Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àníyàn Ṣíṣe Ohun Tó Ń Fà Á àti Ọṣẹ́ Tó Máa Ń Ṣe

Àníyàn Ṣíṣe Ohun Tó Ń Fà Á àti Ọṣẹ́ Tó Máa Ń Ṣe

Àníyàn Ṣíṣe Ohun Tó Ń Fà Á àti Ọṣẹ́ Tó Máa Ń Ṣe

KÍ LÓ ń jẹ́ àníyàn? Dókítà Melissa C. Stöppler sọ pé, a lè túmọ̀ àníyàn sí “ohunkóhun tó bá ti lè gani lára, tó lè mú kí ara gbóná sódì, tàbí tó lè kóni lọ́kàn sókè.” Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé kéèyàn máa ṣàníyàn ò dáa rárá ni? Ó tì o. Gẹ́gẹ́ bí Dókítà Melissa C. Stöppler ṣe sọ, “nígbà mìíràn, bí ohun kan bá rọra ṣe bí ẹní gani lára tàbí tó kóni lọ́kàn sókè, ó lóore tó ń ṣe fún ara. Bó bá dà bíi pé ohun kan ń lé wa léré nígbà tá a bá ń lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò kan tàbí tá a bá ń ṣe iṣẹ́ kan tí wọ́n gbé fún wa, ó máa ń sábà jẹ́ ká ṣe iṣẹ́ náà dáadáa ká sì fi gbogbo ara ṣe é.”

Ìgbà wo gan-an wá ni àníyàn ṣíṣe ò dáa? Stöppler sọ pé: “Nígbà tí àníyàn ṣíṣe bá pọ̀ débi pé ó kóni sí pákáǹleke, téèyàn ò sì mọ èwo ni ṣíṣe mọ́, ìgbà yẹn gan-an ló tó lè pani lára.” Díẹ̀ rèé lára àwọn nǹkan tó sábà máa ń fa àníyàn ṣíṣe.

Ṣíṣàníyàn Nítorí Àtijẹ Àtimu

Sólómọ́nì Ọba sọ pé: “Fún ènìyàn, kò sí ohun tí ó sàn ju pé kí ó máa jẹ kí ó sì máa mu ní tòótọ́, kí ó sì jẹ́ kí ọkàn òun rí ohun rere nítorí iṣẹ́ àṣekára rẹ̀.” (Oníwàásù 2:24) Àmọ́ ṣá o, bí ààrò ní ibi iṣẹ́ ń gbóná mọ́ àwọn míì nítorí wàhálà tí wọ́n ń bá pàdé.

Ìròyìn kan látọ̀dọ̀ Àjọ Tó Ń Rí sí Ọ̀ràn Ààbò àti Ìlera Lẹ́nu Iṣẹ́ Nílẹ̀ Yúróòpù sọ pé bá a bá yọwọ́ àwọn nǹkan míì tó ṣeé ṣe kó máa mú káwọn òṣìṣẹ́ ṣàníyàn lẹ́nu iṣẹ́ wọn, ohun tó sábà máa ń fà á ni pé káwọn aláṣẹ ilé iṣẹ́ máà jẹ́ káwọn òṣìṣẹ́ mọ bọ́rọ̀ iṣẹ́ ṣe ń lọ sí, kó jẹ́ pé agbára káká làwọn aláṣẹ á fi fún àwọn òṣìṣẹ́ lọ́rọ̀ sọ nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ìpinnu tó kàn wọ́n, káwọn òṣìṣẹ́ máa bára wọn jà, bẹ́ẹ̀ sì tún ni ìjayà pé iṣẹ́ lè bọ́ mọ́ni lọ́wọ́ tàbí kí wọ́n má sanwó tó tó fún òṣìṣẹ́. Ohun yòówù tí ì báà máa fà á, fífi àyà rán ìnira lẹ́nu iṣẹ́ lè mú kó rẹ àwọn òbí tó ń ṣiṣẹ́ débi pé wọn ò ní lè bójú tó àwọn nǹkan tó ń fẹ́ àfiyèsí wọn kíákíá nínú ilé. Irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ tó yẹ kí wọ́n bójú tó sì lè pọ̀ jàáǹtìrẹrẹ. Bí àpẹẹrẹ, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ọdún kan wà tó jẹ́ pé nǹkan bí àádọ́ta mílíọ̀nù èèyàn ló ní aláìsàn tàbí arúgbó tí wọ́n ń bójú tó nílé. Ó tún ṣeé ṣe kí ìṣòro ìṣúnná owó máa mú kí àníyàn wà nínú ilé. Rita, tó jẹ́ ìyá ọlọ́mọ méjì náà kó sí ìṣòro ìṣúnná owó nígbà tí ìjàǹbá mọ́tò ṣẹlẹ̀ sí ọkọ rẹ̀, Leandro, tó sì dẹni tí wọ́n ń fi kẹ̀kẹ́ tì. Rita gbà pé ìṣòro ìṣúnná owó máa ń fa àníyàn ṣíṣe. Ó sọ pé: “Bó ò bá rówó gbọ́ bùkátà nínú ilé, ó lè mú kó o máa ṣe bákan bákan.”

