Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ewu Tó Wà Nínú Kéèyàn Fẹ́ Lẹ́wà Ní Gbogbo Ọ̀nà

Ewu Tó Wà Nínú Kéèyàn Fẹ́ Lẹ́wà Ní Gbogbo Ọ̀nà

Ewu Tó Wà Nínú Kéèyàn Fẹ́ Lẹ́wà Ní Gbogbo Ọ̀nà

KÍ LÀWỌN nǹkan tá a fi lè mọ ojúlówó ẹwà? Èyí wù mí ò wù ọ́ lọ̀rọ̀ ẹwà. Ká sòótọ́, ohun tẹ́nì kan bá kà sí ẹwà náà ló mọ̀ sí ẹwà. Yàtọ̀ sí ìyẹn ohun táwọn èèyàn kà sí ẹwà láwọn ibì kan yàtọ̀ pátápátá sí ohun táwọn ará ibòmíràn kà sí ẹwà, bọ́jọ́ sì ṣe ń gorí ọjọ́ lohun táwọn èèyàn ń kà sí ẹwà ń yí padà.

Jeffery Sobal, tó ti fẹ́ di ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ oúnjẹ tó ṣara lóore nílé ẹ̀kọ́ gíga Cornell University nílẹ̀ Amẹ́ríkà, sọ pé: “Láàárín ọdún 1800 sí 1899, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé níbi gbogbo ni wọ́n ti gbà pé gbajúmọ̀ èèyàn lẹni tó bá kí sára. Wọ́n gbà pé ọlọ́lá àti ẹni tára ẹ le ló máa ń yọkùn, nígbà tó jẹ́ pé akúṣẹ̀ẹ́ tí ò rówó jẹun kánú ló máa ń pẹ́lẹ́ńgẹ́.” Àwòrán táwọn ayàwòrán ń yà lákòókò yẹn fi hàn pé ìgbàgbọ́ wọn nìyẹn. Ìdí ni pé àwọn tí wọ́n máa ń yà bí àwòfiṣàpẹẹrẹ, tí wọ́n sábà máa ń jẹ́ obìnrin, máa ń ki lápá ki lẹ́sẹ̀, wọ́n sì máa ń ki sí ẹ̀yìn àti sí ìbàráàdí. Àwòrán àwọn èèyàn gidi tí wọ́n kà sí awẹ́lẹ́wà sì ni ọ̀pọ̀ àwòrán wọ̀nyẹn.

Ẹ̀rí ṣì wà dòní pé àwọn kan ṣì ní irú èrò yẹn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ sísanra tàbí pípẹ́lẹ́ńgẹ́ nìkan kọ́ ni wọ́n fi ń díwọ̀n ẹwà. Síbẹ̀, láàárín àwọn kan ní Gúúsù Pàsífíìkì, ojú èèyàn pàtàkì ni wọ́n fi ń wo ẹni bá sanra. Láwọn apá ibì kan nílẹ̀ Áfíríkà, wọ́n máa ń mú àwọn obìnrin tó bá ń múra ilé ọkọ lọ sí ibì kan tí wọ́n á ti lọ fi oúnjẹ ọlọ́ràá bọ́ wọn ní àbọ́sanra kí wọ́n bàa lè lẹ́wà sí i.

Ẹnì kan tó ní ilé ìgbafàájì alaalẹ́ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà sọ pé: “Àwọn obìnrin ilẹ̀ Áfíríkà máa ń rí rùmúrùmú ni . . . Ohun tó máa ń gbé ẹwà wọn yọ nìyẹn. Obìnrin tí ò bá rí bẹ́ẹ̀ ò lẹ́wà lọ́dọ̀ tiwa.” Láàárín àwọn èèyàn tí wọ́n ṣẹ̀ wá láti ilẹ̀ Sípéènì, ọlọ́lá àti ẹni tó ti rọ́wọ́ mú ni wọ́n máa ń ka àwọn tó bá lómi lára sí.

