Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Nairobi “Odò Omi Tútù”

Nairobi “Odò Omi Tútù”

Nairobi “Odò Omi Tútù”

LÁTỌWỌ́ ÒǸKỌ̀WÉ JÍ! NÍ KẸ́ŃYÀ

“Aṣálẹ̀ ni, ilẹ̀ àkùrọ̀ tómi rin gbingbin ni, ẹ̀fúùfù ti gbá gbogbo ohun tó wà níbẹ̀ lọ, kò séèyàn kankan tó ń gbébẹ̀, onírúurú ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ẹranko ẹhànnà ló fibẹ̀ ṣe ibùgbé. Ohun kan ṣoṣo tá a fi lè mọ̀ pé èèyàn máa ń débẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni ti ipasẹ̀ ọkọ̀ onílé tó gba etí ilẹ̀ àbàtà náà kọjá.” ÌWÉ “THE GENESIS OF KENYA COLONY” LÓ SỌ̀RỌ̀ YÌÍ.

BÍ ÌLÚ Nairobi ṣe rí ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún ó lé díẹ̀ sẹ́yìn nìyẹn. Àwọn kìnnìún, àgbáǹréré, àmọ̀tẹ́kùn, àgùnfọn àwọn ejò olóró àti àìmọye ẹranko ìgbẹ́ mìíràn ló wà níbẹ̀ lákòókò yẹn. Àwọn akọni tó jẹ́ ẹ̀yà Masai máa ń da àwọn ẹran wọn tí wọ́n fẹ́ràn wá síbẹ̀ láti wá mu omi tó mọ́ lóló. Ibẹ̀ yẹn tẹ́ àwọn èèyàn yìí tí wọ́n jẹ́ aṣíkiri lọ́rùn gan-an ni. Kódà, àwọn Masai sọ odò yẹn ní Uaso Nairobi, tó túmọ̀ sí “Omi Tútù,” wọ́n sì sọ ibi tí odò náà wà ní Enkarre Nairobi, tó túmọ̀ sí “Odò Omi Tútù.” Bí wọ́n ṣe fún ibi tó máa sọ orílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà di nǹkan tó dà lónìí lórúkọ nìyẹn o.

Ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kan nínú ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ ìlú Nairobi ni ọ̀nà ọkọ̀ ojú irin tí wọ́n là sí orílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà, èyí tí wọ́n fìgbà kan mọ̀ sí Lunatic Express. a Nígbà tí ọdún 1899 fi máa dé ìlàjì, wọ́n ti la ọ̀nà ọkọ̀ ojú irin tó gùn tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta àti ọgbọ̀n [530] kìlómítà dé ìlú Nairobi láti ìlú Mombasa tó wà létí òkun. Nǹkan ò rọgbọ fáwọn òṣìṣẹ́ tó ń la ojú ọ̀nà náà lákòókò yìí nítorí àwọn kìnnìún méjì kan báyìí tí wọ́n ń pè ní “àwọn Tsavo ajèèyàn” tí wọ́n ti pa ọ̀pọ̀ lára wọn . Ìṣòro sì tún ni ibì kan tí wọ́n ń pè ní Àfonífojì Ńlá jẹ́ fún wọn. Nítorí pé wọ́n fẹ́ la ọ̀nà ọkọ̀ ojú irin náà wọ àárín ìlú, wọn ò fẹ́ máa gúnlẹ̀ sí ìlú Mombasa tí wọ́n mọ̀ tẹ́lẹ̀ bí ibùdókọ̀ mọ́. Kàkà kí wọ́n máa gúnlẹ̀ síbẹ̀, ìlú Nairobi tó ṣòroó gbé ló wá di ibi táwọn òṣìṣẹ́ kà síbi tó dáa jù fún wọn láti sinmi àti ibi tí wọ́n yóò máa já àwọn ohun èlò tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ sí. Ohun tó mú kí wọ́n fi ṣe olú ìlú orílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà nígbà tó yá nìyẹn.

Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, Nairobi ni ibùjókòó ìjọba Gẹ̀ẹ́sì ní Ìlà Oòrùn Áfíríkà, ìyẹn orúkọ tí wọ́n ń pe Kẹ́ńyà nígbà náà. Ká ní wọ́n mọ̀ ni, wọn ì bá ti ṣètò ìlú tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bọ́ sójú táyé yìí dáadáa. Dípò kí wọ́n ṣètò ìlú náà, àwọn ẹgẹrẹmìtì ilé ni wọ́n kọ́, tí gbogbo wọn kàn tò jọ gátagàta sí eteetí ibùdókọ̀ ojú irin náà. Ẹni tó bá rí bí Nairobi ṣe rí lákòókò yẹn kò lè rò pé ó lè di ibi táwọn èèyàn láti oríṣiríṣi orílẹ̀-èdè á máa wá, nítorí pé ńṣe ló dà bí abà tí wọ́n fi igi, páànù àtàwọn nǹkan jágajàga míì kọ́ àwọn ilé tó wà níbẹ̀. Bí wọ́n ṣe kọ́ àwọn ẹ̀ta hóró ilé tó wà ní Nairobi ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn ò tiẹ̀ fi hàn pé wọ́n rò pé ó lè di ìlú olókìkí páàpáà. Ti tàwọn ẹranko ẹhànnà tí wọ́n máa ń pààrà ibẹ̀ gan-an ń ba àwọn èèyàn lẹ́rù.

Nígbà tó yá oríṣiríṣi àìsàn tún bẹ̀rẹ̀ sí kọlu àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń ṣí lọ síbẹ̀. Àjàkálẹ̀ àrùn tó bẹ́ sílẹ̀ níbẹ̀ ló kọ́kọ́ fídan han àwọn òyìnbó ajẹ́lẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ débẹ̀. Báwo ni wọ́n ṣe rí àrùn náà dá dúró kíákíá? Wọ́n sọná sí àwọn ibi tárùn náà ti tàn dé láti dáwọ́ ríràn rẹ̀ dúró! Nígbà tó fi máa tó àádọ́ta ọdún sígbà yẹn, ìlú Nairobi ti bẹ̀rẹ̀ sí lajú díẹ̀díẹ̀ débi pé ẹni tó bá fojú àná wò ó, kò ní dá a mọ̀ mọ́, ó ti wá di ibi tí káràkátà ti ń wáyé tí nǹkan amúlùúdùn sì wà ní apá Àárín Gbùngbùn Áfíríkà.

Bí Nairobi Ṣe Di Ìlú Olókìkí

Nítorí pé orí òkè tó ga tó ọ̀rìnlélẹ́gbẹ̀jọ [1,680] mítà [ìyẹn bí ọgọ́jọ òpó iná tí wọ́n tò léra lóòró] ni Nairobi wà, kedere lèèyàn á máa rí ẹwà àwọn ilẹ̀ tó yí i ká níbẹ̀. Nígbà tójú ọjọ́ bá mọ́ rekete, èèyàn lè rí àwọn òkè ńláńlá méjì tó ń bù kún ẹwà ilẹ̀ Áfíríkà níbẹ̀. Òkè kan tí wọ́n ń pè ní Òkè Kẹ́ńyà wà ní apá àríwá, ó ga tó ẹgbẹ̀rún márùn-ún ó lé oókàndínnígba [5,199] mítà [ìyẹn bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta òpó iná lóòró tá a bá tò wọ́n léra]. Òun ni òkè tó ga jù lọ lórílẹ̀-èdè náà, òun ló sì ga ṣìkejì nílẹ̀ Áfíríkà. Òkè kejì tó wà lápá gúúsù ilẹ̀ náà nibi tó ti bá orílẹ̀-èdè Tanzania pààlà ni Òkè Kilimanjaro, ó ga tó ẹgbẹ̀rún márùn-ún àti àrùndínlẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún [5,895] mítà [ìyẹn bí ọ̀tàlélẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ́ta òpò iná lóòró, tá a bá tò wọ́n léra], òun ló sì ga jù nílẹ̀ Áfíríkà. Ní nǹkan bí àádọ́jọ ọdún sẹ́yìn, ó jọ àwọn ará ilẹ̀ Yúróòpù tí wọ́n jẹ́ onímọ̀ nípa báyé ṣe rí àtàwọn olùṣàwárí lójú bó ṣe jẹ́ pé kò sígbà téèyàn dé orí òkè Kilimanjaro tó wà nítòsí àárín méjì ayé tí kò ní bá yìnyín.

Ó ti ju àádọ́ta ọdún lọ báyìí tí wọ́n ti tẹ ìlú Nairobi dó, ìlú náà sì ti yàtọ̀ pátápátá. Téèyàn bá gbójú sókè nísinsìnyí nílùú Nairobi, èèyàn á rí i pé gbogbo ojú òfuurufú ò mọ́ foo bó ṣe máa ń rí látijọ́ nígbà tí kò tíì sí àwọn ilé gogoro níbẹ̀. Nígbà tóòrùn bá wọ̀, àwòṣífìlà lèèyàn á máa wo àwọn ilé dígí àti ilé onírin tí wọ́n ga gogoro, tí wọ́n sì bu ẹwà kún ìlú náà. Táwọn tó ń ṣèbẹ̀wò sí àgbègbè tí wọ́n ti ń nájà gbogbo gbòò nílùú Nairobi bá gbọ́ pé ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, kò sẹ́ni tó jẹ́ ta félefèle débi tí wọ́n ti ń nájà yẹn àti pé àwọn ẹranko ẹhànnà ló máa ń jẹ̀ níbẹ̀, wọn ò ní gbà gbọ́.

