Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìdààmú Àwọn Dókítà

Ìdààmú Àwọn Dókítà

Ìdààmú Àwọn Dókítà

“Tọkọtaya kan gbé àkọ́bí wọn wá sọ́dọ̀ mi nírètí pé màá lè tọ́jú ọmọ wọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bí náà. Bí mo ṣe yẹ ọmọ yẹn wò báyìí, ṣe ni jẹbẹtẹ gbọ́mọ lé mi lọ́wọ́. Ohun tó ń ṣe é ti kọjá wíwò. Ẹni bá rí mi nígbà tí mo sọ fún wọn pé ọmọkùnrin wọn ò lè ríran mọ́, á mọ̀ pé mo rọ́jú sọ ọ́ ni. Nígbà tí wọ́n jáde ní ọ́fíìsì mi, ọkàn mi bàjẹ́. Ṣùgbọ́n kí n tó ṣẹ́jú pẹ́, ẹlòmíì tó fẹ́ rí mi ti wọlé ó sì ń retí pé kí n kí òun káàbọ̀ tẹ̀rín tọ̀yàyà! Ohun tó máa ń dà mí láàmú jù nìyẹn.” —Dókítà kan tó ń tọ́jú ojú ní Gúúsù Amẹ́ríkà.

ÀWỌN èèyàn kì í sábà lọ rí dókítà ní ọ́fíìsì nítorí ìṣòro tiẹ̀. Gbogbo ohun tó wà lọ́kàn ẹni tó fẹ́ lọ gba ìtọ́jú ni bí dókítà ṣe máa ran òun lọ́wọ́. Ìdí nìyẹn tí ọ̀pọ̀ èèyàn ò fi mọ bí ìṣòro tó ń kojú àwọn dókítà ṣe pọ̀ tó.

A gbà pé gbogbo èèyàn ló ní láti máa fara da ìnira, kì í sì í ṣe iṣẹ́ dókítà nìkan ló nira. Àmọ́ nígbà tó ti jẹ́ pé lọ́nà kan ṣá, ó fẹ́ẹ̀ máà sẹ́ni tí kì í lọ gba ìtọ́jú lọ́dọ̀ dókítà, ó yẹ ká mọ ohun tó máa ń dá àwọn dókítà lágara ká sì tún mọ ọṣẹ́ tó lè ṣe fún wọn.

Láti ìjíǹjí ayé àwọn dókítà ni wọ́n ti ń fi ìdààmú kọ́ra, bí wọ́n ti ń ṣe wàhálà láti rọ́nà wọ yunifásítì. Àmọ́ nígbà tí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ ìṣègùn, wọ́n máa ń rí i pé bọ́mọdé bá débi ẹ̀rù, ẹ̀rù á bà á. Ibẹ̀ gan-an ni akẹ́kọ̀ọ́ á ti bẹ̀rẹ̀ sí ráwọn nǹkan tá á yí ìwà àti èrò ẹ̀ padà pátápátá.

Ẹni Tí Ò Bá Láyà Ò Lè Kọ́ṣẹ́ Ìṣègùn

Ó lè jẹ́ ọ̀sẹ̀ àkọ́kọ́ táwọn akẹ́kọ̀ọ́ bá lò nílé ẹ̀kọ́ ìṣègùn ni wọ́n á ti kọ́kọ́ lọ fojú wọn rí nǹkan ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ nínú yàrá tí wọ́n ti ń la ara èèyàn fún àyẹ̀wò. Ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ lè máà tí ì rí òkú èèyàn rí. Nígbà tí wọ́n bá wá rí oríṣiríṣi òkú èèyàn níhòòhò, ní gbígbẹ tókítókí, tí wọ́n wá ń là wọ́n lábala lábala kí wọ́n lè ṣàyẹ̀wò bí ara ṣe rí, ńṣe lara á máa rí wọn. Á wá di pé kí wọ́n máa ta oríṣiríṣi ọgbọ́n tí wọn ò fi ní bara jẹ́. Nígbà míì àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yìí á máa ṣàwàdà, bíi kí wọ́n máa fún àwọn òkú yẹn lóríṣiríṣi orúkọ ẹ̀fẹ̀. Ó pọn dandan fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ yìí láti hùwà tó dà bí ìwà ọ̀dájú gbáà àti ìwà àrífín lójú àwọn ẹlòmíì nítorí pé wọ́n ń gbìyànjú láti má ṣe máa ronú nípa ẹni tó ni ara tí wọ́n fi ń kọ́ṣẹ́.

