfésù 5:28) Ó tún pàṣẹ fáwọn ọkọ pé kí wọ́n “fi ọlá fún” àwọn aya wọn. (1 Pétérù 3:7) Ẹ̀wẹ̀, ọ̀dọ́mọkùnrin yìí lè fẹ́ràn ẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ ẹ̀. Ṣùgbọ́n bí ò ṣe gbà kẹ́ ẹ máa fẹ́ra yìí, ó ti fi hàn pé òun ò lè nífẹ̀ẹ́ ẹ báyìí òun ò sì tíì lè máa ṣìkẹ́ ẹ gẹ́gẹ́ bí ìyàwó ẹ̀. Ó lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣèpinnu tó ṣe yẹn. Ìwọ rò ó wò ná: Bó bá jẹ́ pé ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀ nìyẹn, ṣé irú ọkọ tó máa bá ẹ kalẹ́ nìyẹn? Wo inú ìbànújẹ́ ńlá tí wàá lọ kọrùn bọ̀ tó o bá lọ fẹ́ ẹni tí ò nífẹ̀ẹ́ ẹ tí kò sì lè máa ṣìkẹ́ ẹ bí Ìwé Mímọ́ ṣe là á kalẹ̀!

Nísinsìnyí tó o ti mọ̀ pé ọmọkùnrin yìí ò ní ẹ fẹ́, á dáa kó o tún ìwà ẹ̀ wò lẹ́ẹ̀kan sí i. Nígbà míì, ìfẹ́ onígbòónára lè ru bo èèyàn lójú débi tí ò fi ní rí àwọn àléébù táwọn ẹlòmíì ń rí kedere. Bí àpẹẹrẹ, ṣé kò mọ̀ pé ìfẹ́ òun ti ń wọ̀ ẹ́ lọ́kàn ni, àbí ó mọ̀ọ́mọ̀ jẹ́ kí ìfẹ́ yẹn máa gbóná sí i lọ́kàn ẹ nípa bó ṣe ń bá ẹ ṣe wọléwọ̀de nìṣó? Bó bá jẹ́ pé ńṣe ló mọ̀ọ́mọ̀ ń gbé ẹ lọ́kàn sókè, ṣé ìyẹn ò ní fi í hàn bí ọkọ tí ò ní ìgbatẹnirò àti ìfọ̀ràn-rora-ẹni-wò gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ó dáa tó o wádìí òótọ́ yẹn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè dùn ẹ́.

Nígbà tí ọmọkùnrin kan bẹ̀rẹ̀ sí ṣe gulegule tẹ̀ lé Marcia, ọkàn rẹ̀ ń fà sí ọmọkùnrin náà. Nígbà tí Marcia béèrè ohun tó wà lọ́kàn ọmọkùnrin yìí lọ́wọ́ ẹ̀, ó sọ pé òun ò ní in lọ́kàn láti fẹ́ ẹ. Kí ló ràn án lọ́wọ́ láti mú ìjákulẹ̀ yìí mọ́ra? Ó sọ pé: “Bí mi ò ṣe jẹ́ kó dà mí lọ́kàn rú tí mo sì rorí ara mi dáadáa ló mú kí n lè mú un mọ́ra.” Bó tún ṣe ń rántí àwọn nǹkan tí Bíbélì là sílẹ̀ pé káwọn ọkọ máa ṣe tún jẹ́ kó mọ̀ pé ọmọkùnrin yẹn ò yẹ lẹ́ni téèyàn fi ń ṣọkọ. Èyí ló ràn án lọ́wọ́ láti gbé ìbànújẹ́ yẹn kúrò lọ́kàn ẹ̀.