Àwọn Òbí Tó Ń Dá Tọ́mọ Máa Ń Ṣàníyàn

Bákan náà, ṣíṣàníyàn máa ń fa pákáǹleke fáwọn òbí tó ń dá tọ́mọ, bí wọ́n ṣe ń sapá láti gbọ́ ti ìdílé wọn. Bí òbí kan tó ń dá tọ́mọ ṣe ń jí ní kùtùkùtù láti dáná oúnjẹ àárọ̀, tó ń múra fáwọn ọmọ tó sì ń mú wọn relé ìwé, tó ń kánjú kó bàa lè débi iṣẹ́ lákòókò, tó sì tún ń sá sókè sá sódò lẹ́nu iṣẹ́, lè mú kó rẹ̀ ẹ́ tẹnutẹnu kí ọkàn rẹ̀ sì pò pọ̀. Bí ìyá yìí bá sì ti ń ṣe tán lẹ́nu iṣẹ́, sá sókè sá sódò míì tún bẹ̀rẹ̀ nìyẹn. Nítorí pé á lọ mú àwọn ọmọ ẹ̀ nílé ìwé, á gbọ́únjẹ alẹ́ fún wọn, á sì tún ṣe àwọn iṣẹ́ ilé pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́. María, ìyá kan tó ń dá tọ́ àwọn ọmọbìnrin mẹ́rin tí wọn ò tíì pé ogún ọdún sọ pé ńṣe ni ìgbésí ayé òun dà bíi fèrè tẹ́nì kan ń fọn, ó wá fi kún un pé: “Ìgalára náà máa ń pọ̀ nígbà míì débi pé á dà bí ẹni pé mo fẹ́ bẹ́.”

Àwọn Ọmọ Ń Ṣàníyàn

Ọ̀gbẹ́ni Ronald L. Pitzer, tó jẹ́ onímọ̀ nípa ìbágbépọ̀ ẹ̀dá, sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ni ọkàn wọn kì í balẹ̀ nítorí pé wọ́n ń ṣàníyàn.” Lára ẹ̀ ni ìṣòro tó máa ń yọjú bí wọ́n ṣe ń bàlágà, àtàwọn ìdààmú tó máa ń wà lọ́kàn wọn. Wàhálà tilé ìwé náà ò sì gbẹ́yìn. Ìwé Childstress! tiẹ̀ sọ pé ilẹ̀ ọjọ́ kan ò lè mọ́ “kí ìṣòro má yọjú nílé ìwé. Ọ̀pọ̀ ṣe tibí, ṣe tọ̀hún, tó máa ń mú kí wọ́n ṣàníyàn sì máa ń wà, èyí tó dá lórí ẹ̀kọ́ wọn, eré ìdárayá, àjọṣe pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tàbí àjọṣe pẹ̀lú àwọn olùkọ́.”

Àwọn ibì kan wà tó jẹ́ pé ohun tó ń mú káwọn èèyàn ṣàníyàn ni ìwà jàgídíjàgan nílé ìwé, kékeré nìyẹn tún wá jẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ tí ẹ̀rù ń bà nítorí àwọn apániláyà àtàwọn jàǹbá míì tó lè ṣẹlẹ̀. Ọmọbìnrin kan tí ò tíì pé ogún ọdún tiẹ̀ kọ̀wé pé, “báwọn òbí bá ń sọ̀rọ̀ lemọ́lemọ́ nípa bí ayé ṣe le sí lákòókò tá a wà yìí, ńṣe ni ẹ̀rù á máa bá àwa ọmọdé.”

Igi lẹ́yìn ọgbà ló yẹ káwọn òbí jẹ́ fáwọn ọmọ wọn. Ṣùgbọ́n Ọ̀gbẹ́ni Pitzer sọ pé: “Ó ṣeni láàánú pé gbogbo báwọn ọmọ ṣe ń gbìyànjú tó láti sọ bí nǹkan ṣe rí lọ́kàn wọn fáwọn òbí, àwọn òbí kì í kà á kún, wọ́n tiẹ̀ lè máà tẹ́tí gbọ́ wọn, wọ́n sì lè wá àwáwí lásán, tàbí káwọn òbí má kọbi ara sí wọn rárá.” Àwọn ìgbà míì sì wà tó jẹ́ pé ohun tó ń kó àwọn òbí lọ́kàn sókè nínú ìgbéyàwó wọn ló máa ń mú kí wọ́n kọtí ikún sáwọn ọmọ. Ọmọdé kan tó ń jẹ́ Tito, tí ìṣòro àwọn òbí ẹ̀ pàpà mú kí wọ́n kọra wọn tiẹ̀ sọ pé ńṣe ló dà bí ẹni pé gbogbo ìgbà ṣáá làwọn òbí òun máa ń jà. Nínú àkíyèsí tí ìwé Childstress! ṣe, ó sọ pé, “ìjà àti ọ̀rọ̀ kòbákùngbé nìkan kọ́ ló máa ń fa ìdààmú ọkàn” fáwọn ọmọ o. Ó tún fi kún un pé: “Ọkàn àwọn ọmọdé máa ń dàrú bí àwọn òbí bá ń fi ìkanra mọ́ wọn, tí wọ́n sì ń díbọ́n bí ẹni pé àwọn fẹ́ràn wọn.”

