Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àníyàn Ṣíṣe Ń Da Aráyé Ríborìbo!

Àníyàn Ṣíṣe Ń Da Aráyé Ríborìbo!

Àníyàn Ṣíṣe Ń Da Aráyé Ríborìbo!

“OLÓRÍ Ìṣòro Tó Ń Bá Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà Fínra.” Bí àkọlé àpilẹ̀kọ inú ìwé ìròyìn kan tí Àjọ Tó Ń Rí sí Ṣíṣàníyàn Lórílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà tẹ̀ jáde ṣe kà nìyẹn, ó sì sọ gbangba gbàǹgbà pé lóde tòní o, kì í ṣe àrùn jẹjẹrẹ tàbí éèdì ló ń gbẹ̀mí èèyàn jù lọ. Ó ní: “Wọ́n ti fojú bù ú pé bá a bá fi iye ìgbà táwọn èèyàn ń lọ sọ́dọ̀ oníṣègùn fún àyẹ̀wò dá ọgọ́rùn-ún, ìgbà márùndínlọ́gọ́rin sí ìgbà àádọ́rùn-ún nínú ẹ̀ ló jẹ́ nítorí ìṣòro tó jẹ mọ́ ṣíṣàníyàn.”

Kì í ṣe àsọdùn bá a bá sọ pé lóde tòní, ńṣe ni àníyàn ń da aráyé ríborìbo. Ẹgbẹ́ Agbọ̀ràndùn Fáwọn Òǹrajà Lórílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà tiẹ̀ sọ pé, ‘bá a bá fi àwọn àgbà tí wọ́n ń ṣàníyàn tí ọkàn wọn ò sì balẹ̀ dá ọgọ́rùn-ún, iṣẹ́ ni olórí ohun tó ń fa àníyàn náà fún ìdá mọ́kàndínlógójì nínú wọn. Lẹ́yìn ìyẹn, ọ̀rọ̀ ìdílé ló ń fà á fún ìdá ọgbọ̀n nínú wọn. Àwọn nǹkan míì tún wà tó ń fa àníyàn ṣíṣe fún wọn, ìyẹn ni ìlera, fún ìdá mẹ́wàá, àìfararọ ètò ọrọ̀ ajé, fún ìdá mẹ́sàn-án, àti ìbẹ̀rù nítorí rúkèrúdò láàárín àwọn orílẹ̀-èdè àti ìpániláyà, fún ìdá mẹ́rin.’

Àmọ́ ṣá o, àwọn ará Amẹ́ríkà nìkan kọ́ ló ń ṣàníyàn. Nínú ìwádìí tí wọ́n ṣe káàkiri ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lọ́dún 2002, wọ́n fojú bù ú pé “ó lé ní ìdajì mílíọ̀nù èèyàn ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tí wọ́n gbà láàárín ọdún 2001 àti ọdún 2002 pé ṣíṣàníyàn ń kó àwọn lọ́kàn sókè lẹ́nu iṣẹ́ débi pé ó ti wá di àárẹ̀ sí àwọn lára.” Nítorí “àìbalẹ̀ ọkàn, ìdààmú ọkàn tàbí ṣíṣàníyàn lẹ́nu iṣẹ́,” wọ́n ti fojú bù ú pé “ó tó nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́tàlá ààbọ̀ ọjọ́ táwọn èèyàn fi ń pa ibi iṣẹ́ jẹ lọ́dọọdún nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.”

Bí ọ̀rọ̀ ṣe pakasọ náà nìyẹn nílẹ̀ Yúróòpù. Gẹ́gẹ́ bí Àjọ Tó Ń Rí sí Ọ̀ràn Ààbò àti Ìlera Lẹ́nu Iṣẹ́ Nílẹ̀ Yúróòpù ṣe sọ, “ṣíṣàníyàn lẹ́nu iṣẹ́ ti wá ń kó ìdààmú bá àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ nílẹ̀ Yúróòpù báyìí, ibi yòówù tí wọn ì báà ti máa ṣiṣẹ́.” Ìwádìí kan fi hàn pé ó tó “àwọn òṣìṣẹ́ [Àjọ Ilẹ̀ Yúróòpù] bíi mílíọ̀nù mọ́kànlélógójì tí iṣẹ́ ń kó pákáǹleke bá lọ́dọọdún.”

Ilẹ̀ Éṣíà wá ń kọ́ o? Ibi tí wọ́n fẹnu ọ̀rọ̀ tì sí níbi àpérò kan tó wáyé ní ìlú Tokyo ni pé: “Ìṣòro ńlá ni pákáǹleke tí iṣẹ́ ń kó bá ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè jákèjádò ayé báyìí, lára àwọn orílẹ̀-èdè náà la ti rí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń lajú àtàwọn tí wọ́n ní ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ ńláńlá.” Ìròyìn náà tún wá sọ pé “àwọn orílẹ̀-èdè mélòó kan ní Ìlà Oòrùn Éṣíà, tó fi mọ́ orílẹ̀-èdè Ṣáínà, orílẹ̀-èdè Korea àti orílẹ̀-èdè Taiwan tètè rọ́wọ́ mú gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè tó nílé iṣẹ́ ẹ̀rọ tí ètò ọrọ̀ ajé rẹ̀ sì dáa. Ṣùgbọ́n báyìí, ṣíṣàníyàn lẹ́nu iṣẹ́ àti àkóbá tó máa ń ṣe fáwọn òṣìṣẹ́ ti ń kó pákáǹleke bá àwọn náà báyìí.”

Àmọ́ ṣá o, kò dìgbà tá a bá ṣèwádìí ká tó mọ̀ pé àníyàn ṣíṣe ń dá àwọn èèyàn lágara. Àfàìmọ̀ ni kò sì ti ní máa pa itú ọwọ́ rẹ̀ fún ìwọ náà! Àkóbá wo ló lè ṣe fún ìwọ àtàwọn aráalé rẹ? Ọgbọ́n wo làwọn ìdílé lè rí dá sí i? Àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí á gbé àwọn ìbéèrè wọ̀nyí yẹ̀ wò.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Iṣẹ́ tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń ṣe ni olórí ohun tó ń fà á tí wọ́n fi ń ṣàníyàn