Andrea fara gbá irú nǹkan tó jọ bẹ́ẹ̀ lọ́dọ̀ ọmọkùnrin kan. Ó mọ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn pé bí ọmọkùnrin náà ṣe ń ṣe sí i fi hàn pé ọmọdé ṣì ń ṣe é. Ó wá rí i pé kò tíì tó níyàwó, ó sì dúpẹ́ pé Jèhófà jẹ́ kóun mọ bọ́ràn ṣe rí. Ó sọ pé: “Mo gbà gbọ́ pé Jèhófà lè dáàbò bò èèyàn lọ́wọ́ nǹkan tó lè bà á lọ́kàn jẹ́, àmọ́ àfi kéèyàn gbẹ́kẹ̀ lé E.” Lọ́pọ̀ ìgbà ṣá o, ọmọkùnrin kan lè jẹ́ ọmọlúwàbí síbẹ̀ kó pàpà sọ pé òun ò fẹ́ ẹ fáwọn ìdí tẹ́nikẹ́ni ò lè dáa lẹ́bi lé lórí. Bó ti wù kí ọ̀ràn rí, báwo ni wàá ṣe borí ẹ̀dùn ọkàn tó máa bá ẹ nígbà tí ẹnì kan bá ní òun ò fẹ́ ẹ?

Ohun Tó O Lè Ṣe sí Ẹ̀dùn Ọkàn Rẹ

Ó lè pẹ́ díẹ̀ kó o tó lè mọ́kàn kúrò lórí ẹ̀ lẹ́yìn tó bá ti sọ pé òun ò fẹ́ ẹ. Ọjọ́ kan kọ́ ni ìfẹ́ ẹ̀ fi wọ̀ ẹ́ lọ́kàn, bákan náà á ṣe díẹ̀ kí ìfẹ́ ẹ̀ tó kúrò lọ́kàn ẹ. Ọ̀rọ̀ ìfẹ́ kì í sábà dà bí iná téèyàn kàn lè fẹ́ pa. Nígbà míì sì rèé, bí àdánwò lọ̀rọ̀ ìfẹ́ máa ń rí! Ní sùúrù fún ẹ̀mí ẹ. Bọ́jọ́ bá ṣe ń gorí ọjọ́, àwọn ìmọ̀lára wọ̀nyẹn á wábi gbà. Àmọ́ tó o bá fẹ́ kí ìmọ̀lára wọ̀nyẹn tètè kúrò lọ́kàn ẹ, má máa ṣe àwọn nǹkan tá á mú kó máa wá sí ọ lọ́kàn.

Bí àpẹẹrẹ, bó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé kó o máa ro ohun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹlẹ̀ ní àròtúnrò, tó dà bíi pé kó o máa ro ohun tó o ṣe, àtàwọn ọ̀rọ̀ tó o sọ nígbà tó ò ń sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ fún ọmọkùnrin yẹn, má fàyè gba irú èrò bẹ́ẹ̀. Tó o bá fàyè gba irú èrò yẹn, o lè bẹ̀rẹ̀ sí rò pé bó ṣe lóun ò fẹ́ ẹ yẹn ò dénú ẹ̀ tàbí pé tó o bá wá ọgbọ́n míì dá, ó lè gbà. Mọ́kàn kúrò nínú pé o lè yí ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀ padà. Kò sí ọgbọ́n tó o lè dá láti sọ fún un, bóyá ló lè yí ohun tó ti sọ padà.

Tún ṣọ́ra fún àlá ọ̀sán gangan. O lè bẹ̀rẹ̀ sí fọkàn yàwòrán ìgbà tí ẹ̀yin méjèèjì á máa gbé pọ̀ bíi tọkọtìyàwó. Àwọn ìrònú asán yẹn lè máa dùn mọ́ ẹ o, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Nígbà tó o bá parí àlá tó ò ń lá, wàá tún bẹ̀rẹ̀ sí rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ tìbánújẹ́ tìbànújẹ́. Ó lè pẹ́ díẹ̀ kó o tó lè gbara ẹ lọ́wọ́ ìdára ẹni nínú dùn yìí àti ìbànújẹ́ tó máa ń tẹ̀ lé e àyàfi tó o bá tiraka láti fòpin sí i.

