Irú Ẹwà Tó Ṣe Pàtàkì Jù
Irú Ẹwà Tó Ṣe Pàtàkì Jù
ẸNI táwọn èèyàn bá rí pé ìrísí ẹ̀ fani mọ́ra ni wọ́n máa ń fẹ́ bá rìn. Ṣùgbọ́n kí ló lè sọ ọ́ dẹni tó fani mọ́ra? Ó ṣáà lójú ohun tó o lè ṣe láti lè yí àbùdá ẹ padà, tó ò bá fẹ́ ṣe ara ẹ léṣe. Àti pàápàá, ẹwà ara máa ń ṣá, nítorí pé lójúmọ́ tó mọ́ lónìí, kò sẹ́ni tó rọ́gbọ́n dá sí kẹ́gẹkẹ̀gẹ ọjọ́ ogbó àti àìsàn. Ǹjẹ́ irú ẹwà mìíràn wà tó ṣe pàtàkì jù, tí kò ní ṣá láé, tó o sì lè ní?
Ẹwà Inú Ló Ṣe Pàtàkì Jù
Bíbélì fi dá wa lójú pé Jèhófà Ọlọ́run, Ẹlẹ́dàá ka ẹwà inú sí ju ẹwà ara lọ. Jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ kan.
Nígbà tí Jèhófà sọ fún wòlíì Sámúẹ́lì pé kó lọ yan ọba fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì láàárín àwọn ọmọ Jésè, ara Élíábù lojú Sámúẹ́lì kọ́kọ́ lọ nítorí pé arẹwà ni. Sámúẹ́lì sọ pé: “Òun ló ní láti jẹ́ ẹni tí Olúwa yàn.” Ṣùgbọ́n Jèhófà sọ fún Sámúẹ́lì pé: “Má ṣe rò pé Élíábù ni nítorí pé ó ga ó sì lẹ́wà. Òun kọ́ ni ẹni tí mo yàn. Àwọn èèyàn máa ń fi bí ojú ẹlòmíràn bá ṣe rí sọ irú ẹni tí wọ́n jẹ́, ṣùgbọ́n èmi ń fi ohun tó wà nínú ọkàn wọn sọ irú ẹni tí wọ́n jẹ́.”—1 Sámúẹ́lì 16:6, 7, Contemporary English Version.
Èyí tó kéré jù nínú àwọn ọmọkùnrin náà, ìyẹn Dáfídì ni Jèhófà wá yàn láti jọba. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì sọ pé “ojú rẹ̀ lẹ́wà, ó sì rẹwà ní ìrísí,” Dáfídì ò tíì lè lẹ́wà tó àwọn ẹ̀gbọ́n ẹ̀ tí wọ́n ti di ọkùnrin. Ṣùgbọ́n “ẹ̀mí Jèhófà . . . bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ lára Dáfídì láti ọjọ́ yẹn lọ.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ẹni pípé, ó sì dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ńlá kan, ó dá yàtọ̀ pátápátá bí ẹni tó ní ọkàn tí inú Ọlọ́run dùn sí àti gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó sìn ín tọkàntọkàn títí tó fi kú. (1 Sámúẹ́lì 16:12, 13) Kò sí àníàní pé olórí ohun tó mú kó jẹ́ ẹni fífanimọ́ra lójú Ọlọ́run ni ẹwà inú tó ní.
Ẹ wo Ábúsálómù, ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin Dáfídì ní tiẹ̀. Pẹ̀lú gbogbo ẹwà tó ní yẹn, kì í ṣe ẹni tó wu èèyàn rárá. Ohun tí Bíbélì sọ nípa ẹ̀ nìyí: “Wàyí o, ní ìfiwéra, kò sí ọkùnrin kankan tí ó lẹ́wà bí Ábúsálómù tí ó yẹ fún ìyìn tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ ní gbogbo Ísírẹ́lì. Láti àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ títí dé àtàrí rẹ̀, kò sí àbùkù kankan lára rẹ̀.” (2 Sámúẹ́lì 14:25) Àmọ́, fífẹ́ tó fẹ́ láti di ẹni ńlá sún un tó fi dìtẹ̀ mọ́ bàbá ẹ̀ kó báa lè gbàjọba mọ́ ọn lọ́wọ́. Àní ó tiẹ̀ bá àwọn àlè bàbá rẹ̀ lò pọ̀. Nítorí ohun tí Ábúsálómù ṣe yìí, ó forí kóná ìbínú Ọlọ́run, ó sì kúkú oró.—2 Sámúẹ́lì 15:10-14; 16:13-22; 17:14; 18:9, 15.