Àmọ́ lọ́pọ̀ ibòmíràn, wọn ò gbà pé ẹní bá sanra lè lẹ́wà. Kí nìdí? Àwọn kan sọ pé ó ti ń wọ́pọ̀ pé káwọn orílẹ̀-èdè máa bá ara wọn ṣòwò báyìí, ilé iṣẹ́ tó ń pọ̀ sí i sì ti mú kó rọrùn fáwọn èèyàn tó pọ̀ sí i láti máa rí oúnjẹ rà. Èyí ti mú kí àwọn “mẹ̀kúnnù” náà lè máa jẹ oúnjẹ táwọn olówó ń jẹ nígbà kan rí. Bó ṣe di pé àwọn tó ki pọ́pọ́ kúrò lẹ́ni táráyé ń gba tiwọn nìyẹn. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn onísìn kan gbà gbọ́ pé alájẹkì lẹni tó bá ki pọ́pọ́, èyí sì ti mú kí wọ́n máa wo ẹni tó bá lára bákan bákan. Bákan náà, ìwádìí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, ti jẹ́ ká rí i pé sísanra jọ̀kọ̀tọ̀ léwu fún ìlera wa, ìyẹn náà tún mú káwọn èèyàn máà nífẹ̀ẹ́ sí sísanra. Fún àwọn ìdí wọ̀nyí àtàwọn ìdí mìíràn, èrò àwọn èèyàn nípa ohun tó ń jẹ́ ẹwà ń yí padà. Ọ̀pọ̀ ọdún ló sì ti kọjá báyìí táwọn èèyàn níbi tó pọ̀ jù lọ lágbàáyé ti ń sọ pé èèyàn tẹ́ẹ́rẹ́ ló dáa jù.

Àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn ò gbẹ́yìn nínú pípolongo èrò yìí. Nígbà míì àwọn tí wọ́n ń gbé jáde lára àwọn pátákó ìpolówó àti lórí tẹlifíṣọ̀n máa ń jẹ́ àwọn ọ̀pẹ́lẹ́ńgẹ́ èèyàn tára wọn rọ̀. Ohun tí wọ́n ń fàwọn àwòrán yẹn sọ ni pé ẹni tó bá lo nǹkan táwọn èèyàn tó rí lẹ́gẹ́lẹ́gẹ́ yẹn polówó kò lè níṣòro, á sì rọ́wọ́ mú. Ohun tí wọ́n ń fi àwòrán àwọn èèkàn nínú eré orí ìtàgé àtàwọn tó ń ṣètò lórí tẹlifíṣọ̀n sọ nìyẹn.

Báwo wá ni ọ̀rọ̀ yìí ṣe ń nípa lórí àwọn èèyàn o, tó fi mọ́ àwọn ọ̀dọ́? Àpilẹ̀kọ kan tí wọ́n kọ láìpẹ́ yìí nípa ojú téèyàn fi ń wo ara ẹ̀ fi hàn pé “nígbà tí ọmọbìnrin ará Amẹ́ríkà kan bá fi máa jáde nílé ìwé gíga, yóò ti fi ohun tó ju ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbàá [22,000] wákàtí wo tẹlifíṣọ̀n.” Léyìí tó pọ̀ jù láàárín àkókò yẹn, á ti wo àwòrán àwọn obìnrin tó jẹ́ àrímáleèlọ tí wọ́n ní ara tí wọ́n kà sí “aláìlábààwọ́n.” Àpilẹ̀kọ náà fi kún un pé: “Nígbà tó bá pẹ́ táwọn obìnrin ti ń rí irú àwọn àwòrán báyìí, á di pé kí wọ́n máa nífẹ̀ẹ́ irú ara yẹn kí wọ́n sì máa rò pé ẹni tára ẹ̀ bá dà bíi tàwọn tí wọ́n ń rí yẹn ni ẹni iyì, ẹni tó láyọ̀, ẹni táyé fẹ́ àti ẹni tó rọ́wọ́ mú.” Abájọ nígbà náà tó fi jẹ́ pé lẹ́yìn tí àwọn ọmọbìnrin kan ti rí àwòrán àwọn tí wọ́n fi ń ṣàpẹẹrẹ nínú ìwé ìròyìn, wọ́n wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu wọn, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlàjì àwọn ọmọbìnrin náà tí wọ́n fẹ́ dín bí wọ́n ṣe sanra kù, nígbà tó sì jẹ́ pé bí ìdámẹ́rin péré lára wọn ló ki pọ́pọ́ jù.