Gbìyànjú láti gbé àlá ọ̀sán gangan kúrò lọ́kàn. Gbàrà tó bá ti yọjú gbéra ńlẹ̀ kó o rìn lọ rìn bọ̀. Wá iṣẹ́ kan tó lágbára ṣe, ìyẹn iṣẹ́ tá á lè gbé ọkàn ẹ lọ sórí nǹkan míì. Máa ronú nípa àwọn nǹkan tó lè fún ẹ lókun nípa tẹ̀mí, kì í ṣe àwọn nǹkan tó lè dà ẹ́ lọ́kàn rú. (Fílípì 4:8) Ó lè ṣòro ṣe lákọ̀ọ́kọ́, àmọ́ wàá borí ẹ̀ ọkàn ẹ á sì balẹ̀ bó bá yá, wàá bọ́ lọ́wọ́ àníyàn.

Àwọn ọ̀rẹ́ ẹ tó sún mọ́ ẹ tún lè fún ẹ níṣìírí. (Òwe 17:17) Àmọ́ ṣá o, Sonja kìlọ̀ pé: “Kì í ṣe ohun tó dáa tó bá jẹ́ pé kìkì àpọ́n tọ́jọ́ orí yín ò jura lọ, táwọn náà ṣì ń wá bí wọ́n ṣe máa ṣègbéyàwó làwọn ọ̀rẹ́ ẹ. Ó yẹ kó o tún máa bá àwọn àgbààgbà náà ṣọ̀rẹ́, ìyẹn àwọn tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ bí nǹkan ṣe rí gan-an.” Sì rántí pé ẹnì kan wà tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ ju gbogbo àwọn tó kù lọ láti borí ẹ̀dùn ọkàn ẹ.

Jèhófà Jẹ́ Ọ̀rẹ́ àti Orísun Agbára

Nígbà tí ọkùnrin olóòótọ́ kan nígbà àtijọ́ rí nǹkan tó bà á nínú jẹ́, ó gbàdúrà pé kí Jèhófà ran òun lọ́wọ́. Kí ló wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà? Ó kọ̀wé pé: “Ninu ọ̀pọlọpọ ibinujẹ mi ninu mi, itunu irẹ li o nmu inu mi dùn.” (Sáàmù 94:19, Bibeli Mimọ) Jèhófà yóò tù ẹ́ nínú yóò sì dúró tì ẹ́ tó o bá fi ìgbàgbọ́ gbàdúrà sí i. Ohun tí Andrea ṣe nìyẹn. Ó sọ pé: “Àdúrà ṣe pàtàkì gan-an láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ tí wàá fi borí ìbànújẹ́ náà tí wàá sì lè máa gbé ìgbésí ayé ẹ lọ.” Sonja náà sọ nípa àdúrà gbígbà pé: “Á ràn ẹ́ lọ́wọ́ tó ò bá fi bóyá àwọn èèyàn fẹ́ràn ẹ̀ tàbí wọ́n pa ẹ́ tì díwọ̀n bó o ṣe ṣe pàtàkì tó.”

Kò sí èèyàn kankan tí gbogbo bó ṣe ń ṣe ẹ́ pátápátá lè yé, ṣùgbọ́n ó yé Jèhófà. Ó dá wa nídàá tá a fi máa lè nífẹ̀ẹ́ ọkọ tàbí aya ẹni táwọn náà á sì lè nífẹ̀ẹ́ wa. Ó mọ bí òǹfà ìfẹ́ ṣe lágbára tó ó mọ béèyàn ṣe lè darí òǹfà náà. Ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí ìṣòro ńlá tó kà wá láyà, nítorí pé 1 Jòhánù 3:20 sọ pé: “Ọlọ́run tóbi ju ọkàn-àyà wa lọ, ó sì mọ ohun gbogbo.”