Lẹ́yìn èyí ni wọ́n á tún wá bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ nílé ìwòsàn nípa fífojú ara wọn rí bí wọ́n ṣe ń tọ́jú aláìsàn. Kò sí nǹkan tó máa ń mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn ronú nípa bí ìgbésí ayé ṣe kúrú tó, bóyá títí dìgbà tí wọ́n á fi pé bí ọmọ ogójì sí ọgọ́ta ọdún. Ṣùgbọ́n, nígbà táwọn akẹ́kọ̀ọ́ ìṣègùn ṣì jẹ́ ọ̀dọ́, kòrókòró báyìí ni wọ́n máa ń ráwọn tó lárùn tí ò gbóògùn tí wọ́n sì ń kú. Ọ̀kan nínú wọn sọ pé nígbà tóun kọ́kọ́ délé ìwòsàn àwọn nǹkan tóun ń rí ‘kó òun nírìíra gan-an ni.’ Àní, ì báà jẹ́ láwọn orílẹ̀-èdè ọlọ́rọ̀ tàbí èyí tí kò lọ́rọ̀, ó máa ń ṣe àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní kàyéfì nígbà tí wọ́n bá kọ́kọ́ rí i bí wọn kì í ṣeé fáwọn aláìsàn ní ìtọ́jú tó yẹ nítorí pé owó ọwọ́ wọn kò tó.

Báwo làwọn tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ di dókítà ṣe máa ń ṣe ti ìdààmú tí wọ́n máa ń rí lẹ́nu iṣẹ́ wọn ná? Ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń pọn dandan pé káwọn tó ń ṣiṣẹ́ nílé ìwòsàn gbé ọkàn wọn kúrò lára àwọn aláìsàn nípa ṣíṣe bí ẹni pé àwọn aláìsàn náà kì í ṣèèyàn. Dípò kí nọ́ọ̀sì sọ pé ẹnì kan dá lẹ́sẹ̀, ó lè sọ pé, “Dókítà, ẹsẹ̀ kan tó dá wà ní yàrá kejì nínú wọ́ọ̀dù.” Tó ò bá mọ̀dí tí wọ́n fi ń júwe èèyàn báyẹn ó lè dà bí ẹ̀fẹ̀ létí ẹ.

Agara Ń Dá Wọn Nítorí Kì Í Rọrùn Láti Ṣàánú Aláìsàn

Iṣẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nínú ìṣègùn làwọn dókítà kọ́, ṣùgbọ́n èyí tó pọ̀ jù nínú iṣẹ́ wọn ló gba kí wọ́n máa bá àwọn tó wá gba ìtọ́jú sọ̀rọ̀. Àwọn kan nínú wọn máa ń wò ó pé àwọn ò mọ bí dókítà ṣeé jókòó ti agbàtọ́jú kó sì máa fara balẹ̀ gba tiẹ̀ rò. Ńṣe ló dà bí ìrírí tá a fi nasẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, ọ̀kan lára àwọn nǹkan tó máa ń nira jù fún dókítà láti ṣe ni sísọ ìròyìn tí ò dáa. Àwọn dókítà kan ò sì lè má sọ ọ́ lójúmọ́. Àwọn tó níṣòro máa ń fẹ́ sọ ohun tó ń bà wọ́n lọ́kàn jẹ́ jáde, iṣẹ́ àwọn oníṣègùn sì ni láti tẹ́tí sí wọn. Ó máa ń nira gan-an láti tọ́jú ẹni tó ń ṣàníyàn tẹ́rù sì ń bà, débi pé ó ti mú kí agara máa dá àwọn oníṣègùn kan nítorí pé kì í rọrùn fún wọn láti ṣàánú aláìsàn.

Nígbà tí dókítà kan tó ń tọ́jú ìdílé lórílẹ̀-èdè Kánádà rántí ìgbà tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, ó sọ pé: “Òjò iṣẹ́ kàn ń rọ̀ lé mi lórí ni: àwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́ ń fẹ́ kí n gbọ́ tàwọn; àwọn tí ò gbádùn ń wá ẹni tí wọ́n á lọ kó ìdààmú wọn bá; àwọn aláìsàn ń fẹ́ rí mi; àwọn kan tí wọ́n fẹ́ lo agbárí fún mi ò fi mí lọ́rùn sílẹ̀; àwọn èèyàn ń wá rí mi ṣáá ni; àwọn èèyàn dúró lé mi lọ́rùn pé dandan ni kí n tẹ̀ lé àwọn; kódà bí mo wà nínú ilé, àní nínú yàrá, wọ́n á tún máa fóònù mi. Àwọn èèyàn ò jẹ́ n rímú mí. Lóòótọ́ ni mo fẹ́ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, àmọ́ èyí ò wa pọ̀ jura lọ bí.”—Ìwé A Doctor’s Dilemma, látọwọ́ John W. Holland.