Àmọ́, ìyẹn ti dìtàn. Wọ́n ti gbin àwọn igi olódòdó bíi bougainvillea, igi jacaranda olódòdó búlúù, igi eucalyptus olóje tó máa ń yára hù, àti igi wattle olódòdó táwọn ẹ̀ka rẹ̀ máa ń so kọ́ra síbẹ̀. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ bẹ́ẹ̀, ojú ọ̀nà eléruku tẹ́lẹ̀ di ọ̀nà ringindin tí wọ́n gbin igi sí eteetí rẹ̀ tó wá di ibòji fáwọn tó ń fẹsẹ̀ rìn kọjá níbẹ̀ lákòókò tí oòrùn bá ń mú. Ọgbà igi kan wà létí ìlú náà tí igi tó wà níbẹ̀ ju ọ̀rìnlérúgba ó dín mẹ́wàá [270] lọ. Abájọ tí òǹkọ̀wé míì fi sọ pé ńṣe ni Nairobi “dà bí ìlú tí wọ́n tẹ̀ dó sáàárín igbó níbi táwọn igi pọ̀ sí.” Àwọn igi tó rúwé gẹ̀rugẹ̀ru tó wà ní ìlú Nairobi kì í jẹ́ kí ibẹ̀ gbóná jù tàbí kó tutù jù, ńṣe ni ojú ọjọ́ á rọra lọ́ wọ́ọ́rọ́wọ́ lọ́wọ́ ọ̀sán, á sì tutù fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ lọ́wọ́ òru.

Onírúurú Àṣà àti Èèyàn Ló Wà Níbẹ̀

Àfi bí òǹfà ni ìlú Nairobi ṣe ń fa onírúurú àwọn èèyàn láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ibi mọ́ra. Iye àwọn èèyàn tó ń gbé inú ìlú yìí ti ju mílíọ̀nù méjì lọ báyìí. Bí wọ́n ṣe parí ọ̀nà ọkọ̀ ojú irin yẹn báyìí, ńṣe làwọn èèyàn ń rọ́ lọ sí àgbègbè yẹn tí wọ́n sì ń fibẹ̀ ṣe ibùgbé. Àwọn ará Íńdíà tí wọ́n bá wọn la ọ̀nà ojú irin yẹn dúró síbẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n parí iṣẹ́ wọn, wọ́n sì dá àwọn ilé iṣẹ́ sílẹ̀ níbẹ̀, àwọn ilé iṣẹ́ náà sì gbòòrò káàkiri gbogbo orílẹ̀-èdè náà. Àwọn oníṣòwò mìíràn wá láti orílẹ̀-èdè Ọsirélíà, Kánádà, àtàwọn orílẹ̀-èdè bíi mélòó kan nílẹ̀ Áfíríkà.

Àṣà onírúurú àwọn èèyàn ló kún ìlú Nairobi. Béèyàn bá wà láàárín ìgboro, èèyàn lè pàdé obìnrin ará Íńdíà tó wọ aṣọ sari tó máa ń fẹ́ lẹlẹ, tó ń lọ sí ilé ìtajà. Èèyàn tún lè rí ọmọ ilẹ̀ Pakistan tó jẹ́ amojú ẹ̀rọ tó ń kánjú lọ síbi tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ lọ́wọ́. Ó sì lè jẹ́ ará Netherlands tó jẹ́ òṣìṣẹ́ nínú ọkọ̀ òfuurufú tó rí nigínnigín tó fẹ́ wọ̀ sí òtẹ́ẹ̀lì kan lèèyàn á rí; tàbí kéèyàn rí ọkùnrin oníṣòwò ara ilẹ̀ Japan kan tó ń kánjú lọ sí ìpàdé pàtàkì kan tó jẹ́ tàwọn oníṣòwò, bóyá nílé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń ṣe káràkátà ìpín ìdókòwò ní ìlú Nairobi. Yàtọ̀ sáwọn wọ̀nyí, a tún lè ráwọn tó ń gbé ìlú náà, nínú kí wọ́n dúró ní ibùdókọ̀ èrò tàbí kí wọ́n máa tajà nínú àwọn káńtà tí wọ́n gbé kalẹ̀ tàbí níbi tí wọ́n pàtẹ sí gbangba àti láwọn ṣọ́ọ̀bù. Ó sì tún lè jẹ́ àwọn tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ láwọn ọ́fíìsì tàbí ní ọ̀kan lára àwọn ilé iṣẹ́ tó wà ní Nairobi la máa rí.

