Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Iléeṣẹ́ Gbẹ̀mígbẹ̀mí

Iléeṣẹ́ Gbẹ̀mígbẹ̀mí

Iléeṣẹ́ Gbẹ̀mígbẹ̀mí

LÁTỌWỌ́ ÒǸKỌ̀WÉ JÍ! NÍ JÁMÁNÌ

ÀWỌN kan sọ pé iléeṣẹ́ Mittelwerk ló tóbi jù lágbàáyé lára àwọn iléeṣẹ́ tí wọ́n kọ́ sábẹ́ ilẹ̀. Iléeṣẹ́ yẹn wà níbi àwọn Òkè Harz ti ilẹ̀ Jámánì, ní nǹkan bí ọ̀tàlénígba [260] kìlómítà lápá ìwọ̀ oòrùn gúúsù ìlú Berlin. Iléeṣẹ́ ńlá tó fẹ̀ tó ogún kìlómítà yìí gbalẹ̀ rẹrẹẹrẹ lójú ọ̀nà abẹ́ ilẹ̀ tí wọ́n kọ́ ọ sí, lábẹ́ òkè. Láàárín ọdún 1943 sí ọdún 1945, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn tí wọ́n kó sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ló ṣiṣẹ́ bí ẹni àmúsìn láwọn ojú ọ̀nà abẹ́ ilẹ̀ yìí. Ńṣe ni wọ́n ń fi wọ́n ṣe àwọn ohun ìjà fún Ìjọba Násì, ipò tí wọ́n sì wà bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ náà léwu púpọ̀.

Kì í ṣe ohun ìjà tó wọ́pọ̀ làwọn ẹrú tí wọ́n ṣiṣẹ́ bọ́ra yìí ṣe. Àwọn ọkọ̀ ogun ojú òfuurufú tí wọ́n fi ń yin àgbáàràgbá ohun ìjà olóró ni wọ́n ń ṣe ní iléeṣẹ́ náà. Wọ́n á ti iléeṣẹ́ Mittelwerk gbé àwọn ohun ìjà yìí lọ sí ibi tí wọ́n ti sábà máa ń yìn wọ́n ní ilẹ̀ Faransé àti ilẹ̀ Netherlands. Tí wọ́n bá ti yìn wọ́n láti ibẹ̀, wọ́n á lọ balẹ̀ níbi tí wọ́n bá yìn wọ́n sí lórílẹ̀-èdè Belgium, nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, àti nílẹ̀ Faransé, wọ́n á sì bú gbàù. Kódà àwọn ìjọba Násì tún ń múra bóyá wọ́n á lè ṣe ọkọ̀ ogun ojú òfuurufú tá á lágbára débi tá á fi lè gbé bọ́ǹbù gba orí òkun Àtìláńtíìkì kọjá lọ sí ìpínlẹ̀ New York. Nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì fi máa parí, ọgọ́rọ̀ọ̀rún ohun ìjà àwọn ará Jámánì yìí ni wọ́n ti yìn sáwọn ìlú tó wà nílẹ̀ Yúróòpù. Síbẹ̀, kékeré ṣì nìyẹn lára àwọn ohun ìjà táwọn Násì ti ṣe tí wọ́n sì rò pé àwọn máa yìn lu àwọn ọ̀tá wọn lọ́jọ́ kan. Àmọ́, kò sí èyí tó dé ìpínlẹ̀ New York nínú àwọn ohun ìjà yìí.

Ìdí Tí Kò Fi Sí Méjì Irú Ẹ̀

Gbàrà tí ogun ti parí, ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ará Jámánì àtàwọn amojú ẹ̀rọ tí wọ́n jọ ṣe àwọn ohun ìjà yìí kúrò lórílẹ̀-èdè Jámánì. Gbogbo ìmọ̀ tí wọ́n ní ni wọ́n kó ságbárí lọ. Wọ́n sì ń lo ìmọ̀ náà láti máa ṣe ọkọ ogun ojú òfuurufú nìṣó níbi tí olúkúlùkù wọn kó lọ. Ọ̀kan lára àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ yìí ni Wernher von Braun. Ó kó lọ sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà níbi tó ti bá wọn ṣe ọkọ ogun ojú òfuurufú tí wọ́n ń pè ní Saturn, èyí tí wọ́n gbé lọ sínú òṣùpá.

Ní báyìí, wọ́n ti kọ́ àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ kan sí ẹ̀gbẹ́ ibi tí iléeṣẹ́ Mittelwerk wà tẹ́lẹ̀ láti máa ṣèrántí àwọn ọ̀kẹ́ mẹ́ta [60,000] èèyàn tí wọ́n ṣẹ̀wọ̀n níbẹ̀. Lábẹ́ ilẹ̀ tí òtútù ti mú hóí hóí lọ̀pọ̀ àwọn tó ṣẹ̀wọ̀n níbẹ̀ ti ń ṣiṣẹ́, ibẹ̀ sì ni wọ́n ń gbé. Abájọ, gẹ́gẹ́ bí ìṣirò táwọn kan ṣe, nǹkan bí ọ̀kẹ́ kan [20,000] èèyàn tó ṣẹ̀wọ̀n níbẹ̀ ló ṣègbé síbẹ̀. Wọ́n máa ń mú àwọn tó bá wá wo ibi ìrántí yìí káàkiri inú àwọn ilé tí wọ́n kọ́ sábẹ́ ilẹ̀ náà, wọ́n sì máa ń rí àwọn ẹ̀yà ara ọkọ̀ ogun ojú òfuurufú tí wọ́n ti pa tì láti bí ọgọ́ta ọdún, yẹ-yẹ̀-yẹ nílẹ̀. Ìwé ìròyìn After the Battle sọ pé kò sí méjì irú àwọn ohun ìjà tí wọ́n ṣe nílé iṣẹ́ Mittelwerk. Ó ní: “Àwọn ohun ìjà yìí nìkan ni iye ẹ̀mí tí wọ́n máa ń gbà nígbà tí wọ́n bá ń ṣe wọ́n, máa ń pọ̀ ju iye ẹ̀mí tí wọ́n máa ń gbà nígbà tí wọ́n bá yìn wọ́n.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Fọ́tò ọkọ̀ ogun ojú òfuurufú kan tí wọ́n yà lọ́dún 1945 rèé lórí nǹkan tí wọ́n fi máa ń gbé e

[Credit Line]

Quelle: Dokumentationsstelle Mittelbau-Dora

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Àwọn àlejò ń wo ibi tí wọ́n fi ń rántí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, tí àwọn ẹ̀yà ara ọkọ̀ ogun ojú òfuurufú ṣì wà nílẹ̀ ibẹ̀