Ṣé pákáǹleke náà á máa dín kù bí dókítà kan bá ṣe ń dàgbà sí i? Béèyàn bá ṣe ń pẹ́ sí i lẹ́nu iṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni iṣẹ́ tó já lé e léjìká á ṣe máa pọ̀ sí. Lọ́pọ̀ ìgbà, ọ̀ràn tó lè lakú lọ á wà nílẹ̀ tó yẹ kéèyàn ṣe nǹkan lé lórí lójú ẹsẹ̀, èèyàn sì lè má tí ì mọ púpọ̀ tó nípa ọ̀ràn náà. Dókítà kan nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ pé: “Nígbà tí mo ṣì kéré, n kì í kà á sí, báwọn ọ̀dọ́ kì í ṣeé ka wíwakọ̀ níwàkuwà sí. Ṣùgbọ́n bó o bá ṣe ń dàgbà sí i lẹ̀mí èèyàn á túbọ̀ máa jọ ẹ́ lójú. Báyìí, mo máa ń ṣàníyàn ju ti tẹ́lẹ̀ lọ kí n tó pinnu bí mo ṣe máa tọ́jú àwọn èèyàn.”

Ipa wo ni ìnira ń ní lórí àwọn dókítà o? Gbígbé táwọn dókítà kì í gbé ọ̀ràn àwọn aláìsàn tí wọ́n ń tọ́jú sọ́kàn yìí lè di nǹkan tá á bá wọn dénú ilé. Nítorí náà, ó gba ìṣọ́ra kó má bàa mọ́ wọn lára délé. Àwọn oníṣègùn kan lójú àánú débi pé wọ́n máa ń ran àwọn aláìsàn lọ́wọ́ láti borí ẹ̀dùn ọkàn wọn. Ṣùgbọ́n ibo ni wọ́n fẹ́ ṣèyẹn dé tí agara á fi dá wọn? Ìdààmú dókítà lẹ rí yẹn.

Àwọn Aláìsàn Tó Ń Múṣẹ́ Nira Fáwọn Dókítà

Bí wọ́n bá bi àwọn dókítà pé ìṣòro wo ló máa ń wáyé láàárín dókítà àti aláìsàn, ohun tí wọ́n sábà fi máa ń bẹ̀rẹ̀ ni ọ̀rọ̀ àwọn aláìsàn tó máa ń múṣẹ́ nira fún wọn. Bóyá o ti rí irú àwọn tá a fẹ́ sọ̀rọ̀ wọn yìí rí.

Lákọ̀ọ́kọ́ ná, bí aláìsàn míì bá déwájú dókítà ńṣe lá máa fi àkókò ṣòfò nípa mímú àtamọ́ mọ́ àtamọ̀ dípò kó ṣàlàyé ohun tó ń ṣe é ní tààràtà. Àwọn míì sì wà tí wọn kì í jẹ́ kí dókítà gbádùn, ńṣe ni wọ́n á máa fóònù dókítà lóru tàbí lópin ọ̀sẹ̀ láìṣe pé ọ̀rọ̀ pàjáwìrì délẹ̀. Wọ́n sì lè sọ pé irú ìtọ́jú tí dókítà kò fẹ́ fún wọn gan-an làwọn ń fẹ́. Àwọn kan sì tún wá wà tí wọn ò ní ìgbàgbọ́ nínú dókítà. Àwọn kan máa ń lọ ṣèwádìí wọ́n sì ti rí àwọn ìsọfúnni tó wúlò nípa ohun kan tó ń ṣe wọ́n, bóyá lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ìyẹn lè ràn wọ́n lọ́wọ́ lóòótọ́, àmọ́ irú ìwádìí náà lè mú kí wọ́n má lè fọkàn tán oníṣègùn tí wọ́n lọ rí. Dókítà sì lè máà ráyè láti ṣàlàyé síwá sẹ́yìn lórí àbọ̀ ìwádìí tí wọ́n ti ṣe. Ó máa ń fiṣẹ́ sú dókítà ni bí aláìsàn kò bá fẹ́ gbọ́ràn sí i lẹ́nu nítorí pé kò gbà á gbọ́. Paríparì ẹ̀ ni tẹni tó fẹ́ gbàwòsàn ṣùgbọ́n tí kò lè ní sùúrù. Kó tó di pé ìtọ́jú tí dókítà ń fún un ṣiṣẹ́, ó ti pa á tì, bóyá ó sì ti lọ ń gbàmọ̀ràn níbòmíràn.