Rò Ó Síwá Kó O sì Rò Ó Sẹ́yìn

Ìgbéyàwó lè dùn bí oyin, ṣùgbọ́n òun nìkan kọ́ ló ń fúnni láyọ̀. Gbogbo àwọn tó ń sin Jèhófà ló ń láyọ̀, kì í ṣe àwọn tó lọ́kọ tàbí aya nìkan. Àwọn ọ̀nà kan wà táwọn àpọ́n fi ń gbádùn ju àwọn tó ṣègbéyàwó lọ. Àwọn kì í “ní ìpọ́njú nínú ẹran ara wọn” bí 1 Kọ́ríńtì 7:28 ṣe sọ. Ìpọ́njú yìí làwọn àìfararọ àti pákáǹleke tí gbogbo lọ́kọláya ń dojú kọ. Kò fi bẹ́ẹ̀ sí ohun tó ń dí àwọn àpọ́n lọ́wọ́, ó sì rọrùn fún wọn láti fi ìgbésí ayé wọn ṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ìdí rèé tí Bíbélì fi kọ́ wa pé: “Ẹni náà tí ó fi ipò wúńdíá rẹ̀ fúnni nínú ìgbéyàwó ṣe dáadáa, ṣùgbọ́n ẹni tí kò fi í fúnni nínú ìgbéyàwó yóò ṣe dáadáa jù.” (1 Kọ́ríńtì 7:38) Kódà tó bá wà ní góńgó orí ẹ̀mí ẹ láti lọ́kọ, ríronú lórí àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì yìí lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti rò ó dáadáa tí wàá sì lè gbádùn ìgbésí ayé ẹ bó o ṣe wà yìí.

Àwọn ọ̀rẹ́ ẹ tó fẹ́re fún ẹ lè máa sọ fún ẹ pé, “Ṣáà má mikàn, ọjọ́ kan á jọ́kan tí wàá rọ́kọ tó máa múnú ẹ dùn.” Òótọ́ sì ni pé bí ẹnì kan ṣe lóun ò lè fẹ́ ẹ ò fi hàn pé kò sẹ́ni tó máa fẹ́ ẹ. Síbẹ̀, ọ̀dọ́bìnrin Kristẹni kan tó ń jẹ́ Candace sọ bó ṣe máa ń wo ọ̀ràn pé: “Mo gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Mi ò fi dandan lé e pé kó pèsè ọkọ fún mi kí n lè láyọ̀. Ṣùgbọ́n mo mọ̀ pé á ṣe nǹkan tó máa fi dí àlàfo ọkọ tí mi ò ní fún mi.” Ríronú lọ́nà yẹn ló ràn án lọ́wọ́ láti mú un mọ́ra nígbà tí ọmọkùnrin tí ọkàn ẹ̀ yàn ò gbà fún un.

Ọ̀pọ̀ àwọn tó ti dẹnu ìfẹ́ kọ àwọn ẹlòmíràn láyé yìí ni ò bọ́ sí i fún, àmọ́ ọ̀pọ̀ ìgbéyàwó náà ló ti forí ṣánpọ́n. Tó o bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tó o sì ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn rẹ̀, ó lágbára láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fi ayọ̀ dípò ìjákulẹ̀. Ìwọ náà lè nírú ìrírí tí Ọba Dáfídì ní nígbà tó kọ̀wé pé: “Jèhófà, iwájú rẹ ni gbogbo ìfẹ́-ọkàn mi wà, ìmí ẹ̀dùn mi kò sì pa mọ́ fún ọ. Nítorí pé ìwọ, Jèhófà, ni mo dúró dè; ìwọ fúnra rẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí dá mi lóhùn, ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi.”—Sáàmù 38:9, 15.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Báwo Ni Mo Ṣe Lè Sọ Ohun Tó Wà Lọ́kàn Mi fún Un?” (tó wà nínú ìtẹ̀jáde November 8, 2004) ṣàlàyé pé ó lè lòdì sí àṣà wọn láwọn ilẹ̀ kan pé kí obìnrin lọ bá ọkùnrin pé òun fẹ́ káwọn máa fẹ́ra. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì ò lòdì sírú nǹkan bẹ́ẹ̀, ó gba àwọn Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n má ṣe ohun tó bá lè mú ẹlòmíì kọsẹ̀. Nítorí náà, ó yẹ káwọn tó bá fẹ́ rí ìbùkún Ọlọ́run tẹ̀ lé ìmọ̀ràn inú Bíbélì yìí kí wọ́n tó lọ dẹnu kọ ọkùnrin.—Mátíù 18:6; Róòmù 14:13; 1 Kọ́ríńtì 8:13.

b A ti yí àwọn orúkọ kan padà.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Wá ìrànlọ́wọ́ sọ́dọ̀ Ọlọ́run