Ǹjẹ́ irú Ábúsálómù yẹn wù ẹ́? Láéláé. Tá a bá wo gbogbo ọ̀ràn ẹ̀ látòkè
délẹ̀, a ó rí i pé èèyàn kéèyàn ni. Ó kàn fi gbogbo ara ṣẹwà ni, ó jọra ẹ̀ lójú, ọ̀dàlẹ̀ ni, gbogbo ẹwà tó ní ò sì lè kó o yọ nígbà tí ìparun ẹ̀ dé. Àmọ́ Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn èèyàn míì tí wọ́n gbọ́n tí wọ́n sì wuni láti bá rìn, bẹ́ẹ̀ sì rèé kò sọ nǹkan kan nípa ìrísí wọn. Ó hàn gbangba pé ohun tó ṣe pàtàkì jù ni ẹwà inú lọ́hùn-ún tí wọ́n ní.Ẹwà Inú Máa Ń Fa Àwọn Ẹlòmíràn Mọ́ra
Ṣé ẹwà inú lè fa àwọn ẹlòmíràn mọ́ra? Georgina, tó ti fẹ́ẹ̀ tó ọdún mẹ́wàá báyìí tó ti ṣègbéyàwó sọ pé: “Láti ọdún yìí wá, ohun tó ń mú kí ọkọ mi máa dá mi lọ́rùn ni bó ṣe ń fòótọ́ àti inú kan bá mi lò. Ohun tó ṣe pàtàkì jù láyé ẹ̀ ni bó ṣe máa ṣe ohun tó tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn. Èyí wà lára ohun tó máa ń jẹ́ kó gba tèmi rò kó sì máa fìfẹ́ bá mi lò. Ó máa ń ro tèmi mọ́ tiẹ̀ kó tó pinnu ohunkóhun ó sì máa ń fi hàn mí pé òun ò lè fi mí ṣeré. Mo mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ mi gan-an ni.”
Daniel tó gbéyàwó sílé lọ́dún 1987 sọ pé: “Lójú mi, arẹwà ni ìyàwó mi. Kì í ṣe ẹwà ẹ̀ nìkan ni mo rí ṣùgbọ́n bó ṣe máa ń hùwà gan-an ló jẹ́ kí n túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. Ó máa ń ro ti àwọn ẹlòmíràn mọ́ tiẹ̀ ó sì máa ń ṣe nǹkan tó máa ń mú kí inú wọn dùn. Ó láwọn ànímọ́ Kristẹni tó ṣeyebíye. Èyí ló máa ń jẹ́ kó wù mí láti wà pẹ̀lú ẹ̀ ṣáá.”
Láyé tó jẹ́ pé ojú làwọn èèyàn ń wò yìí, ó yẹ ká máa wo nǹkan ní àwòfín. Ó yẹ ká mọ̀ pé kò ṣeé ṣe féèyàn láti ní ìrísí “tí ò lábùkù,” tó bá sì ṣeé ṣe, á ṣòro fún èèyàn láti ní in, kò sì sí àǹfààní gidi kan nídìí ẹ̀ tó bẹ́ẹ̀. Àmọ́, ó ṣeé ṣe fún èèyàn láti ní àwọn ànímọ́ inú tó ń fani mọ́ra tó sì ń fún èèyàn láyọ̀. Bíbélì sọ pé: “Òòfà ẹwà lè jẹ́ èké, ẹwà ojú sì lè jẹ́ asán; ṣùgbọ́n obìnrin tí ó bẹ̀rù Jèhófà ni ẹni tí ó gba ìyìn fún ara rẹ.” Dípò ká máa ṣe kìràkìtà torí pé a fẹ́ lẹ́wà, Ìwé Mímọ́ kìlọ̀ fún wa pé: “Gẹ́gẹ́ bí òrùka imú oníwúrà ní imú ẹlẹ́dẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni obìnrin tí ó jẹ́ arẹwà, ṣùgbọ́n tí ó yí padà kúrò nínú ìlóyenínú.”—Òwe 11:22; 31:30.
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́ láti rí i pé jíjẹ́ “ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà nínú aṣọ ọ̀ṣọ́ tí kò lè díbàjẹ́ ti ẹ̀mí ìṣejẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ àti ti ìwà tútù, èyí tí ó níye lórí gidigidi lójú Ọlọ́run” ló ṣe pàtàkì jù. (1 Pétérù 3:4) Dájúdájú, irú ẹwà inú bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì ju ẹwà ti ara lọ. Gbogbo èèyàn pátá ló sì lè ní irú ẹwà yẹn.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21, 22]
Àwọn ànímọ́ tó wuyì lè mú kó o lẹ́wà tó ju èyí tí ìṣàralóge èyíkéyí lè mú kó o ní lọ