Àmọ́ láwọn apá ibì kan, wàhálà táwọn dókítà máa ń bá pàdé lọ́dọ̀ aláìsàn kò tó tọ̀dọ̀ àwọn lọ́yà.

Àwọn Dókítà Ò Fẹ́ Ṣiṣẹ́ Rógun Ẹjọ́

Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè la ti ń gbọ́ ìròyìn pé ńṣe làwọn tó ń pe àwọn dókítà lẹ́jọ́ pé wọ́n tọ́jú àwọn lọ́nà tí ò bófin mu túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Àwọn lọ́yà kan á wá ẹ̀sùn tí ò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ sí dókítà lẹ́sẹ̀ kí wọ́n lè rówó gbà. Ààrẹ Ẹgbẹ́ Oníṣègùn Nílẹ̀ Amẹ́ríkà sọ pé: “Wọ́n ti jẹ́ kí owó táwọn ilé iṣẹ́ adójútòfò ń gbà láti bá àwọn dókítà tán ọ̀ràn tí wọ́n bá dá lórí pé wọ́n tọ́jú ẹnì kan pọ̀ sí i. Bí wọ́n ṣe ń pè wọ́n lẹ́jọ́ yìí lè fa ẹ̀dùn ọkàn míì pẹ̀lú. Bí wọ́n bá pe oníṣègùn kan lẹ́jọ́ láìṣẹ̀ láìrò, ó lè fa ìpalára tó pọ̀ gan-an, irú bí ìtìjú, fífi àkókò ṣòfò, . . . ìnira àti àníyàn.” Èyí ti mú kí àwọn dókítà kan para wọn.

Nítorí gbogbo èyí, ọ̀pọ̀ oníṣègùn ti rí i pé àfi káwọn yáa mọ irú ìtọ́jú táwọn á máa fún aláìsàn torí ìgbà tọ́rọ̀ bá ń déwájú dẹjọ́, dípò tí wọ́n á fi fún un ní ìtọ́jú tó dáa jù. Ìwé ìròyìn Physician’s News Digest sọ pé: “Ní báyìí, ńṣe làwọn dókítà rọra ń tọ́jú aláìsàn lọ́nà tí wọn ò fi ní rógun ẹjọ́.”

Bó ṣe di pé ìṣòro àwọn dókítà ń pọ̀ sí i báyìí, ọ̀pọ̀ nínú wọn ló ń kọminú nípa ibi tọ́rọ̀ iṣẹ́ wọn máa já sí lọ́jọ́ iwájú. Ìbéèrè kan náà yìí ni ọ̀pọ̀ àwọn tó fẹ́ gbàtọ́jú ń béèrè bí wọ́n ti ń wò ó tí àìsàn ń dá àwọn tó pọ̀ sí i gúnlẹ̀ níbi tí ìmọ̀ ìṣègùn jinlẹ̀ dé yìí. Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí fa kòmóòkun ọ̀rọ̀ yọ lórí bọ́jọ́ iwájú ṣe máa rí fáwọn oníṣègùn àtàwọn tí wọ́n ń tọ́jú.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

RAN DÓKÍTÀ RẸ LỌ́WỌ́ LÁTI RÀN Ọ́ LỌ́WỌ́

1. Má fàkókò tó o bá máa lò níwájú dókítà ṣòfò, torí náà múra bó o ṣe máa ṣàlàyé ìṣòro rẹ fún dókítà láìfọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀, kó o sì fi ohun tó jẹ ọ́ lógún jù ṣáájú

2. Má ṣe fóònù dókítà rẹ tí àkókò iṣẹ́ bá ti parí tí ò bá sọ́rọ̀ pàjáwìrì ńlẹ̀

3. Máa ní sùúrù. Àyẹ̀wò tó nítumọ̀ àti ìtọ́jú tó múná dóko máa ń gba àkókò

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

‘TÍTỌ́JÚ ORÍṢI ÀÌSÀN KAN ṢOṢO Ò NÍ KÍ IṢẸ́ SÚNI’

“Ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀ gbọọrọ ló wà láàárín iṣẹ́ ìṣègùn tibí àti tàwọn àgbègbè tí ojú ti là. Níbí, torí kéèyàn lè bọ́ lọ́wọ́ ìṣẹ́ lèèyàn ṣe ń kàwé kó lè níṣẹ́ lọ́wọ́, nítorí náà làwọn tó máa ń lọ kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìṣègùn ṣe pọ̀. Ṣùgbọ́n àwọn dókítà pọ̀ ju iṣẹ́ lọ. Nítorí ìdí èyí, owó táṣẹ́rẹ́ làwọn dókítà ń gbà. Ó lójú ẹni tó lè dá gba dókítà. Ilé àtijọ́ kan báyìí tí páànù rẹ̀ ń jò ni wọ́n fi ṣe ọsibítù tí mo ti ń ṣiṣẹ́, kò sì sáwọn irin iṣẹ́ gidi níbẹ̀. Àwa dókítà méjì àti nọ́ọ̀sì márùn-ún la wà níbẹ̀. Ẹgbàáje [14,000] èèyàn là ń dá lóhùn.

“Nígbà míì, àwọn tó wá gbàtọ́jú máa ń rò pé mi ò yẹ àwọn wò dáadáa, ṣùgbọ́n níbo ni mo ti fẹ́ ráyè máa fàkókò gígùn dá èèyàn lóhùn nígbà táwọn mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ń dúró láti rí mi. Síbẹ̀, inú mi máa ń dùn bí mo ṣe ń tọ́jú àwọn aláìsàn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé oríṣi àìsàn kan náà ni wọ́n sábà máa ń gbé wá. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìyálọ́mọ sábà máa ń gbé àwọn ọmọ wọn tí wọn ò fún lóúnjẹ tó dáa, tí wọ́n ń yàgbẹ́ gbuuru tí wọ́n sì ti fẹ́ẹ̀ ṣu gbogbo omi ara wọn dà nù wá. Ojú àwọn ọmọ wọ̀nyí á dá gùdẹ̀, ìbànújẹ́ sì máa ń hàn lójú wọn. Ńṣe ni mo wulẹ̀ máa ń ṣàlàyé fún ìyá irú ọmọ bẹ́ẹ̀ bó ṣe máa lo omi ìyè tí wọ́n fi iyọ̀ àti ṣúgà ṣe, àti bó ṣe máa lo àwọn oògùn agbógunti kòkòrò àrùn. Báwọn oògùn wọ̀nyí bá ti ṣiṣẹ́ báyìí, ńṣe lọmọ náà á bẹ̀rẹ̀ sí jẹun padà. Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan ọmọ náà á ti yàtọ̀, ojú ẹ̀ á ti wálẹ̀ á ti máa rẹ́rìn-ín á sì máa ṣeré. Nítorí irú ayọ̀ tó máa ń tìdí irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ wá ló mú kí n fẹ́ di dókítà.

“Láti kékeré ayé mi ló ti wà lọ́kàn mi láti máa ran àwọn tó bá ń ṣàìsàn lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n ẹ̀kọ́ nípa iṣẹ́ dókítà tí mo kọ́ ti yí mi padà kọjá wẹ́rẹwẹ̀rẹ. Mò ń rí báwọn èèyàn ṣe máa ń kú nítorí pé kò sí owó táṣẹ́rẹ́ tí wọ́n ní kí wọ́n lọ mú wá kí wọ́n fi tọ́jú wọn kí ẹ̀mí wọn máa bàa bọ́. Mo sì ní láti sọ ara mi di ọ̀dájú kí ìbànújẹ́ yẹn má bàa dí mi lọ́wọ́. Ìgbà tí wọ́n tó fi ohun tó ń fà á táwọn èèyàn fi ń jìyà hàn mí nínú Bíbélì ni mo tó mọ ìyọ́nú Ọlọ́run, ìgbà yẹn ló sì ṣeé ṣe fún mi láti tún máa ṣàánú àwọn èèyàn. Mo wá lè yọmi lójú lẹ́ẹ̀kan sí i.”

[Àwọn àwòrán]

Dókítà Marco Villegas tó ń ṣiṣẹ́ ní ìlú àdádó kan níbi odò Amazon lórílẹ̀-èdè Bolivia