Ohun tó yani lẹ́nu níbẹ̀ ni pé, ìwọ̀nba kéréje lára àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà tó ń gbé ní ìlú yìí ló jẹ́ ojúlówó ọmọ ìlú Nairobi. Ọ̀pọ̀ ló ti apá ibòmíràn lórílẹ̀-èdè yẹn wá síbẹ̀, nítorí pé wọ́n fẹ́ máa gbé níbi “tilẹ̀ ti lẹ́tù lójú.” Tá a bá wò ó dáadáa, a óò rí i pé àwọn ẹni bí ọ̀rẹ́ tó sì kó èèyàn mọ́ra làwọn tó ń gbé ní ìlú Nairobi. Bóyá nítorí bí wọ́n ṣe máa ń gba àlejò yẹn ló mú kí wọ́n gbé ilé iṣẹ́ àwọn lájọlájọ lágbàáyé àti ti ẹlẹ́kùnjẹkùn wá sí ìlú náà. Nairobi ni olú ilé iṣẹ́ Ètò Àbójútó Àyíká ti Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè wà.

Kí Ló Ń Mú Kí Ibẹ̀ Máa Wu Àwọn Àlejò?

Orílẹ̀-èdè tí onírúurú àwọn ẹranko pọ̀ sí ni Kẹ́ńyà. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn ló máa ń lọ wo ọ̀pọ̀ igbó àti ọgbà ẹranko tó wà níbẹ̀ lọ́dọọdún. Nairobi ni wọ́n ti máa ń ṣètò ọ̀pọ̀ ìrìn àjò afẹ́. Síbẹ̀, ìlú Nairobi gan-an fúnra ẹ̀, ibì kan táwọn èèyàn máa ń fẹ́ rìnrìn àjò afẹ́ lọ ni. Ó lójú ìlú náà láyé táwọn ẹranko ti máa ń rìn wá sẹ́nu ọ̀nà ilé téèyàn ń gbé. Ọgbà Ẹranko ti Orílẹ̀-Èdè Nairobi kò tó kílòmítà mẹ́wàá sí àárín ìlú náà, àwọn tó rìnrìn-àjò wá sí ìlú Nairobi sì máa ń fẹ́ ṣeré lọ síbẹ̀ ni ṣáá. b Béèyàn bá dé ọgbà yìí, á rí àwọn ẹranko tó kọ́kọ́ fi ìlú Nairobi ṣe ibùgbé. Wáyà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ tí wọ́n lọ́ mọ́ra ló pààlà sáàárín àwọn ẹranko yìí àtàwọn èèyàn. Láìpẹ́ yìí, lóṣù September ọdún 2002, akọ àmọ̀tẹ́kùn kan ṣìnà láti inú igbó tó wà nítòsí ìgboro ìlú Nairobi, nínú yàrá táwọn èèyàn ń gbé lọwọ ti bà á!

Ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí tó wà nílùú Nairobi kò ju ìrìn ìṣẹ́jú mélòó kan lọ sí àárín ìlú. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún àlejò ló máa ń wá síbẹ̀ lójoojúmọ́ láti wá mọ̀ nípa ìtàn alárinrin ti ìṣẹ̀dálẹ̀ orílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà. Ibi kan wà nínú ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí náà tí wọ́n kó ejò sí, oríṣiríṣi ẹ̀dá afàyàfà ló kúnbẹ̀. Ńṣe làwọn ọ̀nì tó wà níbẹ̀ máa ń ṣe bíi pé wọn ò rí àwọn àlejò tó ń wò wọ́n. Ìjàpá kan náà wà nítòsí tó jẹ́ pé bí ò tilẹ̀ lè sáré, síbẹ̀ kò dà bíi pé gbogbo báwọn èèyàn ṣe ń lọ tí wọ́n ń bọ̀ nítòsí ẹ̀ kàn án. Ṣá, àwọn ẹranko tó pọ̀ jù níbí yìí làwọn ejò bíi sèbé, àwọn òjòlá àtàwọn paramọ́lẹ̀. Pẹ̀lú irú àwọn ẹ̀dá tó wà níbẹ̀ wọ̀nyẹn, tó o bá ń lọ síbẹ̀ jọ̀wọ́ ṣàkíyèsí àmí tí wọ́n kọ síbẹ̀ pé: “Ṣọ́ra Fáwọn Ejò Olóró”!