Ọṣẹ́ Tó Máa Ń Ṣe

Yálà o jẹ́ ọmọdé tàbí àgbà, ì báà sì jẹ́ pé lẹ́nu iṣẹ́ tàbí nílé ìwé ni àníyàn ti máa ń kó ọ lọ́kàn sókè, bí àníyàn náà bá pàpọ̀ jù, ó lè di àìsàn sí ọ lára. Ẹnì kan tó máa ń kọ̀wé lórí ọ̀ràn ìṣègùn sọ pé: “Bí ọkọ̀ òfuurufú tó rọra ń rìn díẹ̀díẹ̀ títí tá á fi bẹ̀rẹ̀ sí sáré, kó tó wá gbéra sọ ni àníyàn ṣíṣe ṣe máa ń rí lára.” Kò sírọ́ ńbẹ̀, bó o bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣàníyàn, ńṣe lọkàn rẹ á máa lù kìkì tí ìfúnpa rẹ̀ á sì ga. Ìwọ̀n ṣúgà tó wà nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ á lọ sókè. Omi ara tó máa ń súnni ṣe nǹkan á sì bẹ̀rẹ̀ sí sun sínú ẹ̀jẹ̀. Òǹkọ̀wé náà ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Béèyàn bá ń ṣàníyàn nígbà gbogbo ṣá, gbogbo ẹ̀yà ara tí ọ̀ràn sábà máa ń kàn (àwọn bí ọpọlọ, ọkàn, ẹ̀dọ̀fóró, òpójẹ̀ àti iṣan ara) á bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ sódì tàbí kí wọ́n má ṣiṣẹ́ dáadáa mọ́. Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, agara á bẹ̀rẹ̀ sí dáni tàbí kéèyàn bẹ̀rẹ̀ sí ní ìdààmú ọkàn.” Àwọn àìsàn tí àníyàn ṣíṣe lè yọrí sí pọ̀ kọja sísọ, díẹ̀ lára wọn ni àìsàn ọkàn, rọpárọsẹ̀, kí ara má lè gbógun ti àìsàn mọ́, àrùn jẹjẹrẹ, àrùn tó jẹ mọ́ egungun àti iṣan ara, àti àtọ̀gbẹ.

Èyí tó ń kọni lóminú jù lọ ni ohun tí ò dáa tí ọ̀pọ̀ èèyàn, pàápàá jù lọ àwọn ọ̀dọ́, ń ṣe kí àníyàn má bàa dá wọn lágara. Ọ̀rọ̀ náà ká Ọ̀mọ̀wé Bettie B. Youngs lára, ó sọ pé: “Ó bani lọ́kàn jẹ́ gan-an láti rí i pé níbi táwọn ọ̀dọ́ ti ń gbìyànjú láti wá ìtura, ohun tó lè kó wọn sínú ọ̀pọ̀ ìṣòro tó lágbára jù èyí tí wọ́n fẹ́ bọ́ nínú ẹ̀ ni wọ́n ń ṣe. Lára rẹ̀ sì ni kí wọ́n máa mú ọtí líle, kí wọ́n máa lo oògùn olóró, kí wọ́n máa sá nílé ìwé, kí wọ́n máa hùwà ìpáǹle, kí wọ́n máa hùwà pálapàla, kí wọ́n máa finni níràn, kí wọ́n máa hùwà ipá, kí wọ́n sì máa sá kúrò nílé.”

Kò sẹ́ni tá á sọ pé òun kì í ṣàníyàn lákòókò tá à ń gbé yìí; kò ṣeé lé lọ pátápátá. Àmọ́ gẹ́gẹ́ bí àpilẹ̀kọ tó kàn á ṣe fi hàn, ọ̀pọ̀ nǹkan la lè ṣe tí àníyàn ṣíṣe ò fi ní dá wa lágara!

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]

“Ìgalára náà máa ń pọ̀ nígbà míì débi pé á dà bí ẹni pé mo fẹ́ bẹ́”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Gbogbo ìgbà làwọn òbí tó ń dá tọ́mọ máa ń ṣàníyàn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ lè mú kí agara dá àwọn ọmọdé