Àwọn ilé iṣẹ́ aṣaralóge náà ń nípa lórí ojú táwọn èèyàn fi ń wo ẹwà. Jennifer, ọmọ ilẹ̀ Venezuela, tó máa ń polówó oge tó wà lóde, tó ń ṣiṣẹ́ ní Ìlú Mẹ́síkò, sọ pé: “Iṣẹ́ ẹ gẹ́gẹ́ bí agbóge lárugẹ ni láti lẹ́wà, ohun tí ìyẹn sì túmọ̀ sí lóde òní ni pé kéèyàn pẹ́lẹ́ńgẹ́.” Ọmọ ilẹ̀ Faransé kan tó ń jẹ́ Vanessa tóun náà ń ṣe irú iṣẹ́ yẹn sọ pé: “Kì í ṣe àwọn gan-an ló máa sọ fún ọ pé kó o tẹ́ẹ́rẹ́, ìwọ fúnra ẹ lo máa mọ̀ pé ó yẹ kó o di ọ̀pẹ́lẹ́ńgẹ́. Gbogbo ayé ló ń ṣe irú ẹ̀.” Nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe láàárín àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin, ìdá mọ́kàndínláàádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún wọn ló sọ pé àpẹẹrẹ àwọn tó ń ṣe ìpolówó oge nínú ìwé ìròyìn làwọn ń tẹ̀ lé táwọn fi ń díwọ̀n bí ara arẹwà èèyàn ṣe yẹ kó rí.

Ṣùgbọ́n kì í ṣe àwọn obìnrin nìkan ló lè dẹni tó ń kóra wọn sí ìṣòro nítorí pé wọ́n fẹ́ kí ara wọn rí bí “ara tí ò lábùkù” o. Ìwé ìròyìn ilẹ̀ Mẹ́síkò náà, El Universal sọ pé: “Èròjà táwọn ọkùnrin fi ń ṣara lóge ò tíì pọ̀ tó báyìí rí lórí àtẹ.”

Kí Ló Máa Ń Tìdí Fífẹ́ Láti NíÌrísí Tí Ò LábùkùWá?

Nítorí pé àwọn kan fẹ́ ní “ìrísí tí ò lábùkù” tàbí pé wọ́n ṣáà fẹ́ lẹ́wà débi téèyàn bá lè lẹ́wà dé, wọ́n máa ń ṣe iṣẹ́ abẹ tó ń yí ìrísí padà. Iṣẹ́ abẹ̀ yìí ò fi bẹ́ẹ̀ wọ́n mọ́, oríṣiríṣi ọ̀nà sì ni wọ́n ń gbà ṣe é lóde òní. Báwo ni iṣẹ́ abẹ tó ń yí ìrísí padà ṣe bẹ̀rẹ̀?

