Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọ̀kan Pàtàkì Ni Ìwé Náà Jẹ́ Fáwọn Ọ̀dọ́

Ọ̀kan Pàtàkì Ni Ìwé Náà Jẹ́ Fáwọn Ọ̀dọ́

Ọ̀kan Pàtàkì Ni Ìwé Náà Jẹ́ Fáwọn Ọ̀dọ́

GÁ Ilé Ìwé Àwọn Obìnrin ní ìlú Limuru, lórílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà, kọ̀wé sí ẹ̀ka ilé iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè yẹn pé kí wọ́n kó ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́ ránṣẹ́ sí òun. Ó sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí ẹ ṣe mọ̀, kò rọrùn láti bójú tó àwọn ọ̀dọ́. Àmọ́, a ní àwọn ìwé yín méjì lọ́wọ́, wọ́n sì ti ran àwa olùkọ́ àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ gan-an ni. Kò sí ohun tá a fẹ́ tí ò sí nínú ìwé náà, ohun tó sì wà níbẹ̀ gan-an làwa olùkọ́ àtàwọn ọ̀dọ́ akẹ́kọ̀ọ́ nílò.”

Ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́ náà wá fi kún un pé: “Ìgbìmọ̀ aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ á fẹ́ ká máa fi àwọn ẹ̀kọ́ wíwúlò tó wà nínú ìwé náà kọ́ àwọn ọmọbìnrin tó wà nílé ìwé wa. Wọ́n fẹ́ràn ìwé yẹn gan-an ni. Àwọn òbí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa ò sì lòdì sí ohunkóhun tá a bá lè ṣe láti ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́. Ẹ̀dà mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n á ṣì tó fún wa báyìí ná.”

Ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, fọ́ ọ̀rọ̀ sí wẹ́wẹ́ lórí ohun táwọn ọ̀dọ́ ń rò àti bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wọn. Ó jíròrò lọ́nà tó gbámúṣé nípa àwọn kókó ẹ̀kọ́ bíi: “Bawo ni Mo Ṣe Lè Mú Ki Awọn Obi Mi Túbọ̀ Fun Mi Ní Ominira Sii?,” Mo Ha Nilati Fi Ilé Silẹ Bi?,” Bawo Ni Mo Ṣe Lè Ní Awọn Ọ̀rẹ́ Tootọ?,” Iṣẹ́ Igbesi-Aye Wo Ni Mo Nilati Yàn?,” Ki Ni Nipa Ti Ibalopọ Takọtabo Ṣaaju Igbeyawo?,” àti Bawo Ni Mo Ṣe Lè Mọ̀ Bi O Ba Jẹ́ Ifẹ Gidi Ni?”

Díẹ̀ nìwọ̀nyí lára àwọn àkòrí tó wà nínú ìwé náà. Ọ̀pọ̀ nǹkan ni ìwé náà tún sọ̀rọ̀ lé lórí nínú àkòrí mọ́kàndínlógójì tó wà nínú ẹ̀. Bó o bá fẹ́ gba ẹ̀dà kan, o lè kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí kó o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sójú ewé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.

□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ wá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.