Irú Omi Mìíràn

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé odò tí wọ́n fi orúkọ rẹ̀ pe ìlú Nairobi ṣì ń ṣàn, omi tó wà nínú ẹ̀ ti dìdàkudà. Ìdí ni pé bó ṣe sábà máa ń rí ní ọ̀pọ̀ ìlú tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, àwọn ìdọ̀tí àti omi ẹlẹ́gbin ń ṣàn sínú ẹ̀ láti àwọn iléeṣẹ́ àtàwọn iléègbé. Àmọ́ ṣá, láti bí ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, “omi” kan ti ń ṣàn wá sọ́dọ̀ àwọn ará ìlú Nairobi láti orísun tó ga jù. Èyí ni ọ̀rọ̀ ìyè táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ wọn látinú Bíbélì.—Jòhánù 4:14.

Lọ́dún 1931, nígbà tí ò tíì jọ pé ìlú Nairobi lè da ohun tó dà lónìí, Gray Smith àti Frank Smith, àwọn ọkùnrin méjì tí wọ́n jẹ́ tẹ̀gbọ́n tàbúrò tí wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè South Africa ṣèbẹ̀wò sí orílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà kí wọ́n lè mú òtítọ́ Bíbélì débẹ̀. Wọ́n gba ìlú Mombasa wọlé, ọ̀nà ọkọ̀ ojú irin tí wọ́n là síbẹ̀ ni wọ́n gbà láìbẹ̀rù ewukéwu, kódà wọ́n máa ń sùn níbi tó sún mọ́ àwọn ẹranko ẹhànnà nígbà mìíràn. Wọ́n pín àwọn ìwé kékeré tó tó ẹgbẹ̀ta [600] ní ìlú Nairobi pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àwọn ìwé mìíràn tó ṣàlàyé Bíbélì. Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní ìlú Nairobi báyìí á tó ẹgbẹ̀rún márùn-ún láwọn ìjọ mọ́kànlélọ́gọ́ta. Àwọn ìpàdé ìjọ, àwọn àpéjọ àyíká àti àgbègbè, tó fi mọ́ àwọn àpéjọ àgbáyé ti jẹ́ káwọn ará ìlú Nairobi mọ̀ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà dáadáa. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló ti fi tayọ̀tayọ̀ gba ọ̀rọ̀ ìrètí tó wà nínú Bíbélì gbọ́.

Ọjọ́ Iwájú Á Dáa

Ìwé gbédègbéyọ̀ Encyclopædia Britannica sọ pé: “Àwọn ìlú tí iléeṣẹ́ pọ̀ sí sábà máa ń níṣòro àìrílégbé . . . Ńṣe làwọn ilé iṣẹ́ máa ń ba omi àti afẹ́fẹ́ jẹ́.” Ọ̀rọ̀ yìí ò yọ ìlú Nairobi sílẹ̀. Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé ojoojúmọ́ làwọn èèyàn ń ti àwọn ìlú kéékèèké ya lọ síbẹ̀, àwọn ìṣòro yìí tún lè burú sí i. Pẹ̀lú báwọn ìṣòro yìí ṣe ń han ìlú Nairobi léèmọ̀, ẹwà ìlú yìí lè tètè ṣá.

Inú wa dùn pé àkókò ń bọ̀ nínú Ìjọba Ọlọ́run tí gbogbo èèyàn yóò gbádùn ìgbésí ayé wọn lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́, àwọn ìṣòro tó mú kó nira láti gbé ní ìlú ńlá ò sì ní sí mọ́.—2 Pétérù 3:13.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bí o bá fẹ́ kà nípa bí wọ́n ṣe la ọ̀nà ọkọ̀ ojú irin náà, lọ wo àpilẹ̀kọ náà “East Africa’s ‘Lunatic Express,’” tó jáde nínú Jí! ti September 22, 1998, ojú ìwé 21 sí 24, lédè Gẹ̀ẹ́sì.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 24]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Ìlú Nairobi

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Òkè Kilimanjaro

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Òkè Kẹ́ńyà

[Credit Line]

Duncan Willetts, Camerapix

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ọjà ìta gbangba

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Frank Smith àti Gray Smith rèé lọ́dún 1931

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 25]

© Fọ́tò tí Crispin Hughes/Panos yà