Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wọ́n Ti Ba Ayé Yìí Jẹ́ Jìnnà

Wọ́n Ti Ba Ayé Yìí Jẹ́ Jìnnà

Wọ́n Ti Ba Ayé Yìí Jẹ́ Jìnnà

NÍ ỌDÚN 1805 làwọn olùṣàwárí táwọn èèyàn mọ̀ bí ẹní mowó, Meriwether Lewis àti William Clark, ṣàwárí Odò Columbia. Odò náà wà ní Ìpínlẹ̀ Washington, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà òde òní. a Odò yẹn ò wá ṣe wọ́n ní kàyéfì bíi tàwọn ẹja aláràn-án tí wọ́n kún inú ẹ̀. Wọ́n kọ ọ́ sínú àkọsílẹ̀ wọn ojoojúmọ́ pé: “Àwọn ẹja náà pọ̀ débi pé fọ́fọ́ ni wọ́n kún inú odò náà. Níbi tí wọ́n pọ̀ dé, ńṣe lomi odò tó ń ru gùdù ń gbé wọn lọ gbé wọn bọ̀, tó sì ń rù wọ́n wá sí etídò. Àwọn ará Íńdíà tó wà létídò náà á kó wọn, wọ́n á là wọ́n sí méjì, wọ́n á sì yan wọ́n lórí ayanran tí wọ́n figi ṣe.” Àwọn ẹja aláràn-án náà sì pọ̀ débi pé àwọn ará Íńdíà náà tún máa ń sá wọn gbẹ kí wọ́n lè máa fi wọ́n dáná!

Tóò, ìyẹn mà ti dìtàn o. Ìwé ìròyìn Newsweek sọ pé: “Ó ti lé lọ́dún mẹ́wàá báyìí táwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ti mọ̀ pé báwọn èèyàn ṣe ń pẹja pọ̀ ju bí àwọn ẹja ṣe ń pamọ lọ.” Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ti fojú díwọ̀n rẹ̀ pé wọ́n ti pa ìdá mẹ́sàn-án nínú mẹ́wàá lára àwọn ẹja aláràn-án tó wà lápá Àríwá Òkun Àtìláńtíìkì.

Àmọ́ kì í ṣe ẹja nìkan ni wọ́n ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pa tán lómi o. Èyí tí wọ́n ń lò lára àwọn àlùmọ́ọ́nì bí èédú, àwọn ohun àmúṣọrọ̀ àtàwọn igi gẹdú náà ò kéré. Àjọ Akówójọ fún Ìdáàbòbò Ohun Alààyè Inú Ìgbẹ́ Lágbàáyé ròyìn pé láàárín ọdún 1970 sí 1995, wọ́n ti lo ìdá mẹ́ta nínú mẹ́wàá lára àwọn àlùmọ́ọ́nì inú ilẹ̀. Tibi tire sì lọ̀rọ̀ lílò tí wọ́n ń lo àwọn àlùmọ́ọ́nì ọ̀hún, nítorí pé bí wọ́n ṣe ń lò wọ́n ń ba ibùgbé àwọn ohun alààyè jẹ́.

Àwọn kan lérò pé níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn èèyàn ló dá àwọn ìṣòro náà sílẹ̀, ọwọ́ ara wọn náà ni wọ́n á fi yanjú ẹ̀. Àpẹẹrẹ kan tí wọ́n sì mú wá ni ti bíba afẹ́fẹ́ jẹ́ tó ti dín kù láti bí ọdún mélòó kan báyìí láwọn orílẹ̀-èdè tílé iṣẹ́ ẹ̀rọ pọ̀ sí. Ṣé a wá lè tìtorí ìyẹn sọ pé aráyé ti mọ ọ̀nà tí wọ́n á gbà yanjú ìṣòro tó wà nílẹ̀?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìjọba orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ló rán Lewis àti Clark pé kí wọ́n lọ wo bí ilẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ rà lápá ìwọ̀ oòrùn Odò Mississippi ṣe rí kí wọ́n sì ya àwòrán rẹ̀.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

© Kevin Schafer/CORBIS