Gẹ́gẹ́ bí ìwé gbédègbéyọ̀ Encyclopædia Britannica ṣe sọ, ọdún mélòó kan lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kìíní ni ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ṣe iṣẹ́ abẹ tó ń yí ìrísí padà báyìí bẹ̀rẹ̀, nígbà tí wọ́n fẹ́ máa tún ojú àpá ọgbẹ́ táwọn èèyàn fara gbà lójú ogun ṣe. Látìgbà náà wá ni wọ́n ti ń lo ọgbọ́n ìṣègùn yìí láti tún ibi tí iná bá jó lára àwọn èèyàn ṣe, wọ́n tún ń lò ó láti pa ojú ọgbẹ́ rẹ́ lára àwọn tó bá fara pa yánnayànna, wọ́n sì tún ń lò ó fún àwọn tó ní àléébù lára nígbà tí wọ́n bí wọn. Àmọ́, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà sọ pé wọ́n sábà máa ń ṣe iṣẹ́ abẹ tó ń yí ìrísí padà “fún àwọn tí ara wọ́n pé, láìsí nǹkan míì tó fà á ju pé wọ́n fẹ́ tún ìrísí wọn ṣe.” Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè fi tún imú èèyàn rọ, wọ́n lè fi gé kúrò lára ẹran tó wà lójú tàbí lọ́rùn èèyàn, wọ́n lè fi dín etí tó tóbi kú, wọ́n lè fi fa ọ̀rá kúrò níkùn tàbí ní ìbàdí, wọ́n lè fi mú káwọn ẹ̀yà ara kan tóbi sí i, kódà wọ́n lè fi mú kí ìdodo “dára” sí i.

Àmọ́, kí la lè sọ nípa àwọn tí nǹkan kan ò ṣe tí wọ́n dédé lọ ń fẹ̀mí ara wọn wéwu nítorí kí ìrísí wọn lè fani mọ́ra sí i? Ewu wo ló wà nínú nǹkan tí wọ́n ń ṣe? Angel Papadopulos tó jẹ́ akọ̀wé fún ẹgbẹ́ àwọn tó ń ṣe onírúurú iṣẹ́ abẹ tó ń yí ìrísí ara padà nílẹ̀ Mẹ́síkò ṣàlàyé pé nígbà míì, àwọn tí wọn ò kọ́ṣẹ́ dójú àmì máa ń ṣe iṣẹ́ abẹ yìí fáwọn èèyàn, ó sì máa ń ṣe àwọn ẹni elẹ́ni léṣe gan-an ni. Àwọn ilé ìwòsàn alábọ́dé kan wà tí wọ́n máa ń fún àwọn tó bá wá sọ́dọ̀ wọn láwọn oògùn tó léwu láti lè fi tún ìrísí ara wọn ṣe. Níbẹ̀rẹ̀ ọdún 2003, ìwé ìròyìn kan sọ pé wàhálà ṣẹlẹ̀ ní Erékùṣù Canary nígbà tí ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn obìnrin kàgbákò iṣẹ́ abẹ tó léwu láwọn ilé ìṣaralóge tí ò ti sí ààbó tó péye. a

Àwọn ọkùnrin náà lè kó ara wọn sí wàhálà lórí pé wọ́n fẹ́ ní “ìrísí tí ò lábùkù.” Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló máa ń pẹ́ níbi tí wọ́n ti máa ń fi ẹ̀rọ ṣe eré ìmárale, wọ́n á lo gbogbo àkókò tó yẹ kí wọ́n fi tura níbi tí wọ́n ti ń tún bára wọn ṣe rí ṣe tí wọ́n sì ń tún iṣan ara wọn tò. Ìwé ìròyìn Milenio ròyìn pé: “Nígbà tó ti di pé kí wọ́n máa fẹ́ láti ṣeré ìdárayá ní gbogbo ọ̀nà, wọn ò ráyè fún fàájì mọ́, wọn ò sì ráyè fún ọ̀rẹ́ àti ẹbí mọ́.” Bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe ń fi dandan lé e pé àwọn fẹ́ kí iṣan ara àwọn rí bí wọ́n ṣe fẹ́ kó rí báyìí ń mú kí wọ́n lo àwọn oògùn olóró tó lè ṣèjàǹbá fún àgọ́ ara wọn, tó fi mọ́ èyí tó máa ń mú kí iṣan ara le.

Àníyàn tó pọ̀ jù lórí ìrísí ara wọn ti mú káwọn ọ̀dọ́bìnrin kan láwọn ìṣòro oúnjẹ jíjẹ, bí kí wọ́n máa mọ̀ọ́mọ̀ bì lẹ́yìn tí wọ́n bá ti jẹun tàbí kí wọ́n máa rí oúnjẹ sá. Àwọn kan máa ń lo àwọn oògùn tó ń mú kéèyàn fọn débi pé láàárín ọjọ́ mélòó kan wọ́n á fọn yàtọ̀ yàtọ̀, láìsí oníṣègùn tó ní kí wọ́n máa lò ó. Lílo irú oògùn bẹ́ẹ̀ lé fa ìjàǹbá ńláǹlà fún àgọ́ ara èèyàn.

Ewu tó wà nínú kéèyàn máa ṣàníyàn jù nípa bóun ṣe rí tún lè kọjá èyí tó ṣeé fojú rí. Dókítà Katherine Phillips ti ilé ẹ̀kọ́ gíga Brown University lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé àwọn èèyàn tó bá ti ń ṣàníyàn jù nípa ìrísí wọn lè ní irú àárẹ̀ kan tó jẹ mọ́ ìrònú òun ìhùwà, èyí tó máa ń mú káwọn tó bá mú máa rò pé àwọn ní àbùkù lára. Tá a bá kó àádọ́ta èèyàn jọ, ó ṣeé ṣe kí àárẹ̀ yìí wà lára ẹnì kan nínú wọn. Dókítà yìí sọ pé àwọn tí àìsàn yìí ń bá jà “máa ń tẹnu mọ́ ọn pé ó dá àwọn lójú pé àwọn burẹ́wà, débi pé wọn ò ní fẹ́ máa sún mọ́ tẹbí tará. Ìrẹ̀wẹ̀sì sì lè mú kí wọ́n máa ṣe bí ẹni tó fẹ́ para ẹ̀.” Ó wá mẹ́nu ba àpẹẹrẹ ọmọbìnrin arẹwà kan tí rorẹ́ bíi mélòó kan lé sójú ẹ̀ ṣùgbọ́n tó ń sọ pé ó dá òun lójú pé rorẹ́ ti gba gbogbo ojú òun. Nítorí pé kò fẹ́ kí wọ́n máa rí òun níta mọ́, ọmọbìnrin náà pa ilé ìwé tì ní nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́tàlá.

Ǹjẹ́ ìrísí èèyàn ṣe pàtàkì débi pé kó wá máa ṣe gbogbo ohun tó bá lè ṣe láti lè ní “ìrísí tí ò lábùkù,” ì báà tiẹ̀ ṣàkóbá fún ìrònú àti ìlera ara ẹ̀? Ṣé irú ẹwà kan wà tó ṣe pàtàkì jù tó yẹ kéèyàn gbìyànjú láti ní?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Kristẹni kọ̀ọ̀kan ló máa dá pinnu bóyá kí wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ tó ń yí ìrísí padà fóun tàbí kí wọ́n má ṣe é. Síbẹ̀ ó láwọn nǹkan pàtàkì tó yẹ ká kíyè sí. Bó o bá fẹ́ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí ìyẹn, wo Jí! August 22, 2002, ojú ìwé 18 sí 20, lédè Gẹ̀ẹ́sì.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 17]

Tá a bá fi àwọn ọ̀dọ́bìnrin dá ọgọ́rùn-ún, mọ́kàndínláàádọ́rin nínú wọn ló jẹ́ pé àpẹẹrẹ àwọn èèyàn tí wọ́n fi ń polówó ọjà nínú àwọn ìwé ìròyìn ni wọ́n ń tẹ̀ lé láti mọ bó ṣe yẹ kára ẹni tó lẹ́wà rí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Ìpolówó ọjà ń nípa tó lágbára lórí ojú táwọn èèyàn fi ń wo ẹwà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Àwọn kan ti fi iṣẹ́ abẹ tó ń yí ìrísí ẹni padà ṣe ara wọn léṣe nígbà tó ti di pé ó pọ̀ jù

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Àwọn kan ń forí ṣe fọrùn ṣe kí ìrísí wọn lè rí bí wọ́n ṣe fẹ́